Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Wọn Ò Dáwọ́ Iṣẹ́ Ìwàásù Dúró Lásìkò Àjàkálẹ̀ Àrùn

Wọn Ò Dáwọ́ Iṣẹ́ Ìwàásù Dúró Lásìkò Àjàkálẹ̀ Àrùn

 Lásìkò àjàkálẹ̀ àrùn Corona, àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin ti lo onírúurú àwọn ọ̀nà míì láti wàásù fáwọn èèyàn. Dípò kí wọ́n máa wàásù láti ilé dé ilé tàbí níbi térò pọ̀ sí, ṣe ni wọ́n máa ń pe àwọn èèyàn lórí fóònù tàbí kí wọ́n kọ lẹ́tà sí wọn. a Ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọyì ohun tá à ń ṣe yìí, ó sì dájú pé Jèhófà ń bù kún àwọn ọ̀nà tá à ń gbà wàásù. (Òwe 16:​3, 4) Ẹ jẹ́ ká wo àwọn ìrírí díẹ̀ láti orílẹ̀-èdè kan.

 Ṣáájú àjàkálẹ̀ àrùn náà, ọ̀pọ̀ ìgbà ni Helen ti gbìyànjú láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú obìnrin kan, àmọ́ obìnrin náà kì í gbà. Lọ́jọ́ tó ṣáájú ọjọ́ tí ìjọba gbé òfin kónílégbélé kalẹ̀, Helen fún obìnrin náà ní Bíbélì àti ìwé Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa? Lásìkò kónílégbélé, Helen tún kàn sí obìnrin náà, ó sì bi í bóyá ó máa fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kódà ó ṣàlàyé fún un pé àwọn á máa ṣe é látorí fóònù. Lọ́tẹ̀ yìí, obìnrin náà gbà. Obìnrin náà gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ náà gan-an débi tó fi sọ fún Helen pé kó máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ lójoojúmọ́. Yàtọ̀ síyẹn, obìnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí í wá sí àwọn ìpàdé tá à ń ṣe látorí fóònù. Kò tán síbẹ̀ o, kì í kàn ń ṣe pé ó ń fi ohun tó ń kọ́ sílò nígbèésí ayé ẹ̀ nìkan, ó tún ń sọ ohun tó ń kọ́ fáwọn míì.

 Àwọn ará tó wà níjọ kan pinnu láti kọ lẹ́tà sáwọn ọlọ́pàá tó wà ládùúgbò wọn, kí wọ́n lè fi dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn fún iṣẹ́ ribiribi tí wọ́n ń ṣe. Nígbà táwọn ọlọ́pàá rí lẹ́tà náà, ó yà wọ́n lẹ́nu gan-an. Ọ̀kan lára àwọn ọlọ́pàá náà sọ fún alàgbà kan tó ń jẹ́ Jefferson pé, “Mo rò pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kórìíra àwa ọlọ́pàá ni.” Jefferson wá jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Inú àwọn ọlọ́pàá náà dùn sí lẹ́tà náà débi pé, wọ́n lẹ̀ ẹ́ mọ́ ẹnu ọ̀nà àgọ́ wọn. Ọlọ́pàá míì wá sọ pé, “O ṣeé ṣe kí lẹ́tà yìí mú kàwọn èèyàn ní èrò tó dáa nípa wa.”

 Aṣáájú-ọ̀nà déédéé ni Edna àti Ednalyn. b Àmọ́ wọn ò lè dara pọ̀ mọ́ ìpàdé ìjọ tí wọ́n ń ṣe lórí fóònù torí pé wọn ò ní Íntánẹ́ẹ̀tì ní ilé wọn. Wọ́n wá pe aládùúgbò wọn kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì bi í bóyá àwọn lè lo Íntánẹ́ẹ̀tì rẹ̀ kí àwọn sì san owó fún un. Obìnrin náà gbà kí wọ́n lò ó láìgba owó lọ́wọ́ wọn. Edna and Ednalyn wá sọ fún obìnrin náà pé òun náà lè dara pọ̀ mọ́ ìpàdé, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. Ní báyìí, obìnrin yẹn, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹ̀, àti àwọn ọmọ-ọmọ ẹ̀ méjì ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì ń wá sí ìpàdé déédéé.

 Àwọn ará pe àwọn aládùúgbò wọn, àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ àtàwọn míì pé kí wọ́n wá gbọ́ àsọyé kan tí wọ́n máa sọ lórí fóònù. Àmọ́, kò kọ́kọ́ rọrùn fún Ellaine tó ń ṣiṣẹ́ ní ilé ìwòsàn kan láti pé àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́. Ìdí ni pé ó ronú pé àwọn dókítà kan lè ní èrò tí kò tọ́ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bó ti wù kó rí, ó fi àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ́ sí àwọn dókítà náà kó lè fi pè wọ́n wá fún àsọyé yìí, àmọ́ ó ní àwọn dókítà méjì ní pàtó tí wọ́n jẹ́ tọkọtaya tó ṣòro fún Ellaine láti pè. Lẹ́yìn tó ro ọ̀rọ̀ náà dáadáa, tó sì fi sádùúrà, ó fọ̀rọ̀ ránṣé sí wọn. Ìyàwó náà sọ pé, “Ṣé o fẹ́ kí n di Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni?” Ellaine wá dáhùn pé gbogbo èèyàn ni ìpàdé wa wà fún kì í ṣe àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan. Lọ́jọ́ kejì, ó ya Ellaine lẹ́nu láti rí i pé tọkọtaya náà dara pọ̀ mọ́ ìpàdé náà, kódà wọ́n tètè dé. Ellaine sọ pé: “Kí ìpàdé náà tó parí, ìyàwó yẹn fi ọ̀rọ̀ ránṣé sí mi, ó sọ pé: ‘Ìgba àkọ́kọ́ rèé tí màá wá sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo gbádùn ẹ̀ gan-an, inú mi sì dùn. O ṣeun tó o pè mí.’”

Ellaine

 Inú Ellaine dùn gan-an pé nínú ogún (20) dókítà tí òun pè wá sípàdé, mẹ́rìndínlógún (16) nínú wọn ló wá. Ellaine wá fa ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù yọ, pé: “Inú mi dùn gan-an pé mo ‘mọ́kàn le,’ mo sì fìgboyà sọ ‘ìhìn rere Ọlọ́run’ fáwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́.”​—1 Tẹsalóníkà 2:2.

 Àjàkálẹ̀ àrùn yìí ti mú kí nǹkan nira fún gbogbo èèyàn. Àmọ́ àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin ní orílẹ̀-èdè yìí àti láwọn ibòmíì ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti tu àwọn míì nínú kí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́, ìyẹn ń jẹ́ kí wọ́n láyọ̀ kí wọ́n sì ní èrò tó tọ́.​—Ìṣe 20:35.

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń tẹ̀ lé òfin tí ìjọba ṣe lórí lílo ìsọfúnni ẹlòmíì tá a bá ń wàásù.

b Àwọn Kristẹni tó ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù là ń pè ní aṣáájú-ọ̀nà.