Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Má Ṣe Sọ̀rètí Nù!

Má Ṣe Sọ̀rètí Nù!

Ṣó o ti ń sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún tó sì wù ẹ́ kí ọkọ tàbí aya rẹ máa sin Jèhófà pẹ̀lú rẹ?

Àbí ńṣe lo rẹ̀wẹ̀sì torí pé ẹnì kan tí ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tó sì ń ṣe dáadáa nígbà kan kò fọwọ́ pàtàkì mú òtítọ́ mọ́?

Tó o bá kà nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ará wa kan ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, wàá rí ìdí tí kò fi yẹ kó o sọ̀rètí nù. Wàá tún mọ bó o ṣe lè “fọ́n oúnjẹ rẹ sí ojú omi,” kó o bàa lè ran àwọn tí kò fọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀kọ́ òtítọ́ lọ́wọ́.—Oníw. 11:1.

ÌFARADÀ ṢE PÀTÀKÌ

Ìfaradà jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ohun tó o nílò. O gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nìṣó kó o sì rọ̀ mọ́ Jèhófà. (Diu. 10:20) Ohun tí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Georgina ṣe nìyẹn. Nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dún 1970, inú bí Kyriacos, ọkọ rẹ̀. Ó gbìyànjú láti dá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà dúró, kò jẹ́ kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sílé wọn mọ́, tó bá sì ti rí ìtẹ̀jáde àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ńṣe ló máa mú un kúrò nílẹ̀.

Nígbà tí Georgina bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ, inú túbọ̀ wá bí ọkọ rẹ̀ gan-an. Lọ́jọ́ kan, ó lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba láti lọ dá wàhálà sílẹ̀. Nígbà tí arábìnrin kan ṣàkíyèsí pé Kyriacos mọ èdè Gíríìkì sọ ju èdè Gẹ̀ẹ́sì lọ, ó pe arákùnrin kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì lórí fóònù pé kó wá báwọn bá a sọ̀rọ̀. Kyriacos fara balẹ̀ tẹ́tí sí arákùnrin náà, arákùnrin náà sì kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún oṣù bíi mélòó kan. Àmọ́ kò pẹ́ tí Kyriacos ò fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ́.

Kò dáwọ́ àtakò tó ń ṣe sí aya rẹ̀ dúró fún odindi ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà. Ó tiẹ̀ sọ fún ìyàwó rẹ̀ pé tó bá fi lè ṣe ìrìbọmi pẹ́nrẹ́n, ńṣe ni òun máa kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Lọ́jọ́ tí Georgina máa ṣèrìbọmi, ó gbàdúrà kíkankíkan sí Jèhófà pé kó má ṣe jẹ́ kí ọkọ òun kọ òun sílẹ̀. Nígbà tí àwọn ará dé láti wá fi mọ́tò gbé Georgina lọ sí Gbọ̀ngàn Àpéjọ, Kyriacos sọ fún wọn pé: “Ẹ máa nìṣó. Àwa náà ń gbé mọ́tò wa bọ̀.” Ó gbé ìyàwó rẹ̀ lọ sí àpéjọ náà, ó bá wọn ṣe ìpàdé àárọ̀, ó sì rí bí wọ́n ṣe ri ìyàwó rẹ̀ bọmi!

Lẹ́yìn nǹkan bí ogójì ọdún tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti kọ́kọ́ wàásù fún Georgina ni ọkọ rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ wá ṣèrìbọmi

Látìgbà yẹn lọ, kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe àtakò sí ìyàwó rẹ̀ mọ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn ìyípadà pàtàkì. Lẹ́yìn nǹkan bí ogójì ọdún tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti kọ́kọ́ wàásù fún Georgina ni ọkọ rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ wá ṣèrìbọmi! Kí ló mú kí Kyriacos pinnu láti sin Jèhófà? Ó sọ pé: “Inú mi dùn pé Georgina dúró lórí ìpinnu rẹ̀ láti máa sin Jèhófà nìṣó láìka inúnibíni sí.” Georgina sọ pé: “Pẹ̀lú bí ọkọ mi ṣe ṣe àtakò sí mi tó, mo pinnu pé mi ò ní fi Ọlọ́run sílẹ̀. Gbogbo ìgbà ni mo máa ń gbàdúrà sí Jèhófà, mi ò sì sọ̀rètí nù.”

ÌWÀ RERE ṢE PÀTÀKÌ

Ohun pàtàkì míì tó tún lè mú kí ọkọ tàbí aya rẹ di olùjọ́sìn Jèhófà ni ìwà rere rẹ. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni aya níyànjú pé: “Ẹ wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ tiyín, kí ó lè jẹ́ pé, bí ẹnikẹ́ni kò bá ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ náà, kí a lè jèrè wọn láìsọ ọ̀rọ̀ kan nípasẹ̀ ìwà àwọn aya wọn.” (1 Pét. 3:1) Àpẹẹrẹ míì tá a máa gbè yẹ̀ wò ni ti arábìnrin kan tó ń jẹ́ Christine. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọdún kọjá kí John, ọkọ rẹ̀, tó wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ó tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ìyànjú Pọ́ọ̀lù, ó ń bá a nìṣó láti tẹrí ba fún ọkọ rẹ̀. Nígbà tí Christine ṣèrìbọmi ní nǹkan bí ogún ọdún sẹ́yìn, John ò tiẹ̀ gba Ọlọ́run gbọ́ rárá. Ọ̀rọ̀ ìsìn kò sì ṣe pàtàkì sí i. Àmọ́, ó rí i pé Christine fẹ́ràn ẹ̀sìn tuntun tó ń ṣe gan-an ni. Ó sọ pé: “Mo rí i pé ẹ̀sìn rẹ̀ ń fún un láyọ̀ gan-an. Ńṣe ni ìwà rẹ̀ túbọ̀ ń dára sí i, ó sì tún jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán. Èyí sì ràn mí lọ́wọ́ gan-an láwọn ìgbà tí nǹkan le koko pàápàá.”

Christine kì í rọ̀jò àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì lé ọkọ rẹ̀ lórí. Ọkọ rẹ̀ sì jẹ́rìí sí èyí, ó sọ pé: “Christine mọ̀ pé mi ò fẹ́ kí òun máa sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sìn rẹ̀ fún mi rárá, ó sì ṣe sùúrù fún mi. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ohun tí mò ń kọ́ ń yé mi. Nígbà tó sì yá, fúnra mi ni mo pinnu láti sìn Jèhófà.” Christine mọ̀ pé àwọn àpilẹ̀kọ kan wà tí ọkọ rẹ̀ máa ń fẹ́ láti kà, irú bí àwọn tó dá lórí sáyẹ́ǹsì àti ìṣẹ̀dá. Torí náà, nígbàkigbà tó bá rí àpilẹ̀kọ kan tó sọ̀rọ̀ nípa irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ nínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tàbí Jí! ó máa ń fi han ọkọ rẹ̀, á sì sọ pé, “mo mọ̀ pé ẹ máa gbádùn àpilẹ̀kọ́ yìí.”

Nígbà tó yá, John fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ olùtọ́jú ọgbà. Ní báyìí tí ọwọ́ rẹ̀ ti dilẹ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, ó máa ń ronú nípa àwọn ìbéèrè pàtàkì nípa ìgbésí ayé, irú bíi, ‘Ṣé nípasẹ̀ èèṣì ni àwa èèyàn fi wà láyé, àbí ẹnì kan ló dìídì ṣẹ̀dá wa nítorí ìdí pàtàkì kan?’ Lọ́jọ́ kan, arákùnrin kan tí òun àti John jọ ń tàkúrọ̀sọ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ṣé ká jọ máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?” John sọ pé: “Nígbà yẹn, mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í gba Ọlọ́run gbọ́, torí náà mo gbà pé kó wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”

Ẹ ò rí i pé ó dára gan-an bí Christine kò ṣe sọ̀rètí nù! Lẹ́yìn ogún ọdún tó ti ń gbàdúrà pé kí ọkọ rẹ̀ wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ni ọkọ rẹ̀ tó ṣèrìbọmi. Àwọn méjèèjì ti jùmọ̀ ń sin Jèhófà, wọ́n sì jẹ́ onítara. John sọ pé: “Ohun méjì ló mú kí n kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ohun àkọ́kọ́ ni pé àwọn ará fìfẹ́ hàn sí mi, wọ́n sì sọ mí di ọ̀rẹ́ wọn. Èkejì ni pé ó máa ń fini lọ́kàn balẹ̀ gan-an téèyàn bá fẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n máa ń jẹ́ olóòótọ́, wọ́n ṣeé fọkàn tán, wọ́n sì ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ.” Ó ṣe kedere pé Christine fi ohun tó wà nínú 1 Pétérù 3:1 sílò, ó sì ṣàṣeyọrí.

IRÚGBÌN ÒTÍTỌ́ SÈSO LẸ́YÌN Ọ̀PỌ̀ ỌDÚN

Tó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹnì kan tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kò fọwọ́ pàtàkì mú òtítọ́ mọ́ ńkọ́? Sólómọ́nì Ọba sọ pé: “Ní òwúrọ̀, fún irúgbìn rẹ àti títí di ìrọ̀lẹ́, má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ sinmi; nítorí ìwọ kò mọ ibi tí èyí yóò ti ṣe àṣeyọrí sí rere, yálà níhìn-ín tàbí lọ́hùn-ún, tàbí kẹ̀, bóyá àwọn méjèèjì ni yóò dára bákan náà.” (Oníw. 11:6) Nígbà míì, ó máa ń gba ọ̀pọ̀ ọdún kí ẹni tá a kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ tó di ìránṣẹ́ Jèhófà. Àmọ́, nígbà tó bá yá, ẹni náà lè wá rí i pé ó ṣe pàtàkì pé kí òun sún mọ́ Jèhófà. (Ják. 4:8) Ohun tá a sọ yìí lè ṣẹlẹ̀ sí ìwọ náà lọ́jọ́ kan.

Obìnrin kan wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Alice. Orílẹ̀-èdè Íńdíà ló ń gbé tẹ́lẹ̀ kó tó kó lọ sí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Ọdún 1974 ló bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Èdè Híńdì ló ń sọ, ṣùgbọ́n ó wù ú kó máa sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì dáadáa. Alice ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nìṣó fún ọdún bíi mélòó kan, ó sì lọ sí ìjọ kan tí wọ́n ti ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì ní ìgbà mélòó kan. Ó mọ̀ pé ẹ̀kọ́ òtítọ́ ni òun ń kọ́, àmọ́ kò fọwọ́ pàtàkì mú un. Àti pé ó fẹ́ràn owó gan-an, ó sì máa ń lọ síbi àríyá. Nígbà tó yá, Alice ò kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ́.

Ní nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún lẹ́yìn náà, Alice fi lẹ́tà kan ránṣẹ́ sí arábìnrin Stella tó kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dún 1974. Lẹ́tà náà kà pé: “Mo mọ̀ pé inú rẹ máa dùn gan-an láti gbọ́ pé ẹni tó o kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dún 1974 ti ṣèrìbọmi ní àpéjọ àgbègbè kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Nǹkan ńlá lo gbé ṣe láyé mi o! O gbin irúgbìn òtítọ́ sínú ọkàn mi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò ṣe tán nígbà yẹn láti ya ara mi sí mímọ́ fún Ọlọ́run, ńṣe ni mo tọ́jú irúgbìn òtítọ́ yẹn sínú ọkàn mi àti èrò inú mi.”

Lẹ́tà tí Alice kọ sí Stella kà pé: “Mo mọ̀ pé inú rẹ máa dùn gan-an láti gbọ́ pé ẹni tó o kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dún 1974 ti ṣèrìbọmi ní àpéjọ àgbègbè kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí”

Kí ló mú kí Alice wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́? Alice sọ pé ọkàn òun gbọgbẹ́ gan-an nígbà tí ọkọ òun kú lọ́dún 1997. Ó gbàdúrà sí Ọlọ́run. Ní nǹkan bí ìṣẹ́jú mẹ́wàá lẹ́yìn náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì tí wọ́n ń sọ èdè Punjabi wá sí ilé rẹ̀, wọ́n sì fún un ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Ireti Wo ni Ó Wà fun Awọn Ololufẹ Tí wọn Ti Kú? Alice gbà pé Ọlọ́run ló gbọ́ àdúrà òun, ó sì pinnu pé òun máa wá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ. Àmọ́, ibo ló ti máa rí wọn? Ó rí ìwé kan tí Stella fún un. Ibẹ̀ ló ti rí àdírẹ́sì Gbọ̀ngàn Ìjọba tí wọ́n ti ń ṣèpàdé ní èdè Punjabi. Ó lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba náà, àwọn ará tó ń sọ èdè Punjabi sì fọ̀yàyà kí i káàbọ̀. Alice sọ pé: “Ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn sí mi yẹn wọ̀ mí lọ́kàn gan-an ni, ó sì mú kí ìbànújẹ́ mi fò lọ.

Alice bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé déédéé, ó ń bá a nìṣó láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì tún ń kọ́ bó ṣe lè túbọ̀ máa sọ èdè Punjabi kó sì máa kọ ọ́ dáadáa. Ó ṣèrìbọmi lọ́dún 2003. Ohun tó fi parí lẹ́tà tó kọ sí Stella rèé, “O ṣeun tó o gbin irúgbìn yẹn sí mi lọ́kàn ní ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n sẹ́yìn. Àpẹẹrẹ àtàtà lo jẹ́ fún mi.”

“O ṣeun gan-an tó o gbin irúgbìn yẹn sí mi lọ́kàn ní ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n sẹ́yìn àpẹẹrẹ àtàtà lo jẹ́ fún mi.”—Alice

Kí lo rí kọ látinú àwọn ìrírí yìí? Òótọ́ ni pé ó lè pẹ́ ju bó o ṣe rò lọ, ṣùgbọ́n, tí ebi òtítọ́ bá ń pa ẹni kan, tó bá jẹ́ pé olóòótọ́ èèyàn ni, tó sì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, Jèhófà máa jẹ́ kí òtítọ́ fìdí múlẹ̀ lọ́kàn rẹ̀. Rántí ohun tí Jésù sọ nínú àkàwé kan: “Irúgbìn náà sì rú jáde, ó sì dàgbà sókè, gan-an bí ó ṣe ṣẹlẹ̀, òun kò mọ̀. Ilẹ̀ fúnra rẹ̀ ń so èso ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, lákọ̀ọ́kọ́ ewé koríko, lẹ́yìn náà pòròpórò erínkà, ní ìkẹyìn ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọkà nínú erínkà.” (Máàkù 4:27, 28) Díẹ̀díẹ̀ ni irú ìtẹ̀síwájú bẹ́ẹ̀ máa ń wáyé àti pé “fúnra rẹ̀” ni yóò máa dàgbà. Bó sì ṣe máa ń rí náà nìyẹn, olúkúlùkù wa ò mọ bí ìtẹ̀síwájú yìí ṣe ń wáyé. Torí náà, máa fún irúgbìn ní yanturu. Wàá sì kárúgbìn ní yanturu.

Má sì ṣe gbàgbé pé àdúrà ṣe pàtàkì gan-an. Georgina àti Christine kò dákẹ́ àdúrà sí Jèhófà. Tó o bá ní “ìforítì nínú àdúrà” ti o kò sì sọ̀rètí nù, “lẹ́yìn ọjọ́ púpọ̀,” ó lè wá rí “oúnjẹ” tó o fọ́n sójú omi.—Róòmù 12:12; Oníw. 11:1.