Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ KEJÌ

Ó “Bá Ọlọ́run Tòótọ́ Rìn”

Ó “Bá Ọlọ́run Tòótọ́ Rìn”

1, 2. Iṣẹ́ wo ni Nóà àti ìdílé rẹ̀ ń ṣe, àwọn ìṣòro wo ni wọ́n sì bá pàdé?

NÓÀ dáwọ́ dúró díẹ̀ láti na ẹ̀yìn àti àwọn iṣan rẹ̀ tó ti ń ro ó. Fojú inú wò ó bó ṣe jókòó lé òpó igi ńlá kan, tó ń sinmi, tó sì ń wo bí iṣẹ́ áàkì ràgàjì náà ṣe ń lọ sí. Òórùn ọ̀dà bítúmẹ́nì gbígbóná gbalẹ̀ kan, ìró irinṣẹ́ sì ń dún kíkankíkan. Níbi tí Nóà jókòó sí, ó ń rí bí àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe ń ṣiṣẹ́ lọ ní pẹrẹu, tí kálukú wọn ń ṣe onírúurú iṣẹ́ lára àwọn òpó ńláńlá tí wọ́n fi kan áàkì náà. Òun àti aya rẹ̀ ọ̀wọ́n, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìyàwó wọn ti ń bá iṣẹ́ áàkì yìí bọ̀ láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn. Wọ́n ti bá iṣẹ́ yìí jìnnà, àmọ́ èyí tó kù ṣì pọ̀ gan-an!

2 Àwọn èèyàn àgbègbè ibẹ̀ rò pé òmùgọ̀ ni Nóà àti ìdílé rẹ̀. Bí iṣẹ́ náà ṣe ń lọ, tí àwọn èèyàn ń rí bí áàkì náà ṣe rí lóòótọ́, wọ́n túbọ̀ ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ pé, kí ni wọ́n tiẹ̀ rò débi pé ìkún-omi ń bọ̀ wá bo gbogbo ayé? Lójú wọn, ìparun tí Nóà ń kìlọ̀ fún wọn nípa rẹ̀ dà bí àlá tí kò lè ṣẹ, àní ohun tí kò tiẹ̀ bọ́gbọ́n mu rárá! Ṣe ló ń ṣe wọ́n ní kàyéfì pé, ọkùnrin kan ń fi ayé rẹ̀ àti ti ìdílé rẹ̀ ṣòfò lórí iṣẹ́ tí kò bọ́gbọ́n mu bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n Jèhófà, Ọlọ́run tí Nóà ń sìn, kò ka Nóà sí òmùgọ̀ o.

3. Báwo ni Nóà ṣe bá Ọlọ́run rìn?

3 Ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ni pé: “Nóà bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn.” (Ka Jẹ́nẹ́sísì 6:9.) Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Kì í ṣe pé Ọlọ́run fìgbà kan rìn lórí ilẹ̀ ayé rí, tàbí pé Nóà gòkè lọ sí ọ̀run lọ́nà kan ṣá. Ṣe ni Nóà ṣègbọràn sí Ọlọ́run délẹ̀délẹ̀, ó sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tọkàntọkàn, tó fi wá dà bíi pé òun àti Jèhófà jọ ń rìn bí ọ̀rẹ́. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún lẹ́yìn náà, Bíbélì sọ nípa Nóà pé: “Nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ [rẹ̀], ó dá ayé lẹ́bi.” (Héb. 11:7) Báwo ló ṣe dá ayé lẹ́bi nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ rẹ̀? Ẹ̀kọ́ wo ni àwa tá a wà láyé lónìí lè rí kọ́ nínú ìgbàgbọ́ rẹ̀?

Ó Jẹ́ Oníwà Mímọ́ Nínú Ayé Oníwà Burúkú

4, 5. Kí ló mú kí ayé túbọ̀ burú nígbà ayé Nóà?

4 Inú ayé tó túbọ̀ ń burú sí i ni Nóà dàgbà sí. Kódà, ayé ti bà jẹ́ nígbà ayé Énọ́kù pàápàá, ìyẹn bàbá tó bí baba ńlá Nóà, tóun náà jẹ́ olódodo, tó sì bá Ọlọ́run rìn. Nígbà yẹn, Énọ́kù tiẹ̀ sọ tẹ́lẹ̀ pé ọjọ́ ìdájọ́ ń bọ̀ wá bá àwọn èèyàn burúkú tó wà láyé. Nígbà tó sì fi máa di ìgbà ayé Nóà, ìwà ibi ti pọ̀ lápọ̀jù. Àní lójú Jèhófà, ilẹ̀ ayé ti bà jẹ́ pátápátá, torí pé ṣe ni ìwà ipá kún inú rẹ̀ bámúbámú. (Jẹ́n. 5:22; 6:11; Júúdà 14, 15) Kí ló fà á tí nǹkan fi wá burú tó bẹ́ẹ̀?

5 Nǹkan burúkú kan ló jẹ yọ láàárín àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, ìyẹn àwọn áńgẹ́lì. Ọ̀kan lára wọn ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà, ó wá di Sátánì Èṣù torí pé ó ba Ọlọ́run lórúkọ jẹ́, ó sì tan Ádámù àti Éfà sínú ẹ̀ṣẹ̀. Nígbà ayé Nóà, àwọn áńgẹ́lì míì bá Sátánì lẹ̀dí àpò pọ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà tó ń ṣàkóso lọ́nà tó tọ́. Wọ́n pa iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún wọn ní ọ̀run tì, wọ́n wá sí ayé, wọ́n sì gbé àwọ̀ èèyàn wọ̀, wọ́n wá ń fi àwọn arẹwà obìnrin ṣe aya. Àwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ àti agbéraga, tó jẹ́ pé tara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀ yìí, wá kó ìwà ibi ran aráyé.—Jẹ́n. 6:1, 2; Júúdà 6, 7.

6. Àkóbá wo làwọn Néfílímù ṣe ní ayé, kí ni Jèhófà sì pinnu láti ṣe?

6 Yàtọ̀ sí èyí, àwọn áńgẹ́lì tó gbé àwọ̀ èèyàn wọ̀ yìí ń bá àwọn obìnrin lò pọ̀, èyí tó lòdì sí irú ẹ̀dá tí Ọlọ́run dá wọn. Àwọn obìnrin yìí sì wá ń bí àwọn àdàmọ̀dì ọmọ tó jẹ́ òmìrán, tí agbára wọn bùáyà. Bíbélì pe àwọn òmìrán yìí ní Néfílímù, èyí tó túmọ̀ sí “Abiniṣubú.” Ìkà paraku ni wọ́n, wọ́n sì túbọ̀ jẹ́ kí ìwà tó burú jáì pàpọ̀jù láyé. Abájọ tí Ẹlẹ́dàá fi wò ó pé “ìwà búburú ènìyàn pọ̀ yanturu ní ilẹ̀ ayé, gbogbo ìtẹ̀sí ìrònú ọkàn-àyà rẹ̀ sì jẹ́ kìkì búburú ní gbogbo ìgbà.” Jèhófà wá pinnu pé òun máa pa àwọn èèyàn burúkú yẹn run ní ọgọ́fà [120] ọdún sí ìgbà yẹn.—Ka Jẹ́nẹ́sísì 6:3-5.

7. Kí ni kò ní jẹ́ kó rọrùn fún Nóà àti aya rẹ̀ láti tọ́ àwọn ọmọ wọn kí ìwà ibi ayé ìgbà yẹn má bàa ràn wọ́n?

7 Ẹ wo bó ṣe máa nira tó fún òbí láti tọ́ ọmọ yanjú nínú irú ayé bẹ́ẹ̀! Síbẹ̀, Nóà tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ yanjú. Lákọ̀ọ́kọ́, ó wá aya rere fẹ́. Lẹ́yìn tó sì di ẹni ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ọdún, aya rẹ̀ bí ọmọkùnrin mẹ́ta fún un. * Orúkọ wọn ni Ṣémù, Hámù àti Jáfẹ́tì. Nóà àti aya rẹ̀ jọ sapá gan-an láti tọ́ àwọn ọmọ wọn lọ́nà tí ìwà ibi tó gbòde kan kò fi ní ràn wọ́n. Bí ẹ ṣe mọ̀, tí àwọn ọmọdékùnrin bá rí àwọn “alágbára ńlá” àti “àwọn ọkùnrin olókìkí,” ó máa ń jọ wọ́n lójú gan-an, ó sì máa ń wù wọ́n. Nígbà tó sì jẹ́ pé irú èèyàn bẹ́ẹ̀ ni àwọn Néfílímù, àwọn ọmọdékùnrin á fẹ́ máa fi wọ́n ṣèran wò. Kò sí bí Nóà àti aya rẹ̀ ṣe lè gbìyànjú tó tí àwọn ọmọ wọn kò ní máa gbọ́ ìròyìn nípa itú tí àwọn òmìrán wọ̀nyẹn ń pa. Àmọ́, wọ́n lè kọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó fani mọ́ra nípa Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tó kórìíra gbogbo ìwà ibi pátá. Wọ́n ní láti jẹ́ kó yé àwọn ọmọ wọn pé ìwà ipá àti ọ̀tẹ̀ tó kún inú ayé nígbà yẹn ń dun Jèhófà gan-an.—Jẹ́n. 6:6.

Nóà àti aya rẹ̀ ní láti sapá gan-an kí ìwà ibi tó gbòde kan má bàa ran àwọn ọmọ wọn

8. Báwo ni àwọn òbí tó gbọ́n ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Nóà àti aya rẹ̀?

8 Lóde òní, àwọn òbí máa gbà pé iṣẹ́ gidi ni Nóà àti aya rẹ̀ ṣe kí wọ́n tó lè kọ́ àwọn ọmọ wọn ní ìwà rere láyé ìgbà yẹn. Torí pé bí ìwà ipá àti ọ̀tẹ̀ ṣe gbòde kan lónìí náà nìyẹn. Àwọn ọmọọ̀ta oníwàkiwà kún ìgboro. Kódà àwọn nǹkan eré ìnàjú tí wọ́n ń ṣe fún àwọn ọmọdé sábà máa ń gbé ìwà ipá àti ọ̀tẹ̀ lárugẹ. Ṣe ni àwọn òbí tó gbọ́n máa ń sa gbogbo ipá wọn kí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ má bàa kó èèràn ran àwọn ọmọ wọn. Ohun tí wọ́n ń ṣe ni pé wọ́n máa ń kọ́ wọn nípa Jèhófà, Ọlọ́run àlàáfíà, tó máa mú kí gbogbo ìwà ipá dópin lọ́jọ́ kan. (Sm. 11:5; 37:10, 11) Ó dájú ṣáká pé àwọn òbí lè ṣàṣeyọrí. Ìdí ni pé Nóà àti aya rẹ̀ ṣàṣeyege. Àwọn ọmọ wọn dàgbà di èèyàn rere, wọ́n sì fẹ́ aya tí wọ́n jọ nífẹ̀ẹ́ sí fífi ìfẹ́ Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́ sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wọn.

“Ṣe Áàkì Kan fún Ara Rẹ”

9, 10. (a) Àṣẹ wo ni Jèhófà pa fún Nóà tó yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà? (b) Kí ni Jèhófà sọ fún Nóà nípa bó ṣe máa kan áàkì náà àti ìdí tó fi ní kó kàn án?

9 Lọ́jọ́ kan, ìgbésí ayé Nóà yí pa dà, àyípadà títí láé sì ni. Jèhófà sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ tó fẹ́ràn yìí pé òun ti pinnu láti pa ayé ìgbà yẹn run. Ó sì pàṣẹ fún Nóà pé: “Fi igi ṣe áàkì kan fún ara rẹ láti ara igi olóje.”—Jẹ́n. 6:14.

10 Áàkì yìí kì í ṣe ọkọ̀ ojú omi o, bí àwọn kan ṣe rò. Torí kò níbi tó jẹ́ iwájú tàbí ẹ̀yìn, kò ní àkànṣe igi tàbí irin tó máa ń wà lábẹ́ ọkọ̀ ojú omi láti iwájú dé ẹ̀yìn, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní ìtọ́kọ̀ àti àwọn igun tàbí ẹ̀gbẹ́ tó ṣe kọdọrọ bíi ti ọkọ̀ ojú omi. Àpótí tó tóbi fàkìàfakia kan ni. Jèhófà sọ bí áàkì náà ṣe máa gùn tó, bó ṣe máa fẹ̀ tó àti bó ṣe máa ga tó fún Nóà, ó tún ṣe àwọn àlàyé kan nípa bí áàkì náà ṣe máa rí, ó sì sọ pé kó fi ọ̀dà bò ó nínú àti lóde. Ó sọ ìdí rẹ̀ fún un pé: “Kíyè sí i, èmi yóò mú àkúnya omi wá sórí ilẹ̀ ayé . . . Ohun gbogbo tí ó wà ní ilẹ̀ ayé yóò gbẹ́mìí mì.” Ṣùgbọ́n Jèhófà bá Nóà dá májẹ̀mú, ó ní: “Ìwọ yóò sì wọnú áàkì náà, ìwọ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ àti aya rẹ àti aya àwọn ọmọkùnrin rẹ pẹ̀lú rẹ.” Ó ní kí Nóà mú lára gbogbo onírúurú ẹranko sínú áàkì náà. Torí pé kìkì àwọn tó bá wà nínú áàkì ni yóò la Àkúnya Omi tó ń bọ̀ náà já!—Jẹ́n. 6:17-20.

Nóà àti ìdílé rẹ̀ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti ṣe àwọn nǹkan tí Ọlọ́run pa láṣẹ

11, 12. Iṣẹ́ bàǹtàbanta wo ni Nóà gbà, kí ló sì wá ṣe nípa rẹ̀?

11 Bí Nóà ṣe gba iṣẹ́ bàǹtàbanta nìyẹn o. Fàkìàfakia ni áàkì yẹn máa tóbi. Gígùn rẹ̀ yóò jẹ́ mítà mẹ́tàléláàádóje [133], fífẹ̀ rẹ̀ yóò jẹ́ mítà méjìlélógún, gíga rẹ̀ yóò sì jẹ́ mítà mẹ́tàlá. Ó gùn ju pápá ìṣeré tí wọ́n ti ń gbá bọ́ọ̀lù lọ, ó sì ga ju ilé alájà mẹ́ta. Ṣé Nóà wá yẹ iṣẹ́ náà sílẹ̀, tàbí kó ṣàròyé nípa àwọn ìṣòro tó máa ní, tàbí kó tiẹ̀ yí àwọn nǹkan kan pa dà nínú bí wọ́n ṣe ní kó ṣe é, kó bàa lè rọ̀ ọ́ lọ́rùn? Rárá o. Ohun tí Bíbélì sọ ni pé: “Nóà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti pa láṣẹ fún un. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́.”—Jẹ́n. 6:22.

12 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ni iṣẹ́ náà gbà. Ó ṣeé ṣe kó tó ogójì sí àádọ́ta ọdún kó tó parí. Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ igi ńlá ni wọ́n máa ní láti gé lulẹ̀, wọ́n á wọ́ wọn lọ sí ibi tí wọ́n ti máa lò wọ́n, wọ́n á là wọ́n, wọ́n á gé wọn sí ìwọ̀n tó yẹ, wọ́n á wá kàn wọ́n pa pọ̀. Áàkì náà yóò ní àjà mẹ́ta àti àwọn yàrá bíi mélòó kan, yóò sì ní ilẹ̀kùn kan ní ẹ̀gbẹ́. Ẹ̀rí fi hàn pé apá òkè ni àwọn fèrèsé áàkì náà máa wà, ó sì jọ pé orí rẹ̀ lókè máa dagun síhà méjèèjì láti àárín kó lè dami nù.—Jẹ́n. 6:14-16.

13. Èwo lára iṣẹ́ Nóà ló ṣeé ṣe kó gba ìgboyà ju áàkì tí wọ́n ń kàn lọ? Ǹjẹ́ àwọn èèyàn kọbi ara sí ìkìlọ̀ rẹ̀?

13 Bí ọdún ṣe ń gorí ọdún, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í rí bí áàkì yẹn ṣe máa rí gan-an. Ó dájú pé Nóà á máa dúpẹ́ pé ìdílé rẹ̀ kọ́wọ́ tì í lẹ́nu iṣẹ́ náà! Ṣùgbọ́n iṣẹ́ kan wà lára iṣẹ́ Nóà tó ṣeé ṣe kó tiẹ̀ gba ìgboyà ju áàkì tí wọ́n ń kàn lọ. Bíbélì sọ pé Nóà jẹ́ “oníwàásù òdodo.” (Ka 2 Pétérù 2:5.) Ó fi ìgboyà mú ipò iwájú lẹ́nu iṣẹ́ kíkìlọ̀ fún àwọn èèyàn oníwà ibi àti àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run pé ìparun ń bọ̀ wá sórí wọn. Ǹjẹ́ wọ́n kọbi ara sí ìkìlọ̀ rẹ̀? Nígbà tí Jésù Kristi ń sọ̀rọ̀ nípa ayé ìgbà náà, ó sọ pé àwọn èèyàn yẹn “kò sì fiyè sí i.” Ó ní ìgbòkègbodò bíi jíjẹ, mímu àti gbígbé ìyàwó ló gbà wọ́n lọ́kàn tí wọn kò fi fetí sí ọ̀rọ̀ Nóà. (Mát. 24:37-39) Ó dájú pé ṣe ni ọ̀pọ̀ nínú wọn á máa fi Nóà àti ìdílé rẹ̀ ṣe yẹ̀yẹ́, àwọn míì tiẹ̀ lè lérí léka sí i, kí wọ́n sì fìbínú ta kò ó. Bóyá wọ́n tiẹ̀ gbìyànjú láti dí wọn lọ́wọ́ lẹ́nu áàkì tí wọ́n ń kàn.

Pẹ̀lú gbogbo bí àwọn èèyàn ṣe ń rí i pé Ọlọ́run ń bù kún Nóà, síbẹ̀ wọ́n fi ń ṣe yẹ̀yẹ́, wọn kò sì fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀

14. Ẹ̀kọ́ wo ni àwọn ìdílé Kristẹni lóde òní lè rí kọ́ lára Nóà àti ìdílé rẹ̀?

14 Síbẹ̀, Nóà àti ìdílé rẹ̀ kò pa ohun tí wọ́n ń ṣe tì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn yẹn ka áàkì tí ìdílé Nóà ń kàn sí àìríkan-ṣèkan, iṣẹ́ àṣedànù tàbí ìranù, Nóà àti ìdílé rẹ̀ gbájú mọ́ iṣẹ́ wọn. Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ni àwọn ìdílé Kristẹni lóde òní lè rí kọ́ látinú bí Nóà àti ìdílé rẹ̀ ṣe lo ìgbàgbọ́. Ó ṣe tán, àkókò tí Bíbélì pè ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ayé burúkú yìí ni àwa náà wà báyìí. (2 Tím. 3:1) Jésù sọ pé ìgbà tiwa yìí máa dà bí ayé ìgbà tí Nóà kan áàkì. Nítorí náà, tí àwọn èèyàn bá dágunlá sí ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run tí à ń sọ fún wọn, tàbí wọ́n fi wá ṣe yẹ̀yẹ́, tàbí wọ́n tiẹ̀ ṣe inúnibíni sí wa, ṣe ni ká máa rántí pé wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ sí Nóà. Àti pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí àwọn ará ìṣáájú náà.

“Lọ . . . Sínú Áàkì Náà”

15. Àwọn èèyàn Nóà wo ló kú nígbà tí Nóà fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ẹni ẹgbẹ̀ta ọdún?

15 Ogún ọdún kọjá, ọgbọ́n ọdún kọjá, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ áàkì náà dúró rekete. Nígbà tí Nóà fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ẹni ẹgbẹ̀ta [600] ọdún, àwọn èèyàn rẹ̀ kan kú. Bí àpẹẹrẹ, Lámékì bàbá rẹ̀ kú. * Ọdún márùn-ún lẹ́yìn náà, Mètúsélà bàbá Lámékì, ìyẹn baba ńlá Nóà, kú lẹ́ni ẹgbẹ̀rún ọdún ó dín mọ́kànlélọ́gbọ̀n [969]. Òun ló pẹ́ jù láyé nínú gbogbo èèyàn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn. (Jẹ́n. 5:27) Mètúsélà àti Lámékì ṣì bá Ádámù, ọkùnrin àkọ́kọ́, láyé kó tó kú.

16, 17. (a) Kí ni Ọlọ́run tún wá sọ fún Nóà nígbà tó wà ní ẹni ẹgbẹ̀ta ọdún? (b) Ṣàlàyé ohun tí kò ṣeé gbàgbé tí Nóà àti ìdílé rẹ̀ rí.

16 Nígbà tí Nóà wà ní ẹni ẹgbẹ̀ta [600] ọdún, Jèhófà Ọlọ́run tún wá sọ fún un pé: “Lọ, ìwọ àti gbogbo agbo ilé rẹ, sínú áàkì náà.” Bákan náà, ó tún sọ fún un pé kí ó kó gbogbo onírúurú ẹran sínú áàkì náà. Ó ní kí ó kó méjeméje lára àwọn tó mọ́, tó ṣeé fi rúbọ, kó sì kó àwọn yòókù ní méjìméjì.—Jẹ́n. 7:1-3.

17 Ó dájú pé bí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹranko wọ̀nyẹn ṣe ń rọ́ wọlé tìrítìrí lọ́tùn-ún lósì máa jẹ́ ohun tí kò ṣeé gbàgbé. Ọ̀tọ̀ ni àwọn tó ń rìn bọ̀, àwọn tó ń fò, àwọn tó ń tọ àti àwọn tó ń fi àyà fà. Àti ńlá àti kékeré wọn, èyí tó ga àti èyí tó kúrú, gbogbo wọn ń bọ̀ lónírúurú ọ̀nà, kálukú wọn pẹ̀lú ìṣe tirẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pé Nóà ń sá sókè sódò kó lè ká àwọn ẹranko wọ̀nyẹn mọ́ ibì kan, bẹ́ẹ̀ ni kò pariwo tàbí kó máa fọgbọ́n tàn wọ́n láti lè dà wọ́n lọ sí àyè wọn nínú áàkì náà. Bíbélì sọ pé ṣe ni “wọ́n wọlé . . . lọ bá Nóà nínú áàkì náà.”—Jẹ́n. 7:9.

18, 19. (a) Báwo la ṣe lè dáhùn ìbéèrè àwọn oníyèmejì nípa àwọn nǹkan tí ìtàn Nóà sọ pé ó ṣẹlẹ̀? (b) Báwo ni ọgbọ́n Jèhófà ṣe hàn kedere nínú ọ̀nà tó lò láti gba àwọn ẹranko là?

18 Àmọ́ àwọn oníyèmejì kan lè béèrè pé: ‘Báwo ni irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣe lè ṣẹlẹ̀ láyé yìí? Báwo ni onírúurú ẹranko wọ̀nyẹn ṣe máa lè wà pa pọ̀ ní àlàáfíà, tí wọ́n bá jọ wà nínú ibì kan náà?’ Ṣùgbọ́n rò ó wò ná: Ṣé Ẹlẹ́dàá tó dá ọ̀run òun ayé kò ní lágbára tó fi lè darí àwọn ẹranko tó dá, bóyá kó rọ̀ wọ́n lójú kí wọ́n sì rọrùn láti darí, tó bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀? Má sì gbàgbé pé Jèhófà ni Ọlọ́run tó dá àwọn ẹranko o. Kódà, ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìgbà ayé Nóà, ó pín Òkun Pupa níyà, ó sì tún mú kí oòrùn dúró sójú kan lójú ọ̀run. Ǹjẹ́ kò wá ní lè ṣe gbogbo nǹkan tí ìtàn Nóà yìí sọ pé ó ṣẹlẹ̀? Dájúdájú ó lè ṣe wọ́n, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ lóòótọ́!

19 Lóòótọ́, Ọlọ́run lè lo ọ̀nà míì láti fi gba àwọn ẹranko wọ̀nyẹn là. Ṣùgbọ́n, ó lo ọ̀nà ọlọ́gbọ́n ní ti pé ó yan ọ̀nà táá jẹ́ ká lè máa rántí iṣẹ́ tó fà lé àwa èèyàn lọ́wọ́ níbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, ìyẹn ni pé ká máa tọ́jú gbogbo ẹ̀dá abẹ̀mí orí ilẹ̀ ayé. (Jẹ́n. 1:28) Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ọ̀pọ̀ òbí lónìí máa ń fi ìtàn Nóà kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà fọwọ́ pàtàkì mú àwa èèyàn àti àwọn ẹranko tó dá.

20. Kí ni Nóà àti ìdílé rẹ̀ á máa ṣe nígbà tó ku ọ̀sẹ̀ kan kí Àkúnya Omi dé?

20 Jèhófà sọ fún Nóà pé ní ọ̀sẹ̀ kan sí i, Àkúnya Omi máa dé. Ó dájú pé ọwọ́ ìdílé náà máa dí gidigidi láàárín àkókò yìí. Fojú inú wo iṣẹ́ ńlá tí wọ́n á máa ṣe láti kó àwọn ẹranko àti oúnjẹ wọn sí àyè tó yẹ wọ́n àti bí wọ́n á tún ṣe máa kó ẹrù ìdílé náà sínú áàkì. Aya Nóà àti àwọn ìyàwó Ṣémù, Hámù àti Jáfẹ́tì á sì tún fẹ́ rí i dájú pé àwọn nǹkan tí wọ́n máa nílò àti ibi tí wọ́n máa wà nínú áàkì náà wà ní sẹpẹ́.

21, 22. (a) Kí nìdí tí kò fi yẹ kó yà wá lẹ́nu pé àwọn èèyàn tó yí Nóà ká dágunlá sí ọ̀rọ̀ rẹ̀? (b) Ìgbà wo ni gbogbo yẹ̀yẹ́ tí àwọn tó wà nítòsí Nóà ń ṣe sí òun àti ìdílé rẹ̀ dópin?

21 Àwọn èèyàn tó yí wọn ká ńkọ́, kí ni wọ́n ń ṣe? Pẹ̀lú gbogbo bí wọ́n ṣe ń rí ọwọ́ ìbùkún Jèhófà kedere lára Nóà àti gbogbo ohun tó ń ṣe, Bíbélì sọ pé wọn “kò sì fiyè sí i.” Wọ́n á ṣáà rí bí onírúurú ẹranko ṣe ń rọ́ wọnú áàkì náà, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Àmọ́ ṣá, kò yẹ kó yà wá lẹ́nu pé wọ́n dágunlá sí i. Ṣebí àwọn èèyàn òde òní náà kò fiyè sí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ẹ̀rí tó fi hàn pé àwa náà wà ní àkókò òpin ayé burúkú yìí. Bí àpọ́sítélì Pétérù sì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, àwọn olùyọṣùtì ti wá pẹ̀lú ìyọṣùtì wọn, wọ́n sì ń fi àwọn tó ń tẹ̀ lé ìkìlọ̀ Ọlọ́run ṣe yẹ̀yẹ́. (Ka 2 Pétérù 3:3-6.) Àwọn èèyàn ìgbàanì náà kúkú fi Nóà ṣe ẹlẹ́yà nígbà yẹn.

22 Ìgbà wo ni gbogbo yẹ̀yẹ́ tí wọ́n ń ṣe dópin? Bíbélì sọ pé gbàrà tí Nóà kó ìdílé rẹ̀ àti àwọn ẹranko sínú áàkì tán “Jèhófà ti ilẹ̀kùn mọ́ ọn.” Bí èyíkéyìí lára àwọn tó ń fi wọ́n ṣe ẹlẹ́yà bá wà nítòsí, ṣe ni ohun tí Jèhófà ṣe yẹn máa pa wọ́n lẹ́nu mọ́. Bí ìyẹn kò bá sì tó, òjò ńlá tó bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn náà máa jẹ́ kí wọ́n panu mọ́! Òjò náà ń dà wìì-wìì-wìì láìdáwọ́dúró, títí tó fi di ìkún-omi tó bo gbogbo ayé bí Jèhófà ṣe wí.—Jẹ́n. 7:16-21.

23. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé inú Jèhófà kò dùn pé àwọn èèyàn burúkú ìgbà ayé Nóà kú dà nù? (b) Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé kó o tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Nóà lóde òní?

23 Ṣé inú Jèhófà wá dùn pé àwọn èèyàn burúkú yẹn kú dà nù? Ó tì o! (Ìsík. 33:11) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fún wọn láyè tó pọ̀ tó kí wọ́n lè ronú pìwà dà kí wọ́n sì ṣe ohun tó tọ́. Ǹjẹ́ wọ́n tiẹ̀ lè yí pa dà? Bẹ́ẹ̀ ni o. Ìwà àti ìṣe Nóà fi hàn pé wọ́n lè ṣe ohun tó tọ́ tí wọ́n bá fẹ́ bẹ́ẹ̀. Bí Nóà ṣe bá Jèhófà rìn, ní ti pé ó ṣègbọràn sí Ọlọ́run délẹ̀délẹ̀, jẹ́ kó hàn kedere pé àwọn èèyàn yòókù náà ṣì lè yí pa dà, kí wọ́n ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run kí wọ́n sì la ìkún-omi náà já. Nóà tipa bẹ́ẹ̀ fi ìgbàgbọ́ rẹ̀ dá ayé ìgbà náà lẹ́bi; ó jẹ́ kó hàn kedere pé àwọn oníwà ibi inú ayé ìgbà yẹn jẹ̀bi. Ìgbàgbọ́ rẹ̀ sì gba òun àti ìdílé rẹ̀ là. Bí ìwọ náà bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Nóà, tó o ní irú ìgbàgbọ́ tó ní, wàá lè gba ara rẹ àti àwọn èèyàn rẹ là. Ó dájú pé ìwọ náà lè bá Jèhófà Ọlọ́run rìn, kí o sì di ọ̀rẹ́ rẹ̀ bíi ti Nóà. Ìwọ àti Ọlọ́run sì lè jẹ́ ọ̀rẹ́ títí láé!

^ ìpínrọ̀ 7 Àwọn èèyàn ayé ìgbà náà lọ́hùn-ún máa ń pẹ́ láyé gan-an ju àwa ti òde òní lọ. Ìdí sì ni pé ìran wọn kò jìnnà púpọ̀ sí ti Ádámù àti Éfà tí wọ́n ní ara pípé àti ìlera pípé kí wọ́n tó pàdánù rẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 15 Lámékì sọ orúkọ ọmọ rẹ̀ ní Nóà, tó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “Ìsinmi” tàbí “Ìtùnú.” Ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé orúkọ yìí máa ro Nóà lóòótọ́ nítorí ó máa kó àwọn èèyàn yọ nínú làálàá tí wọ́n ń ṣe lórí ilẹ̀ tí Ọlọ́run fi gégùn-ún. (Jẹ́n. 5:28, 29) Ṣùgbọ́n Lámékì kú kí àsọtẹ́lẹ̀ yìí tó ṣẹ. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìyá Nóà, àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò rẹ̀ lọ́kùnrin àti lóbìnrin bá ìkún-omi lọ.