Diutarónómì 18:1-22

  • Ìpín àwọn àlùfáà àtàwọn ọmọ Léfì (1-8)

  • Wọn ò gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sí ìbẹ́mìílò (9-14)

  • Wòlíì bíi Mósè (15-19)

  • Bí wọ́n ṣe máa mọ wòlíì èké (20-22)

18  “Àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì àti gbogbo ẹ̀yà Léfì pàápàá kò ní bá Ísírẹ́lì ní ìpín tàbí ogún kankan. Wọ́n á máa jẹ lára àwọn ọrẹ àfinásun sí Jèhófà, èyí tó jẹ́ tirẹ̀.+  Torí náà, wọn ò gbọ́dọ̀ ní ogún kankan láàárín àwọn arákùnrin wọn. Jèhófà ni ogún wọn, bó ṣe sọ fún wọn.  “Ohun tó máa jẹ́ ẹ̀tọ́ àwọn àlùfáà látọwọ́ àwọn èèyàn nìyí: Kí ẹnikẹ́ni tó bá fi ẹran rúbọ, ì báà jẹ́ akọ màlúù tàbí àgùntàn, fún àlùfáà ní apá, páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ àti àpòlúkù.  Kí o fún un ní àkọ́so ọkà rẹ, wáìnì tuntun rẹ, òróró rẹ àti irun tí o bá kọ́kọ́ rẹ́ lára agbo ẹran rẹ.+  Jèhófà Ọlọ́run yín ti yan òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ nínú gbogbo ẹ̀yà yín pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ ní orúkọ Jèhófà nígbà gbogbo.+  “Àmọ́ tí ọmọ Léfì kan bá kúrò ní ọ̀kan lára àwọn ìlú yín ní Ísírẹ́lì, níbi tó ń gbé,+ tó sì wù ú* pé kó lọ sí ibi tí Jèhófà yàn,*+  ó lè máa ṣiṣẹ́ níbẹ̀ ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ bíi ti gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì, tí wọ́n wà níbẹ̀ níwájú Jèhófà.+  Iye oúnjẹ tí wọ́n bá pín fún àwọn yòókù ni kí wọ́n fún òun náà,+ ní àfikún sí ohun tó bá rí látinú ogún àwọn baba ńlá rẹ̀ tó tà.  “Tí ẹ bá ti dé ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run yín fẹ́ fún yín, ẹ ò gbọ́dọ̀ bá àwọn orílẹ̀-èdè yẹn ṣe àwọn ohun ìríra tí wọ́n ń ṣe.+ 10  Ẹnì kankan láàárín yín ò gbọ́dọ̀ sun ọmọkùnrin rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin rẹ̀ nínú iná,+ kò gbọ́dọ̀ woṣẹ́,+ kò gbọ́dọ̀ pidán,+ kò gbọ́dọ̀ wá àmì ohun tó fẹ́ ṣẹlẹ̀,+ kò gbọ́dọ̀ di oṣó,+ 11  kò gbọ́dọ̀ fi èèdì di àwọn ẹlòmíì, kò gbọ́dọ̀ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ abẹ́mìílò+ tàbí woṣẹ́woṣẹ́,+ kò sì gbọ́dọ̀ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ òkú.+ 12  Torí Jèhófà kórìíra ẹnikẹ́ni tó bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, torí àwọn ohun ìríra yìí sì ni Jèhófà Ọlọ́run yín ṣe máa lé wọn kúrò níwájú yín. 13  Kí ẹ rí i pé ẹ jẹ́ aláìlẹ́bi níwájú Jèhófà Ọlọ́run yín.+ 14  “Àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ máa lé kúrò yìí máa ń fetí sí àwọn tó ń pidán+ àti àwọn tó ń woṣẹ́,+ àmọ́ Jèhófà Ọlọ́run yín kò gbà kí ẹ ṣe ohunkóhun tó jọ èyí. 15  Jèhófà Ọlọ́run yín máa gbé wòlíì kan bí èmi dìde fún yín láàárín àwọn arákùnrin yín. Ẹ gbọ́dọ̀ fetí sí i.+ 16  Èyí jẹ́ ìdáhùn sí ohun tí ẹ béèrè lọ́wọ́ Jèhófà Ọlọ́run yín ní Hórébù, lọ́jọ́ tí ẹ pé jọ,*+ tí ẹ sọ pé, ‘Má ṣe jẹ́ kí n gbọ́ ohùn Jèhófà Ọlọ́run mi mọ́, má sì jẹ́ kí n rí iná ńlá yìí mọ́, kí n má bàa kú.’+ 17  Jèhófà wá sọ fún mi pé, ‘Ohun tí wọ́n sọ dáa. 18  Mo máa gbé wòlíì kan bíi tìẹ+ dìde fún wọn láàárín àwọn arákùnrin wọn, màá fi ọ̀rọ̀ mi sí i lẹ́nu,+ gbogbo ohun tí mo bá sì pa láṣẹ fún un ló máa sọ fún wọn.+ 19  Tí ẹnì kan kò bá fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ mi tó máa sọ lórúkọ mi, ó dájú pé màá mú kí ẹni náà jíhìn.+ 20  “‘Tí wòlíì èyíkéyìí bá kọjá àyè* rẹ̀, tó sọ̀rọ̀ lórúkọ mi, ọ̀rọ̀ tí mi ò pa láṣẹ fún un pé kó sọ tàbí tó sọ̀rọ̀ lórúkọ àwọn ọlọ́run mìíràn, wòlíì yẹn gbọ́dọ̀ kú.+ 21  Àmọ́, ẹ lè sọ lọ́kàn yín pé: “Báwo la ṣe máa mọ̀ pé Jèhófà kọ́ ló sọ ọ̀rọ̀ náà fún un?” 22  Tí wòlíì náà bá sọ̀rọ̀ lórúkọ Jèhófà, tí ọ̀rọ̀ náà kò sì ṣẹ tàbí tí ohun tó sọ kò ṣẹlẹ̀, á jẹ́ pé Jèhófà kọ́ ló sọ ọ̀rọ̀ náà. Ìkọjá àyè ló mú kó sọ ọ́. Ẹ ò gbọ́dọ̀ bẹ̀rù rẹ̀.’

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “wù ú lọ́kàn.”
Ìyẹn, ibi tí Jèhófà yàn pé kí wọ́n ti máa wá jọ́sìn òun.
Tàbí “kóra jọ.”
Lédè Hébérù, ó tún túmọ̀ sí “ìgbójú” tàbí “orí kunkun.”