Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ọwọ́ Wọn Ń Tẹ Ohun Tí Wọ́n Ń Lé Lẹ́nu Iṣẹ́ Ọlọ́run

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti rí i pé Bíbélì ń mú kí ìgbàgbọ́ wọn túbọ̀ lágbára, kí ọwọ́ wọn sì tẹ ohun tí wọ́n ń lé lẹ́nu iṣẹ́ Ọlọ́run.

Cameron Gbé Ìgbésí Ayé Tó Dára Jù Lọ

Ṣé o fẹ́ káyé ẹ nítumọ̀? Gbọ́ bí Cameron ṣe ń sọ bí ayọ̀ rẹ̀ ṣe pọ̀ tó ní ibi tí kò lérò.

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú

Ọ̀pọ̀ àwọn arábìnrin tó ti sìn nílẹ̀ òkèèrè ló kọ́kọ́ lọ́ tìkọ̀ kí wọ́n tó lọ. Àmọ́, kí ló mú kí wọ́n ṣọkàn akin? Kí ni wọ́n sì ti kọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn lórílẹ̀-èdè mí ì?

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—Ní Alibéníà àti Kosovo

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn yìí kojú ìṣòro, kí ló mú kí wọ́n lè fara dà á?

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—Ní Brazil

Ka àwọn ìrírí tó ń gbéni ró nípa àwọn tí wọ́n kó lọ síbò míì kí wọ́n lè túbọ̀ sin Ọlọ́run lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́.

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—Ní Bulgaria

Kí ni díẹ̀ lára ìṣòro tó wà nínú kéèyàn ṣí lọ sí ilẹ̀ míì láti lọ wàásù?

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—Ní Gánà

Ìṣòro táwọn tó lọ sìn níbi tí àìní wà máa ń pọ̀. Àmọ́ èyí kì í tó nǹkan kan tá a bá fi wé àwọn ìbùkún tí wọ́n máa ń rí.

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú Lórílẹ̀-èdè Guyana

Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la rí kọ́ lára àwọn tó lọ sìn níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i? Tó bá wù ẹ́ láti lọ sìn nílẹ̀ òkèèrè, báwo làwọn ẹ̀kọ́ tó o kọ́ yìí ṣe lè mú kó o múra sílẹ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀?

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú​—Ní Madagásíkà

Ẹ jẹ́ ká mọ díẹ̀ lára àwọn akéde tó ṣí lọ sórílẹ̀-èdè Madagásíkà kí wọ́n lè wàásù ìhìn rere jákèjádò orílẹ̀-èdè yìí.

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—Ní Micronesia

Ó kéré tán ìpèníjà mẹ́ta làwọn tó ti òkèèrè wá sìn ní erékùṣù Pàsífí ìkì sábà máa ń ní. Àmọ́, kí ló ran àwọn àkéde yìí lọ́wọ́?

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú​—Ní Myanmar

Kí ló mú kí ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ìlú wọn sílẹ̀ kí wọ́n lè ṣe nínú iṣẹ́ ìkórè tó ń lọ ní Myanmar?

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—ní New York

Kí nìdí tí tọkọtaya kan tó rí towó ṣe fi kó kúrò nínú ilé ńlá tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí gan-an, tí wọ́n sì kó lọ sí yàrá kékeré kan?

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—ní Norway

Báwo ni ìbéèrè kan tó wá láìròtẹ́lẹ̀ ṣe mú kí ìdílé kan kó lọ síbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i?

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú ní Philippines.

Kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tó mú kí àwọn kan fi iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe sílẹ̀, kí wọ́n ta àwọn ohun ìní wọn, tí wọ́n sì lọ sí àdádó ní orílẹ̀-èdè Philippines

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—Ní Rọ́ṣíà

Kà nípa àwọn tí kò tíì ṣègbéyàwó àti àwọn tó ti ṣègbéyàwó tí wọ́n kó lọ sí orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà kí wọ́n lè sìn ní ibi tí a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Wọ́n ti kọ́ láti túbọ̀ gbára lé Jèhófà!

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú​​—Ní Tọ́kì

Lọ́dún 2014, wọ́n ṣe àkànṣe ìwàásù kan ní Tọ́kì. Kí nìdí tí wọ́n fi ṣe àkànṣe ìwàásù náà? Kí ló sì yọrí sí?

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—Ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà

Kí lóhun tó mú kí àwọn kan fi ilẹ̀ Yúróòpù sílẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Áfíríkà? Kí ló sì ti jẹ́ àbájáde ìgbésẹ̀ tí wọ́n gbé yìí?

A Pinnu Láti Jẹ́ Kí Nǹkan Díẹ̀ Tẹ́ Wa Lọ́rùn

Àsọyé ní àpéjọ kan ran tọkọtaya kan lọ́wọ́ lórílẹ̀-èdè Colombia láti ṣàyẹ̀wò ohun tó jẹ́ àfojúsùn wọn.

Ṣé Apá Mi Á Lè Ká Ohun Tí Mo Dáwọ́ Lé Yìí?

Kà nípa bí miṣọ́nnárì kan lórílẹ̀-èdè Benin ṣe kọ́ èdè àwọn adití kó lè ran àwọn adití lọ́wọ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run.

Ìpinnu Tí Mo Ṣe Nígbà Tí Mo Wà ní Kékeré

Ọmọkùnrin kan láti Columbus, ní ìpínlẹ̀ Ohio, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà pinnu láti kọ́ èdè Cambodian. Kí nìdí? Báwo ló ṣe mú kó yan ohun tó fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe?