Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ KẸFÀ

Ó Sọ Ẹ̀dùn Ọkàn Rẹ̀ fún Ọlọ́run Nínú Àdúrà

Ó Sọ Ẹ̀dùn Ọkàn Rẹ̀ fún Ọlọ́run Nínú Àdúrà

1, 2. (a) Kí ló dé tí inú Hánà fi bà jẹ́ nígbà tó ń múra ìrìn àjò? (b) Kí la lè rí kọ́ nínú ìtàn Hánà?

HÁNÀ ń múra sílẹ̀ fún ìrìn àjò tí wọ́n fẹ́ lọ. Tọkàn tara ló sì fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ kó má bàa máa ronú nípa ìṣòro rẹ̀. Ńṣe ló yẹ kí inú Hánà máa dùn ní àkókò yìí torí pé ọdọọdún ni ọkọ rẹ̀, Ẹlikénà, máa ń kó gbogbo wọn lọ sí àgọ́ ìjọsìn tó wà ní Ṣílò kí wọ́n lè lọ sin Jèhófà níbẹ̀. Jèhófà fẹ́ kí àwọn èèyàn rẹ̀ tó bá lọ síbẹ̀ máa láyọ̀. (Ka Diutarónómì 16:15.) Ó sì dájú pé láti kékeré ni Hánà ti máa ń fẹ́ láti lọ síbi àjọyọ̀ náà. Àmọ́, nǹkan ti yí pa dà fún un láti bí ọdún díẹ̀ sẹ́yìn.

2 Hánà ní ọkọ tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an. Àmọ́, ọkọ rẹ̀, Ẹlikénà, tún ní ìyàwó míì. Pẹ̀nínà ni orúkọ rẹ̀, ó sì jọ pé ńṣe ló mọ̀ọ́mọ̀ fẹ́ láti fi ayé sú Hánà. Kódà, ó bá a débi pé ó máa ń sọ ibi àjọyọ̀ ọdọọdún tí wọ́n máa ń lọ náà di àkókò ìbànújẹ́ fún Hánà. Lọ́nà wo? Tàbí, ní pàtàkì ju lọ, báwo ni ìgbàgbọ́ tí Hánà ní nínú Jèhófà ṣe mú kó borí ìṣòro tó dà bíi pé kò ṣeé fara dà yìí? Ìtàn Hánà máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, ó sì lè tù ẹ́ nínú tó o bá ń dojú kọ àwọn ìṣòro tó ń mu ẹ́ lómi.

Kí Nìdí Tí Inú Rẹ Fi Bà Jẹ́?

3, 4. Ìṣòro ńlá méjì wo ló ń bá Hánà fínra? Báwo ni ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ṣe kanpá?

3 Bíbélì sọ fún wa nípa ìṣòro ńlá méjì tó ń bá Hánà fínra. Ó lè rí nǹkan díẹ̀ ṣe sí ìṣòro àkọ́kọ́, àmọ́ ìṣòro kejì kọjá agbára rẹ̀. Ìṣòro àkọ́kọ́ ni pé ọkọ rẹ̀ ní ju ìyàwó kan lọ, orogún rẹ̀ sì kórìíra rẹ̀. Ìṣòro kejì ni pé ó yàgàn. Ìṣòro yìí kò rọrùn rárá fún ìyàwó ilé èyíkéyìí tó ń wá ọmọ. Ohun tó ń fa ìbànújẹ́ ọkàn tó lé kenkà ló tún wá jẹ́ nígbà ayé Hánà àti nínú àṣà ìbílẹ̀ wọn. Ìdí ni pé ìdílé kọ̀ọ̀kan gbà pé ọmọ bíbí ni kò ní jẹ́ kí orúkọ ìdílé àwọn pa rún. Nǹkan ẹ̀gàn àti ìtìjú burúkú ni wọ́n kà á sí téèyàn bá yàgàn.

4 Ì bá rọrùn fún Hánà láti fara da ipò náà bí kì í bá ṣe ti Pẹ̀nínà tó ń dá kún ìṣòro rẹ̀. Kò tíì sí ìgbà kan rí tí ìkóbìnrinjọ dára. Oní ìjà, ọ̀la ariwo, owú àti ìbànújẹ́ kì í wọ́n nílé olóbìnrin púpọ̀. Ó yàtọ̀ pátápátá sí ìlànà ọkọ kan aya kan tí Ọlọ́run fi lélẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì. (Jẹ́n. 2:24) Torí náà, Bíbélì ò sọ̀rọ̀ rere nípa ìkóbìnrinjọ, wàhálà tó wà nínú ilé Ẹlikénà sì jẹ́ ká mọ̀ pé òótọ́ ni ìkóbìnrinjọ kò dára.

5. Kí nìdí tí Pẹ̀nínà fi fẹ́ kí ayé nira fún Hánà? Báwo ló ṣe fòòró ẹ̀mí Hánà?

5 Láàárín àwọn méjèèjì, Hánà ni Ẹlikénà fẹ́ràn jù. Ó wà nínú ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Júù pé Hánà ló kọ́kọ́ fẹ́, ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà ló wá fẹ́ Pẹ̀nínà. Àmọ́, ohun tó dájú ni pé, Pẹ̀nínà ń jowú Hánà gan-an, ó sì fi ayé ni ín lára ni ọ̀pọ̀ ọ̀nà. Ohun tó ń gun Pẹ̀nínà ni pé ó rí ọmọ bí ní tiẹ̀. Ńṣe ló ń bímọ lémọ, bó sì ṣe ń bí ọmọ kọ̀ọ̀kan ló túbọ̀ ń jọra rẹ̀ lójú. Dípò tí Pẹ̀nínà ì bá fi máa káàánú Hánà, kó sì máa tù ú nínú, ńṣe ló ń fi àìrí ọmọ bí gún un lára. Bíbélì sọ pé Pẹ̀nínà mú Hánà bínú gidigidi “nítorí àtimú kí àìbalẹ̀-ọkàn bá a.” (1 Sám. 1:6) Pẹ̀nínà mọ̀ọ́mọ̀ ṣe àwọn nǹkan tó ń ṣe yẹn ni. Ó fẹ́ ba Hánà lọ́kàn jẹ́, ó sì rí i ṣe.

Ìdààmú ọkàn bá Hánà gidigidi nítorí pé ó yàgàn, Pẹ̀nínà sì túbọ̀ ń bà á nínú jẹ́

6, 7. (a) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ẹlikénà gbìyànjú láti tu Hánà nínú, kí nìdí tí Hánà ò fi ṣàlàyé gbogbo nǹkan tó ń bà á lọ́kàn jẹ́ fún un? (b) Ṣé torí pé inú Jèhófà ò dùn sí Hánà ni kò ṣe rí ọmọ bí? Ṣàlàyé. (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

6 Ó jọ pé ìgbà tí wọ́n bá ń rìnrìn-àjò ọdọọdún lọ sí Ṣílò láti lọ jọ́sìn ni Pẹ̀nínà fẹ́ràn jù láti máa ba Hánà nínú jẹ́. Ẹlikénà máa ń fún ọ̀kọ̀ọ̀kan lára àwọn ọmọ Pẹ̀nínà, ìyẹn “gbogbo ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀,” ní ìpín lára ohun tó bá fi rúbọ sí Jèhófà. Àmọ́ nítorí pé Hánà kò bímọ, ìpín kan ṣoṣo ni Ẹlikénà máa ń fún un. Látàrí èyí, Pẹ̀nínà máa ń fi Hánà ṣe yẹ̀yẹ́, ó sì máa ń fi àwọn ọmọ rẹ̀ yán an lójú débi pé ńṣe ni Hánà á máa sunkún tí kò sì ní lè jẹun. Nígbà tí Ẹlikénà rí i pé ọkàn olólùfẹ́ òun bà jẹ́ kò sì jẹun, ó wá bó ṣe máa tù ú nínú. Ó bi í pé, “Hánà, èé ṣe tí o fi ń sunkún, èé sì ti ṣe tí o kò fi jẹun, èé sì ti ṣe tí ìbànújẹ́ fi dé bá ọkàn-àyà rẹ? Èmi kò ha sàn fún ọ ju ọmọkùnrin mẹ́wàá lọ bí?”—1 Sám. 1:4-8.

7 Bí Ẹlikénà ṣe rò ó gan-an ló rí, àìrí ọmọ bí ló fa ìbànújẹ́ Hánà. Hánà sì mọyì bí Ẹlikénà ṣe máa ń fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. * Àmọ́ ṣá o, Ẹlikénà ò mẹ́nu kan bí Pẹ̀nínà ṣe ń fòòró Hánà, àkọsílẹ̀ náà ò sì sọ pé Hánà sọ fún un. Ó ṣeé ṣe kó ronú pé bí òun bá sọ nǹkan tí Pẹ̀nínà ṣe, ńṣe nìyẹn á dá kún ìṣòro náà. Àti pé bí òun bá tiẹ̀ sọ, ǹjẹ́ ohun kan wà ti Ẹlikénà lè ṣe sí i? Ṣé ìyẹn ò tiẹ̀ ní mú kí Pẹ̀nínà túbọ̀ máa pẹ̀gàn Hánà? Ṣé àwọn ọmọ òfínràn náà àtàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ò ní dá tiwọn sí i, kí wọ́n sì mú kí ayé túbọ̀ nira fún Hánà? Bí ọ̀rọ̀ bá sì rí bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Hánà á túbọ̀ máa dà bí àjèjì ní ọ̀ọ̀dẹ̀ ọkọ rẹ̀.

Nígbà tí orogún Hánà mú ayé nira fún un, ó wá ìtùnú lọ sọ́dọ̀ Jèhófà

8. Bí àwọn èèyàn bá ń fòòró rẹ tàbí tí wọ́n ń ṣe ohun tí kò tọ́ sí ẹ, tó o bá rántí pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run ìdájọ́ òdodo, báwo nìyẹn ṣe lè tù ẹ́ nínú?

8 Ẹlikénà lè má mọ bí Pẹ̀nínà ṣe ń fòòró Hánà tó, àmọ́ ojú Jèhófà Ọlọ́run tó gbogbo rẹ̀. Bíbélì sì sọ gbogbo bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí fún wa. Kí nìdí? Kó lè jẹ́ ìkìlọ̀ pàtàkì fún àwọn tó bá ń jowú nítorí ohun tí kò tó nǹkan, tí ìkórìíra sì máa ń mú kí wọ́n hùwà tí kò tọ́. Bákan náà, àwọn tó dà bíi Hánà, tí wọn kì í fi ibi san ibi, tí wọn kì í sì í fa wàhálà máa rí ìtùnú gbà. Lọ́nà wo? Ní ti pé Ọlọ́run ìdájọ́ òdodo máa mú gbogbo ọ̀ràn tọ́ ní àkókò tó fẹ́ àti ní ọ̀nà tó wù ú. (Ka Diutarónómì 32:4.) Ó ṣeé ṣe kí Hánà mọ̀ bẹ́ẹ̀, torí pé Jèhófà ló bẹ̀ pé kó ran òun lọ́wọ́.

“Ìdàníyàn fún Ara Ẹni Kò sì Hàn Lójú Rẹ̀ Mọ́”

9. Kí la rí kọ́ látinú bí Hánà ṣe yàn láti lọ sí Ṣílò bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó mọ irú ìwà tí Pẹ̀nínà máa hù sí òun?

9 Láti òwúrọ̀ kùtù ni tọmọdé tàgbà nínú ìdílé Ẹlikénà ti ń di ẹrù, bí wọ́n ṣe ń múra láti rìnrìn-àjò lọ sí Ṣílò. Ìdílé ńlá ni ìdílé Ẹlikénà, wọ́n sì máa rin ìrìn tó ju ọgbọ̀n kìlómítà lọ ní àwọn àgbègbè Éfúráímù tí òkè pọ̀ sí, kí wọ́n tó dé Ṣílò. * Ìrìn-àjò náà máa ń gbà tó ọjọ́ kan tàbí méjì téèyàn bá fi ẹsẹ̀ rìn ín. Hánà mọ ohun tí orogún rẹ̀ máa ṣe. Àmọ́, kò torí ìyẹn jókòó sílé. Ó tipa bẹ́ẹ̀ fi àpẹẹrẹ rere tó ṣì wúlò títí di òní lélẹ̀ fún àwa olùjọ́sìn Ọlọ́run. Kò bọ́gbọ́n mu ká jẹ́ kí ìwà àìtọ́ àwọn míì dí wa lọ́wọ́ láti máa sin Ọlọ́run. Tá a bá jẹ́ kí èyí ṣẹlẹ̀ sí wa, a ò ní rí ìbùkún Jèhófà gbà mọ́. Ìbùkún yẹn ló sì máa jẹ́ ká lè fara da ipò tó nira.

10, 11. (a) Kí nìdí tí Hánà ò fi jáfara láti lọ sí àgọ́ ìjọsìn lẹ́yìn tí wọ́n gúnlẹ̀ ìrìn-àjò wọn? (b) Báwo ni Hánà ṣe sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún Baba rẹ̀ ọ̀run nínú àdúrà?

10 Látàárọ̀ tí ìdílé ńlá náà ti ń rìn gba àárín àwọn òkè ńlá, níkẹyìn wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wo Ṣílò lọ́ọ̀ọ́kán. Orí òkè ló wà. Àwọn òkè ńláńlá míì sì fẹ́rẹ̀ẹ́ yí i po. Bí wọ́n ṣe ń sún mọ́ ibẹ̀, ó ṣeé ṣe kí Hánà máa ronú gan-an nípa ohun tó máa sọ fún Jèhófà nínú àdúrà. Nígbà tí wọ́n débẹ̀, gbogbo wọn jẹun. Láìjáfara, Hánà fi àwọn yòókù sílẹ̀, ó sì lọ síbi àgọ́ ìjọsìn Jèhófà. Élì tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà wà níbẹ̀, ó jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ òpó ilẹ̀kùn. Àmọ́ àdúrà tí Hánà fẹ́ gbà sí Ọlọ́run ló gbà á lọ́kàn. Ó dá a lójú pé Ọlọ́run á fetí sí àdúrà tó bá gbà níbẹ̀. Bí kò bá tiẹ̀ sí èèyàn tó mọ ohun tó jẹ́ ẹdùn ọkàn rẹ̀ dunjú, Baba rẹ̀ ọ̀run mọ̀ ọ́n. Bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í rántí àwọn ohun tó ń bà á lọ́kàn jẹ́, ńṣe ló bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún.

11 Bí ara Hánà ṣe ń gbọ̀n torí ẹkún tó ń sun, ó bá Jèhófà sọ̀rọ̀ nínú ọkàn rẹ̀. Ètè rẹ̀ ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ bó ṣe ń ronú àwọn ọ̀rọ̀ tó lè fi ṣàlàyé ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀. Ó sì gbàdúrà fún àkókò gígùn, ó sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún Baba rẹ̀ ọ̀run. Àmọ́ ṣá o, Hánà ò fi ọ̀rọ̀ náà mọ sórí wíwulẹ̀ béèrè pé kí Ọlọ́run fún òun ni ọmọ. Kì í wulẹ̀ ṣe ìbùkún tó fẹ́ rí gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run nìkan ló jẹ ẹ́ lógún, ó tún fẹ́ láti fún Ọlọ́run ní gbogbo ohun tó bá wà ní agbára rẹ̀. Torí náà ó jẹ́jẹ̀ẹ́ pé bí òun bá bí ọkùnrin, òun á mú un wá sí àgọ́ ìjọsìn, kó lè máa sin Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.—1 Sám. 1:9-11.

12. Kí ni ìtàn Hánà kọ́ wa nípa ohun tó yẹ ká máa fi sọ́kàn tá a bá fẹ́ gbàdúrà?

12 Ohun tí Hánà ṣe yìí jẹ́ àpẹẹrẹ tó yẹ kí gbogbo àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa tẹ̀ lé tá a bá fẹ́ gbàdúrà. Aláàánú ni Jèhófà, ó sì fẹ́ kí àwọn èèyàn òun máa bá òun sọ̀rọ̀ fàlàlà. Kò fẹ́ kí wọ́n fi ohunkóhun pa mọ́, ó fẹ́ kí wọ́n sọ gbogbo ẹ̀dùn ọkàn wọn fún òun bí ọmọ tó fọkàn tán àwọn òbí rẹ̀ torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Ka Sáàmù 62:8; 1 Tẹsalóníkà 5:17.) Jèhófà mí sí àpọ́sítélì Pétérù láti ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tó ń tuni nínú yìí nípa àdúrà. Ó ní: “Ẹ . . . kó gbogbo àníyàn yín lé e, nítorí ó bìkítà fún yín.”—1 Pét. 5:7.

13, 14. (a) Èrò tí kò tọ̀nà wo ni Élì ní nípa Hánà? (b) Báwo ni èsì tí Hánà fún Élì ṣe fi hàn pé ó ní ìgbàgbọ́ tó ta yọ?

13 Àmọ́ ṣá o, àwa èèyàn ò ní òye bíi ti Jèhófà, a ò sì lè báni kẹ́dùn bíi tiẹ̀. Bí Hánà ṣe ń sunkún tó sì ń gbàdúrà, ó ṣàdédé gbọ́ ohùn ẹnì kan. Ohùn Élì àlùfáà àgbà ni. Ó ṣe díẹ̀ tó ti ń wo Hánà láti ibi tó jókòó sí. Ó ní: “Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò fi máa ṣe bí ọ̀mùtípara? Mú wáìnì rẹ kúrò lára rẹ.” Élì ti ṣàkíyèsí pé ètè Hánà ń gbọ̀n, ó ń sunkún, ó sì ní ẹ̀dùn ọkàn. Dípò tí ì bá fi béèrè ohun tó ṣe é, ńṣe ló gbà pé ó ti mutí yó.—1 Sám. 1:12-14.

14 Lákòókò tí Hánà wà nínú ìdààmú ọkàn yẹn, ó máa dùn ún gan-an pé ẹnì kan fi ẹ̀sùn tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ kan òun, àgàgà tó tún lọ jẹ́ ẹni táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún! Síbẹ̀, Hánà tún fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ pé òun ní ìgbàgbọ́ tó ta yọ. Kò jẹ́ kí àìpé Élì dí òun lọ́wọ́ láti máa jọ́sìn Jèhófà. Ó dá Élì lóhùn tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó sì ṣàlàyé ohun tó ń ṣe é fún un. Élì fi ohùn tútù fèsì lọ́nà tó fi hàn pé ó kábàámọ̀, ó ní: “Máa lọ ní àlàáfíà, kí Ọlọ́run Ísírẹ́lì sì yọ̀ǹda ìtọrọ tí o ṣe lọ́dọ̀ rẹ̀.”—1 Sám. 1:15-17.

15, 16. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Hánà lẹ́yìn tó sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún Jèhófà, tó sì jọ́sìn rẹ̀ nínú àgọ́ ìjọsìn? (b) Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Hánà tí ìṣòro bá wọ̀ wá lọ́rùn tàbí tí ìbànújẹ́ bá dorí wa kodò?

15 Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Hánà lẹ́yìn tó sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún Jèhófà tó sì tún jọ́sìn rẹ̀ nínú àgọ́ ìjọsìn? Bíbélì sọ pé: “Obìnrin náà sì bẹ̀rẹ̀ sí bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó sì jẹun, ìdàníyàn fún ara ẹni kò sì hàn lójú rẹ̀ mọ́.” (1 Sám. 1:18) Bíbélì Mímọ́ sọ pé: “Kò sì fa ojú ro mọ́.” Ara tu Hánà. Ìdí ni pé ó ti fa ohun tó jẹ́ ìdààmú ọkàn rẹ̀ lé ẹni tó lágbára jù ú lọ fíìfíì lọ́wọ́, ìyẹn Baba rẹ̀ ọ̀run. (Ka Sáàmù 55:22.) Ǹjẹ́ ìṣòro kan wà tó tóbi jù fún Ọlọ́run? Rárá o, kò tíì sí irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ rí, kò sì lè sí láéláé!

16 Nígbà tí ìṣòro bá wọ̀ wá lọ́rùn tàbí tí ìbànújẹ́ bá dorí wa kodò, á dára ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Hánà, ká sọ̀rọ̀ fàlàlà fún Ẹni tí Bíbélì pè ní “Olùgbọ́ àdúrà.” (Sm. 65:2) Tá a bá ní ìgbàgbọ́ pé Ọlọ́run máa gbọ́ àdúrà wa, àwa náà á rí i pé Ọlọ́run lè fi “àlàáfíà” rẹ̀ “tí ó ta gbogbo ìrònú yọ” rọ́pò ìbànújẹ́ wa.—Fílí. 4:6, 7.

‘Kò Sí Àpáta Kan Tó Dà Bí Ọlọ́run Wa’

17, 18. (a) Báwo ni Ẹlikénà ṣe fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Hánà kó lè mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ṣẹ? (b) Kí ni Pẹ̀nínà ò lè ṣe fún Hánà mọ́?

17 Ní àárọ̀ ọjọ́ kejì, Ẹlikénà bá Hánà pa dà lọ sí àgọ́ ìjọsìn. Ó ṣeé ṣe kí Hánà ti sọ fún un nípa ohun tó tọrọ àti ẹ̀jẹ́ tó jẹ́. Ìdí ni pé bí obìnrin kan bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ lẹ́yìn ọkọ rẹ̀, Òfin Mósè fún ọkọ ní ẹ̀tọ́ láti fagi lé irú ẹ̀jẹ́ bẹ́ẹ̀. (Núm. 30:10-15) Olùfọkànsìn ni Ẹlikénà, torí náà kò fagi lé ẹ̀jẹ́ tí Hánà jẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni òun àti Hánà jùmọ̀ jọ́sìn Jèhófà nínú àgọ́ ìjọsìn kí wọ́n tó pa dà sílé.

18 Ìgbà wo ló tó hàn sí Pẹ̀nínà pé yẹ̀yẹ́ tí òun ń fi Hánà ṣe ò lè bà á nínú jẹ́ mọ́? Bíbélì kò sọ fún wa, àmọ́ gbólóhùn náà, “ìdàníyàn fún ara ẹni kò sì hàn lójú rẹ̀ mọ́” fi hàn pé inú Hánà bẹ̀rẹ̀ sí í dùn láti ìgbà yẹn lọ. Pẹ̀nínà wá rí i nígbà tó yá pé ìwà òǹrorò òun kò tu irun kankan lára Hánà mọ́. Látìgbà yẹn lọ, Bíbélì ò dárúkọ Pẹ̀nínà mọ́.

19. Ìbùkún wo ni Hánà rí gbà? Kí ló ṣe tó fi hàn pé ó mọ ibi tí ìbùkún náà ti wá?

19 Bí oṣù ṣe ń gorí oṣù, ìdùnnú tún wá ṣubú lu ayọ̀ fún Hánà tí ọkàn rẹ̀ ti balẹ̀ pẹ̀sẹ̀. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ó lóyún! Ṣùgbọ́n, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ayọ̀ Hánà pọ̀ jọjọ, kò fìgbà kan rí gbàgbé ibi tí ìbùkún náà ti wá. Nígbà tó bí ọmọkùnrin náà, ó sọ ọ́ ní Sámúẹ́lì, èyí tó túmọ̀ sí “Orúkọ Ọlọ́run.” Ó dájú pé èyí ní í ṣe pẹ̀lú bí Hánà ṣe ké pe orúkọ Jèhófà. Lọ́dún yẹn, kò bá Ẹlikénà àti àwọn yòókù lọ sí Ṣílò. Ó tọ́jú ọmọ náà nílé fún ọdún mẹ́ta títí tó fi já a lẹnu ọmú. Lẹ́yìn náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í múra ọkàn rẹ̀ sílẹ̀ de ọjọ́ tó máa gbé ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n yìí lọ sí Ṣílò.

20. Báwo ni Hánà àti Ẹlikénà ṣe mú ìlérí tí wọ́n ṣe fún Jèhófà ṣẹ?

20 Ó dájú pé kò rọrùn fún Hánà láti fi ọmọ náà sílẹ̀ ní Ṣílò. Àmọ́, ó mọ̀ pé wọ́n á tọ́jú Sámúẹ́lì dáadáa ní Ṣílò, ó sì lè jẹ́ lára àwọn obìnrin tó ń sìn nínú àgọ́ ìjọsìn náà ló máa tọ́jú rẹ̀. Àmọ́ ọmọ náà ṣì kéré gan-an, ta ló sì mọ̀ ọ́n wò bí ọlọ́mọ? Síbẹ̀, Hánà àti Ẹlikénà mú ọmọdékùnrin náà lọ sí àgọ́ ìjọsìn. Wọ́n ò ṣe bẹ́ẹ̀ torí pé ẹnikẹ́ni fi ipá mú wọn, àmọ́ ó jẹ́ nítorí pé wọ́n moore. Wọ́n rú ẹbọ ní ilé Ọlọ́run, wọ́n sì rán Élì létí ẹ̀jẹ́ tí Hánà jẹ́ níbẹ̀ ní ọdún mélòó kan sẹ́yìn. Lẹ́yìn náà wọ́n fa Sámúẹ́lì lé e lọ́wọ́.

Ìyá tó mọyì ọmọ ni Hánà jẹ́ fún Sámúẹ́lì

21. Báwo ni àdúrà tí Hánà gbà ṣe fi bí ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Jèhófà ṣe jinlẹ̀ tó hàn? (Tún wo àpótí náà, “Àdúrà Àrà Ọ̀tọ̀ Méjì.”)

21 Lẹ́yìn náà, Hánà gba àdúrà kan tí Ọlọ́run rí i pé ó yẹ kó wà nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ tó mí sí. Bó o ṣe ń ka ọ̀rọ̀ Hánà tó wà nínú 1 Sámúẹ́lì 2:1-10, wàá rí bí ìgbàgbọ́ rẹ̀ ṣe jinlẹ̀ tó nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tó wà níbẹ̀. Ó yin Jèhófà nítorí bó ṣe ń lo agbára rẹ̀ lọ́nà àgbàyanu, ìyẹn bó ṣe lè lo agbára rẹ̀ tí kò lẹ́gbẹ́ láti rẹ àwọn agbéraga sílẹ̀, láti bù kún àwọn tí a ń ni lára, láti pani, tàbí láti gbani lọ́wọ́ ikú pàápàá. Hánà yin Baba rẹ̀ ọ̀run nítorí pé òun ni ẹni mímọ́ jù lọ, nítorí ìdájọ́ òdodo rẹ̀ àti nítorí ìṣòtítọ́ rẹ̀. Abájọ tí Hánà fi sọ pé: “Kò sí àpáta kan tó dà bí Ọlọ́run wa.” Jèhófà ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, kì í sì í yí pa dà, ó máa ń dáàbò bo àwọn tí à ń ni lára àti àwọn tí a tẹ̀ lórí ba, tí wọ́n ń wojú rẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́.

22, 23. (a) Kí ló mú kó dá wa lójú pé Sámúẹ́lì gbà pé àwọn òbí rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ bó ṣe ń dàgbà? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe bù kún Hánà síwájú sí i?

22 Ìyá Sámúẹ́lì ní ìgbàgbọ́ gan-an nínú Jèhófà, àǹfààní ńlá nìyẹn sì jẹ́ fún Sámúẹ́lì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àárò ìyá rẹ̀ á máa sọ ọ́ bó ṣe ń dàgbà, ó mọ̀ pé kò jẹ́ gbàgbé òun. Ọdọọdún ni Hánà máa ń wá sí Ṣílò, ó sì máa ń mú ẹ̀wù àwọ̀lékè kékeré tí kò lápá wá fún Sámúẹ́lì kó lè máa fi ṣe iṣẹ́ ìsìn nínú àgọ́ ìjọsìn. Hánà fúnra rẹ̀ ló máa ń hun ẹ̀wù náà, èyí sì fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ ọmọ náà gan-an àti pé kò fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣeré. (Ka 1 Sámúẹ́lì 2:19.) A lè fojú inú wo bó ṣe ń wọ ẹ̀wù náà fún ọmọ rẹ̀, tó ń fọwọ́ tún un ṣe lára rẹ̀, tó ń wò ó tìdùnnú-tìdùnnú, tó ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ fún un, tó sì ń fún un ní ìṣírí. Ìbùkún ló jẹ́ fún Sámúẹ́lì pé ó ní irú ìyá rere bẹ́ẹ̀, òun fúnra rẹ̀ sì dàgbà di àrídunnú ọmọ fún àwọn òbí rẹ̀ àti fún gbogbo Ísírẹ́lì.

23 Hánà wá ńkọ́? Ọlọ́run ò gbàgbé òun náà. Jèhófà túbọ̀ ṣíjú àánú wò ó, ó sì bímọ márùn-ún míì fún Ẹlikénà. (1 Sám. 2:21) Àmọ́ ṣá o, ó ní láti jẹ́ pé ohun tí Hánà kà sí ìbùkún tó ga jù lọ ni bó ṣe túbọ̀ ń ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Baba rẹ̀ Jèhófà, bí ọdún ṣe ń gorí ọdún. Ǹjẹ́ kí ọ̀rọ̀ tìrẹ náà rí bíi ti Hánà, bó o ṣe ń gbìyànjú láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ rẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 7 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì sọ pé Jèhófà ti ‘sé ilé ọlẹ̀ Hánà,’ kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé inú Ọlọ́run kò dùn sí obìnrin onírẹ̀lẹ̀ àti olóòótọ́ yìí. (1 Sám. 1:5) Nígbà míì, Bíbélì máa ń sọ pé Ọlọ́run ló ṣe àwọn nǹkan kan tó wulẹ̀ fàyè gbà fún àwọn àkókò kan.

^ ìpínrọ̀ 9 Ó dà bíi pé ìlú ìbílẹ̀ Ẹlikénà, ìyẹn Rámà, ló wá ń jẹ́ Arimatíà nígbà ayé Jésù. Èyí ló jẹ́ ká mọ bí ìrìn-àjò náà ṣe gùn tó.