Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìwé Hósíà

Orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí

  • 1

    • Ìyàwó Hósíà àti àwọn ọmọ tó bí (1-9)

      • Jésírẹ́lì (4), Lo-ruhámà (6), àti Lo-ámì (9)

    • Ìmúbọ̀sípò àti ìṣọ̀kan ń bọ̀ (10, 11)

  • 2

    • Ọlọ́run fìyà jẹ Ísírẹ́lì aláìṣòótọ́ (1-13)

    • Ó pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà ọkọ rẹ̀ (14-23)

      • “Ọkọ Mi ni wàá máa pè mí” (16)

  • 3

    • Hósíà gba ìyàwó rẹ̀ alágbèrè pa dà (1-3)

    • Ísírẹ́lì máa pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà (4, 5)

  • 4

    • Jèhófà pe Ísírẹ́lì lẹ́jọ́ (1-8)

      • Kò sí ìmọ̀ Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà (1)

    • Ísírẹ́lì bọ̀rìṣà, ó sì ṣe ìṣekúṣe (9-19)

      • Ẹ̀mí ìṣekúṣe mú kí wọ́n ṣìnà (12)

  • 5

    • Éfúrémù àti Júdà gba ìdájọ́ (1-15)

  • 6

    • Ẹ jẹ́ ká pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà (1-3)

    • Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí àwọn èèyàn náà ní tètè ń pòórá (4-6)

      • Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sàn ju ẹbọ lọ (6)

    • Ìwà àìnítìjú tí àwọn èèyàn náà hù (7-11)

  • 7

    • Àpèjúwe nípa ìwà ibi Éfúrémù (1-16)

      • Kò sí ọ̀nà àbáyọ nínú àwọ̀n Ọlọ́run (12)

  • 8

    • Wọ́n jìyà torí pé wọ́n bọ̀rìṣà (1-14)

      • Wọ́n gbin afẹ́fẹ́, wọ́n sì ká ìjì (7)

      • Ísírẹ́lì ti gbàgbé Ẹni tó dá a (14)

  • 9

    • Ẹ̀ṣẹ̀ Éfúrémù mú kí Ọlọ́run kọ̀ ọ́ (1-17)

      • Wọ́n fi ara wọn fún ọlọ́run tó ń tini lójú (10)

  • 10

    • Ísírẹ́lì jẹ́ igi àjàrà tí kò dáa, ó máa pa run (1-15)

      • Fífúnrúgbìn àti kíkórè (12, 13)

  • 11

    • Ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí Ísírẹ́lì láti ìgbà tó wà lọ́mọdé (1-12)

      • ‘Láti Íjíbítì ni mo ti pe ọmọkùnrin mi’ (1)

  • 12

    • Éfúrémù ní láti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà (1-14)

      • Jékọ́bù bá Ọlọ́run jà (3)

      • Jékọ́bù sunkún kó lè rí ojú rere Ọlọ́run (4)

  • 13

    • Éfúrémù abọ̀rìṣà gbàgbé Jèhófà (1-16)

      • “Ìwọ Ikú, oró rẹ dà?” (14)

  • 14

    • Hósíà bẹ̀ wọ́n pé kí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà (1-3)

      • Ẹ fi ètè rú ẹbọ ìyìn (2)

    • Ísírẹ́lì aláìṣòótọ́ máa gba ìwòsàn (4-9)