Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Òṣìṣẹ́ Ilé Ìwòsàn Tó Ń Fara Da Àárẹ̀

Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Òṣìṣẹ́ Ilé Ìwòsàn Tó Ń Fara Da Àárẹ̀

 Ọkùnrin kan wà tó ń jẹ Bryn, ìpínlẹ̀ North Carolina ló ń gbé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ó sì wà lára Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn. Ìgbìmọ̀ yìí máa ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ilé ìwòsàn kí wọ́n lè pèsè ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó bá ń ṣàìsàn nílò.

 Nítorí àjàkálẹ̀ àrùn Corona, ọ̀pọ̀ ilé ìwòsàn ni ò jẹ́ káwọn èèyàn wá kí àwọn aláìsàn mọ́. Bryn pe ẹni tó ń mójú tó ọ̀rọ̀ tó bá jẹ́ mọ́ ẹ̀sìn àwọn aláìsàn nílé ìwòsàn kan, ó sì bi í nípa bóun ṣe lè ṣèrànwọ́ fáwọn aláìsàn tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

 Wọ́n jẹ́ kí Bryn bá igbá kejì ọ̀gá ilé ìwòsàn náà sọ̀rọ̀ lórí fóònù. Torí pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ gbà káwọn èèyàn wá máa kí àwọn aláìsàn, Bryn béèrè bóyá wọ́n lè fún àwọn aláìsàn tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní nọ́ńbà fóònù òun kóun lè bá wọn sọ̀rọ̀. Wọ́n sì gbà.

 Ọkàn Bryn wá lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nílé ìwòsàn náà. Ó sọ fún igbá kejì ọ̀gá náà pé òun mọyì iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe nílé ìwòsàn náà, òun sì fẹ́ béèrè àlàáfíà àwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Ó lóun ti kà nípa bí àárẹ̀ ṣe ń mú àwọn èèyàn níbi gbogbo, pàápàá àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nílé ìwòsàn torí gbogbo wàhálà tí àjàkálẹ̀ àrùn yìí ti dá sílẹ̀.

 Igbá kejì ọ̀gá náà ní wàhálà kékeré kọ́ ni àrùn Corona ti fà nílé ìwòsàn náà.

 Bryn dá a lóhùn pé: “Ìkànnì wa ṣàlàyé àwọn ọ̀nà téèyàn lè gbà fara da àárẹ̀. Tí ẹ bá tẹ ‘àárẹ̀’ síbi téèyàn ti lè wá nǹkan lórí jw.org, ẹ máa rí àwọn àpilẹ̀kọ tó máa wúlò gan-an fáwọn òṣìṣẹ́ yín.”

 Bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, igbá kejì ọ̀gá náà lọ sórí ìkànnì wa, ó sì tẹ “àárẹ̀” síbi téèyàn ti lè wá nǹkan níbẹ̀. Bó ṣe rí àwọn àpilẹ̀kọ tó gbé jáde, ẹnu yà á, ó sì sọ pé “Ó ga o! Màá fi han ọ̀gá mi. Ó máa wúlò gan-an fáwọn òṣìṣẹ́ wa àtàwọn míì. Ńṣe ni màá tẹ̀ ẹ́ jáde kí n lè pín in fún wọn.”

 Lọ́sẹ̀ mélòó kan lẹ́yìn náà, Bryn bá ọ̀gá ilé ìwòsàn náà sọ̀rọ̀, ọ̀gá náà sì sọ fún un pé àwọn ti lọ sórí ìkànnì náà, àwọn sì ti tẹ àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àárẹ̀ àtàwọn míì tó jẹ mọ́ ọn. Wọ́n fún àwọn nọ́ọ̀sì àtàwọn òṣìṣẹ́ míì nílé ìwòsàn náà.

 Bryn sọ pé: “Ọ̀gá náà dúpẹ́ lọ́wọ́ mi fún iṣẹ́ tí à ń ṣe àtàwọn àpilẹ̀kọ tó jíire náà. Ó ní wọ́n ran àwọn lọ́wọ́ gan-an.”