Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Wọ́n Ń Kọ́ni ní Òtítọ́ Bíbélì

Kà nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń lo àyè èyíkéyìí tó bá yọ láti kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ní òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

Wọ́n Fi Fóònù Tó Wà fún Gbogbo Èèyàn Kọ́ Ọ̀pọ̀ Lẹ́kọ̀ọ́

Báwo ni Daiane ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní abúlé kan tó jìnnà, tí ò sí síná mọ̀nàmọ́ná àti Íńtánẹ́ẹ̀tì?

Kò Retí Pé Àṣeyọrí Náà Máa Pọ̀ Tóyẹn

Báwo ni Desicar tó jẹ́ ìyá tó ń dá tọ́mọ lórílẹ̀-èdè Fẹnẹsúélà ṣe wàásù lásìkò àjàkálẹ̀ àrùn Kòrónà?

Wọ́n Mọyì Àwọn Lẹ́tà Tó Kọ

Àwọn àǹfààní wo lèèyàn máa rí tó bá ń fi lẹ́tà wàásù?

“Mo Ti Ń Retí Kí Ẹ Pè Mí”

Kí ló múnú tọkọtaya kan dùn pé wọ́n fìgboyà kópa nínú ìwàásù orí fóònù?

Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Òṣìṣẹ́ Ilé Ìwòsàn Tó Ń Fara Da Àárẹ̀

Ibo làwọn nọ́ọ̀sì àtàwọn ọ̀ṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn kan ti rí ìṣírí nígbà àjàkálẹ̀ àrùn Corona?

Wọn Ò Dáwọ́ Iṣẹ́ Ìwàásù Dúró Lásìkò Àjàkálẹ̀ Àrùn

Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ń láyọ̀ bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà míì ni wọ́n ń gbà wàásù ọ̀rọ̀ ìtùnú tó wà nínú Bíbélì fáwọn èèyàn.

Àkúnya Omi Mú Kí Wọ́n Gbọ́ Ìwàásù

Lẹ́yìn tí omi ya wọ àwọn abúlé kan ní Nicaragua, àwọn ará abúlé yẹn rí ìrànlọ́wọ́ gbà látọ̀dọ̀ àwọn tí wọn ò mọ̀ rí.

Ọlọ́run Dáhùn Àdúrà Obìnrin Afọ́jú Kan

Mingjie gbàdúrà pé kí Ọlọ́run jẹ́ kóun pàdé àwọn Kristẹni tòótọ́. Kí ló jẹ́ kó dá a lójú pé Ọlọ́run ti dáhùn àdúrà yẹn?

Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Kan Di Púpọ̀

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Guatemala mú òtítọ́ Bíbélì dé ọ̀dọ̀ àwọn tó ń sọ èdè Kekchi.

Àlùfáà Kan Rí Ìdáhùn sí Ìbéèrè Rẹ̀

Lẹ́yìn tọ́mọ wọn kú, àlùfáà kan àti ìyàwó rẹ̀ sunkún gan-an. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni wọ́n rí ìdáhùn tó tẹ́ wọn lọ́rùn sí àwọn ìbéèrè wọn nípa ikú.

Wọ́n Rò Pé Pásítọ̀ Wọn Ni

Lórílẹ̀-èdè Chile, Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan lo àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ tó ṣì sílẹ̀ láti wàásù ìhìn rere, ó sì ṣàlàyé pé Ọlọ́run ò ní in lọ́kàn pé kí àwa èèyàn máa kú.

Ìrìn Àjò Lágbègbè Odò Maroni

Àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́tàlá (13) ń múra láti rìnrìn àjò, kí wọn lè wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún àwọn tó ń gbé nínú igbó kìjikìji Amazon tó wà ní Gúúsù Amẹ́ríkà.

Ọlọ́pàá Ń Tẹ̀ Lé Joseph

Báwo ni ọlọ́pàá tó wà ní erékùṣù kékeré kan ṣe ran àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́ láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run?

Wọ́n Dúró Ran Ẹnì Kan Lọ́wọ́

Kí ló jẹ́ kí àwọn ọ̀dọ́ márùn-ún pinnu láti fara da òtútù àti yìnyín tó ń bọ́ kí wọ́n lè ran aládùúgbò wọn kan lọ́wọ́?

‘Inú Rere àti Ìṣòtítọ́ Tẹ́nì Kan Fi Hàn’

Mọ ìdí tí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní South Africa fi ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kó lè dá báàgì àti pọ́ọ̀sì tí ẹnì kan gbàgbé sí ṣọ́ọ̀bù tí wọ́n ti ń ta kọfí pa dà.

“Mò Ń Ṣèwọ̀n Tí Mo Lè Ṣe”

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Irma ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ẹni àádọ́rùn-ún (90) ọdún, àwọn lẹ́tà rẹ̀ tó dá lórí Bíbélì wọ ọ̀pọ̀ àwọn tó ń kọ ọ́ sí lọ́kàn.

Sọ fún Wọn Pé O Nífẹ̀ẹ́ Wọn

Kọ́ nípa bí Bíbélì ṣe ran ìdílé kan lọ́wọ́ tí wọ́n fi túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wọn, tí ilé wọn sì túbọ̀ tòrò.

“Èyí Mà Rọrùn Gan-an O!”

Àwọn fídíò tó wà ní ìkànnì jw.org ń ṣàǹfààní fún àwọn olùkọ́, agbaninímọ̀ràn àtàwọn mí ì.

Oore Kan Tó Sèso Rere

Báwo ni inú rere tẹ́nì kan ṣe ṣe mú kí ẹni tó ń ta ko àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

Má Ṣe Sọ̀rètí Nù!

Má ṣe ronú pé ẹnì kan ò lè wá sin Jèhófà. Kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn tí kò sọ̀rètí nù àti ìdí tí wọn kò fi ṣe bẹ́ẹ̀.

Ọwọ́ Hulda Tẹ Ohun Tó Ń Wá

Báwo ni Hulda ṣe rówó ra tablet tó fi ń wàásù, tó sì fi ń ṣèpàdé?

Ọmọbìnrin Kan Lo Ìdánúṣe

Kà nípa bí ọmọbìnrin kan lórílẹ̀-èdè Chile tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́wàá ṣe ṣiṣẹ́ kára láti pé gbogbo àwọn tó ń sọ èdè Mapudungun níléèwé rẹ̀ wá síbi ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan.

Ọkàn Àwọn Èèyàn Ló Ṣe Pàtàkì, Kì Í Ṣe Ìrísí Wọn

Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan fi sùúrù bá Ọkùnrin aláìrílégbé kan sọ̀rọ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í fẹ́ bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀?