Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìwé Diutarónómì

Orí

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí

  • 1

    • Wọ́n kúrò ní Òkè Hórébù (1-8)

    • Wọ́n yan àwọn olórí àti àwọn onídàájọ́ (9-18)

    • Wọ́n ṣàìgbọràn ní Kadeṣi-bánéà (19-46)

      • Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ̀ láti wọ ilẹ̀ náà (26-33)

      • Wọn ò borí àwọn ọmọ Kénáánì (41-46)

  • 2

    • Wọ́n fi ọdún 38 rìn kiri ní aginjù (1-23)

    • Wọ́n ṣẹ́gun Síhónì ọba Hẹ́ṣíbónì (24-37)

  • 3

    • Wọ́n ṣẹ́gun Ógù ọba Báṣánì (1-7)

    • Wọ́n pín ilẹ̀ tó wà ní ìlà oòrùn Jọ́dánì (8-20)

    • Mósè sọ fún Jóṣúà pé kó má bẹ̀rù (21, 22)

    • Mósè ò ní wọ ilẹ̀ náà (23-29)

  • 4

    • Wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ onígbọràn (1-14)

      • Wọn ò gbọ́dọ̀ gbàgbé àwọn ohun tí Ọlọ́run ṣe (9)

    • Jèhófà fẹ́ kí wọ́n máa jọ́sìn òun nìkan (15-31)

    • Kò sí Ọlọ́run míì àfi Jèhófà (32-40)

    • Àwọn ìlú ààbò ní ìlà oòrùn Jọ́dánì (41-43)

    • Ó fún Ísírẹ́lì ní Òfin (44-49)

  • 5

    • Jèhófà bá wọn dá májẹ̀mú ní Hórébù (1-5)

    • Wọ́n tún Òfin Mẹ́wàá sọ (6-22)

    • Ẹ̀rù ba àwọn èèyàn náà ní Òkè Sínáì (23-33)

  • 6

    • Fi gbogbo ọkàn rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà (1-9)

      • “Fetí sílẹ̀, ìwọ Ísírẹ́lì” (4)

      • Kí àwọn òbí máa kọ́ àwọn ọmọ wọn (6, 7)

    • Ẹ má ṣe gbàgbé Jèhófà (10-15)

    • Ẹ ò gbọ́dọ̀ dán Jèhófà wò (16-19)

    • Ẹ sọ fún àwọn ọmọ yín (20-25)

  • 7

    • Orílẹ̀-èdè méje tí wọ́n máa pa run (1-6)

    • Ìdí tí Ọlọ́run fi yan Ísírẹ́lì (7-11)

    • Wọ́n á ṣàṣeyọrí tí wọ́n bá ṣègbọràn (12-26)

  • 8

    • Ó rán wọn létí bí Jèhófà ṣe bù kún wọn (1-9)

      • “Kì í ṣe oúnjẹ nìkan ṣoṣo ló ń mú kí èèyàn wà láàyè” (3)

    • Má ṣe gbàgbé Jèhófà (10-20)

  • 9

    • Ìdí tó fi fún Ísírẹ́lì ní ilẹ̀ náà (1-6)

    • Ísírẹ́lì múnú bí Jèhófà lẹ́ẹ̀mẹrin (7-29)

      • Ère ọmọ màlúù tí wọ́n fi wúrà ṣe (7-14)

      • Mósè bá wọn bẹ̀bẹ̀ (15-21, 25-29)

      • Wọ́n tún múnú bí Ọlọ́run lẹ́ẹ̀mẹta (22)

  • 10

    • Ó gbẹ́ wàláà òkúta méjì míì (1-11)

    • Ohun tí Jèhófà fẹ́ (12-22)

      • Bẹ̀rù Jèhófà, kí o sì máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ (12)

  • 11

    • Ẹ ti rí bí Jèhófà ṣe tóbi tó (1-7)

    • Ilẹ̀ Ìlérí (8-12)

    • Wọ́n á rí ìbùkún tí wọ́n bá ṣègbọràn (13-17)

    • Kí wọ́n tẹ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mọ́ ọkàn wọn (18-25)

    • “Ìbùkún àti ègún” (26-32)

  • 12

    • Ibi tí Ọlọ́run bá yàn ni kí ẹ ti máa jọ́sìn (1-14)

    • Wọ́n lè jẹ ẹran àmọ́ wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ (15-28)

    • Má ṣe kó sí ìdẹkùn àwọn ọlọ́run míì (29-32)

  • 13

    • Ohun tí wọ́n máa ṣe fún ẹni tó bá sin ọlọ́run míì (1-18)

  • 14

    • Ohun tí kò yẹ kí wọ́n ṣe nítorí òkú (1, 2)

    • Àwọn oúnjẹ tó mọ́ àti èyí tí kò mọ́ (3-21)

    • Kí wọ́n mú ìdá mẹ́wàá wá fún Jèhófà (22-29)

  • 15

    • Lẹ́yìn ọdún méje-méje, kí wọ́n má ṣe san gbèsè pa dà (1-6)

    • Bí wọ́n á ṣe máa ran àwọn aláìní lọ́wọ́ (7-11)

    • Kí wọ́n máa dá ẹrú sílẹ̀ ní ọdún keje (12-18)

      • Kí wọ́n fi òòlù dá etí ẹrú wọn lu (16, 17)

    • Kí wọ́n ya àwọn àkọ́bí ẹran sí mímọ́ (19-23)

  • 16

    • Ìrékọjá; Àjọyọ̀ Àkàrà Aláìwú (1-8)

    • Àjọyọ̀ Àwọn Ọ̀sẹ̀ (9-12)

    • Àjọyọ̀ Àtíbàbà (13-17)

    • Bí wọ́n ṣe máa yan àwọn onídàájọ́ (18-20)

    • Àwọn ohun tí wọn ò gbọ́dọ̀ jọ́sìn (21, 22)

  • 17

    • Ẹbọ wọn kò gbọ́dọ̀ ní àbùkù lára (1)

    • Ohun tí wọ́n máa ṣe fún ẹni tó bá sin ọlọ́run míì (2-7)

    • Àwọn ẹjọ́ tó bá ṣòroó dá (8-13)

    • Ìlànà fún ọba tí wọ́n bá yàn (14-20)

      • Kí ọba fi ọwọ́ ara rẹ̀ kọ ẹ̀dà Òfin (18)

  • 18

    • Ìpín àwọn àlùfáà àtàwọn ọmọ Léfì (1-8)

    • Wọn ò gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sí ìbẹ́mìílò (9-14)

    • Wòlíì bíi Mósè (15-19)

    • Bí wọ́n ṣe máa mọ wòlíì èké (20-22)

  • 19

    • Ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ àtàwọn ìlú ààbò (1-13)

    • Wọn ò gbọ́dọ̀ sún ààlà sẹ́yìn (14)

    • Àwọn ẹlẹ́rìí níbi ìgbẹ́jọ́ (15-21)

      • Ẹni méjì tàbí mẹ́ta ni kó jẹ́ ẹlẹ́rìí (15)

  • 20

    • Àwọn òfin tó wà fún ogun jíjà (1-20)

      • Àwọn tí kò ní lọ sójú ogun (5-9)

  • 21

    • Tí wọn ò bá mọ ẹni tó pààyàn (1-9)

    • Tí wọ́n bá fẹ́ fi ẹrú ṣaya (10-14)

    • Ẹ̀tọ́ àkọ́bí (15-17)

    • Tí ọmọ bá ya alágídí (18-21)

    • Ẹni ègún ni ẹni tí wọ́n bá gbé kọ́ sórí òpó igi (22, 23)

  • 22

    • Kí wọ́n máa bójú tó ẹran ọmọnìkejì wọn (1-4)

    • Obìnrin ò gbọ́dọ̀ wọ aṣọ ọkùnrin, ọkùnrin ò sì gbọ́dọ̀ wọ ti obìnrin (5)

    • Máa ṣàánú àwọn ẹyẹ (6, 7)

    • Ṣe ìgbátí sí òrùlé (8)

    • Àwọn ohun tí wọn ò gbọ́dọ̀ ṣe pọ̀ (9-11)

    • Kókó wajawaja lára aṣọ (12)

    • Àwọn òfin nípa ìbálòpọ̀ tí kò tọ́ (13-30)

  • 23

    • Àwọn tí kò gbọ́dọ̀ wá sínú ìjọ Ọlọ́run (1-8)

    • Kí ibùdó máa wà ní mímọ́ (9-14)

    • Ẹrú tó sá lọ (15, 16)

    • Wọn ò gbọ́dọ̀ ṣe aṣẹ́wó (17, 18)

    • Èlé àti ẹ̀jẹ́ (19-23)

    • Ohun tí ẹni tó ń kọjá lọ lè jẹ (24, 25)

  • 24

    • Ìgbéyàwó àti ìkọ̀sílẹ̀ (1-5)

    • Kí wọ́n máa ka ẹ̀mí sí pàtàkì (6-9)

    • Kí wọ́n máa gba tàwọn aláìní rò (10-18)

    • Òfin nípa pípèéṣẹ́ (19-22)

  • 25

    • Iye ẹgba tí wọ́n lè na èèyàn (1-3)

    • O ò gbọ́dọ̀ dí akọ màlúù tó ń pa ọkà lẹ́nu (4)

    • Ṣíṣú obìnrin lópó (5-10)

    • Tí obìnrin bá rá ọkùnrin mú ní abẹ́ (11, 12)

    • Ìwọ̀n àti òṣùwọ̀n tó péye (13-16)

    • Kí wọ́n pa àwọn Ámálékì run (17-19)

  • 26

    • Kí wọ́n mú àkọ́so èso wọn wá (1-11)

    • Ìdá mẹ́wàá kejì (12-15)

    • Ísírẹ́lì jẹ́ ohun ìní pàtàkì fún Jèhófà (16-19)

  • 27

    • Kí wọ́n kọ Òfin sára òkúta (1-10)

    • Òkè Ébálì àti Òkè Gérísímù (11-14)

    • Wọ́n tún àwọn ègún náà kà (15-26)

  • 28

    • Ìbùkún fún àwọn tó bá ṣègbọràn (1-14)

    • Ègún fún àwọn tó bá ṣàìgbọràn (15-68)

  • 29

    • Májẹ̀mú tó bá Ísírẹ́lì dá ní Móábù (1-13)

    • Ìkìlọ̀ fún àwọn tó bá ṣàìgbọràn (14-29)

      • Ohun tó wà nípamọ́, ohun tí a ṣí payá (29)

  • 30

    • Bí wọ́n ṣe máa pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà (1-10)

    • Àwọn àṣẹ Jèhófà kò nira (11-14)

    • Kí wọ́n yan ìyè tàbí ikú (15-20)

  • 31

    • Ikú Mósè sún mọ́lé (1-8)

    • Kí wọ́n máa ka Òfin Ọlọ́run sí wọn létí (9-13)

    • Ó faṣẹ́ lé Jóṣúà lọ́wọ́ (14, 15)

    • Àsọtẹ́lẹ̀ bí Ísírẹ́lì ṣe máa ya ọlọ̀tẹ̀ (16-30)

      • Orin láti fi kọ́ Ísírẹ́lì (19, 22, 30)

  • 32

    • Orin tí Mósè kọ (1-47)

      • Jèhófà jẹ́ Àpáta (4)

      • Ísírẹ́lì gbàgbé Àpáta rẹ̀ (18)

      • “Tèmi ni ẹ̀san” (35)

      • “Ẹ bá àwọn èèyàn rẹ̀ yọ̀, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè” (43)

    • Mósè máa kú sórí Òkè Nébò (48-52)

  • 33

    • Mósè súre fún àwọn ẹ̀yà wọn (1-29)

      • “Ọwọ́ ayérayé” Jèhófà (27)

  • 34

    • Jèhófà fi ilẹ̀ náà han Mósè (1-4)

    • Ikú Mósè (5-12)