Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọkàn Àwọn Èèyàn Ló Ṣe Pàtàkì, Kì Í Ṣe Ìrísí Wọn

Ọkàn Àwọn Èèyàn Ló Ṣe Pàtàkì, Kì Í Ṣe Ìrísí Wọn

ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ ni Don lórílẹ̀-èdè Kánádà, ó sì máa ń sapá gan-an kó lè wàásù fáwọn èèyàn tí kò nílé. Nígbà tí Don ń sọ nípa ọ̀kan lára wọn, ó ní: “Ọkùnrin kan wà tó ń jẹ́ Peter, ibi kọ̀rọ̀ kan ládùúgbò ló ń sùn, ara rẹ̀ dọ̀tí gan-an, kódà mi ò rẹ́ni tó dọ̀tí bẹ́ẹ̀ rí. Ìrísí rẹ̀ máa ń kó àwọn èèyàn nírìíra, òun náà sì tún máa ń lé àwọn èèyàn sá. Kì í gbà káwọn èèyàn ṣe òun lóore.” Síbẹ̀, fún ohun tó lé lọ́dún mẹ́rìnlá [14] ni Don fi ń wá bó ṣe máa ṣe ọkùnrin náà lóore. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ọkùnrin náà kì í gbà, Don kò jẹ́ kó sú òun.

Lọ́jọ́ kan, Peter bi Don pé: “Kí ló dé tó o fi ń dà mí láàmú? Àwọn yòókù ti pa mí tì. Síbẹ̀, o ò fi mí sílẹ̀, kí nìdí?” Don tọ́ka sí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ mẹ́ta, ó sì fọgbọ́n ṣàlàyé wọn kó lè dé ọkàn Peter. Lákọ̀ọ́kọ́, ó béèrè lọ́wọ́ Peter bóyá ó mọ orúkọ Ọlọ́run, lẹ́yìn náà ó ṣí Bíbélì rẹ̀ sí Sáàmù 83:18, ó sì ní kó kà á. Ẹ̀yìn ìyẹn ni Don wá ṣàlàyé ìdí tóun ò fi pa á tì, ó ní kó ka ìwé Róòmù 10:13, 14 tó sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni a ó gbà là.” Ẹsẹ Bíbélì kẹta tí Don kà ni Mátíù 9:36, ó sì tún ní kí Peter kà á. Ẹsẹ yẹn sọ pé: “Nígbà tí [Jésù] rí àwọn ogunlọ́gọ̀, àánú wọn ṣe é, nítorí a bó wọn láwọ, a sì fọ́n wọn ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.” Nígbà tí Peter ka ẹsẹ yẹn, omi lé ròrò sójú rẹ̀, ó sì bi Don pé: “Ṣé èmi náà wà lára àwọn àgùntàn yẹn?”

Peter bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn àyípadà kan. Ó wẹ̀, ó gé irùngbọ̀n rẹ̀ mọ́lẹ̀, ó sì wọ àwọn aṣọ dáadáa tí Don fún un. Àtìgbà yẹn ni Peter ti máa ń múra dáadáa, tó sì dùn ún wò.

Peter ní àkọsílẹ̀ kan. Àwọn ojú ìwé tó wà níbẹ̀rẹ̀ kún fún ọ̀rọ̀ ìbànújẹ́ àti ẹ̀dùn ọkàn, àmọ́ àwọn nǹkan tó kọ sílẹ̀ látìgbà tó ti pàdé Don yàtọ̀ pátápátá. Bí àpẹẹrẹ, lára ohun tó kọ ni pé: “Òní ni mo mọ orúkọ Ọlọ́run. Ní báyìí, Jèhófà ni mo máa ń gbàdúrà sí. Inú mi dùn gan-an pé mo mọ orúkọ Ọlọ́run. Don kọ́ mi pé mo lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà, pé kò sígbà tí mo fẹ́ bá Jèhófà sọ̀rọ̀ tí kò ní ráyè tèmi, ó ṣe tán láti gbọ́ ohunkóhun tí mo bá fẹ́ sọ.”

Peter kọ àwọn ọ̀rọ̀ tó kẹ́yìn yìí sí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin àti àbúrò rẹ̀ ọkùnrin. Ó ní:

“Ó tẹ̀ mí díẹ̀ lónìí. Mo gbà pé ara mi ti di ara àgbà. Tó bá sì jẹ́ pé òní náà ni màá kú, ó dá mi lójú pé màá pa dà rí ọ̀rẹ́ mi Don nínú Párádísè. Tó bá jẹ́ pé ìwé tí mo kọ yìí lẹ̀ ń kà, a jẹ́ pé mo ti lọ nìyẹn. Tẹ́ ẹ bá rí ojú tó ṣàjèjì níbi ìsìnkú mi, ẹ sún mọ́ onítọ̀hún, kẹ́ ẹ sì bá a sọ̀rọ̀. Lẹ́yìn náà, mo fẹ́ kẹ́ ẹ ka ìwé aláwọ̀ búlúù yìí. * Ìwé yẹn sọ pé màá tún pa dà rí ọ̀rẹ́ mi nínú Párádísè. Ó sí dá mi lójú pé òótọ́ ni. Èmi ni tiyín ní tòótọ́, Peter.”

Lẹ́yìn ìsìnkú náà, ẹ̀gbọ́n Peter obìnrin tó ń jẹ́ Ummi sọ pé: “Nǹkan bí ọdún méjì sẹ́yìn ni Peter kàn sí mi tá a sì jọ sọ̀rọ̀. Àmọ́, fúngbà àkọ́kọ́ lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, ó jọ pé inú rẹ̀ dùn, kọ́dà ó rẹ́rìn-ín sí mi.” Ummi wá sọ fún Don pé: “Mo gbà pé àkànṣe ìwé ni ìwé yìí, torí òun ló mú kí àbúrò mi dèèyàn gidi, torí náà, èmi náà máa kà á.” Ummi tún gbà pé kí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan máa fi ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Àwa náà lè fi hàn pé kì í ṣe ìrísí àwọn èèyàn nìkan là ń wò, ó yẹ ká máa ronú nípa irú ẹni tí wọ́n jẹ́. Ká máa fìfẹ́ tòótọ́ hàn sí wọn, ká sì máa ní sùúrù fún gbogbo èèyàn láìka ibi tí wọ́n ti wá tàbí bí wọ́n ṣe rí. (1 Tím. 2:3, 4) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwa náà lè yí àwọn tó dà bíi Peter lérò pa dà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìrísí wọn lè má fani mọ́ra, síbẹ̀ wọ́n lè ní ọkàn tó dáa. Ó dá wa lójú pé Ọlọ́run tó “ń wo ohun tí ọkàn-àyà jẹ́,” máa jẹ́ kí irúgbìn òtítọ́ hù nínú ọkàn àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́.1 Sám. 16:7; Jòh. 6:44.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 7 Ìyẹn ìwé Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye tí Peter ti gbà láwọn ọdún mélòó kan sẹ́yìn. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde, àmọ́ a ò tẹ̀ ẹ́ mọ́ báyìí.