Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Wọ́n Dúró Ran Ẹnì Kan Lọ́wọ́

Wọ́n Dúró Ran Ẹnì Kan Lọ́wọ́

 Lọ́jọ́ kan tí òtútù mú, tí atẹ́gùn sì ń fẹ́ gan-an nílùú Alberta, lórílẹ̀-èdè Kánádà, ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Bob ń wa mọ́tò lọ, bó ṣe rọra ń tẹná lọ ni táyà ẹ̀yìn ti apá òsì mọ́tò ẹ̀ bá fọ́. Bob ò kọ́kọ́ mọ nǹkan tó ṣẹlẹ̀, ó kàn ń wa mọ́tò lọ ní tiẹ̀ ni torí kò ní pé mọ́ tó fi máa délé.

 Bob ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà nínú lẹ́tà tó kọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè náà. Ó ní: “Mọ́tò kan rọra pẹ́wọ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀dọ̀ mi, àwọn ọ̀dọ́ márùn-ún ló wà nínú ẹ̀, wọ́n sì sọ fún mi pé táyà mọ́tò mi ti fọ́. Bí mo ṣe dúró nìyẹn, àwọn náà dúró, wọ́n sì sọ pé àwọn máa bá mi pààrọ̀ táyà ọ̀hún. Mi ò tiẹ̀ mọ̀ bóyá mo ní ìpààrọ̀ táyà nínú mọ́tò àbí bóyá mo tiẹ̀ ní jáàkì tí wọ́n fi ń gbé mọ́tò sókè. Kẹ̀kẹ́ arọ ni mò ń lò, bí mo ṣe jókòó lórí kẹ̀kẹ́ náà lẹ́gbẹ̀ẹ́ títì, bẹ́ẹ̀ ni mo rí wọn tí wọ́n rápálá wọ abẹ́ mọ́tò mi, tí wọ́n yọ ìpààrọ̀ táyà àti jáàkì jáde níbẹ̀, tí wọ́n sì bá mi pààrọ̀ táyà tó fọ́ náà. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, òtútù mú gan-an, yìnyín sì ń bọ́. Aṣọ ìṣeré kọ́ ló wà lọ́rùn àwọn ọ̀dọ́ yìí o, àmọ́ wọ́n ṣì bá mi pààrọ̀ táyà mọ́tò mi tó fọ́, tí mo tún fi lè máa bá ọ̀nà mi lọ. Ọpẹ́lọpẹ́ wọn lára mi, ǹ bá má lè dá a ṣe.

 “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà márùn-ún tó ràn mí lọ́wọ́. Ilé àwọn tí wọ́n ti fẹ́ lọ wàásù fún ni wọ́n ń lọ lọ́jọ́ yẹn. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé ohun tí wọ́n ń wàásù ẹ̀ fáwọn èèyàn ni wọ́n ń hù níwà. Ìrànlọ́wọ́ ńlá gbáà ni wọ́n ṣe fún mi torí àtiṣe é fúnra mi ì bá nira, mo mọrírì ẹ̀ gan-an. Bóyá kí n kúkú sọ pé àwọn ni áńgẹ́lì tí Ọlọ́run rán sí mi lójú ọ̀nà lọ́jọ́ yẹn.”