Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ọlọ́pàá Ń Tẹ̀ Lé Joseph

Ọlọ́pàá Ń Tẹ̀ Lé Joseph

 Tó o bá jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, Báwo ló ṣe máa rí lára rẹ tí ọlọ́pàá bá ń tẹ̀ lé ẹ bó o ṣe ń wàásù ìhin rere láti ilé dé ilé? Ohun tó ṣẹ́lẹ̀ sí Joseph ní Micronesia lọ́dún 2017 nìyẹn. Òun àti àwọn mẹ́ta míì ń ṣe àkànṣe ìwàásù kan láti bá àwọn tó wà láwọn erékùṣù tó jìnnà sọ̀rọ̀.

 Nígbà tó di ọ̀sán, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́rin yìí dé erékùṣù kékeré kan tó ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) èèyàn. Olórí erékùṣù náà ló kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yẹn káàbọ̀ ní èbúté náà. Joseph ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn, ó ní: “Olórí erékùṣù náà sọ pé kí ọkọ̀ ọlọ́pàá máa gbé wa lọ sí ilé àwọn èèyàn. Ó yà wá lẹ́nu gan-an, àmọ́ a sọ fún un tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pé a kò fẹ́. Tori pé ó wù wá láti lọ bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ láti ilé dé ilé bá a ṣe sábà máa ń ṣe.”

 Àwọn akéde náà bẹ̀rẹ̀ sí í fi ẹsẹ̀ rìn, wọ́n sì pinnu pé àwọn máa bá gbogbo ẹni tí àwọn bá pàdé sọ̀rọ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí náà sọ pé: “Àwọn èèyàn náà láájò gan-an, wọ́n sì fẹ́ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ wa. Torí náà, àkókò tá a lò nílé kọ̀ọ̀kan pọ̀ ju bá a ṣe rò lọ.”

 Nígbà tó fi máa di ìrọ̀lẹ́, ọkọ̀ ọlọ́pàá kọ́já lẹ́gbẹ̀ẹ́ Joseph lẹ́ẹ̀mejì, ó sì dúró nígbà tó fẹ́ kọjá lẹ́ẹ̀kẹta. Àwọn ọlọ́pàá náà bèèrè lọ́wọ́ Joseph pé ṣe kí àwọn gbé e lọ sáwọn ilé tí kò tíì dé. Joseph dáhùn pé, “Rárá. Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, àwọn ọlọ́pàá yẹn ò gbà, wọ́n bá sọ pé, ‘Ọjọ́ ti lọ, ẹ ò ní pẹ́ kúrò ní erékùṣù yìí, tórí náà à máa gbé ẹ lọ sáwọn ilé tó kù.’ Mi ò lè kọ̀ mọ́, tori pé ilé tí mi ò tíì dé ṣì pọ̀. Bá a ṣe ń dé ilé kọ̀ọ̀kan, àwọn ọlọ́pàá náà á sọ orúkọ ìdílé náà fún mi, wọ́n á sì sọ pé tí mo bá kan ilẹ̀kùn tí ẹnì kankan ò sì ṣí i, àwọn máa fọn fèrè láti jẹ́ kí àwọn ará ilé náà mọ̀ pé a ti dé.

 “Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ńlá yẹn, ó ṣeé ṣe fún wa láti dé gbogbo ilé lọ́jọ́ yẹn. Ìwé tá a fi síta pọ̀ gan-an, á sì ṣètò láti pa dà wá sọ́dọ̀ àwọn tó fẹ́ mọ púpọ̀ sí i.”

 Àwọn ọlọ́pàá yẹn sọ fún Joseph pé àwọn “gbádùn iṣẹ́ ìwàásù yẹn gan-an.” Nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà fi ibẹ̀ sílẹ̀ nígbà tí oòrùn wọ̀, àwọn ọlọ́pàá tó wà ní èbúté yẹn mú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dání, wọ́n sì juwọ́ sí wọn tẹ̀ríntẹ̀rín pé ó dàbọ̀.