Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kò Retí Pé Àṣeyọrí Náà Máa Pọ̀ Tóyẹn

Kò Retí Pé Àṣeyọrí Náà Máa Pọ̀ Tóyẹn

 Ìyá tó ń dá tọ́ ọmọ ni Desicar ó sì wù ú láti túbọ̀ máa wàásù fáwọn èèyàn torí náà, ó pinnu láti di aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Orílẹ̀-èdè Fẹnẹsúélà ló ń gbé, àtijẹ-àtimu ò sì rọrùn níbẹ̀. Láìka ìṣòro yìí sí, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Inú ẹ̀ dùn nígbà tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà, àmọ́ ká tó ṣẹ́jú pẹ́ àjàkálẹ̀ àrùn Kòrónà bẹ̀rẹ̀.

 Kò rọrùn fún Desicar láti máa wàásù nígbà tí àjàkálẹ̀ àrùn náà kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀. Ìdí ni pé ó nira fún un láti máa fi lẹ́tà wàásù. Bákan náà, torí pé owó gọbọi ni wọ́n ń san fún Íńtánẹ́ẹ̀tì lágbègbè ibi tó ń gbé, ìyẹn ò jẹ́ kó lè máa wàásù lórí fóònù. Ó sọ pé, “Gbogbo nǹkan tojú sú mi, torí pé mi ò lè wàású bíi ti tẹ́lẹ̀. Ó wá ń ṣe mí bíi pé mi ò ṣe tó bó ṣe yẹ káwọn aṣáájú-ọ̀nà máa ṣe.”

 Ní January 2021, ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Fẹnẹsúélà fọwọ́ sí i pé kí wọ́n ṣe àkànṣe ìwàásù. Wọ́n wá ṣètò kí ọgọ́ta (60) iléeṣẹ́ rédíò àti iléeṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n méje gbé àwọn àsọyé Bíbélì tí wọ́n máa sọ ní oṣù náà sáfẹ́fẹ́. Ẹ̀ka ọ́fíìsì gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n pe àwọn aládùúgbò àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn láti tẹ́tí sáwọn àsọyé náà tàbí kí wọ́n wò ó. Nínú àwọn àsọyé náà, wọ́n sọ àwọn ìbéèré àtàwọn ẹsẹ Bíbélì táwọn ará lè lò tí wọ́n bá ń fi lẹ́tà tàbí fóònù wàásù. Yàtọ̀ síyẹn, ẹ̀ka ọ́fíìsì tún ṣètò ọ̀nà tuntun míì táwọn ará lè máa gbà wàásù ní Fẹnẹsúélà, ìyẹn lílo àtẹ̀jíṣẹ́.

 Inú Desicar dùn gan-an láti kópa nínú àkànṣe ìwàásù náà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò fi àtẹ̀jíṣẹ́ wàásù rí, ó pinnu láti gbìyànjú ẹ̀ wò. Àmọ́ ìṣòro kan wà níbẹ̀, Desicar fúnra ẹ̀ sọ pé, “Mi ò mọ fóònù lò dáadáa.” Kí ni Desicar wá ṣe? Ó ní kí ọmọ òun ran òun lọ́wọ́, ọmọ náà sì ṣe bẹ́ẹ̀. Kò pẹ́ sígbà yẹn ló bẹ̀rẹ̀ sí í lò ó fúnra ẹ̀, bó ṣe di pé òun náà kópa tó jọjú nínú àkànṣe ìwàásù náà nìyẹn.

Desicar

 Desicar fi àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ́ sáwọn tó mọ̀, kí wọ́n lè tẹ́tí sí àwọn àsọyé Bíbélì tí wọ́n ti gbohùn ẹ̀ sílẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn tó fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí ló tẹ́tí sí àsọyé náà tí wọ́n sì béèrè ìbéèrè, àbájáde ohun tó ṣe yìí sì múnú rẹ̀ dùn gan-an. Ó tiẹ̀ tún yani lẹ́nu pé àwọn tí kò lè gbọ́ àsọyé náà tún béèrè ohun tí àsọyé náà dá lé lọ́wọ́ rẹ̀. Desicar sọ pé, “Àkọsílẹ̀ ṣókí tí mo ṣe nígbà àpéjọ ni mo fi dáhùn ìbéèrè wọn. Ìpadàbẹ̀wò mi ò kọjá márùn-un rí lóṣù kan, àmọ́ lẹ́yìn àkànṣe ìwàásù náà iye ìpadàbẹ̀wò tí mo ṣe tó méjìléláàádọ́fà (112).” a

 Desicar tún sọ fún ẹ̀gbọ́n ẹ̀ obìnrin tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń gbé nítòsí ilé rẹ̀ pé kó tẹ́tí sáwọn àsọyé náà lórí rédíò. Desicar sọ pé, “Ó yà mí lẹ́nu gan-an pé ẹ̀gbọ́n mi gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀. Gbogbo ọjọ́ Sunday láago mẹ́jọ àárọ̀ ni mo máa ń lọ sọ́dọ̀ wọn ká lè jọ gbọ́ àsọyé náà. Ọ̀pọ̀ ìbéèrè ni wọ́n máa ń béèrè tá a bá ń gbọ́ àsọyé náà àti lẹ́yìn tá a bá gbọ́ ọ tán.” Ó wúni lórí gan-an pé ẹ̀gbọ́n Desicar lọ sí Ìrántí Ikú Kristi tí wọ́n ṣe lórí zoom, ó tiẹ̀ tún gbà kí àbúrò ẹ̀ máa lo Íńtánẹ́ẹ̀tì ẹ̀ láti wàásù.

 Desicar sọ pé, “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà, mo sì tún dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn alàgbà tó fún mi níṣìírí, kí n lè máa gbádùn iṣẹ́ ìwàásù pa dà.” (Jeremáyà 15:16) Desicar ń bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lọ, ó sì ń kàn sí àwọn tó fi àtẹ̀jíṣẹ́ wàásù fún.

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń tẹ̀ lé òfin tó dá lórí lílo ìsọfúnni ẹlòmíì tá a bá ń wàásù.