Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ọlọ́run Dáhùn Àdúrà Obìnrin Afọ́jú Kan

Ọlọ́run Dáhùn Àdúrà Obìnrin Afọ́jú Kan

 Yanmei tó jẹ́ ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí nílẹ̀ Éṣíà mú obìnrin afọ́jú kan tó ń jẹ́ Mingjie a sọdá títì. Mingjie sọ fún Yanmei pé: “O ṣé o. Ọlọ́run á bù kún ẹ!” Yanmei béèrè lọ́wọ́ Mingjie bóyá ó máa fẹ́ kóun wá máa kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Mingjie wá sọ pé, ojoojúmọ́ lòun máa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó darí òun síbi tóun á ti máa sìn ín lọ́nà tó fẹ́. Kí nìdí tó fi ń gba irú àdúrà bẹ́ẹ̀?

 Mingjie sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan tó jẹ́ afọ́jú pè é sí ṣọ́ọ̀ṣì àwọn aláàbọ̀ ara lọ́dún 2008. Ó ṣàlàyé pé lẹ́yìn tí wọ́n parí ìwáàsù, òun ní kí àlùfáà náà sọ ìwé tó ti mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ jáde fóun. Àlùfáà náà sọ fún Mingjie pé Bíbélì tó jẹ́ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni. Torí náà, ó wu Mingjie gan-an pé kó ka Bíbélì. Ló bá ra Bíbélì tó wà fún àwọn afọ́jú lédè Chinese, ó sì ka ìdìpọ̀ méjìlélọ́gbọ̀n (32) náà tán láàárín oṣù mẹ́fà. Bí Mingjie ṣe ń bá Bíbélì kíkà rẹ̀ lọ, ó rí i pé irọ́ ni ẹ̀kọ́ mẹ́talọ́kan tí wọ́n fi kọ́ni ní ṣọ́ọ̀ṣì tó ń lọ, ó sì rí i pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.

 Nígbà tó yá, ìwà àwọn ará ṣọ́ọ̀ṣì tí Mingjie ń lọ ò bá a lára mu, ó sì ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá a. Ó rí i pé ìwà wọn yàtọ̀ sóhun tóun ń kà nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, oúnjẹ àjẹkù ni wọ́n máa ń fún àwọn afọ́jú, nígbà tó jẹ́ pé oúnjẹ tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ sè làwọn tó kù máa ń jẹ. Ìwà ìrẹ́jẹ yìí bí Mingjie nínú, torí náà ó bẹ̀rẹ̀ sí í wá ṣọ́ọ̀ṣì míì tó máa lọ ládùúgbò rẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run jẹ́ kóun rí ìjọ Kristẹni tòótọ́.

 Inú Mingjie dùn bí Yanmei ṣe fi inú rere hàn sí i, torí náà ó gbà kí Yanmei máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́yìn náà, ó lọ sípàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fúngbà àkọ́kọ́. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn, ó ní: “Mi ò lè gbàgbé ìpàdé tí mo kọ́kọ́ lọ. Tayọ̀tayọ̀ làwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin fi kí mi káàbọ̀. Ó wú mi lórí gan-an ni. Afọ́jú ni mí lóòótọ́, síbẹ̀ mo rí ojúlówó ìfẹ́ lọ́jọ́ yẹn.”

 Mingjie tẹ̀ síwájú gan-an débi pé ó bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé déédéé. Ó sábà máa ń gbádùn kó máa kọ àwọn orin ìjọba Ọlọ́run, àmọ́ kò rọrùn fún un, torí kò tíì sí ìwé orin lédè afọ́jú tó lè kà nígbà yẹn. Àwọn ará ìjọ wá ràn án lọ́wọ́ kó lè ṣe ìwé orin tiẹ̀. Ó gbà á ní wákàtí méjìlélógún (22) kó tó lè ṣe àdàkọ gbogbo àwọn orin mọ́kànléláàádọ́jọ (151) tó wà nínú ìwé orin sí èdè àwọn afọ́jú. Ní April 2018, Mingjie bẹ̀rẹ̀ sí í lọ wàásù, àtìgbà yẹn ló sì ti máa ń lo ọgbọ̀n (30) wákàtí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù lóṣooṣù.

Ó gba ọ̀pọ̀ ìsapá kéèyàn tó lè kọ ìwé kan ní èdè àwọn afọ́jú

 Kí Mingjie lè ṣèrìbọmi, Yanmei ràn án lọ́wọ́ láti múra àtúnyẹ̀wò tó wà nínú ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà. Yanmei bá a ka àwọn ìbéèrè àti àwọn ẹsẹ Bíbélì tó wà níbẹ̀ sórí ẹ̀rọ kó lè máa tẹ́tí sí i. Nígbà tó di July 2018, Mingjie ṣèrìbọmi. Ó sọ pé: “Ìfẹ́ tí àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin fi hàn sí mi ní àpéjọ agbègbè yẹn wọ̀ mí lọ́kàn gan-an. Inú mi dùn débi pé ńṣe ni omijé ayọ̀ ń bọ́ lójú mi. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, èmi náà ti wà nínú ìjọ Ọlọ́run tòótọ́.” (Jòhánù 13:​34, 35) Ní báyìí, Mingjie ti di òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, torí òun náà ti pinnu láti máa fìfẹ́ hàn sáwọn ẹlòmíì.

a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.