Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìwé Ìsíkíẹ́lì

Orí

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí

  • 1

    • Ìsíkíẹ́lì wà ní Bábílónì, ó ń rí ìran látọ̀dọ̀ Ọlọ́run (1-3)

    • Ìran kẹ̀kẹ́ ẹṣin Jèhófà tó wà lọ́run (4-28)

      • Ìjì líle, ìkùukùu àti iná (4)

      • Ẹ̀dá alààyè mẹ́rin (5-14)

      • Àgbá kẹ̀kẹ́ mẹ́rin (15-21)

      • Ohun kan tó tẹ́ pẹrẹsẹ, tó ń tàn yinrin bíi yìnyín (22-24)

      • Ìtẹ́ Jèhófà (25-28)

  • 2

    • Ọlọ́run sọ Ìsíkíẹ́lì di wòlíì (1-10)

      • “Bóyá wọ́n gbọ́ tàbí wọn ò gbọ́” (5)

      • Ó rí àkájọ ìwé tí orin arò wà nínú rẹ̀ (9, 10)

  • 3

    • Ọlọ́run ní kí Ìsíkíẹ́lì jẹ àkájọ ìwé tó fún un (1-15)

    • Ìsíkíẹ́lì máa ṣe olùṣọ́ (16-27)

      • Tí kò bá kìlọ̀, yóò jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ (18-21)

  • 4

    • Bí wọ́n ṣe máa dó ti Jerúsálẹ́mù (1-17)

      • Ó ru ẹ̀bi fún 390 ọjọ́ àti 40 ọjọ́ (4-7)

  • 5

    • Bí Jerúsálẹ́mù ṣe máa pa run (1-17)

      • Wòlíì pín irun rẹ̀ tó fá sí ọ̀nà mẹ́ta (1-4)

      • Ìwà Jerúsálẹ́mù burú ju ti àwọn orílẹ̀-èdè lọ (7-9)

      • Ìyà mẹ́ta tó máa jẹ àwọn ọlọ̀tẹ̀ (12)

  • 6

    • Ọlọ́run yóò bá àwọn òkè Ísírẹ́lì jà (1-14)

      • Ọlọ́run máa rẹ àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wálẹ̀ (4-6)

      • ‘Ẹ ó wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà’ (7)

  • 7

    • Òpin ti dé (1-27)

      • Àjálù tó ṣàrà ọ̀tọ̀ (5)

      • Wọ́n ju owó sí ojú ọ̀nà (19)

      • Wọ́n á sọ tẹ́ńpìlì di aláìmọ́ (22)

  • 8

    • Wọ́n gbé Ìsíkíẹ́lì lọ sí Jerúsálẹ́mù nínú ìran (1-4)

    • Ó rí àwọn ohun ìríra nínú tẹ́ńpìlì (5-18)

      • Àwọn obìnrin ń sunkún torí Támúsì (14)

      • Àwọn ọkùnrin ń forí balẹ̀ fún oòrùn (16)

  • 9

    • Àwọn ọkùnrin mẹ́fà tó ń pààyàn àti ọkùnrin kan tó ní ìwo yíǹkì (1-11)

      • Ìdájọ́ máa bẹ̀rẹ̀ ní ibi mímọ́ (6)

  • 10

    • Wọ́n mú iná láàárín àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà (1-8)

    • Bí àwọn kérúbù àti àgbá kẹ̀kẹ́ náà ṣe rí (9-17)

    • Ògo Ọlọ́run kúrò ní tẹ́ńpìlì náà (18-22)

  • 11

    • Ọlọ́run dá àwọn ìjòyè burúkú lẹ́jọ́ (1-13)

      • Wọ́n fi ìlú wé ìkòkò oúnjẹ (3-12)

    • Ọlọ́run ṣèlérí pé wọ́n á pa dà sílé (14-21)

      • Ọlọ́run fún wọn ní “ẹ̀mí tuntun” (19)

    • Ògo Ọlọ́run kúrò ní Jerúsálẹ́mù (22, 23)

    • Ìsíkíẹ́lì pa dà sí Kálídíà nínú ìran (24, 25)

  • 12

    • Ó fi àwọn àmì sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n á lọ sígbèkùn (1-20)

      • Ẹrù ìgbèkùn (1-7)

      • Ìjòyè yóò lọ nínú òkùnkùn (8-16)

      • Wọ́n jẹ búrẹ́dì láìní ìfọ̀kànbalẹ̀, wọ́n mu omi pẹ̀lú ìbẹ̀rù (17-20)

    • Ọlọ́run sọ pé irọ́ ni ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn wọn (21-28)

      • “Kò sí èyí tó máa falẹ̀ nínú gbogbo ọ̀rọ̀ mi” (28)

  • 13

    • Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn wòlíì èké (1-16)

      • Àwọn ògiri tí wọ́n kùn ní ẹfun yóò wó (10-12)

    • Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn obìnrin tó jẹ́ wòlíì èké (17-23)

  • 14

    • Ọlọ́run dá àwọn abọ̀rìṣà lẹ́jọ́ (1-11)

    • Jerúsálẹ́mù ò ní yè bọ́ lọ́wọ́ ìdájọ́ (12-23)

      • Nóà, Dáníẹ́lì àti Jóòbù tó jẹ́ olódodo (14, 20)

  • 15

    • Àjàrà tí kò wúlò ni Jerúsálẹ́mù (1-8)

  • 16

    • Ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí Jerúsálẹ́mù (1-63)

      • Ọlọ́run rí i níbi tí wọ́n jù ú sí bí ọmọ kékeré (1-7)

      • Ọlọ́run ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́, ó sì bá a dá májẹ̀mú ìgbéyàwó (8-14)

      • Ó di oníwàkiwà (15-34)

      • Ó jìyà tó tọ́ sí alágbèrè obìnrin (35-43)

      • Ọlọ́run fi í wé Samáríà àti Sódómù (44-58)

      • Ọlọ́run rántí májẹ̀mú rẹ̀ (59-63)

  • 17

    • Àlọ́ nípa ẹyẹ idì méjì àti àjàrà (1-21)

    • Ọ̀mùnú yóò di igi kédárì ńlá (22-24)

  • 18

    • Kálukú ló máa jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ (1-32)

      • Ọkàn tó bá ṣẹ̀ ni yóò kú (4)

      • Ọmọ ò ní jìyà torí ẹ̀ṣẹ̀ bàbá rẹ̀ (19, 20)

      • Inú rẹ̀ kì í dùn sí ikú ẹni burúkú (23)

      • Ìrònúpìwàdà máa ń mú kéèyàn wà láàyè (27, 28)

  • 19

    • Orin arò torí àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì (1-14)

  • 20

    • Ìtàn nípa bí Ísírẹ́lì ṣe ṣọ̀tẹ̀ (1-32)

    • Ọlọ́run ṣèlérí pé òun yóò dá Ísírẹ́lì pa dà sórí ilẹ̀ wọn (33-44)

    • Sọ tẹ́lẹ̀ nípa gúúsù (45-49)

  • 21

    • Ọlọ́run fa idà tó fẹ́ fi ṣèdájọ́ yọ nínú àkọ̀ (1-17)

    • Ọba Bábílónì máa gbéjà ko Jerúsálẹ́mù (18-24)

    • Ọlọ́run máa mú ìjòyè burúkú Ísírẹ́lì kúrò (25-27)

      • “Ṣí adé” (26)

      • “Títí ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ sí i lọ́nà òfin fi máa dé” (27)

    • Idà yóò bá àwọn ọmọ Ámónì jà (28-32)

  • 22

    • Jerúsálẹ́mù, ìlú tó jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ (1-16)

    • Ísírẹ́lì dà bí ìdàrọ́ tí kò wúlò (17-22)

    • Ọlọ́run bá àwọn aṣáájú àti àwọn èèyàn Ísírẹ́lì wí (23-31)

  • 23

    • Ẹ̀gbọ́n àti àbúrò tí wọ́n di oníwàkiwà (1-49)

      • Òhólà bá Ásíríà ṣèṣekúṣe (5-10)

      • Òhólíbà bá Bábílónì àti Íjíbítì ṣèṣekúṣe (11-35)

      • Ìyà máa jẹ ẹ̀gbọ́n àti àbúrò náà (36-49)

  • 24

    • Jerúsálẹ́mù dà bí ìkòkò oúnjẹ tó ti dípẹtà (1-14)

    • Ikú ìyàwó Ìsíkíẹ́lì jẹ́ àmì (15-27)

  • 25

    • Sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí Ámónì (1-7)

    • Sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí Móábù (8-11)

    • Sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí Édómù (12-14)

    • Sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí Filísíà (15-17)

  • 26

    • Sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí Tírè (1-21)

      • “Ibi tí wọ́n ń sá àwọ̀n sí láàárín òkun” (5, 14)

      • Wọ́n da òkúta àti iyẹ̀pẹ̀ sínú omi (12)

  • 27

    • Orin arò nípa ọkọ̀ òkun Tírè tó ń rì (1-36)

  • 28

    • Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ọba Tírè (1-10)

      • Ó ń sọ pé “ọlọ́run ni mí” (2, 9)

    • Orin arò nípa ọba Tírè (11-19)

      • “O wà ní Édẹ́nì” (13)

      • “Kérúbù aláàbò tí mo fòróró yàn” (14)

      • ‘O di aláìṣòdodo’ (15)

    • Sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí Sídónì (20-24)

    • Ọlọ́run yóò tún kó Ísírẹ́lì jọ (25, 26)

  • 29

    • Sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí Fáráò (1-16)

    • Ọlọ́run yóò fi Íjíbítì ṣe èrè fún Bábílónì (17-21)

  • 30

    • Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí Íjíbítì (1-19)

      • Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé Nebukadinésárì máa gbógun wá (10)

    • Ọlọ́run fòpin sí agbára Fáráò (20-26)

  • 31

    • Ìṣubú Íjíbítì, igi kédárì tó ga fíofío (1-18)

  • 32

    • Orin arò nípa Fáráò àti Íjíbítì (1-16)

    • Wọ́n á sin Íjíbítì pẹ̀lú àwọn aláìdádọ̀dọ́ (17-32)

  • 33

    • Iṣẹ́ olùṣọ́ (1-20)

    • Ìròyìn ìparun Jerúsálẹ́mù (21, 22)

    • Ọlọ́run rán ẹnì kan sí àwọn tó ń gbé inú àwókù (23-29)

    • Àwọn èèyàn ò ṣe ohun tí wọ́n gbọ́ (30-33)

      • Ìsíkíẹ́lì “dà bí orin ìfẹ́” (32)

      • “Wòlíì kan ti wà láàárín wọn” (33)

  • 34

    • Sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí àwọn olùṣọ́ àgùntàn Ísírẹ́lì (1-10)

    • Jèhófà ń bójú tó àwọn àgùntàn rẹ̀ (11-31)

      • “Dáfídì ìránṣẹ́ mi” yóò máa bójú tó wọn (23)

      • “Májẹ̀mú àlàáfíà” (25)

  • 35

    • Sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí àwọn òkè Séírì (1-15)

  • 36

    • Sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí àwọn òkè Ísírẹ́lì (1-15)

    • Ọlọ́run yóò pa dà kó Ísírẹ́lì jọ (16-38)

      • “Màá sọ orúkọ ńlá mi di mímọ́” (23)

      • “Bí ọgbà Édẹ́nì” (35)

  • 37

    • Ìran àfonífojì tí egungun gbígbẹ kún inú rẹ̀ (1-14)

    • Igi méjì yóò wà pa pọ̀ (15-28)

      • Ọba kan yóò máa ṣàkóso wọn bí orílẹ̀-èdè kan (22)

      • Májẹ̀mú àlàáfíà tí yóò wà títí ayérayé (26)

  • 38

    • Gọ́ọ̀gù gbógun ja Ísírẹ́lì (1-16)

    • Jèhófà yóò bínú sí Gọ́ọ̀gù (17-23)

      • ‘Àwọn orílẹ̀-èdè á wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà’ (23)

  • 39

    • Gọ́ọ̀gù àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ yóò pa run (1-10)

    • Wọ́n á sìnkú sí Àfonífojì Hamoni-Gọ́ọ̀gù (11-20)

    • Ọlọ́run yóò pa dà kó Ísírẹ́lì jọ (21-29)

      • Ọlọ́run yóò tú ẹ̀mí rẹ̀ sórí Ísírẹ́lì (29)

  • 40

    • Ọlọ́run mú Ìsíkíẹ́lì wá sí Ísírẹ́lì nínú ìran (1, 2)

    • Ìsíkíẹ́lì rí tẹ́ńpìlì nínú ìran (3, 4)

    • Àwọn àgbàlá àti àwọn ẹnubodè (5-47)

      • Ẹnubodè ìlà oòrùn tó wà níta (6-16)

      • Àgbàlá ìta; àwọn ẹnubodè míì (17-26)

      • Àgbàlá inú àti àwọn ẹnubodè (27-37)

      • Àwọn yàrá tí wọ́n ń lò fún iṣẹ́ tẹ́ńpìlì (38-46)

      • Pẹpẹ (47)

    • Ibi àbáwọlé tẹ́ńpìlì (48, 49)

  • 41

    • Ibi mímọ́ tẹ́ńpìlì (1-4)

    • Ògiri àti àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ (5-11)

    • Ilé tó wà ní ìwọ̀ oòrùn (12)

    • Ó wọn àwọn ilé náà (13-15a)

    • Inú ibi mímọ́ (15b-26)

  • 42

    • Àwọn ilé tó ní yàrá ìjẹun (1-14)

    • Ó wọn ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tẹ́ńpìlì náà (15-20)

  • 43

    • Ògo Jèhófà kún inú tẹ́ńpìlì náà (1-12)

    • Pẹpẹ (13-27)

  • 44

    • Ẹnubodè ìlà oòrùn yóò wà ní títì pa (1-3)

    • Ìlànà Ọlọ́run nípa àwọn àjèjì (4-9)

    • Ìlànà tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Léfì àti àwọn àlùfáà (10-31)

  • 45

    • Ilẹ̀ mímọ́ tí wọ́n mú wá láti fi ṣe ọrẹ àti ìlú náà (1-6)

    • Ilẹ̀ ìjòyè (7, 8)

    • Kí àwọn ìjòyè jẹ́ olóòótọ́ (9-12)

    • Ọrẹ tí àwọn èèyàn mú wá àti ìjòyè (13-25)

  • 46

    • Àwọn ọrẹ tí wọ́n á mú wá láwọn ọjọ́ pàtàkì kan (1-15)

    • Ohun ìní tí ìjòyè fi ṣe ogún fúnni (16-18)

    • Àwọn ibi tí wọ́n á ti máa se ọrẹ (19-24)

  • 47

    • Omi tó ń ṣàn láti tẹ́ńpìlì (1-12)

      • Omi ń jìn sí i (2-5)

      • Omi Òkun Òkú rí ìwòsàn (8-10)

      • Àwọn irà ò rí ìwòsàn (11)

      • Igi tó ń so èso fún jíjẹ àti ìwòsàn (12)

    • Àwọn ààlà ilẹ̀ náà (13-23)

  • 48

    • Wọ́n pín ilẹ̀ náà (1-29)

    • Àwọn ẹnubodè méjìlá tó wà ní ìlú náà (30-35)

      • Orúkọ ìlú náà yóò jẹ́ “Jèhófà Wà Níbẹ̀” (35)