Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Wọ́n Rò Pé Pásítọ̀ Wọn Ni

Wọ́n Rò Pé Pásítọ̀ Wọn Ni

 Osman, ìyàwó rẹ̀ àti ọmọ wọn obìnrin ń wàásù ní ìdí àtẹ ìwé tó ṣeé gbé kiri tá à ń kó àwọn ìtẹ̀jáde wa sí nítòsí itẹ́ òkú kan lórílẹ̀-èdè Chile. Lójijì, àwọn èèyàn kan dé láti wá sìnkú, wọ́n sì ń kọ orin tó ń dún kíkankíkan. Díẹ̀ lára àwọn èèyàn náà rò pé Pásítọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì wọn ni Osman, ni wọ́n bá sún mọ́n ọn, wọ́n sì gbá a mọ́ra. Wọ́n sọ pé: “Ẹ ṣeun tẹ́ ẹ tètè dé síbí Pásítọ̀, a ti ń retí yín!”

 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Osman gbìyànjú láti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun kọ́ ni Pásítọ̀ wọn, ariwo wọ́n pọ̀ débi pé wọn ò lè gbọ́ ohun tó ń sọ. Lẹ́yìn ìṣẹ́jú díẹ̀ táwọn èèyàn náà ti lọ sí itẹ́ òkú, díẹ̀ lára wọn pa dà sọ́dọ̀ Osman, wọ́n sì sọ fún un pé: “Pásítọ̀, a ti ń dúró dè yín ní itẹ́ òkú.”

 Lẹ́yìn tí ariwo náà rọlẹ̀, Osman sọ orúkọ rẹ̀, ó sì ṣàlàyé ìdí tó fi wà níbẹ̀. Inú bí wọn gan-an pé Pásítọ̀ àwọn ò wá, ni wọ́n bá bi Osman pé, “Ṣé ẹ lè wọlé wá bá àwọn èèyàn yìí sọ̀rọ̀ díẹ̀ láti inú Bíbélì?” Osman gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀.

 Bí wọ́n ṣe ń lọ sí itẹ́ òkú náà, Osman béèrè nípa irú ìgbésí ayé tí ẹni tó kú náà ti gbé sẹ́yìn, ó sì ronú nípa àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó lè fi bá wọn sọ̀rọ̀. Nígbà tí wọ́n dé etí ibojì, ó sọ orúkọ rẹ̀ fún wọn, ó sì ṣàlàyé pé ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòun àti pé òun máa ń wàásù ìròyìn ayọ̀ fún àwọn èèyàn.

 Lẹ́yìn náà, ó ka Ìfihàn 21:​3, 4 àti Jòhánù 5:​28, 29, ó sì ṣàlàyé pé Ọlọ́run ò fi ìgbà kankan ní in lọ́kan pé kí àwa èèyan máa kú. Kódà ó sọ pé, kò ní pẹ́ mọ́ tí Ọlọ́run á fi jí àwọn òkú dìde, tí wọn a sì ní ìrètí láti gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Nígbà tí Osman parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ọ̀pọ̀ lára àwọn èèyàn náà gbá a mọ́ra tọ̀yàyà-tọ̀yàyà, wọ́n sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún “ìròyìn ayọ̀ látọ̀dọ̀ Jèhófà” tó bá wọn sọ. Lẹ́yìn náà, ó pa dà sí ìdí àtẹ ìwé.

 Lẹ́yìn ìsìnkú náà, díẹ̀ lára àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ wá sí ìdí àtẹ ìwé, wọ́n sì bi Osman àti ìdílé rẹ̀ làwọn ìbéèrè nípa Bíbélì. Wọ́n jọ sọ̀rọ̀ fún àkókò tó pọ̀ díẹ̀, wọ́n sì fẹ́rẹ̀ẹ́ gba gbogbo ìwé tó wà lórí àtẹ ìwé nígbà tí wọ́n ń lọ.