Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ KẸSÀN-ÁN

Ó Hùwà Ọlọgbọ́n

Ó Hùwà Ọlọgbọ́n

1-3. (a) Kí ló fa àjálù ńlá tó ń bọ̀ lórí agboolé Ábígẹ́lì? (b) Kí la fẹ́ kọ́ nípa obìnrin àtàtà yìí?

ÁBÍGẸ́LÌ kíyè sí i pé jìnnìjìnnì bo ọ̀dọ́kùnrin tó ń bá òun sọ̀rọ̀. Ohun tó fẹ́ ṣẹlẹ̀ sì tó bani lẹ́rù lóòótọ́. Àjálù ńlá ni! Irínwó [400] ọmọ ogun ló ń bọ̀ lọ́nà, wọ́n fẹ́ wá pa gbogbo ọkùnrin tó wà nílé Nábálì, ọkọ Ábígẹ́lì. Kí ló fà á?

2 Nábálì leku ẹdá tó dá gbogbo rẹ̀ sílẹ̀. Ó tún ti hùwà burúkú àti ìwà àfojúdi bó ṣe máa ń ṣe. Lọ́tẹ̀ yìí, ṣe ló fẹnu kọ. Ó fàbùkù kan olórí ogun kan, tó ń darí agbo àwọn jagunjagun tí wọ́n fẹ́ràn rẹ̀ gan-an. Ni ọ̀kan lára àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó jẹ́ òṣìṣẹ́ Nábálì, bóyá tó jẹ́ darandaran, bá wá sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún Ábígẹ́lì, torí ó gbà pé yóò wá nǹkan ṣe láti gba àwọn sílẹ̀. Àmọ́, kí ni obìnrin kan ṣoṣo lè ṣe tó máa dá odindi ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan dúró?

3 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ẹ jẹ́ ká kọ́ nǹkan díẹ̀ nípa obìnrin àtàtà yìí. Ta ni Ábígẹ́lì? Kí ló fa wàhálà yìí? Kí la sì lè rí kọ́ látinú ìgbàgbọ́ rẹ̀?

Ó Ní “Ọgbọ́n Inú Dáadáa, Ó sì Lẹ́wà ní Ìrísí”

4. Irú èèyàn wo ni Nábálì jẹ́?

4 Ìwà Ábígẹ́lì àti Nábálì kò bára mu rárá. Aya rere ni Ábígẹ́lì tí Nábálì fẹ́, àmọ́ ó ṣeni láàánú pé ọkùnrin burúkú ni Nábálì ọkọ Ábígẹ́lì. Ọlọ́rọ̀ ni ọkùnrin náà, ìyẹn sì mú kó jọ ara rẹ̀ lójú gan-an. Ṣùgbọ́n kò tún sí ẹlòmíì tí Bíbélì fi àwọn ọ̀rọ̀ tó lágbára júwe bó ṣe jẹ́ èèyànkéèyàn tó bíi ti Nábálì. Orúkọ rẹ̀ pàápàá túmọ̀ sí “Òpònú” tàbí “Arìndìn.” A kò lè sọ bóyá orúkọ tí àwọn òbí rẹ̀ sọ ọ́ nìyẹn nígbà tí wọ́n bí i, àbí àwọn èèyàn ló ń pè é bẹ́ẹ̀ nítorí ìwà rẹ̀, tó sì wá di orúkọ rẹ̀ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. Èyí ó wù kó jẹ́, orúkọ rò ó. Nábálì “le koko, ó sì burú ní àwọn ìṣe rẹ̀.” Ó rorò léèyàn, ó sì jẹ́ òkú ọ̀mùtí. Nítorí náà àwọn èèyàn máa ń bẹ̀rù rẹ̀ gan-an, wọ́n sì kórìíra rẹ̀.—1 Sám. 25:2, 3, 17, 21, 25.

5, 6. (a) Àwọn ìwà dáadáa wo lo rò pé Ábígẹ́lì ní? (b) Kí ló lè jẹ́ ìdí tí Ábígẹ́lì fi fẹ́ irú ọkùnrin tí kò dára fún ohunkóhun yìí?

5 Ìwà Ábígẹ́lì yàtọ̀ pátápátá sí ti Nábálì. Orúkọ rẹ̀ túmọ̀ sí “Bàbá Mi Ti Múnú Ara Ẹ̀ Dùn.” Àmúyangàn ọmọ ni ọmọbìnrin tó bá rẹwà máa ń jẹ́ fún ọ̀pọ̀ bàbá, àmọ́ ohun tó máa ń múnú bàbá tó bá jẹ́ ọlọgbọ́n dùn jù ni pé kí ọmọ rẹ̀ níwà rere, kó sì gbọ́n. Lọ́pọ̀ ìgbà ṣá o, ẹni tó bá jẹ́ arẹwà kì í sábà rí ìdí tó fi yẹ kí òun ní ọgbọ́n inú, òye, ìgboyà tàbí ìgbàgbọ́. Àmọ́ ti Ábígẹ́lì ò rí bẹ́ẹ̀. Bíbélì sọ pé ó ní ọgbọ́n inú dáadáa, ó sì tún lẹ́wà.—Ka 1 Sámúẹ́lì 25:3.

6 Lónìí, àwọn kan lè máa ronú pé kí nìdí tírú obìnrin tó gbọ́n bẹ́ẹ̀ fi fẹ́ ọkùnrin tí kò dára fún ohunkóhun yìí? Má gbàgbé pé láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ọ̀pọ̀ òbí ló máa ń yan ẹni tí ọmọ wọn máa fẹ́. Tí kò bá sì jẹ́ pé àwọn òbí ló yàn án, ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n fọwọ́ sí ẹni tí ọmọ wọn máa fẹ́. Ṣé torí ọrọ̀ àti òkìkí Nábálì làwọn òbí Ábígẹ́lì ṣe jẹ́ kó fẹ́ ẹ, àbí àwọn gan-an ló torí ìyẹn ṣètò bí wọ́n ṣe fẹ́ra? Ṣé àìlówó lọ́wọ́ ló sún wọn ṣe bẹ́ẹ̀? Èyí ó wù kó jẹ́, owó Nábálì ò mú kó jẹ́ ọkọ rere.

7. (a) Kí ni kò yẹ kí àwọn tó jẹ́ òbí lóde òní ṣe tí wọ́n bá fẹ́ kí àwọn ọmọ wọn fi ojú tó tọ́ wo ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó? (b) Kí ni Ábígẹ́lì pinnu láti ṣe?

7 Àwọn òbí tó jẹ́ ọlọgbọ́n máa ń kọ́ àwọn ọmọ wọn pé kí wọ́n fi ojú tó tọ́ wo ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó. Wọn kì í gba ọmọ wọn nímọ̀ràn láti fẹ́ ẹnì kan torí owó tàbí kí wọ́n ti ọmọ wọn lọ fẹ́ ẹnì kan sọ́nà nígbà tí ọjọ́ orí rẹ̀ ṣì kéré sí tẹni tá lè máa ṣe àwọn ojúṣe tọkọtaya. (1 Kọ́r. 7:36) Àmọ́ ọ̀rọ̀ ti Ábígẹ́lì kò rí bẹ́ẹ̀, ó sì ti wá pẹ́ jù fún un láti máa ronú nípa ìyẹn. Ohun yòówù tó mú kó fẹ́ Nábálì, ó ti fẹ́ ẹ ná. Ábígẹ́lì sì pinnu láti ṣe gbogbo ohun tó bá lè ṣe nínú ipò tí kò rọrùn yẹn.

“Ó Fi Ìkanra Sọ̀rọ̀ sí Wọn”

8. Ta ni Nábálì kàn lábùkù, kí sì nìdí tó o fi lè sọ pé ìwà òmùgọ̀ gbáà ló hù yẹn?

8 Nábálì tún wá kó Ábígẹ́lì sí wàhálà ńlá. Ó kan Dáfídì tó jẹ́ ẹni pàtàkì lábùkù. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ìránṣẹ́ Jèhófà olóòótọ́ tí Sámúẹ́lì fòróró yàn ni Dáfídì, tó fi hàn pé òun ni Ọlọ́run yàn pé kó jọba dípò Sọ́ọ̀lù. (1 Sám. 16:1, 2, 11-13) Nígbà yẹn, inú aginjù ni Dáfídì àti ẹgbẹ̀ta [600] jagunjagun tó dúró tì í gbágbáágbá ń gbé, torí pé ó ń sá fún Sọ́ọ̀lù Ọba tó jẹ́ òjòwú àti apààyàn.

9, 10. (a) Abẹ́ ipò wo ni Dáfídì àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ ti ń wá jíjẹ mímu kiri? (b) Kí nìdí tó fi yẹ kí Nábálì mọyì oore tí Dáfídì àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ ti ń ṣe fún un? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé tó wà ní ìpínrọ̀ 10.)

9 Ìlú Máónì ni Nábálì ń gbé, àmọ́ ìlú Kámẹ́lì tí kò jìnnà sí Máónì ló ti ń ṣiṣẹ́, ó sì ṣeé ṣe kó nílẹ̀ síbẹ̀. * Nábálì ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] àgùntàn tó ń sìn láwọn ìlú tó wà níbi tó ga díẹ̀ yẹn. Ibẹ̀ dáa fún sísin àgùntàn torí pé koríko pọ̀ gan-an níbẹ̀. Àmọ́ aginjù ló yí wọn ká. Aginjù Páránì tó lọ súà wà lápá gúúsù àwọn ìlú náà. Aṣálẹ̀ tó dá páropáro tó sì kún fún àfonífojì tóóró àti àwọn hòrò ló wà lápá ìlà oòrùn lọ́nà ibi téèyàn máa gbà lọ sí Òkun Iyọ̀. Àgbègbè yìí ni Dáfídì àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ ti ń ṣe làálàá gidi kí wọ́n tó lè rí jíjẹ mímu wọn, ojú wọn sì ń rí màbo. Wọ́n sì sábà máa ń pàdé àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó ń da àwọn ẹran Nábálì ọlọ́rọ̀.

10 Báwo làwọn ọmọ ogun Dáfídì tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ àṣekára yìí ṣe máa ń ṣe sí àwọn darandaran Nábálì? Tó bá wù wọ́n, wọ́n lè máa pa àgùntàn wọn jẹ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àmọ́ wọn kò ṣe bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n dà bí ògiri tó ń dàábò bo agbo ẹran àtàwọn ìránṣẹ́ Nábálì. (Ka 1 Sámúẹ́lì 25:15, 16.) Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ ewu ló máa ń wu àwọn àgùntàn àti àwọn tó ń dà wọ́n. Àwọn ẹranko ẹhànnà pọ̀ níbẹ̀ gan-an. Ààlà ilẹ̀ Ísírẹ́lì lápá gúúsù ò sì jìnnà síbẹ̀, torí náà àwọn onísùnmọ̀mí àti àwọn olè máa ń ti ilẹ̀ ibòmíì wá ṣọṣẹ́ lágbègbè náà lọ́pọ̀ ìgbà. *

11, 12. (a) Báwo ni iṣẹ́ tí Dáfídì rán sí Nábálì ṣe fi hàn pé ó sọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n, ó sì bọ̀wọ̀ fún un? (b) Kí nìdí tí èsì tí Nábálì fún àwọn tí Dáfídì rán sí i kò fi dáa?

11 Iṣẹ́ ńlá ló jẹ́ fún Dáfídì láti máa bọ́ gbogbo àwọn ọkùnrin yẹn nínú aginjù. Torí náà, lọ́jọ́ kan Dáfídì rán ìránṣẹ́ mẹ́wàá sí Nábálì pé kó ran àwọn lọ́wọ́. Ìgbà tó tọ́ gan-an ni Dáfídì rán àwọn ọkùnrin yìí. Ó jẹ́ ìgbà tí wọ́n ń rẹ́ irun àgùntàn, èyí tó máa ń jẹ́ àkókò àjọyọ̀. Àwọn èèyàn sábà máa ń ta àwọn ẹlòmíì lọ́rẹ, wọ́n sì máa ń se àsè lákòókò yìí. Ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sì ní káwọn tó rán níṣẹ́ sọ tí wọ́n bá dé ọ̀hún jẹ́ ọ̀rọ̀ ọ̀wọ̀, tó bọ́gbọ́n mu, tó sì pọ́nni lé. Ó tiẹ̀ pe ara rẹ̀ ní “Dáfídì ọmọkùnrin rẹ,” bóyá ó fi ìyẹn bọ̀wọ̀ fún Nábálì tó dàgbà jù ú. Báwo ni Nábálì ṣe wá fèsì?—1 Sám. 25:5-8.

12 Nábálì bínú gidigidi! Nígbà tí ọ̀dọ́kùnrin tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ orí yìí ń sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún Ábígẹ́lì, ó ní Nábálì “fi ìkanra sọ̀rọ̀ sí wọn.” Ṣe ni Nábálì ahun fárígá, tó bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo pé òun kò lè fún wọn ní búrẹ́dì aládùn òun, omi òun àtàwọn ẹran àtàtà tóun pa. Ó wá ń láálí Dáfídì pé kò já mọ́ nǹkan kan, pé ìsáǹsá ìránṣẹ́ tó sá kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀ ni. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé èrò kan náà ni Nábálì àti Sọ́ọ̀lù, tó kórìíra Dáfídì ní. Àwọn méjèèjì kò fi ojú tí Jèhófà fi ń wo Dáfídì wò ó. Ọlọ́run fẹ́ràn Dáfídì, kò sì fojú ìránṣẹ́ tó ya ọlọ̀tẹ̀ wò ó. Kàkà bẹ́ẹ̀ ojú ẹni tó máa jọba Ísírẹ́lì láìpẹ́ ló fi ń wò ó.—1 Sám. 25:10, 11, 14.

13. (a) Kí ni Dáfídì kọ́kọ́ ṣe nígbà tó gbọ́ àbùkù tí Nábálì fi kàn án? (b) Kí ni ìlànà tó wà nínú ìwé Jákọ́bù 1:20 jẹ́ ká mọ̀ nípa ìbínú Dáfídì?

13 Inú bí Dáfídì gan-an nígbà táwọn tó rán níṣẹ́ pa dà wá jíṣẹ́ fún un. Ó wá pàṣẹ fáwọn ọmọ ogun rẹ̀ pé: “Kí olúkúlùkù sán idà rẹ̀!” Dáfídì náà bá dira ogun, ó sì kó irínwó [400] lára àwọn ọmọ ogun rẹ̀ láti lọ jà. Ó búra pé òun máa pa gbogbo ọkùnrin tó bá wà ní agboolé Nábálì run. (1 Sám. 25:12, 13, 21, 22) Kò burú bínú ṣe bí Dáfídì, àmọ́ ohun tí ìbínú rẹ̀ fẹ́ mú un ṣe ló burú. Bíbélì sọ pé: “Ìrunú ènìyàn kì í ṣiṣẹ́ yọrí sí òdodo Ọlọ́run.” (Ják. 1:20) Báwo ni Ábígẹ́lì á ṣe gba agboolé rẹ̀ sílẹ̀ báyìí?

“Ìbùkún . . . Ni fún Ìlóyenínú Rẹ”

14. (a) Kí ni Ábígẹ́lì ṣe tó fi hàn pé ó ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbésẹ̀ tó máa jẹ́ kó lè yanjú ìṣòro tí Nábálì dá sílẹ̀? (b) Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú ìwà Ábígẹ́lì tó yàtọ̀ sí ti Nábálì? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

14 A ti rí i níṣàájú pé, dé ìwọ̀n àyè kan, Ábígẹ́lì ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbésẹ̀ tó máa jẹ́ kó lè yanjú ìṣòro ńlá tí Nábálì dá sílẹ̀ yìí. Ó tẹ́tí sílẹ̀ ní tirẹ̀, kò ṣe bíi ti Nábálì ọkọ rẹ̀. Ohun tí ìránṣẹ́ tó bá Ábígẹ́lì sọ̀rọ̀ sọ pé ó fà á tí òun kò fi sọ fún Nábálì ni pé ó jẹ́ “àwé tí kò dára fún ohunkóhun rárá láti bá sọ̀rọ̀.” * (1 Sám. 25:17) Ó mà ṣe o, Nábálì jọra rẹ̀ lójú débi pé kì í fetí sílẹ̀ tí wọ́n bá fẹ́ bá a sọ̀rọ̀. Irú ìwà ìjọra-ẹni-lójú bẹ́ẹ̀ ṣì wọ́pọ̀ gan-an títí dòní. Àmọ́, ọ̀dọ́kùnrin yẹn mọ̀ pé Ábígẹ́lì yàtọ̀ ní tiẹ̀, ìdí sì nìyẹn tó fi lọ ṣàlàyé ìṣòro tó wà nílẹ̀ fún un.

Ábígẹ́lì tẹ́tí sílẹ̀ ní tirẹ̀, kò ṣe bíi ti Nábálì

15, 16. (a) Báwo ni Ábígẹ́lì ṣe fi hàn pé òun jẹ́ irú aya tó dáńgájíá tí ìwé Òwe ṣàpèjúwe? (b) Kí nìdí tí ohun tí Ábígẹ́lì ṣe kò fi túmọ̀ sí pé ó ń ṣe orí kunkun sí ọkọ tó jẹ́ orí rẹ̀?

15 Ábígẹ́lì tètè ronú ohun tó máa ṣe, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe é kíákíá. Bíbélì sọ pé: “Ní kíá, Ábígẹ́lì ṣe kánkán.” Nínú ìtàn yìí, ìgbà mẹ́rin ni Bíbélì lo ọ̀rọ̀ ìṣe náà “ṣe kánkán” nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa Ábígẹ́lì. Ó ṣètò oríṣiríṣi ẹ̀bùn tó máa kó fún Dáfídì àtàwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀. Ara ẹ̀bùn náà ni búrẹ́dì, wáìnì, àgùntàn, àyangbẹ ọkà, èso àjàrà gbígbẹ àti ìṣù èso ọ̀pọ̀tọ́. Ó dájú pé Ábígẹ́lì mọ gbogbo ohun tó ní dáadáa, ó sì ń ṣe ojúṣe rẹ̀ bó ṣe yẹ ní ti pé ó ń bójú tó agbo ilé rẹ̀ dáadáa, bíi ti aya tó dáńgájíá tí ìwé Òwe ṣàpèjúwe nígbà tó yá. (Òwe 31:10-31) Ó ní kí àwọn ìránṣẹ́ kan máa kó àwọn ẹ̀bùn náà nìṣó níwájú, òun nìkan sì ń bọ̀ lẹ́yìn. Bíbélì sọ pé: “Ṣùgbọ́n kò sọ nǹkan kan fún Nábálì ọkọ rẹ̀.”—1 Sám. 25:18, 19.

16 Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé Ábígẹ́lì ṣe orí kunkun sí ọkọ tó jẹ́ orí rẹ̀ ni? Rárá o. Rántí pé ẹni àmì òróró Jèhófà ni Nábálì hùwà ìkà sí, ohun tó ṣe yìí sì lè yọrí sí ikú ọ̀pọ̀ àwọn ará ilé rẹ̀ tí wọn ò mọwọ́ mẹsẹ̀ nínú ohun tó ṣe. Tí Ábígẹ́lì ò bá sì tètè wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá, ǹjẹ́ òun náà kò ní pín nínú ẹ̀ṣẹ̀ ọkọ rẹ̀? Nínú ọ̀rọ̀ yìí, ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ ló fi ṣáájú ti ọkọ rẹ̀.

17, 18. Kí ni Ábígẹ́lì ṣe nígbà tó rí Dáfídì? Kí ni Ábígẹ́lì sọ, kí ló sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ wọ Dáfídì lọ́kàn?

17 Kò pẹ́ tí Ábígẹ́lì fi pàdé Dáfídì àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ lójú ọ̀nà. Lẹ́ẹ̀kan sí i, ó tún ṣe kánkán, ó sọ̀ kalẹ̀ lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì dojú bolẹ̀ níwájú Dáfídì. (1 Sám. 25:20, 23) Ó wá tẹnu bọ ẹ̀bẹ̀, ó ń bẹ Dáfídì pé kó ṣàánú agbo ilé òun, kó má ro ti ìwà ọkọ òun. Kí ló jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ wọ Dáfídì lọ́kàn?

‘Jọ̀wọ́, jẹ́ kí ẹrúbìnrin rẹ sọ̀rọ̀ ní etí rẹ’

18 Ó ní kí Dáfídì gbà pé òun lòun ṣẹ̀, pé kó jọ̀ọ́ kó dárí ji òun. Ó sọ gbangba pé òun mọ̀ pé aláìnírònú ni ọkọ òun gẹ́gẹ́ bí ìtúmọ̀ orúkọ rẹ̀, bóyá láti lè dọ́gbọ́n sọ fún Dáfídì pé ó máa bù ú kù láti lọ bá irú èèyàn bẹ́ẹ̀ jà. Ó ní òun mọ̀ dájú pé Jèhófà ni Dáfídì ń ṣojú fún torí pé “àwọn ogun Jèhófà” ló ń jà. Ó tún fi hàn pé òun mọ ìlérí tí Jèhófà ṣe pé Dáfídì máa jọba, ó sọ pé: “Dájúdájú [Jèhófà] yóò fàṣẹ yàn ọ́ ṣe aṣáájú lórí Ísírẹ́lì.” Yàtọ̀ síyẹn, ó rọ Dáfídì pé kó má ṣe ohun tó máa jẹ́ kó jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ tàbí ohun tó lè “di okùnfà títa gọ̀ọ́gọ̀ọ́,” ìyẹn ohun tí ẹ̀rí ọkàn á fi máa dà á láàmú tó bá yá. (Ka 1 Sámúẹ́lì 25:24-31.) Ẹ ò rí i pé ọ̀rọ̀ tó tura tó sì ń wọni lọ́kàn gbáà ni!

19. Kí ni Dáfídì ṣe nígbà tó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ábígẹ́lì, kí sì nìdí tó fi yìn ín?

19 Kí wá ni Dáfídì ṣe? Ó gba àwọn nǹkan tí Ábígẹ́lì kó wá, ó sì sọ pé: “Ìbùkún ni fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí ó rán ọ lónìí yìí láti pàdé mi! Ìbùkún sì ni fún ìlóyenínú rẹ, ìbùkún sì ni fún ìwọ tí o ti dá mi dúró lónìí yìí kí n má bàa wọnú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀.” Dáfídì yìn ín fún bó ṣe lo ìgboyà, tó ṣe kánkán láti wá pàdé òun, pé ọpẹ́lọpẹ́ rẹ̀ lòun ò fi jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀. Ó wá sọ fún un pé: “Gòkè lọ sí ilé rẹ ní àlàáfíà,” ó sì tún fi ìrẹ̀lẹ̀ sọ pé: “Mo ti fetí sí ohùn rẹ.”—1 Sám. 25:32-35.

“Ẹrúbìnrin Rẹ Rèé”

20, 21. (a) Kí ló wú ọ lórí nípa bí Ábígẹ́lì ṣe múra tán láti pa dà sọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀? (b) Kí nìdí tó fi gba ọgbọ́n àti ìgboyà kí Ábígẹ́lì tó lè yan ìgbà tó dáa láti bá Nábálì sọ̀rọ̀?

20 Bí Ábígẹ́lì ṣe ń pa dà lọ sílé, á máa ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n pàdé, á sì máa ro ìyàtọ̀ tó wà láàárín Dáfídì ẹlẹ́yinjú àánú àti Nábálì ẹhànnà ọkọ tó ní. Àmọ́, kò jẹ́ kíyẹn gba òun lọ́kàn. Bíbélì sọ pé: “Lẹ́yìn náà, Ábígẹ́lì wọlé wá bá Nábálì.” Ó pa dà sọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀, láti lọ máa sa gbogbo ipá rẹ̀ lẹ́nu ojúṣe rẹ̀ tó ti ń ṣe bọ̀ gẹ́gẹ́ bí aya. Ó ní láti sọ fún ọkọ rẹ̀ nípa ẹ̀bùn tó fún Dáfídì àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀. Ohun tó yẹ kí ọkọ rẹ̀ mọ̀ ni. Ó tún ní láti sọ fún un nípa ewu tóun ti jẹ́ kó ré agbo ilé àwọn kọjá, kó tó di pé ó máa gbọ́ ọ níbòmíì, nítorí ìtìjú gbáà ló máa jẹ́ fún Nábálì tó bá jẹ́ pé ibòmíì ló ti gbọ́ ọ. Àmọ́, kò lè sọ fún un lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, torí pé Nábálì ń jayé ọlọ́ba lọ́wọ́, ó sì ti mutí yó bìnàkò.—1 Sám. 25:36.

Ábígẹ́lì fìgboyà sọ fún Nábálì bó ṣe gba ẹ̀mí rẹ̀ là

21 Ábígẹ́lì tún lo ọgbọ́n àti ìgboyà, ó dúró di àárọ̀ ọjọ́ kejì tí ọtí ti dá lójú ọkọ rẹ̀. Ìgbà yẹn ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ lè wọ Nábálì létí, àmọ́ ìyẹn náà léwu torí Nábálì tètè máa ń bínú. Síbẹ̀, Ábígẹ́lì lọ bá a, ó sì sọ gbogbo bọ́rọ̀ ṣe rí fún un. Ó dájú pé Ábígẹ́lì á máa retí pé kí ọkọ rẹ̀ gbaná jẹ, bóyá kó tiẹ̀ sọ ọ́ dìjà pàápàá. Àmọ́, ńṣe ni Nábálì kàn jókòó sójú kan, láìmira.—1 Sám. 25:37.

22. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Nábálì, ẹ̀kọ́ wo ni èyí sì kọ́ wa nípa gbogbo ọ̀ràn híhùwà ìkà sí àwọn tó wà nínú ìdílé tàbí fífìyà jẹ wọ́n?

22 Kí ló ṣe Nábálì? Bíbélì sọ pé: “Ọkàn-àyà rẹ̀ sì kú ní inú rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ sì dà bí òkúta.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àrùn rọpárọsẹ̀ ló kọ lù ú. Nǹkan bí ọjọ́ mẹ́wàá lẹ́yìn náà ó sì kú. Àmọ́ ó lè máà jẹ́ pé àìsàn ló kàn pa á torí Bíbélì sọ pé: “Jèhófà sì kọlu Nábálì, tí ó fi kú.” (1 Sám. 25:38) Lọ́nà yìí, Jèhófà ṣèdájọ́ òdodo, ó pa Nábálì, wàhálà ìdílé tí Ábígẹ́lì ti ń bá yí tipẹ́tipẹ́ sì dópin. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà kì í dá sí ọ̀rọ̀ ìdílé lọ́nà ìyanu bí èyí mọ́ lónìí, ìtàn yìí rán wa létí pé kò sẹ́ni tó ń hùwà ìkà sí àwọn tó wà nínú ìdílé rẹ̀ tàbí tó ń fìyà jẹ wọ́n tí Jèhófà ò rí. Tó bá tó àsìkò lójú rẹ̀, yóò ṣèdájọ́.—Ka Lúùkù 8:17.

23. Ìbùkún míì wo ni Ábígẹ́lì rí gbà? Báwo ló ṣe hàn pé Ábígẹ́lì kò yí ìwà ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ pa dà bó ṣe fẹ́ di ìyàwó Dáfídì?

23 Yàtọ̀ sí pé Ábígẹ́lì bọ́ lọ́wọ́ ọkọ burúkú, ó tún rí ìbùkún míì gbà. Nígbà tí Dáfídì gbọ́ pé Nábálì ti kú, ó rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sí Ábígẹ́lì pé òun fẹ́ fẹ́ ẹ. Ábígẹ́lì dáhùn pé: “Ẹrúbìnrin rẹ rèé gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́bìnrin láti máa wẹ ẹsẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ olúwa mi.” Ó ṣe kedere pé kò torí pé òun fẹ́ di ìyàwó Dáfídì kó wá yí ìwà ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ pa dà. Ńṣe ló ní kí Dáfídì fi òun ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀! Lẹ́yìn náà, a rí i kà pé ó tún ṣe kánkán láti múra, kó lè lọ bá Dáfídì.—1 Sám. 25:39-42.

24. Àwọn ìṣòro wo ni Ábígẹ́lì ní lẹ́yìn tó di aya Dáfídì, àmọ́ ojú wo ni Ọlọ́run rẹ̀ àti ọkọ rẹ̀ fi wò ó?

24 Èyí ò wá fi hàn pé Ábígẹ́lì ò ní níṣòro kankan mọ́ títí gbére. Torí kì í ṣe gbogbo ìgbà ni ìgbésí ayé á máa dùn yùngbà fún un lọ́ọ̀dẹ̀ Dáfídì. Dáfídì ti fẹ́ Áhínóámù tẹ́lẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run fàyè gba ìkóbìnrinjọ, ilé olórogún máa ń fa ìṣòro púpọ̀ fún àwọn obìnrin olóòótọ́ nígbà yẹn. Dáfídì ò sì tíì di ọba nígbà náà, kódà ọ̀pọ̀ ìdíwọ́ àti ìṣòro ni Dáfídì ṣì máa bá pàdé kó tiẹ̀ tó di ọba bí Jèhófà ṣe fẹ́. Àmọ́ bí Ábígẹ́lì ṣe ń ran Dáfídì lọ́wọ́, tó ń tì í lẹ́yìn, tó sì tún bí ọmọkùnrin kan fún un nígbà tó yá, yóò mọ̀ pé òun ní ọkọ tó mọyì òun, tó sì ń dáàbò bo òun. Àní ìgbà kan tiẹ̀ wà tí Dáfídì gba Ábígẹ́lì lọ́wọ́ àwọn ajínigbé! (1 Sám. 30:1-19) Dáfídì tipa báyìí tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà Ọlọ́run tó fẹ́ràn irú àwọn obìnrin tí wọ́n jẹ́ ọlọ́gbọ́n, onígboyà àti olóòótọ́ bẹ́ẹ̀, tí wọ́n sì níyì lójú rẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 9 Kámẹ́lì yìí kì í ṣe Òkè Ńlá Kámẹ́lì tí gbogbo èèyàn mọ̀ o, èyí tó wà lápá àríwá, níbi tí wòlíì Èlíjà ti ko àwọn wòlíì Báálì lójú lẹ́yìn ìgbà náà. (Wo Orí 10.) Ìlú kan ní ìkángun aginjù tó wà lápá gúúsù ni.

^ ìpínrọ̀ 10 Ó ṣeé ṣe kí Dáfídì máa rò ó pé iṣẹ́ ìsìn sí Jèhófà Ọlọ́run ni òun ń ṣe bí òun ṣe ń dáàbò bo àwọn onílẹ̀ àgbègbè yẹn àti agbo ẹran wọn. Nígbà yẹn, ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé kí àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù máa gbé ilẹ̀ náà. Torí náà, dídáàbò bo ilẹ̀ yẹn lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá àtàwọn agbésùnmọ̀mí jẹ́ iṣẹ́ ìsìn sí Ọlọ́run.

^ ìpínrọ̀ 14 Gbólóhùn tí ọ̀dọ́kùnrin náà lò túmọ̀ sí “ọmọ bélíálì (ìyẹn ẹni tí kò wúlò fún ohunkóhun).” Bí àwọn Bíbélì míì ṣe túmọ̀ ẹsẹ yìí ni pé Nábálì jẹ́ ọkùnrin “tí kì í fẹ́ gbọ́ ti ẹnikẹ́ni,” pé nípa bẹ́ẹ̀ “kò yẹ lẹ́ni téèyàn ń bá sọ̀rọ̀.”

Kí ni obìnrin kan ṣoṣo lè ṣe tó máa dá odindi ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan dúró?