Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọwọ́ Hulda Tẹ Ohun Tó Ń Wá

Ọwọ́ Hulda Tẹ Ohun Tó Ń Wá

TÓ O bá ti lọ sí erékùṣù kékeré kan tó ń jẹ́ Sangir Besar lórílẹ̀-èdè Indonéṣíà láwọn ọdún kan sẹ́yìn, ó ṣeé ṣe kó o rí àwọn arábìnrin wa mẹ́ta kan tí wọ́n máa ń wà létíkun. Àwọn èèyàn mọ̀ wọ́n dáadáa torí pé wọ́n máa ń wàásù, wọ́n sì ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti lóye Bíbélì. Àmọ́ nígbà tí wọ́n bá wà létíkun, iṣẹ́ míì ni wọ́n ń ṣe níbẹ̀.

Erékùṣù Sangir Besar tó wà ní àríwá Indonéṣíà

Ohun tí wọ́n máa ń kọ́kọ́ ṣe ni pé wọ́n á wọnú omi, wọ́n á sì kó òkúta tó tóbi jáde wá sí etíkun. Àwọn òkúta kan máa ń tóbi tó bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá. Lẹ́yìn náà, wọ́n á jókòó sórí àpótí onígi, wọ́n á sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi òòlù fọ́ àwọn òkúta náà sí wẹ́wẹ́. Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n á kó àwọn òkúta náà sínú àwọn ike, wọ́n á sì gbé wọn gba ọ̀nà olókè kan lọ sílé wọn. Tí wọ́n bá ti délé, wọ́n á kó àwọn òkúta náà sínú àwọn àpò ńlá, wọ́n á kó wọn sínú ọkọ̀ akẹ́rù, àwọn èèyàn á sì lọ fi ṣe ojú ọ̀nà.

Hulda ń kó òkúta jọ létíkun

Ọ̀kan lára àwọn arábìnrin mẹ́ta yẹn ni Hulda. Ó máa ń ráyè ṣe iṣẹ́ náà ju àwọn arábìnrin yòókù lọ. Owó tó bá pa ló máa ń fi gbọ́ bùkátà ìdílé ẹ̀. Àmọ́ ní báyìí, ó tún tẹra mọ́ iṣẹ́ náà kọ́wọ́ ẹ̀ lè tẹ nǹkan tó ń wá. Ó fẹ́ ra tablet táá jẹ́ kó lè máa lo JW Library®. Hulda mọ̀ pé àwọn fídíò àtàwọn nǹkan míì tó wà nínú JW Library máa jẹ́ kóun túbọ̀ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, á sì jẹ́ kí Bíbélì túbọ̀ yé òun.

Oṣù kan àtààbọ̀ ni Hulda fi ṣe àṣekún iṣẹ́ wákàtí méjì láràárọ̀, ó sì fọ́ òkúta tó kún inú ọkọ̀ akẹ́rù kékeré kan. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ó rówó fi ra tablet náà.

Hulda mú tablet ẹ̀ dání

Hulda sọ pé: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ náà máa ń jẹ́ kó rẹ̀ mí, tó sì máa ń mára ro mí, mo gbàgbé gbogbo ìrora yẹn lẹ́yìn tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í lo tablet náà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, tí mo sì fi ń múra ìpàdé sílẹ̀.” Ó tún sọ pé tablet náà ran òun lọ́wọ́ nígbà tí àjàkálẹ̀ àrùn kòrónà ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ torí pé orí Íńtánẹ́ẹ̀tì la ti ń ṣèpàdé, tá a sì ń wàásù. A bá Hulda yọ̀ torí pé ọwọ́ ẹ̀ tẹ ohun tó ń wá.