Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìwé Àwọn Ọba Kejì

Orí

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí

  • 1

    • Èlíjà sọ tẹ́lẹ̀ pé Ahasáyà máa kú (1-18)

  • 2

    • Ọlọ́run fi ìjì gbé Èlíjà lọ sókè (1-18)

      • Èlíṣà rí ẹ̀wù Èlíjà gbà (13, 14)

    • Èlíṣà wo omi Jẹ́ríkò sàn (19-22)

    • Àwọn bíárì pa àwọn ọmọdékùnrin tó jáde wá láti Bẹ́tẹ́lì (23-25)

  • 3

    • Jèhórámù di ọba Ísírẹ́lì (1-3)

    • Móábù ṣọ̀tẹ̀ sí Ísírẹ́lì (4-25)

    • Wọ́n ṣẹ́gun Móábù (26, 27)

  • 4

    • Èlíṣà sọ òróró opó kan di púpọ̀ (1-7)

    • Obìnrin ará Ṣúnémù ṣe àlejò (8-16)

    • Obìnrin kan rí ọmọ bí; ọmọ náà kú (17-31)

    • Èlíṣà jí ọmọ tó kú dìde (32-37)

    • Èlíṣà mú kí ọbẹ̀ kan ṣeé jẹ (38-41)

    • Èlíṣà sọ búrẹ́dì di púpọ̀ (42-44)

  • 5

    • Èlíṣà wo ẹ̀tẹ̀ Náámánì sàn (1-19)

    • Ẹ̀tẹ̀ kọ lu Géhásì olójúkòkòrò (20-27)

  • 6

    • Èlíṣà mú kí irin àáké léfòó (1-7)

    • Èlíṣà àti àwọn ará Síríà (8-23)

      • Ojú ìránṣẹ́ Èlíṣà là (16, 17)

      • Ojú inú àwọn ará Síríà fọ́ (18, 19)

    • Ìyàn mú ní Samáríà nígbà tí wọ́n dó tì í (24-33)

  • 7

    • Èlíṣà sọ tẹ́lẹ̀ pé ìyàn máa dópin (1, 2)

    • Wọ́n rí oúnjẹ ní ibùdó tí àwọn ará Síríà ti sá kúrò (3-15)

    • Àsọtẹ́lẹ̀ Èlíṣà ṣẹ (16-20)

  • 8

    • Wọ́n dá ilẹ̀ obìnrin ará Ṣúnémù pa dà fún un (1-6)

    • Èlíṣà, Bẹni-hádádì àti Hásáẹ́lì (7-15)

    • Jèhórámù di ọba Júdà (16-24)

    • Ahasáyà di ọba Júdà (25-29)

  • 9

    • Wọ́n fòróró yan Jéhù ṣe ọba lórí Ísírẹ́lì (1-13)

    • Jéhù pa Jèhórámù àti Ahasáyà (14-29)

    • Wọ́n pa Jésíbẹ́lì; àwọn ajá jẹ ẹran ara rẹ̀ (30-37)

  • 10

    • Jéhù pa agbo ilé Áhábù (1-17)

      • Jèhónádábù dara pọ̀ mọ́ Jéhù (15-17)

    • Jéhù pa àwọn olùjọ́sìn Báálì (18-27)

    • Àkópọ̀ ìṣàkóso Jéhù (28-36)

  • 11

    • Ataláyà fi ipá gba ìtẹ́ (1-3)

    • Wọ́n fi Jèhóáṣì jọba ní bòókẹ́lẹ́ (4-12)

    • Wọ́n pa Ataláyà (13-16)

    • Àwọn àtúnṣe tí Jèhóádà ṣe (17-21)

  • 12

    • Jèhóáṣì di ọba Júdà (1-3)

    • Jèhóáṣì tún tẹ́ńpìlì ṣe (4-16)

    • Àwọn ará Síríà gbógun wá (17, 18)

    • Wọ́n pa Jèhóáṣì (19-21)

  • 13

    • Jèhóáhásì di ọba Ísírẹ́lì (1-9)

    • Jèhóáṣì di ọba Ísírẹ́lì (10-13)

    • Èlíṣà dán ìtara Jèhóáṣì wò (14-19)

    • Ikú Èlíṣà; egungun rẹ̀ jí ọkùnrin kan dìde (20, 21)

    • Àsọtẹ́lẹ̀ tí Èlíṣà sọ kẹ́yìn ṣẹ (22-25)

  • 14

    • Amasááyà di ọba Júdà (1-6)

    • Ó bá Édómù àti Ísírẹ́lì jà (7-14)

    • Ikú Jèhóáṣì ọba Ísírẹ́lì (15, 16)

    • Ikú Amasááyà (17-22)

    • Jèróbóámù Kejì di ọba Ísírẹ́lì (23-29)

  • 15

    • Asaráyà di ọba Júdà (1-7)

    • Àwọn ọba tó jẹ kẹ́yìn ní Ísírẹ́lì: Sekaráyà (8-12), Ṣálúmù (13-16), Ménáhémù (17-22), Pekaháyà (23-26), Pékà (27-31)

    • Jótámù di ọba Júdà (32-38)

  • 16

    • Áhásì di ọba Júdà (1-6)

    • Áhásì fún àwọn ará Ásíríà ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀ (7-9)

    • Áhásì ṣe irú pẹpẹ àwọn abọ̀rìṣà (10-18)

    • Ikú Áhásì (19, 20)

  • 17

    • Hóṣéà di ọba Ísírẹ́lì (1-4)

    • Wọ́n ṣẹ́gun Ísírẹ́lì (5, 6)

    • Ísírẹ́lì lọ sí ìgbèkùn nítorí pé ó di apẹ̀yìndà (7-23)

    • Wọ́n kó àwọn àjèjì wá sí àwọn ìlú Samáríà (24-26)

    • Àwọn ará Samáríà ń ṣe oríṣiríṣi ẹ̀sìn (27-41)

  • 18

    • Hẹsikáyà di ọba Júdà (1-8)

    • Bí wọ́n ṣe ṣẹ́gun Ísírẹ́lì (9-12)

    • Senakérúbù wá gbéjà ko Júdà (13-18)

    • Rábúṣákè pẹ̀gàn Jèhófà (19-37)

  • 19

    • Hẹsikáyà wá ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run lọ́dọ̀ Àìsáyà (1-7)

    • Senakérúbù halẹ̀ mọ́ Jerúsálẹ́mù (8-13)

    • Àdúrà Hẹsikáyà (14-19)

    • Àìsáyà sọ ìdáhùn Ọlọ́run fún un (20-34)

    • Áńgẹ́lì pa 185,000 àwọn ará Ásíríà (35-37)

  • 20

    • Àìsàn Hẹsikáyà àti bí ara rẹ̀ ṣe yá (1-11)

    • Àwọn òjíṣẹ́ láti Bábílónì (12-19)

    • Ikú Hẹsikáyà (20, 21)

  • 21

    • Mánásè di ọba Júdà; ó ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ (1-18)

      • Wọ́n máa pa Jerúsálẹ́mù run (12-15)

    • Ámọ́nì di ọba Júdà (19-26)

  • 22

    • Jòsáyà di ọba Júdà (1, 2)

    • Bí wọ́n ṣe máa tún tẹ́ńpìlì ṣe (3-7)

    • Wọ́n rí ìwé Òfin (8-13)

    • Húlídà sọ tẹ́lẹ̀ pé àjálù máa ṣẹlẹ̀ (14-20)

  • 23

    • Àwọn àtúnṣe tí Jòsáyà ṣe (1-20)

    • Wọ́n ṣe Ìrékọjá (21-23)

    • Àwọn àtúnṣe míì tí Jòsáyà ṣe (24-27)

    • Ikú Jòsáyà (28-30)

    • Jèhóáhásì di ọba Júdà (31-33)

    • Jèhóákímù di ọba Júdà (34-37)

  • 24

    • Jèhóákímù ṣọ̀tẹ̀, ó sì kú (1-7)

    • Jèhóákínì di ọba Júdà (8, 9)

    • Ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n kó wọn lọ sí Bábílónì (10-17)

    • Sedekáyà di ọba Júdà; ó ṣọ̀tẹ̀ (18-20)

  • 25

    • Nebukadinésárì dó ti Jerúsálẹ́mù (1-7)

    • Ìparun Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀; wọ́n kó wọn lọ nígbà kejì (8-21)

    • Wọ́n fi Gẹdaláyà ṣe gómìnà (22-24)

    • Wọ́n pa Gẹdaláyà; àwọn èèyàn sá lọ sí Íjíbítì (25, 26)

    • Wọ́n tú Jèhóákínì sílẹ̀ ní Bábílónì (27-30)