Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìwé Jóṣúà

Orí

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí

  • 1

    • Jèhófà fún Jóṣúà níṣìírí (1-9)

      • Máa fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka Òfin (8)

    • Wọ́n ń múra láti sọdá Jọ́dánì (10-18)

  • 2

    • Jóṣúà rán amí méjì lọ sí Jẹ́ríkò (1-3)

    • Ráhábù fi àwọn amí pa mọ́ (4-7)

    • Wọ́n ṣèlérí fún Ráhábù (8-21a)

      • Okùn aláwọ̀ rírẹ̀dòdò máa jẹ́ àmì (18)

    • Àwọn amí pa dà sọ́dọ̀ Jóṣúà (21b-24)

  • 3

    • Ísírẹ́lì sọdá Jọ́dánì (1-17)

  • 4

    • Àwọn òkúta tó máa jẹ́ ohun ìrántí (1-24)

  • 5

    • Wọ́n dádọ̀dọ́ ní Gílígálì (1-9)

    • Wọ́n ṣe Ìrékọjá; mánà ò rọ̀ mọ́ (10-12)

    • Olórí àwọn ọmọ ogun Jèhófà (13-15)

  • 6

    • Ògiri Jẹ́ríkò wó lulẹ̀ (1-21)

    • Wọ́n dá ẹ̀mí Ráhábù àti ìdílé rẹ̀ sí (22-27)

  • 7

    • Wọ́n ṣẹ́gun Ísírẹ́lì ní ìlú Áì (1-5)

    • Àdúrà Jóṣúà (6-9)

    • Ẹ̀ṣẹ̀ mú kí wọ́n ṣẹ́gun Ísírẹ́lì (10-15)

    • Àṣírí Ákánì tú, wọ́n sì sọ ọ́ lókùúta (16-26)

  • 8

    • Jóṣúà ní kí wọ́n lúgọ láti gbéjà ko ìlú Áì (1-13)

    • Wọ́n ṣẹ́gun ìlú Áì (14-29)

    • Wọ́n ka Òfin ní Òkè Ébálì (30-35)

  • 9

    • Àwọn ará Gíbíónì dọ́gbọ́n wá àlàáfíà (1-15)

    • Àṣírí àwọn ará Gíbíónì tú (16-21)

    • Àwọn ará Gíbíónì á máa ṣẹ́gi, wọ́n á sì máa pọnmi (22-27)

  • 10

    • Ísírẹ́lì gbèjà Gíbíónì (1-7)

    • Jèhófà jà fún Ísírẹ́lì (8-15)

      • Òkúta yìnyín já bọ́ lu àwọn ọ̀tá tó ń sá lọ (11)

      • Oòrùn dúró sójú kan (12-14)

    • Wọ́n pa ọba márààrún tó gbéjà kò wọ́n (16-28)

    • Wọ́n gba àwọn ìlú tó wà ní gúúsù (29-43)

  • 11

    • Wọ́n gba àwọn ìlú tó wà ní àríwá (1-15)

    • Àwọn ilẹ̀ tí Jóṣúà ṣẹ́gun (16-23)

  • 12

    • Wọ́n ṣẹ́gun àwọn ọba ìlà oòrùn Jọ́dánì (1-6)

    • Wọ́n ṣẹ́gun àwọn ọba ìwọ̀ oòrùn Jọ́dánì (7-24)

  • 13

    • Àwọn ilẹ̀ tí wọn ò tíì gbà (1-7)

    • Wọ́n pín ilẹ̀ tó wà ní ìlà oòrùn Jọ́dánì (8-14)

    • Ogún Rúbẹ́nì (15-23)

    • Ogún Gádì (24-28)

    • Ogún Mánásè ní ìlà oòrùn (29-32)

    • Jèhófà ni ogún àwọn ọmọ Léfì (33)

  • 14

    • Wọ́n pín ilẹ̀ tó wà ní ìwọ̀ oòrùn Jọ́dánì (1-5)

    • Kélẹ́bù jogún Hébúrónì (6-15)

  • 15

    • Ogún Júdà (1-12)

    • Ọmọbìnrin Kélẹ́bù gba ilẹ̀ (13-19)

    • Àwọn ìlú Júdà (20-63)

  • 16

    • Ogún àwọn àtọmọdọ́mọ Jósẹ́fù (1-4)

    • Ogún Éfúrémù (5-10)

  • 17

    • Ogún Mánásè ní ìwọ̀ oòrùn (1-13)

    • Àwọn àtọmọdọ́mọ Jósẹ́fù tún gba ilẹ̀ míì (14-18)

  • 18

    • Wọ́n pín ilẹ̀ tó kù ní Ṣílò (1-10)

    • Ogún Bẹ́ńjámínì (11-28)

  • 19

    • Ogún Síméónì (1-9)

    • Ogún Sébúlúnì (10-16)

    • Ogún Ísákà (17-23)

    • Ogún Áṣérì (24-31)

    • Ogún Náfútálì (32-39)

    • Ogún Dánì (40-48)

    • Ogún Jóṣúà (49-51)

  • 20

    • Àwọn ìlú ààbò (1-9)

  • 21

    • Àwọn ìlú tí wọ́n fún àwọn ọmọ Léfì (1-42)

      • Ìlú àwọn àtọmọdọ́mọ Áárónì (9-19)

      • Ìlú àwọn ọmọ Kóhátì yòókù (20-26)

      • Ìlú àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì (27-33)

      • Ìlú àwọn ọmọ Mérárì (34-40)

    • Àwọn ìlérí Jèhófà ṣẹ (43-45)

  • 22

    • Àwọn ẹ̀yà tó wà ní ìlà oòrùn pa dà sílé (1-8)

    • Wọ́n mọ pẹpẹ sí Jọ́dánì (9-12)

    • Wọ́n ṣàlàyé ohun tí pẹpẹ náà túmọ̀ sí (13-29)

    • Wọ́n yanjú ọ̀rọ̀ náà (30-34)

  • 23

    • Jóṣúà sọ̀rọ̀ ìdágbére fún àwọn olórí Ísírẹ́lì (1-16)

      • Ìkankan nínú ọ̀rọ̀ Jèhófà ò kùnà (14)

  • 24

    • Jóṣúà sọ ìtàn Ísírẹ́lì (1-13)

    • Ó rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n sin Jèhófà (14-24)

      • “Ní tèmi àti agbo ilé mi, Jèhófà ni àwa yóò máa sìn” (15)

    • Jóṣúà bá Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú (25-28)

    • Jóṣúà kú, wọ́n sì sin ín (29-31)

    • Wọ́n sin egungun Jósẹ́fù sí Ṣékémù (32)

    • Élíásárì kú, wọ́n sì sin ín (33)