Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ KẸRÌNDÍNLÓGÚN

Ó Lo Ọgbọ́n àti Ìgboyà, Kò sì Mọ Tara Rẹ̀ Nìkan

Ó Lo Ọgbọ́n àti Ìgboyà, Kò sì Mọ Tara Rẹ̀ Nìkan

1-3. (a) Báwo ló ṣe rí lára Ẹ́sítérì nígbà tó ń lọ sí ibi tí ọba gúnwà sí? (b) Kí ni ọba ṣe nígbà tó rí Ẹ́sítérì?

Ẹ́SÍTÉRÌ rọra ń lọ sí ibi ti ọba gúnwà sí, bẹ́ẹ̀ ni àyà rẹ̀ ń lù kìkì. Ṣé o lè fojú inú wo bí gbogbo nǹkan á ṣe ṣàdédé pa rọ́rọ́ ní ààfin aláyélúwà ti Ilẹ̀ Ọba Páṣíà tó wà ní Ṣúṣánì? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé lẹ́sọ̀lẹ́sọ̀ ni Ẹ́sítérì ń gbé ẹsẹ̀, síbẹ̀ kẹ́kẹ́ pa débi pé ó ń gbọ́ ìró ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì tún ń gbọ́ bí aṣọ oyè tó wọ̀ ṣe rọra ń rún wúrúwúrú. Òótọ́ ni pé ẹwà ààfin náà kọyọyọ. Àwọn òpó tí wọ́n fi iṣẹ́ ọnà dárà sí wà níbẹ̀. Bákàn náà sì ni àwọn igi kédárì tí wọ́n kó wá láti iyànníyàn ìlú Lẹ́bánónì. Wọ́n gbẹ́ àwọn igi yìí lọ́nà tó fa kíki, wọ́n sì fi wọ́n bo àjà inú ààfin náà. Àmọ́, Ẹ́sítérì ò rí gbogbo ìyẹn rò. Ẹni tó gúnwà sorí ìtẹ́ náà ló tẹjú mọ́, nítorí ọwọ́ ọba yìí ni ẹ̀mí rẹ̀ wà.

2 Ọba náà tẹjú mọ́ Ẹ́sítérì tó ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì na ọ̀pá aládé wúrà rẹ̀ sí i. Èyí lè má dà bí nǹkan bàbàrà, àmọ́ ńṣe ló túmọ̀ sí pé ikú yẹ̀ lórí Ẹ́sítérì. Òfin ilẹ̀ Páṣíà ni Ẹ́sítérì ṣẹ́ sí bó ṣe wọlé wá láìjẹ́ pé ọba ké sí i, ṣùgbọ́n ọ̀pá tí ọba nà sí i túmọ̀ sí pé ọba ti forí jì í. Nígbà tí Ẹ́sítérì dé iwájú ìtẹ́ Ahasuwérúsì, ó na ọwọ́ rẹ̀ ó sì fi kan orí ọ̀pá náà láti fi hàn pé òun mọrírì bí ọba ṣe ṣàánú òun.—Ẹ́sít. 5:1, 2.

Ẹ́sítérì fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn, ó mọrírì àánú tí ọba fi hàn sí i

3 Kò sí ẹni tó rí Ahasuwérúsì Ọba tí kò ní mọ̀ pé ó ní ọrọ̀ àti agbára tó kàmàmà. Àwọn kan tiẹ̀ sọ pé owó tó ń parí aṣọ ìgúnwà àwọn ọba ilẹ̀ Páṣíà ayé ìgbà yẹn máa ń tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀kẹ́ dọ́là. Síbẹ̀, Ẹ́sítérì rí i lójú ọba pé ó ṣì yọ́nú sí òun; ọba fi hàn lọ́nà yìí pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ọba wá bi í pé: “Kí ni ìwọ ń fẹ́, Ẹ́sítérì Ayaba, kí sì ni ìbéèrè rẹ? Títí dé ìdajì ipò ọba—àní kí a fi fún ọ!”—Ẹ́sít. 5:3.

4. Àwọn ìṣòro wo ní Ẹ́sítérì ṣì ń bọ̀ wá dojú kọ?

4 Ẹ́sítérì ti lo ìgbàgbọ́ àti ìgboyà tó kọyọyọ ní ti pé ó wá sọ́dọ̀ ọba kó lè gba àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ Hámánì tó ti pète láti pa gbogbo wọn run. Ní báyìí, ó ti dé ọ̀dọ̀ ọba ó sì rí ojú rere rẹ̀, àmọ́ àwọn ìṣòro kan wà tó ṣì ń bọ̀ wá dojú kọ. Ó ṣì ní láti mú kí ọba tó jọra rẹ̀ lójú yìí gbà pé olubi ẹ̀dá ni agbani-nímọ̀ràn rẹ̀ tó fọkàn tán jù lọ, pé ó ti dọ́gbọ́n tan ọba láti dájọ́ ikú fún gbogbo àwọn èèyàn òun. Báwo ló ṣe máa mú kí ọba gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́, ẹ̀kọ́ wo la sì lè rí kọ́ nínú bó ṣe lo ìgbàgbọ́?

Ó Fi Ọgbọ́n Yan “Ìgbà Sísọ̀rọ̀”

5, 6. (a) Báwo ni Ẹ́sítérì ṣe fi ìlànà tó wà nínú Oníwàásù 3:1, 7 sílò? (b) Báwo ni ọ̀nà tí Ẹ́sítérì gbà bá ọkọ rẹ̀ sọ̀rọ̀ ṣe fi ọgbọ́n hàn?

5 Ṣé ó yẹ kí Ẹ́sítérì sọ gbogbo ìṣòro náà fún ọba lójú gbogbo àwọn tó wà láàfin? Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó lè dójú ti ọba, kó sì jẹ́ kí Hámánì agbani-nímọ̀ràn ọba ráyè ro ẹjọ́ tó máa gbè é. Kí wá ni Ẹ́sítérì ṣe? Ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún ṣáájú ìgbà yẹn, Ọlọ́run mí sí ọlọgbọ́n ọba náà, Sólómọ́nì láti kọ̀wé pé: “Ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún, . . . ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbà sísọ̀rọ̀.” (Oníw. 3:1, 7) Ó dájú pé Módékáì, ọkùnrin adúróṣinṣin tó dà bíi bàbá fún Ẹ́sítérì á ti fi gbogbo irú ìlànà bẹ́ẹ̀ kọ́ ọmọbìnrin náà bó ṣe ń tọ́ ọ títí tó fi dàgbà. Dájúdájú, Ẹ́sítérì mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn fara balẹ̀ yan “ìgbà sísọ̀rọ̀.”

6 Ẹ́sítérì fèsì pé: “Bí ó bá dára ní ojú ọba, kí ọba àti Hámánì wá lónìí síbi àkànṣe àsè tí mo ti sè fún un.” (Ẹ́sít. 5:4) Ọba sọ pé àwọn máa wá, ó sì ránṣẹ́ pe Hámánì. Ǹjẹ́ ò kíyè sí bí Ẹ́sítérì ṣe fi ọgbọ́n sọ̀rọ̀? Ó bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀, ibi tó tọ́ àti ìgbà tó dára jù lọ ló sì yàn láti sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ fún un.—Ka Òwe 10:19.

7, 8. Kí ló ṣẹlẹ̀ níbi àsè àkọ́kọ́ tí Ẹ́sítérì sè fún ọba? Síbẹ̀, kí nìdí tó fi sún ọ̀rọ̀ tó fẹ́ bá ọba sọ síwájú?

7 Kò sí àní-àní pé Ẹ́sítérì fara balẹ̀ se àsè náà, ó sì rí i dájú pé gbogbo nǹkan tí ọkọ òun fẹ́ràn ni òun pèsè. Ọtí wáìnì tó jíire tó máa mú inú ọba dùn tún wà níbi àsè náà. (Sm. 104:15) Ahasuwérúsì gbádùn ara rẹ̀ dọ́ba, ló bá tún bi Ẹ́sítérì léèrè pé kí ló ń fẹ́. Ṣé àkókò ti tó wàyí fún Ẹ́sítérì láti tú kẹ̀kẹ́ ọ̀rọ̀?

8 Ẹ́sítérì kò rò bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló bẹ ọba pé kí òun àti Hámánì tún wá síbi àkànṣe àsè míì tí òun máa sè lọ́jọ́ kejì. (Ẹ́sít. 5:7, 8) Kí nìdí tí Ẹ́sítérì ò fi tíì sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀? Rántí pé gbogbo èèyàn Ẹ́sítérì pátá ni òfin tí ọba fọwọ́ sí sọ pé kí wọ́n pa. Látàrí èyí, Ẹ́sítérì gbọ́dọ̀ rí i pé ìgbà tó dára jù lọ lòun sọ ọ̀rọ̀ náà. Ó wá ṣe sùúrù, kó lè ní àǹfààní láti tún fi han ọkọ rẹ̀ pé òun bọ̀wọ̀ fún un gan-an ni.

9. Báwo ni sùúrù ti ṣe pàtàkì tó? Báwo làwa náà ṣe lè jẹ́ onísùúrù bíi ti Ẹ́sítérì?

9 Sùúrù ṣeyebíye, ó sì ṣọ̀wọ́n gan-an. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkàn Ẹ́sítérì ò balẹ̀, tó sì fẹ́ láti sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún ọba, ó ṣe sùúrù títí di ìgbà tó yẹ kó sọ̀rọ̀. Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ la lè rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Ẹ́sítérì torí pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo wa là ń rí àwọn nǹkan tó nílò àtúnṣe. Tá a bá fẹ́ kí ẹnì kan tó wà nípò àṣẹ bá wá bójú tó ìṣòro kan, ó lè gba pé ká ní sùúrù bíi ti Ẹ́sítérì. Ìwé Òwe 25:15 sọ pé: “Sùúrù ni a fi ń rọ aláṣẹ lọ́kàn, ahọ́n pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ sì lè fọ́ egungun.” Tá a bá ṣe sùúrù di ìgbà tó yẹ, tá a sì sọ̀rọ̀ lọ́nà pẹ̀lẹ́, bíi ti Ẹ́sítérì, àwa náà lè borí àtakò tó le bí egungun. Ǹjẹ́ Ẹ́sítérì ń rí ìbùkún Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ gbà bó ṣe ń lo sùúrù àti ọgbọ́n?

Sùúrù Ẹ́sítérì Mú Kó Rí Ìdájọ́ Òdodo Gbà

10, 11. Kí nìdí tí ojú Hámánì fi yí pa dà lẹ́yìn tó kúrò níbi àkànṣe àsè àkọ́kọ́ yẹn? Kí ni ìyàwó àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ gbà á nímọ̀ràn pé kó ṣe?

10 Ọ̀pọ̀ nǹkan ló bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀ ní àsìkò tí Ẹ́sítérì fi ń ṣe sùúrù. Nígbà tí Hámánì kúrò níbi àkànṣe àsè àkọ́kọ́ yẹn, inú rẹ̀ dùn gan-an pé òun ni ọba àti ayaba yẹ́ sí tó bẹ́ẹ̀. Àmọ́ bí Hámánì ṣe ń gba ẹnubodè ààfin jáde ló rí Módékáì, ìyẹn Júù tó ṣì kọ̀ láti júbà rẹ̀. Bá a ṣe rí i ní orí kẹẹ̀ẹ́dógún, kì í ṣe ìwà ọ̀yájú ló mú kí Módékáì kọ̀ láti júbà Hámánì. Ẹ̀rí ọkàn Módékáì àti àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run ni kò jẹ́ kó ṣe bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, ńṣe ni Hámánì “kún fún ìhónú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.”—Ẹ́sít. 5:9.

11 Hámánì rojọ́ fún aya rẹ̀ àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ pé Módékáì ṣe àfojúdi sí òun. Torí náà, wọ́n sọ fún un pé kó ṣe òpó igi kan tó ga ju mítà méjìlélógún tàbí òpó iná méjì lọ. Lẹ́yìn náà, kó wá lọ gba àṣẹ lọ́dọ̀ ọba pé kí wọ́n gbé Módékáì kọ́ sórí rẹ̀. Ìmọ̀ràn wọn dára lójú Hámánì, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló sì ní kí wọ́n lọ ṣètò òpó náà.—Ẹ́sít. 5:12-14.

12. Kí nìdí tí ọba fi ní kí wọ́n ka ìwé àkọsílẹ̀ àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìjọba òun sí òun létí? Kí ni ọba tipa báyìí mọ̀?

12 Ó ṣẹlẹ̀ pé ohun kan tó ṣàjèjì ṣẹlẹ̀ sí ọba ní òru mọ́jú. Bíbélì sọ pé: “Oorun dá lójú ọba.” Torí náà, ó ní kí wọ́n ka àkọsílẹ̀ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìjọba òun sí òun létí. Ara ohun tí wọ́n kà sí Ahasuwérúsì létí ni ọ̀rọ̀ nípa àwọn kan tó pète láti pa á. Ọba rántí ìṣẹ̀lẹ̀ náà; ọwọ́ tẹ àwọn tó fẹ́ pa ọba wọ́n sì pa wọ́n. Àmọ́ kí ni wọ́n ṣe fún Módékáì tó tú àṣírí ète tí wọ́n pa náà? Ṣàdédé ló sọ sí ọba lọ́kàn pé kó béèrè ohun tí wọ́n ṣe fún Módékáì. Nígbà tó sì béèrè, wọ́n sọ fún un pé wọn ò tíì ṣe nǹkan kan fún un.—Ka Ẹ́sítérì 6:1-3.

13, 14. (a) Báwo ni ọ̀rọ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í dojú rú fún Hámánì? (b) Kí ni àwọn ọ̀rẹ́ Hámánì àti ìyàwó rẹ̀ sọ fún un?

13 Ìdáhùn náà ká ọba lára gan-an, ó wá béèrè òṣìṣẹ́ ààfin tó wà nítòsí tó lè ran òun lọ́wọ́ láti wá nǹkan ṣe sí àṣìṣe yẹn. Àfi bó ṣe jẹ́ pé Hámánì ló wà láàfin lásìkò náà. Ó jọ pé ńṣe ló jí wá ní kùtùkùtù. Ó ṣáà ń wù ú pé kó wá gbàṣẹ láti pa Módékáì. Àmọ́ kí Hámánì tó béèrè ohun tó fẹ́, ọba ní kó sọ ọ̀nà tó dára jù lọ tóun lè gbà dá ọkùnrin kan tó rí ojú rere ọba lọ́lá. Hámánì rò pé òun ni ọba ní lọ́kàn, ló bá yáa dámọ̀ràn àwọn nǹkan ńláńlá. Ó ní kí wọ́n fi aṣọ ọ̀ṣọ́ ọba wọ ọkùnrin náà, kí wọ́n gbé e gun orí ẹṣin ọba, kí wọ́n sì jẹ́ kí ọ̀kan lára àwọn ìjòyè pàtàkì mú un yí ká ìlú Ṣúṣánì, kó sì máa yìn ín bó ṣe ń lọ. Wo bó ṣe máa rẹ Hámánì wá nígbà tó gbọ́ pé Módékáì ni ọkùnrin tí ọba fẹ́ dá lọ́lá! Ta sì ni ọba yàn pé kó máa kókìkí Módékáì? Hámánì gan-an ni!—Ẹ́sít. 6:4-10.

14 Agbára káká ni Hámánì fi ṣe iṣẹ́ tó kà sí ìwọ̀sí ńlá yìí kó tó sá lọ sílé pẹ̀lú ìbànújẹ́ lọ́kàn rẹ̀. Aya rẹ̀ àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ fún un pé ńṣe ni nǹkan tó ṣẹlẹ̀ yẹn fi hàn pé ibi tí wàhálà tó ń bá Módékáì, tó jẹ́ Júù, fà máa já sí ò ní dáa.—Ẹ́sít. 6:12, 13.

15. (a) Báwo ni sùúrù Ẹ́sítérì ṣe já sí ibi tó dáa? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká ní “ẹ̀mí ìdúródeni”?

15 Torí pé Ẹ́sítérì ṣe sùúrù, tó dúró fún ọjọ́ kan sí i kó tó bá ọba sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀, àyè ṣí sílẹ̀ fún Hámánì láti fi ọwọ́ ara rẹ̀ ṣe ara rẹ̀. Àfàìmọ̀ ni ò sì ní jẹ́ pé Jèhófà Ọlọ́run ló mú kí oorun dá lójú ọba mọ́jú ọjọ́ náà. (Òwe 21:1) Abájọ tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi gbà wá níyànjú pé ká ní “ẹ̀mí ìdúródeni”! (Ka Míkà 7:7.) Tá ò bá sì kánjú ju Ọlọ́run lọ, a lè wá rí i pé ọ̀nà tó máa gbà yanjú ìṣòro wa máa ta yọ ọgbọ́n yòówù tí àwa fúnra wa bá fẹ́ dá sí i.

Ó Fi Ìgboyà Sọ̀rọ̀

16, 17. (a) Àkókò wo ni “ìgbà sísọ̀rọ̀” dé fún Ẹ́sítérì? (b) Báwo ni Ẹ́sítérì ṣe yàtọ̀ sí Fáṣítì tó jẹ́ ayaba tẹ́lẹ̀?

16 Ẹ́sítérì ò jẹ́ tán ọba ní sùúrù, torí náà ó gbọ́dọ̀ sọ tẹnu rẹ̀ níbi àkànṣe àsè kejì. Àmọ́, lọ́nà wo? Ọba fúnra rẹ̀ ló fún un láǹfààní láti sọ̀rọ̀, torí ó tún bi Ẹ́sítérì pé kó sọ ohun tó fẹ́ béèrè lọ́wọ́ òun. (Ẹ́sít. 7:2) “Ìgbà sísọ̀rọ̀” tó wàyí fún Ẹ́sítérì.

17 Àfàìmọ̀ kó máà jẹ́ pé ńṣe ni Ẹ́sítérì kọ́kọ́ fọkàn gbàdúrà ìdákẹ́jẹ́ẹ́ sí Ọlọ́run kó tó wá bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Bí mo bá ti rí ojú rere ní ojú rẹ, ọba, bí ó bá sì dára ní ojú ọba, jẹ́ kí a fi ọkàn mi fún mi nípa ohun tí mo tọrọ àti àwọn ènìyàn mi nípa ìbéèrè mi.” (Ẹ́sít. 7:3) Wà á rí i nínú ọ̀rọ̀ tí Ẹ́sítérì sọ pé ó ṣe tán láti fara mọ́ ohun tí ọba bá pinnu pé ó dára. Ẹ ò rí i pé gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ ni Ẹ́sítérì fi yàtọ̀ sí Fáṣítì tó jẹ́ aya ọba tẹ́lẹ̀, ẹni tó dìídì dójú ti ọkọ rẹ̀! (Ẹ́sít. 1:10-12) Bákan náà, Ẹ́sítérì ò ṣe lámèyítọ́ ọba pé ìwà òmùgọ̀ ló hù torí bó ṣe fọkàn tán Hámánì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló bẹ ọba pé kó gba òun torí ẹ̀mí òun wà nínú ewu.

18. Báwo ni Ẹ́sítérì ṣe sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ fún ọba?

18 Ẹ̀bẹ̀ yìí ta ọba kìjí, ó sì yà á lẹ́nu gidigidi. Ta ní lórí láyà láti gba ẹ̀mí ayaba òun? Ẹ́sítérì wá ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “A ti tà wá, èmi àti àwọn ènìyàn mi, láti pa wá rẹ́ ráúráú, láti pa wá àti láti run wá. Wàyí o, ká ní a tà wá láti di ẹrúkùnrin lásán-làsàn àti ìránṣẹ́bìnrin lásán-làsàn ni, èmi ì bá dákẹ́. Ṣùgbọ́n wàhálà náà kò bá a mu nígbà tí yóò jẹ́ sí ìpalára ọba.” (Ẹ́sít. 7:4) Kíyè sí i pé Ẹ́sítérì sọ bí ìṣòro náà ṣe jẹ́ gan-an láìfọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀, síbẹ̀ ó fi kún un pé, òun ì bá dákẹ́ ká ní ẹrú lásán ni wọ́n fẹ́ fi àwọn ṣe. Ṣùgbọ́n ìpalára tó máa ṣe fún ọba tí wọ́n bá pa odindi ẹ̀yà kan run kọjá ohun tí òun lè mú mọ́ra.

19. Kí la lè rí kọ́ lára Ẹ́sítérì nípa béèyàn ṣe lè sọ̀rọ̀ lọ́nà tó ń yíni lọ́kàn pa dà?

19 A rí ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ kọ́ lára Ẹ́sítérì nípa béèyàn ṣe lè sọ̀rọ̀ lọ́nà tó ń yíni lọ́kàn pa dà. Tó o bá fẹ́ mú ìṣòro kan tó burú jáì wá sí etígbọ̀ọ́ èèyàn rẹ kan tàbí ẹnì kan tó wà nípò àṣẹ, ó máa gba pé kó o lo sùúrù, kó o fi ọ̀wọ̀ hàn, kó o sì sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí gan-an.—Òwe 16:21, 23.

20, 21. (a) Báwo ni Ẹ́sítérì ṣe tú Hámánì fó? Kí ni ọba wá ṣe? (b) Kí ni Hámánì ṣe lẹ́yìn tí Ẹ́sítérì fi hàn pé amòòkùnṣìkà ni?

20 Ahasuwérúsì béèrè pé: “Ta ni ẹni yìí, ibo gan-an sì ni ẹni náà wà, tí ó ki ara rẹ̀ láyà láti ṣe bẹ́ẹ̀?” Fojú inú wo bí Ẹ́sítérì ṣe nàka sí Hámánì, tó sì sọ pé: “Ọkùnrin náà, elénìní àti ọ̀tá náà, ni Hámánì búburú yìí.” Ṣàǹgbá fọ́! Ìdí Hámánì domi. Wo bí ojú ọba tí inú rẹ̀ tètè máa ń ru yìí ṣe máa ranko nígbà tó wá rí i pé agbani-nímọ̀ràn tí òun fọkàn tán ti tan òun láti fọwọ́ sí ìwé àṣẹ tó máa yọrí sí ikú aya òun àtàtà! Ọba yára jáde lọ sínú ọgbà ààfin kí ìbínú rẹ̀ lè rọlẹ̀ díẹ̀.—Ẹ́sít. 7:5-7.

Ẹ́sítérì fi ìgboyà tú àṣírí ìwà ibi Hámánì

21 Ní báyìí tí àṣírí ti tú pé amòòkùnṣìkà ni Hámánì, ó wólẹ̀ sẹ́bàá ẹsẹ Ẹ́sítérì ó sì ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí i. Nígbà tí ọba pa dà wọlé tó sì rí Hámánì lórí àga ìrọ̀gbọ̀kú Ẹ́sítérì tó ń bẹ̀bẹ̀, inú bí i, ó sì fi ẹ̀sùn kan Hámánì pé ó fẹ́ fi ipá bá ayaba lò pọ̀ nínú ilé òun. Bí Hámánì ṣe gba ìdájọ́ ikú rẹ̀ nìyẹn o! Ni wọ́n bá daṣọ bò ó lójú wọ́n sì mú un lọ. Ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ààfin wá sọ fún ọba pé Hámánì tiẹ̀ ti ri òpó igi gàgàrà kan sílé rẹ̀ tó fẹ́ gbé Módékáì kọ́. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni ọba pàṣẹ pé Hámánì gan-an ni kí wọ́n lọ gbé kọ́ sórí òpó náà.—Ẹ́sít. 7:8-10.

22. Kí la rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Ẹ́sítérì tí kò ní jẹ́ ká sọ̀rètí nù, ká gbà pé kò sẹ́ni tó ṣeé gbára lé, tàbí kí ìgbàgbọ́ wa yingin?

22 Nínú ayé aláìṣòdodo tá à ń gbé yìí, ó rọrùn láti ronú pé kò síbi tá a ti lè rí ìdájọ́ òdodo. Ṣé irú èrò yẹn ti wá sí ẹ lọ́kàn rí? Ẹ́sítérì ò fìgbà kan sọ̀rètí nù, kò gbà pé kò sẹ́ni tó ṣeé gbára lé, ìgbàgbọ́ rẹ̀ kò sì yingin. Nígbà tí àkókò tó, ó fìgboyà sọ̀rọ̀ nípa ohun tó tọ́, ó sì fi ìyókù lé Jèhófà lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ kí àwa náà máa ṣe bíi ti Ẹ́sítérì! Jèhófà tó ran Ẹ́sítérì lọ́wọ́ ò tíì yí pa dà. Ó ṣì lè mú kí àwọn aṣebi àti àwọn alárèékérekè fi ọwọ́ ara wọn ṣe ara wọn bó ṣe rí nínú ọ̀ràn ti Hámánì.—Ka Sáàmù 7:11-16.

Ó Fínnúfíndọ̀ Lo Ara Rẹ̀ fún Jèhófà Àtàwọn Èèyàn Rẹ̀

23. (a) Báwo ni ọba ṣe dá Módékáì àti Ẹ́sítérì lọ́lá? (b) Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ tí Jékọ́bù sọ nípa Bẹ́ńjámínì ṣe ní ìmúṣẹ? (Wo àpótí náà, “ Àsọtẹ́lẹ̀ Kan Tó Ní Ìmúṣẹ.”)

23 Níkẹyìn, ọba wá mọ̀ pé yàtọ̀ sí bí Módékáì ṣe jẹ́ olóòótọ́ èèyàn tó tú àṣírí àwọn tó fẹ́ pa òun, òun náà tún ni alágbàtọ́ Ẹ́sítérì. Ahasuwérúsì wá fi Módékáì sí ipò igbá kejì ọba tí Hámánì wà tẹ́lẹ̀. Lẹ́yìn náà, ọba fún Ẹ́sítérì ní ilé Hámánì títí kan gbogbo dúkìá rẹpẹtẹ tó ní, Ẹ́sítérì sì fi gbogbo rẹ̀ sí ìkáwọ́ Módékáì.—Ẹ́sít. 8:1, 2.

24, 25. (a) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣírí Hámánì tó pète ibi ti tú, kí ló fà á tí Ẹ́sítérì ò fi káwọ́ gbera kó máa wòran? (b) Báwo ni Ẹ́sítérì ṣe tún fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu?

24 Ní báyìí tí ikú ti yẹ̀ lórí Ẹ́sítérì àti Módékáì, ṣó wá yẹ kí Ẹ́sítérì káwọ́ gbera kó máa wòran? Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé tara rẹ̀ nìkan ló mọ̀. Ní gbogbo ìgbà yẹn, wọ́n ṣì ń fi òfin tí Hámánì ṣe pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn Júù run ránṣẹ́ sí gbogbo àgbègbè ilẹ̀ ọba náà. Hámánì sì ti ṣẹ́ kèké tàbí Púrì, tó jẹ́ oríṣi ọ̀nà ìbẹ́mìílò kan, láti fi mọ àkókò tó dára jù lọ tí wọ́n máa pa àwọn Júù nípa ìkà. (Ẹ́sít. 9:24-26) Òótọ́ ni pé ó ṣì máa tó oṣù mélòó kan sí i, àmọ́ ọjọ́ náà túbọ̀ ń yára sún mọ́lé. Ǹjẹ́ wọ́n tiẹ̀ lè rí nǹkan ṣe sí àjálù náà?

25 Ẹ́sítérì tún fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu, ó lọ sọ́dọ̀ ọba lẹ́ẹ̀kan sí i láìjẹ́ pé ọba ní kó wá. Lọ́tẹ̀ yìí, ńṣe ló ń sunkún nítorí àwọn èèyàn rẹ̀, ó sì ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ọkọ rẹ̀ pé kó wọ́gi lé òfin líle koko yẹn. Ṣùgbọ́n òfin tí wọ́n bá ti ṣe ní orúkọ ọba Páṣíà kò ṣeé wọ́gi lé. (Dán. 6:12, 15) Torí náà, ọba fún Ẹ́sítérì àti Módékáì láṣẹ pé kí wọ́n ṣe òfin míì. Èyí mú kí wọ́n pa dà kéde fún àwọn èèyàn pé ọba ti fún àwọn Júù láṣẹ láti gbèjà ara wọn. Látàrí èyí, àwọn ẹlẹ́ṣin sáré mú ìròyìn ayọ̀ yìí tọ àwọn Júù tó wà jákèjádò ilẹ̀ ọba náà lọ. Ó wá ṣe kedere sí àwọn Júù báyìí pé àwọn ti rí ọ̀nà àbáyọ. (Ẹ́sít. 8:3-16) Ẹ sì wo bí àwọn Júù jákèjádò ilẹ̀ ọba tó gbòòrò náà á ṣe máa kó ohun ìjà jọ tí wọ́n á sì máa gbára dì! Ká ní kì í ṣe ti òfin tuntun yẹn ni, wọn ò ní lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n, pàtàkì ibẹ̀ ni pé, ǹjẹ́ “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun” máa wà pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀?—1 Sám. 17:45.

Ẹ́sítérì àti Módékáì fi àwọn ìkéde ránṣẹ́ sí àwọn Júù tó ń gbé ní Ilẹ̀ Ọba Páṣíà

26, 27. (a) Báwo ni àwọn èèyàn Jèhófà ṣe ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn tó látàrí bó ṣe tì wọ́n lẹ́yìn? (b) Àsọtẹ́lẹ̀ wo ló ṣẹ nígbà tí wọ́n pa àwọn ọmọkùnrin Hámánì?

26 Nígbà tí ọjọ́ tí wọ́n dá pé, àwọn Júù ti múra tán láti gbèjà ara wọn. Kódà ọ̀pọ̀ nínú àwọn olóyè láàfin ọba Páṣíà ti wà lẹ́yìn wọn báyìí, torí òkìkí ti kàn káàkiri pé Módékáì tó jẹ́ Júù ti di igbá kejì ọba. Jèhófà mú kí àwọn èèyàn rẹ̀ ṣẹ́gun lọ́nà tó kàmàmà. Ó dájú pé ó jẹ́ kí àwọn èèyàn rẹ̀ pa àwọn ọ̀tá wọn run yán-ányán-án, kó má bàa di pé wọ́n á pa dà wá gbẹ̀san. *Ẹ́sít. 9:1-6.

27 Bákan náà, ẹ̀mí Módékáì máa wà nínú ewu tó bá ń ṣàkóso ilé Hámánì nígbà tí àwọn ọmọkùnrin mẹ́wàá tí Hámánì bí ṣì wà láàyè. Nítorí èyí, wọ́n pa àwọn ọmọ Hámánì pẹ̀lú. (Ẹ́sít. 9:7-10) Ọlọ́run ti sọ tipẹ́tipẹ́ pé wọ́n máa pa àwọn ará Ámálékì tó jẹ́ ọ̀tá àwọn èèyàn rẹ̀ run pátápátá. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ló wá mú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì náà ṣẹ. (Diu. 25:17-19) Ó sì ṣeé ṣe kí àwọn ọmọ Hámánì yìí jẹ́ ara àwọn tó gbẹ́yìn pátápátá nínú ẹ̀yà Ámálékì tí Ọlọ́run ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa pa run.

28, 29. (a) Kí nìdí tí Jèhófà fi fọwọ́ sí i pé kí Ẹ́sítérì àti àwọn èèyàn rẹ̀ jagun? (b) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ìbùkún ni àpẹẹrẹ tí Ẹ́sítérì fi lélẹ̀ jẹ́ fún wa lónìí?

28 Iṣẹ́ bàǹtàbanta ló já lé Ẹ́sítérì léjìká látàrí bó ṣe bá wọn lọ́wọ́ sí òfin tó ní í ṣe pẹ̀lú ogun jíjà àti pípani. Ó kúrò ni kèrémí. Àmọ́, ó wu Jèhófà pé kó dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó fẹ́ pa wọ́n run. Ìdí sì ni pé orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí yóò ti wá. Ipasẹ̀ Mèsáyà yìí nìkan ṣoṣo ni aráyé fi máa rí ìgbàlà. (Jẹ́n. 22:18) Ó dùn mọ́ àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní pé nígbà tí Jésù tó jẹ́ Mèsáyà wá sáyé, ó pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé wọn kò gbọ́dọ̀ jagun nípa tara mọ́.—Mát. 26:52.

29 Àmọ́ ṣá o, àwa Kristẹni ṣì ń ja irú ogun kan. Torí pé Sátánì túbọ̀ ń wá gbogbo ọ̀nà tó lè fi ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run jẹ́, à ń lọ́wọ́ nínú ogun tẹ̀mí. (Ka 2 Kọ́ríńtì 10:3, 4.) Ìbùkún ńlá ni àpẹẹrẹ tí Ẹ́sítérì fi lélẹ̀ jẹ́ fún wa! Bíi ti Ẹ́sítérì, ẹ jẹ́ kí àwa náà ní ìgbàgbọ́, ká máa fi ọgbọ́n àti sùúrù sọ̀rọ̀ lọ́nà tó ń yíni lérò pa dà, ká jẹ́ onígboyà, ká sì múra tán láti fi ẹ̀mí ara wa wewu ká lè gbèjà àwọn èèyàn Ọlọ́run.

^ ìpínrọ̀ 26 Ọba gba àwọn Júù láyè láti máa bá ìjà náà lọ lọ́jọ́ kejì kí wọ́n lè rẹ́yìn àwọn ọ̀tá wọn. (Ẹ́sít. 9:12-14) Àwọn Júù ṣì máa ń ṣe ìrántí ìṣẹ́gun yẹn lọ́dọọdún. Ó máa ń jẹ́ ní oṣù Ádárì, èyí tó sábà máa ń bọ́ sí ìparí oṣù February àti ìbẹ̀rẹ̀ oṣù March lóde òní. Wọ́n ń pe ayẹyẹ náà ní Púrímù, ìyẹn orúkọ kèké tí Hámánì ṣẹ́ nígbà tó pète láti pá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì run.