Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

“Mo Ti Ń Retí Kí Ẹ Pè Mí”

“Mo Ti Ń Retí Kí Ẹ Pè Mí”

 Ọdún 2010 ni Ed àti Jennie ìyàwó ẹ̀ kọ́kọ́ gbìyànjú láti fi fóònù wàásù. a Jennie sọ pé: “Mi ò tiẹ̀ gbádùn ẹ̀ rárá, mo wá sọ fún ọkọ mi pé, ‘Mi ò ní gbìyànjú ẹ̀ mọ́!’” Bó sì ṣe rí lára Ed náà nìyẹn, torí òun náà sọ pe, “Mi ò mọ bó ṣe máa ń rí lára mi táwọn tó ń fi fóònù polówó ọjà bá pè mí, ìyẹn ló jẹ́ kí n máa ronú pé, kí ni àwọn tí mo bá fẹ́ wàásù fún lórí fóònù á máa rò, ńṣe ló ń ṣe mi bákan.”

 Nígbà tí àrùn Kòrónà bẹ̀rẹ̀, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò lè wàásù láti ilé dé ilé mọ́. Àmọ́ torí pé à ń pa àṣẹ Jésù mọ́ pé á gbọ́dọ̀ wàásù, a bẹ̀rẹ̀ sí í fi fóònù àti lẹ́tà wàásù. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Bákan náà, orí Íńtánẹ́ẹ̀tì la ti ń ṣe àwọn ìpàdé wa títí kan ìpàdé iṣẹ́ ìwàásù. Lẹ́yìn ìpàdé iṣẹ́ ìwàásù kan, Ed gbìyànjú láti wàásù látorí fóònù lẹ́ẹ̀kan sí i, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn, ó lo ìgboyà. Ẹ wo bó ṣe máa rí lára Ed nígbà tó fẹ́ pè ẹni àkọ́kọ́. Ó sọ pé: “Ẹ̀rù bà mí gan-an, mo sì bẹ Jèhófà kó ràn mí lọ́wọ́, bí mo ṣe pè báyìí, ẹnì kan gbé e, Tyrone b lorúkọ ẹ̀”

 Ìlú Kentucky, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni Tyrone àti ìyàwó ẹ̀ Edith ń gbé. Ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́rin (83) ni Tyrone, kò sì fi bẹ́ẹ̀ ríran dáadáa. Síbẹ̀, ó gbà kí Ed máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Awò tó ń mú kí ọ̀rọ̀ tóbi ló fi máa ń kàwé. Òun àti Ed sì máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé látorí fóònù.

 Lẹ́yìn oṣù kan, Tyrone ati Edith bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé. Àmọ́ torí pé kò sí Íńtánẹ́ẹ̀tì níbi tí wọ́n ń gbé, wọ́n á pè wọ́n lórí fóònù, wọ́n á sì máa gbọ́ bí ìpàdé ṣe ń lọ. kí lo ru ìfẹ́ Edith sókè fún ẹ̀kọ́ òtítọ́?

 Láwọn ìgbà tí wọ́n bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Tyrone, Ed àti Jennie máa ń gbọ́ bí Edith ṣe ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ bó ṣe ń ran ọkọ ẹ̀ lọ́wọ́ kó lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè àtàwọn ẹsẹ Bíbélì tí wọ́n tọ́ka sí. Àmọ́ gbogbo ohun tó ń ṣe kò jù yẹn náà lọ. Jennie sọ pé: “Mo kíyèsí nínú ohùn Edith pé inú ẹ̀ kì í dùn rárá. Àmọ́ a ò mọ ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀.”

Ed àti Jennie ń wàásù lórí fóònù

 Jennie wá ronú pé ó yẹ kóun bá Edith sọ̀rọ̀. Lọ́jọ́ kan tí wọ́n ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́, ó sọ fún Tyrone pé: “Mò ń gbọ́ ohùn ìyàwó yín lábẹ́lẹ̀, Ṣé wọ́n lè bá wa ka ẹsẹ Bíbélì kan, tàbí kí wọ́n dá sí ohun tá à ń sọ?”

 Ọkọ rẹ̀ wá gbe fóònù fún un, ó dákẹ́ díẹ̀, ó wá fohùn jẹ́jẹ́ sọ pé: “Ó ti pẹ́ tó ti ń wu èmi náà pé kí n bá yín sọ̀rọ̀, Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí tẹ́lẹ̀, ó sì ti tó ogójì (40) ọdún báyìí tí mo ti di aláìṣiṣẹ́mọ́.”

 Ohun tí Jennie gbọ́ yìí yà á lẹ́nu gan-an. Ó wá sọ pé: “À ṣé arábìnrin mi ni yín!” Àwọn méjèèjì sí bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún.

 Nígbà tó yá, Ed fún Edith ní ìwé Jọ̀wọ́ Pa Dà Sọ́dọ̀ Jèhófà. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, Ed àti Jennie rí i pé bí Edith ṣe ń ṣe ti yàtọ̀. Ed sọ pé: “Mo kíyè si pé inú ẹ̀ kì í dùn tẹ́lẹ̀ tó bá ń sọ̀rọ̀, àmọ́ ní báyìí nǹkan ti yàtọ̀.” Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, Edith bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fayọ̀ sin Jèhófà lẹ́ẹ̀kan sí i. Ní July 2022, ọkọ ẹ̀ náà ṣèrìbọmi ó sì di ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

 Nígbà tí Ed ronú nípa bó ṣe máa ń rí lára ẹ̀ láti wàásù lórí fóònù nígbà kan, ó wá rántí ọ̀rọ̀ kan tóun àti Tyrone jọ sọ nígbà tó ka Jòhánù 6:44 tó sì ṣàlàyé fún un pé Jèhófà ló ń fa àwọn èèyàn wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀. Tyrone gbà pé òótọ́ ni, ó sì sọ pé: “Mo ti ń retí kí ẹ pè mí.” Ìdùnnú ṣubú layọ̀ Jennie àti ọkọ ẹ̀ pé àwọn náà kópa nínú ìwàásù orí fóònù. Jennie tiẹ̀ sọ pé “Jèhófà bù kún ìsapá wa.

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣiṣẹ́ ìwàásù wa lọ́nà tó bá òfin mu tó bá kan ọ̀rọ̀ lílo ìsọfúnni ẹlòmíì.

b A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.