Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ KARÙN-ÚN

“Obìnrin Títayọ Lọ́lá”

“Obìnrin Títayọ Lọ́lá”

1, 2. (a) Iṣẹ́ wo ni Rúùtù ń ṣe? (b) Àwọn nǹkan dáadáa wo ni Rúùtù wá mọ̀ nípa Òfin Ọlọ́run àti nípa àwọn èèyàn Rẹ̀?

RÚÙTÙ kúnlẹ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ìtí ọkà bálì tó ti ń ṣà jọ látàárọ̀. Ní báyìí, ojú ọjọ́ ti bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà nínú oko ní gbogbo àgbègbè Bẹ́tílẹ́hẹ́mù torí pé ó ti ń di ọwọ́ ìrọ̀lẹ́. Ọ̀pọ̀ àwọn tó lọ ṣiṣẹ́ lóko ti ń darí lọ sílé. Wọ́n rọra ń lọ wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ sí ẹnubodè ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, tó wà lórí òkè kékeré kan nítòsí ibẹ̀. Ó dájú pé á ti rẹ Rúùtù gan-an torí àtàárọ̀ ló ti wà lẹ́nu iṣẹ́. Síbẹ̀, kò dáwọ́ iṣẹ́ dúró. Ó ń fi ọ̀pá kékeré kan lu àwọn ìtí ọkà náà kí hóró inú wọn lè jáde. Òótọ́ ni pé Rúùtù ti ń ṣiṣẹ́ látàárọ̀, àmọ́ wàhálà rẹ̀ ò já sásán.

2 Àbí nǹkan ti wá ń lójú bọ̀ díẹ̀díẹ̀ fún opó yìí ni? Nínú orí tó ṣáájú èyí, a ti rí bó ṣe pinnu pé kò sí ohun tó máa ya òun àti Náómì. Ó búra pé òun ò ní fi ìyá ọkọ òun yìí sílẹ̀ àti pé Jèhófà tí Náómì ń sìn ni yóò jẹ́ Ọlọ́run òun. Lẹ́yìn ikú ọkọ àwọn obìnrin yìí, wọ́n kúrò ní ilẹ̀ Móábù, wọ́n sì wá sí ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Kò pẹ́ tí wọ́n dé tí Rúùtù ará Móábù fi mọ̀ nípa ètò kan tó wà nínú Òfin tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ètò náà wúlò fún àwọn tálákà àti àwọn àjèjì, ó sì buyì kún wọn. Kódà, Rúùtù rí i pé àwọn kan lára àwọn èèyàn Jèhófà tí Òfin náà wà fún, tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé e, ń fi hàn pé àwọn ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run, wọ́n sì tún jẹ́ onínúure. Èyí máa ń mú ìtura bá Rúùtù tí ọkàn rẹ̀ ti gbọgbẹ́.

3, 4. (a) Báwo ni Bóásì ṣe fi Rúùtù lọ́kàn balẹ̀? (b) Kí ni Rúùtù ṣe tó lè ràn wá lọ́wọ́ ní àkókò tí ọrọ̀ ajé ò fara rọ yìí?

3 Ọ̀kan lára àwọn èèyàn Jèhófà tó ń tẹ̀ lé òfin yìí ni Bóásì. Oko ọkùnrin àgbàlagbà tó jẹ́ ọlọ́rọ̀ yìí ni Rúùtù ti ń pèéṣẹ́. Ó bá Rúùtù sọ ọ̀rọ̀ baba-sí-ọmọ lónìí. Ńṣe ni inú Rúùtù ń dùn bó ṣe ń rántí àwọn ọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ tí Bóásì fi yìn ín torí pé ó ń tọ́jú Náómì àti bó ṣe wá sá di Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́.—Ka Rúùtù 2:11-14.

4 Síbẹ̀, ó ṣeé ṣe kí Rúùtù máa ronú nípa ọjọ́ iwájú rẹ̀. Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, ó lè máa ronú pé báwo ni òun àjèjì tí òun jẹ́ aláìní, láìsí ọkọ tàbí ọmọ, á ṣe máa gbọ́ bùkátà ara òun àti ti Náómì? Ṣé bí òun ṣe ń pèéṣẹ́ yìí á tó nǹkan tí òun lè jókòó tì? Àti pé tí òun náà bá dàgbà ta ló máa tọ́jú òun? Gbogbo èyí tó rò lóòótọ́! Ní àkókò tí ọrọ̀ ajé ò fara rọ yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣàníyàn bíi ti Rúùtù. Ní ti Rúùtù, ìgbàgbọ́ tó ní nínú Ọlọ́run ló ràn án lọ́wọ́ tó fi lè borí ìṣòro àtijẹ àtimu. Ohun tó sì máa ran àwa náà lọ́wọ́ ni pé ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀.

Àwọn Wo La Lè Kà sí Ìdílé?

5, 6. (a) Báwo ni nǹkan ṣe rí lọ́jọ́ ti Rúùtù kọ́kọ́ lọ pèéṣẹ́ ní oko Bóásì? (b) Báwo ló ṣe rí lára Náómì nígbà tó rí Rúùtù?

5 Nígbà tí Rúùtù pa ọkà náà tán, tó sì kó hóró ọkà náà jọ, ó rí i pé ọkà bálì tí òun pèéṣẹ́ jẹ́ nǹkan bí òṣùwọ̀n eéfà kan, ìyẹn ìdámẹ́ta àpò ìrẹsì ó dín díẹ̀. Ẹ ò rí i pé ẹrù tó wúwo nìyẹn! Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé inú aṣọ ló dì í sí. Ní báyìí, ilẹ̀ ti ń ṣú lọ. Ó gbé ọkà Báálì náà rù, ó sì forí lé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.—Rúùtù 2:17.

6 Inú Náómì dùn nígbà tó rí aya ọmọ rẹ̀ yìí. Ẹni ọ̀wọ́n ni Rúùtù jẹ́ fún un, ó sì ṣeé ṣe kí ẹnu yà á bó ṣe rí ẹrù ọkà bálì tó wà lórí rẹ̀. Nígbà tí Bóásì fún àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ lóúnjẹ, Rúùtù ò jẹ èyí tí wọ́n fún un tán, ó mú díẹ̀ wálé lára rẹ̀, òun àti Náómì sì jọ jẹ ẹ́. Náómì wá béèrè pé: “Ibo ni o ti pèéṣẹ́ lónìí, ibo sì ni o ti ṣiṣẹ́? Kí ẹni tí ó kíyè sí ọ di alábùkún.” (Rúùtù 2:19) Ẹni tó lákìíyèsí ni Náómì; ẹrù ọkà tó pọ̀ tí Rúùtù gbé wálé yẹn mú kó fura pé ẹnì kan ti ní láti rí i pé opó ni Rúùtù tó sì dìídì ṣàánú rẹ̀.

7, 8. (a) Ta ni Náómì gbà pé ó jẹ́ kí Bóásì ṣàánú Rúùtù? Kí nìdí tó fi gbà bẹ́ẹ̀? (b) Báwo ni Rúùtù ṣe túbọ̀ fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí ìyá ọkọ rẹ̀?

7 Bí àwọn méjèèjì ṣe ń bá ọ̀rọ̀ lọ, Rúùtù sọ gbogbo bí Bóásì ṣe ṣàánú òun fún Náómì. Inú Náómì dùn gan-an, ó ní: “Ìbùkún ni fún un láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, ẹni tí kò dẹ́kun inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ sí àwọn alààyè àti àwọn òkú.” (Rúùtù 2:20) Náómì gbà pé Jèhófà ló mú kí Bóásì ṣàánú Rúùtù, torí ó mọ̀ pé òun ló máa ń mú kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ ọ̀làwọ́, tó sì ṣe ìlérí fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé òun á ṣàánú fún ẹni tó bá ń ṣàánú. *Ka Òwe 19:17.

8 Náómì wá sọ fún Rúùtù pé kó ṣe bí Bóásì ṣe sọ. Ó ní kó máa lọ pèéṣẹ́ nínú oko rẹ̀, lẹ́gbẹ̀ẹ́ “àwọn ọ̀dọ́bìnrin” Bóásì, kí àwọn olùkórè má bàa yọ ọ́ lẹ́nu. Rúùtù ṣe ohun tí ìyá ọkọ rẹ̀ sọ fún un. Bákan náà, ó ń bá a nìṣó láti máa “gbé pẹ̀lú ìyá ọkọ rẹ̀.” (Rúùtù 2:22, 23) Bó ṣe pinnu láti máa bá ìyá ọkọ rẹ̀ gbé yẹn tún jẹ́ ká rí i pé òótọ́ ló ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀. Èyí lè wá mú ká bi ara wa pé, Ṣé òótọ́ la fẹ́ kí ìdílé wa ṣe ara wọn lọ́kan? Ṣé alátìlẹyìn la jẹ́ fún àwọn ìbátan wa, ṣé a sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́? Jèhófà ò ní gbàgbé àwọn tó bá ní irú ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ bẹ́ẹ̀ láé.

Àpẹẹrẹ tí Rúùtù àti Náómì fi lélẹ̀ máa ń rán wa létí pé ó yẹ ká mọyì ìdílé wa

9. Kí ni ìtàn Rúùtù àti Náómì jẹ́ ká mọ̀ nípa ìdílé?

9 Ǹjẹ́ a tiẹ̀ lè pe Rúùtù àti Náómì ní ìdílé? Àwọn kan gbà pé “ojúlówó” ìdílé ni ibi tí ọkọ, aya, ọmọkùnrin, ọmọbìnrin, àwọn òbí àgbà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ bá wà. Àmọ́ ìtàn Rúùtù àti Náómì ti jẹ́ ká rí i pé gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà, bí a ò bá tiẹ̀ ju méjì lọ nínú ìdílé kan, a ṣì lè mú kí inúure, ọ̀yàyà àti ìfẹ́ gbilẹ̀ nínú ìdílé náà. Ǹjẹ́ o tiẹ̀ mọyì àwọn tó jẹ́ ara ìdílé rẹ? Jésù rán àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ létí pé ìjọ Kristẹni lè jẹ́ ìdílé fún àwọn tí kò ní ìdílé pàápàá.—Máàkù 10:29, 30.

Rúùtù àti Náómì ran ara wọn lọ́wọ́, wọ́n sì fún ara wọn ní ìṣírí

“Ó Jẹ́ Ọ̀kan Nínú Àwọn Olùtúnnirà Wa”

10. Ìrànlọ́wọ́ wo ni Náómì fẹ́ ṣe fún Rúùtù?

10 Láti ìgbà ìkórè ọkà bálì ní oṣù April títí di ìgbà ìkórè àlìkámà ní oṣù June, inú oko Bóásì ni Rúùtù ti ń pèéṣẹ́. Torí náà, bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, Náómì ń ronú ohun tó lè ṣe fún Rúùtù tó kà sí ẹni ọ̀wọ́n yìí. Nígbà tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Móábù, Náómì ti gbà pé kò sí bí òun ṣe lè rí ọkọ míì fún Rúùtù. (Rúùtù 1:11-13) Àmọ́, ó ti bẹ̀rẹ̀ sí í ronú lọ́nà tó yàtọ̀ báyìí. Ó sọ fún Rúùtù pé: “Ọmọbìnrin mi, kò ha yẹ kí èmi wá ibi ìsinmi fún ọ?” (Rúùtù 3:1) Láyé ìgbà yẹn, àwọn òbí máa ń bá àwọn ọmọ wọn wá ọkọ tàbí aya, Rúùtù sì ti di ọmọ àtàtà fún Náómì. Ó fẹ́ láti bá Rúùtù wá “ibi ìsinmi,” tàbí ilé ọkọ tirẹ̀ tó ti máa rí ààbò àti ìfọ̀kànbalẹ̀. Kí wá ni Náómì máa ṣe báyìí?

11, 12. (a) Nígbà tí Náómì pe Bóásì ní “olùtúnnirà,” ìṣètò onífẹ̀ẹ́ wo ló ń tọ́ka sí nínú Òfin Ọlọ́run? (b) Kí ni Rúùtù ṣe nígbà tí ìyá ọkọ rẹ̀ sọ ohun tó máa ṣe fún un?

11 Ìgbà tí Rúùtù kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ Bóásì ni Náómì ti sọ pé: “Ọkùnrin náà bá wa tan. Ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn olùtúnnirà wa.” (Rúùtù 2:20) Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Nínú Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn ìṣètò kan wà níbẹ̀ tó fi hàn pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ àwọn ìdílé tí nǹkan nira fún torí pé wọ́n jẹ́ aláìní tàbí torí pé èèyàn wọn kan kú. Tí obìnrin kan ò bá tíì bímọ tí ọkọ rẹ̀ fi kú, inú rẹ̀ máa bà jẹ́ gan-an torí pé kò ní sí àtọmọdọ́mọ táá máa jẹ́ orúkọ ọkọ rẹ̀, irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ sì kú àkúrun nìyẹn. Àmọ́ Òfin Ọlọ́run gbà pé kí arákùnrin ẹni tó kú náà ṣú ìyàwó rẹ̀ lópó, kí obìnrin náà lè bí ọmọ tó máa di ajogún tí yóò máa jẹ́ orúkọ olóògbé náà, tí ohun ìní tí olóògbé náà fi sílẹ̀ á sì wà ní ìkáwọ́ rẹ̀. *Diu. 25:5-7.

12 Náómì wá sọ ohun tí Rúùtù máa ṣe fún un. Ẹ sì wo bí ẹnu ṣe máa ya ọmọbìnrin náà tó nígbà tí ìyá ọkọ rẹ̀ tẹnu bọ̀rọ̀! Díẹ̀ ni Rúùtù ṣì mọ̀ nínú Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, bẹ́ẹ̀ sì ni ọ̀pọ̀ nínú àṣà wọn ṣì ṣàjèjì sí i gan-an. Síbẹ̀, ó bọ̀wọ̀ fún Náómì gan-an débi pé ó fetí sí gbogbo ohun tó sọ dáadáa. Ohun tí Náómì ní kí Rúùtù ṣe lè dà bí ohun tí kò rọrùn tàbí kó máa tì í lójú. Ó ṣeé ṣe kó máa wò ó pé ó lè fa ìwọ̀sí, síbẹ̀ ó gbà láti ṣe é. Ó fìrẹ̀lẹ̀ sọ pé: “Gbogbo ohun tí o sọ fún mi ni èmi yóò ṣe.”—Rúùtù 3:5.

13. Kí la rí kọ́ lára Rúùtù nípa ọwọ́ tó yẹ ka máa fi mú ìmọ̀ràn tí àwọn àgbàlagbà bá fún wa? (Tún wo Jóòbù 12:12.)

13 Nígbà míì, ó máa ń ṣòro fún àwọn èwe láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àwọn tó jù wọ́n lọ, tí wọ́n sì tún ní ìrírí jù wọ́n lọ. Wọ́n sábà máa ń ronú pé àwọn àgbàlagbà ò mọ ìṣòro tí àwọn èwe máa ń dojú kọ. Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ Rúùtù rán wa létí pé àǹfààní ńlá ló wà nínú pé ká máa tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n tí àwọn àgbàlagbà tó fẹ́ràn wa, tí wọ́n sì ń fẹ́ kí ayé wa dára bá ń bá wa sọ. (Ka Sáàmù 71:17, 18.) Kí wá ni Náómì sọ fún Rúùtù? Nígbà tí Rúùtù ṣe ohun tí Náómì sọ fún un, ǹjẹ́ ó ṣe é láǹfààní?

Rúùtù Lọ sí Ilẹ̀ Ìpakà

14. Kí ni ilẹ̀ ìpakà? Kí ni wọ́n ń lò ó fún?

14 Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà Rúùtù lọ sí ilẹ̀ ìpakà. Ilẹ̀ ìpakà jẹ́ ibi tó tẹ́jú pẹrẹsẹ ti ilẹ̀ ibẹ̀ sì le dáadáa. Àwọn àgbẹ̀ máa ń kó ọkà lọ síbẹ̀, kí wọ́n lè pa á, kí wọ́n sì fẹ́ ìyàngbò tàbí èèpo ara ọkà náà kúrò. Ẹ̀gbẹ́ òkè tàbí orí òkè tí atẹ́gùn ibẹ̀ máa ń pọ̀ gan-an ní ọjọ́rọ̀ tàbí lọ́wọ́ àṣálẹ́ ni wọ́n sábà máa ń ṣe ilẹ̀ ìpakà sí. Kí ìyàngbò lè kúrò lára ọkà tí àwọn òṣìṣẹ́ ti pa, ńṣe ni wọ́n máa ń fi àmúga tàbí ṣọ́bìrì ńlá bu ọkà náà sókè. Atẹ́gùn á wá máa fẹ́ èèpo fúlẹ́fúlẹ́ tó wà lára rẹ̀ dà nù, hóró ọkà náà á sì máa já bọ́ sílẹ̀.

15, 16. (a) Ṣàlàyé ohun tí Rúùtù rí bí iṣẹ́ ṣe ń parí lọ ní ilẹ̀ ìpakà Bóásì ni ìrọ̀lẹ́. (b) Báwo ni Bóásì ṣe mọ̀ pé Rúùtù dùbúlẹ̀ síbi ẹsẹ̀ òun?

15 Bí iṣẹ́ ṣe ń parí lọ lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, Rúùtù ń fọgbọ́n kíyè sí bí gbogbo nǹkan ṣe ń lọ. Bóásì fúnra rẹ̀ ló bójú tó bí wọ́n ṣe ń fẹ́ ọkà náà. Òkìtì ọkà náà sì ga gègèrè. Lẹ́yìn tí Bóásì sì ti jẹ àjẹgbádùn, ó dùbúlẹ̀ ní ìkángun òkìtì ọkà náà. Ó dájú pé ó wọ́pọ̀ nígbà yẹn pé kí wọ́n sùn ti òkìtì ọkà bóyá láti lè dáàbò bo irè oko wọn tó ṣeyebíye yìí lọ́wọ́ àwọn olè àti àwọn onísùnmọ̀mí. Rúùtù rí i pé Bóásì ti ń lọ sùn, ó sì mọ̀ pé àkókò tó wàyí kí òun ṣe ohun tí Náómì sọ.

16 Àyà Rúùtù ń já bó ṣe rọra ń yọ́ lọ sọ́dọ̀ Bóásì. Nígbà tó débẹ̀, ó rí i pé ó ti sùn lọ fọnfọn. Ló bá ṣe bí Náómì ṣe sọ, ó lọ síbi ẹsẹ̀ Bóásì, ó ṣí aṣọ kúrò níbẹ̀, ó sì dùbúlẹ̀ síbi ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó wá ń retí ohun tó máa ṣẹlẹ̀. Ó wà níbẹ̀ títí. Lójú Rúùtù, ó wá dà bíi pé ó ti ń pẹ́ jù. Nígbà tó ṣe, Bóásì yíra pa dà ní ààjìn òru. Òtútù ti wọ̀ ọ́ lára, ó sì ń gbọ̀n, ó wá nawọ́ láti fa aṣọ bo ẹsẹ̀ rẹ̀ pa dà. Àmọ́, ó fura pé ẹnì kan wà níbẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Wò ó! obìnrin kan dùbúlẹ̀ síbi ẹsẹ̀ rẹ̀!”—Rúùtù 3:8.

17. Nǹkan méjì wo ni àwọn tó sọ pé ohun tí Rúùtù ṣe kò bójú mu gbójú fò?

17 Bóásì béèrè pé: “Ta ni ọ́?” Ó ṣeé ṣe kí ohùn Rúùtù máa gbọ̀n bó ṣe dá Bóásì lóhùn pé: “Èmi ni Rúùtù ẹrúbìnrin rẹ, kí o sì na apá gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ rẹ bo ẹrúbìnrin rẹ, nítorí ìwọ jẹ́ olùtúnnirà.” (Rúùtù 3:9) Àwọn kan lóde òní ti dọ́gbọ́n sọ, nínú àlàyé tí wọ́n ṣe, pé ọ̀rọ̀ tí Rúùtù sọ àti ohun tó ṣe fi hàn pé ńṣe ló fẹ́ kí Bóásì bá òun lò pọ̀. Àmọ́, àwọn ohun méjì kan wà tí wọ́n gbójú fò. Èyí àkọ́kọ́ ni pé àṣà àtijọ́ kan tí kò sí mọ́ lóde òní ni Rúùtù tẹ̀ lé. Torí náà, àṣìṣe ló máa jẹ́ láti fi ojú ìṣekúṣe tó gbilẹ̀ lóde òní wo ohun tí Rúùtù ṣe nígbà yẹn. Èkejì ni pé bí Bóásì ṣe dá Rúùtù lóhùn fi hàn kedere pé ohun tí Rúùtù ṣe yẹ fún ìyìn ó sì bójú mu.

Kì í ṣe ìmọtara-ẹni-nìkan ló mú kí Rúùtù wá Bóásì lọ, ohun tó dáa ló ní lọ́kàn

18. Báwo ni Bóásì ṣe tu Rúùtù nínú? Ìgbà méjì wo ni Bóásì ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé Rúùtù fi inú rere onífẹ̀ẹ́ hàn?

18 Bóásì fèsì sí ọ̀rọ̀ tí Rúùtù sọ, ó sì dájú pé ohùn pẹ̀lẹ́ tó fi bá a sọ̀rọ̀ fi í lọ́kàn balẹ̀, ó sì tù ú nínú. Bóásì ní: “Alábùkún ni ìwọ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, ọmọbìnrin mi. Ìwọ ti fi inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ hàn lọ́nà tí ó dára ní ìgbà ìkẹyìn ju ti ìgbà àkọ́kọ́ lọ, ní ti pé ìwọ kò tẹ̀ lé àwọn ọ̀dọ́ ènìyàn yálà ẹni rírẹlẹ̀ tàbí ọlọ́rọ̀.” (Rúùtù 3:10) “Ìgbà àkọ́kọ́” tí Bóásì ní lọ́kàn ni ìgbà tí “inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́” tàbí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ mú kó bá Náómì pa dà wá sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì tó sì wá ń tọ́jú rẹ̀. “Ìgbà ìkẹyìn” ni bó ṣe gbà láti wá ṣe ohun tí Náómì sọ fún un. Bóásì sọ pé tó bá jẹ́ àwọn ọmọbìnrin míì ni, ọkùnrin tí kò tíì dàgbà tó òun ló máa wù wọ́n láti fẹ́, yálà ó jẹ́ olówó tàbí tálákà. Dípò bẹ́ẹ̀, Rúùtù fẹ́ láti ṣe ohun tó máa ṣe Náómì àti ọkọ rẹ̀ tó ti kú láǹfààní. Kò fẹ́ kí orúkọ ọkùnrin náà di ìgbàgbé láàárín àwọn èèyàn rẹ̀. Abájọ tí ìwà àìmọtara-ẹni-nìkan ọmọbìnrin yìí fi wú Bóásì lórí.

19, 20. (a) Kí nìdí tí Bóásì ò fi fẹ́ Rúùtù lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀? (b) Báwo ni Bóásì ṣe ṣàánú Rúùtù? Báwo ló ṣe fi hàn pé òun ò fẹ́ kí àwọn èèyàn máa fi ojú burúkú wo Rúùtù?

19 Bóásì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Wàyí o, ọmọbìnrin mi, má fòyà. Gbogbo ohun tí o sọ ni èmi yóò ṣe fún ọ, nítorí gbogbo ẹni tí ó wà ní ẹnubodè àwọn ènìyàn mi mọ̀ pé ìwọ jẹ́ obìnrin títayọ lọ́lá.” (Rúùtù 3:11) Inú Bóásì dùn pé òun máa ní àǹfààní láti fẹ́ Rúùtù; ó sì lè má fi bẹ́ẹ̀ yà á lẹ́nu pé Rúùtù fẹ́ kí òun jẹ́ olùtúnnirà rẹ̀. Ṣùgbọ́n Bóásì ò wulẹ̀ kù gìrì láti ṣe ohun to wù ú, torí pé èèyàn dáadáa ni. Ó sọ fún Rúùtù pé ẹlòmíì ṣì wà tó jẹ́ olùtúnnirà tó tan mọ́ ìdílé ọkọ Náómì ju òun lọ. Bóásì wá sọ pé òun máa kọ́kọ́ lọ bá onítọ̀hún wò bóyá ó máa wù ú láti fẹ́ Rúùtù.

Torí pé Rúùtù lójú àánú, ó sì máa ń bọ̀wọ̀ fúnni, àwọn èèyàn wá mọ̀ ọ́n sí obìnrin títayọ lọ́lá

20 Bóásì ní kí Rúùtù sùn pa dà, kó sì gbéra ní àfẹ̀mọ́jú, káwọn èèyàn má bàa rí i tó bá ń pa dà lọ sílé. Kò fẹ́ kí àwọn èèyàn fi ojú burúkú wo òun àti Rúùtù, torí wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í rò pé wọ́n ti bára wọn ṣèṣekúṣe. Rúùtù wá pa dà dùbúlẹ̀ síbi ẹsẹ̀ Bóásì, ó sì jọ pé ọkàn rẹ̀ túbọ̀ balẹ̀ lọ́tẹ̀ yìí torí ọ̀rọ̀ tútù tí Bóásì bá a sọ lẹ́yìn tó ti sọ ohun tó fẹ́. Ní fẹ̀rẹ̀ kí ilẹ̀ tó mọ́ Rúùtù ti jí. Lẹ́yìn tí Bóásì sì ti wọn ọkà bálì tó pọ̀ fún un, ó pa dà sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.—Ka Rúùtù 3:13-15.

21. Kí ló mú káwọn èèyàn mọ Rúùtù sí “obìnrin títayọ lọ́lá”? Báwo la ṣe lè fìwà jọ ọ́?

21 Ó dájú pé inú Rúùtù á máa dùn tó bá ń rántí bí Bóásì ṣe sọ pé “obìnrin títayọ lọ́lá” ni gbogbo èèyàn mọ̀ ọ́n sí. Ó sì dájú pé bó ṣe wù ú pé kó mọ Jèhófà kó sì máa sìn ín wà lára ohun tó mú kó ní orúkọ rere lọ́dọ̀ àwọn èèyàn. Ó tún ṣàánú Náómì gan-an, kò sì fẹ́ kó di ẹni ẹ̀sín lọ́dọ̀ àwọn èèyàn rẹ̀. Èyí ló mú kó fínnúfíndọ̀ pinnu láti máa tẹ̀ lé àwọn àṣà àti ìṣe tó dájú pé kò mọ̀ tẹ́lẹ̀. Tá a bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Rúùtù, a ó máa fi ọ̀wọ̀ àwọn èèyàn wọ̀ wọ́n, a ò sì ní máa fi ojú tẹ́ńbẹ́lú àṣà àti ìṣe wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, àwa náà máa ní orúkọ rere lọ́dọ̀ àwọn èèyàn.

Rúùtù Rí Ibi Ìsinmi

22, 23. (a) Kí ló ṣeé ṣe kí ẹ̀bùn tí Bóásì fún Rúùtù túmọ̀ sí? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.) (b) Kí ni Náómì sọ pé kí Rúùtù ṣe?

22 Nígbà tí Rúùtù pa dà délé ní ìdájí ọjọ́ yẹn, Náómì sọ pé: “Ta ni ọ́, ọmọbìnrin mi?” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ilẹ̀ tí kò tíì mọ́ ló mú kí Náómì béèrè bẹ́ẹ̀, àmọ́ ó tún fẹ́ mọ̀ bóyá opó tí kò tíì ní ẹnikẹ́ni lọ́kàn ni Rúùtù tàbí ó ti ní ẹni tó máa fẹ́. Láìjáfara, Rúùtù sọ gbogbo bí nǹkan ṣe lọ sí láàárín òun àti Bóásì fún ìyá ọkọ rẹ̀. Ó tún fi ọkà bálì tí Bóásì fi rán an sí Náómì jíṣẹ́. *Rúùtù 3:16, 17.

23 Náómì fún Rúùtù ní ìmọ̀ràn tó ṣeé mú lò. Ó ní dípò tí ì bá fi lọ pèéṣẹ́ ní oko lọ́jọ́ náà, ńṣe ni kó jókòó jẹ́ẹ́ sínú ilé. Ó fi Rúùtù lọ́kàn balẹ̀. Ó ní: “Ọkùnrin náà kì yóò sinmi, láìjẹ́ pé ó mú ọ̀ràn náà wá sí òpin lónìí.”—Rúùtù 3:18.

24, 25. (a) Báwo ni Bóásì ṣe fi hàn pé òun jẹ́ olódodo tí kò mọ tara rẹ̀ nìkan? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe bù kún Rúùtù?

24 Gẹ́gẹ́ bí Náómì ṣe sọ, Bóásì ò fi ọ̀rọ̀ náà falẹ̀. Ó lọ sí ẹnubodè, níbi tí àwọn àgbà ìlú ti sábà máa ń pàdé, ó sì dúró síbẹ̀ di ìgbà tí ìbátan rẹ̀ ọkùnrin, tó tan mọ́ ọkọ Náómì jù ú lọ, fi ń kọjá. Ojú àwọn tó wà níbẹ̀ ni Bóásì ti béèrè lọ́wọ́ ọkùnrin náà bóyá ó máa lo àǹfààní rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùtúnnirà láti fẹ́ Rúùtù. Ṣùgbọ́n ọkùnrin náà sọ pé òun ò lè fẹ́ ẹ, torí pé bí òun bá fẹ́ ẹ, ogún òun máa pa run. Bóásì wá sọ níwájú àwọn ẹlẹ́rìí tó wà ní ẹnubodè náà pé òun ṣe tán láti lo àǹfààní tí òun ní gẹ́gẹ́ bí olùtúnnirà. Ó ní òun máa ra gbogbo ohun tó jẹ́ ti Élímélékì ọkọ Náómì àti pé òun máa fẹ́ Rúùtù, opó Málónì tó jẹ́ ọmọ Élímélékì. Bóásì sọ pé lọ́nà yìí, òun máa “gbé orúkọ ọkùnrin tí ó kú náà dìde lórí ogún rẹ̀.” (Rúùtù 4:1-10) Olódodo èèyàn tí kò mọ tara rẹ̀ nìkan ni Bóásì lóòótọ́!

25 Bóásì fẹ́ Rúùtù. Lẹ́yìn náà, Bíbélì sọ pé: “Jèhófà yọ̀ǹda kí ó lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan.” Àwọn obìnrin ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù súre fún Náómì, wọ́n sì yin Rúùtù pé ó wúlò fún Náómì ju ọmọkùnrin méje lọ. Bí ọdún ti ń gorí ọdún, ọmọkùnrin tí Rúùtù bí wá di baba ńlá Dáfídì Ọba. (Rúùtù 4:11-22) Dáfídì náà sì wá di ọ̀kan lára àwọn baba ńlá Jésù Kristi.—Mát. 1:1. *

Jèhófà mú kí Rúùtù wà lára àwọn tó jẹ́ ìyá ńlá Mèsáyà

26. Kí ni ìtàn Rúùtù àti Náómì máa ń mú ká rántí?

26 Jèhófà bù kún Rúùtù àti Náómì ní tòótọ́. Náómì sì bá Rúùtù tọ́jú ọmọ náà bíi pé òun gan-an ló bí i. Mánigbàgbé ni ìtàn àwọn obìnrin méjèèjì yìí. Ìtàn wọn máa ń jẹ́ ká rántí pé Jèhófà Ọlọ́run ń kíyè sí gbogbo àwọn onírẹ̀lẹ̀ tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára nítorí àtigbọ́ bùkátà ìdílé wọn, tí wọ́n sì tún ń dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run kí wọ́n lè máa fi ìṣòtítọ́ sìn ín. Ó máa ń bù kún àwọn tí wọ́n bá jẹ́ olóòótọ́ bíi ti Bóásì, Náómì àti Rúùtù.

^ ìpínrọ̀ 7 Bí Náómì ṣe sọ, kì í ṣe àwọn alààyè nìkan ni Jèhófà máa ń ṣàánú; ó máa ń rántí àwọn tó ti kú náà. Lọ́nà wo? Ọkọ Náómì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin méjèèjì ti kú. Ọkọ Rúùtù náà sì ti kú. Ó dájú pé àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ṣe pàtàkì gan-an sí àwọn obìnrin méjèèjì. Torí náà, bí ẹnikẹ́ni bá ṣàánú Náómì àti Rúùtù, àwọn ọkùnrin yẹn ló ṣàánú fún. Ìdí ni pé bí wọ́n bá wà láàyè, wọn ò ní fẹ́ kí ìyà kankan jẹ àwọn obìnrin àtàtà yẹn.

^ ìpínrọ̀ 11 Ó dájú pé àwọn arákùnrin ẹni tó kú náà ni wọ́n máa ń kọ́kọ́ fún ní ẹ̀tọ́ láti fẹ́ opó náà. Tí wọn ò bá gbà láti ṣú u lópó ló tó lè kan mọ̀lẹ́bí rẹ̀ míì tó jẹ́ ọkùnrin. Bí wọ́n sì ṣe máa ṣe ogún rẹ̀ náà nìyẹn.—Núm. 27:5-11.

^ ìpínrọ̀ 22 Òṣùwọ̀n mẹ́fà ọkà bálì ni Bóásì bù fún Rúùtù, àmọ́ Bíbélì kò sọ ohun tó fi díwọ̀n rẹ̀. Bóyá ńṣe ni Bóásì ṣe bẹ́ẹ̀ láti fi hàn pé bí ìsinmi Sábáàtì ṣe máa ń tẹ̀ lé ọjọ́ iṣẹ́ mẹ́fà, bákan náà ni Ọlọ́run ṣe máa tó fi ọkọ àti ilé aláyọ̀ rọ́pò gbogbo ọjọ́ tí Rúùtù ti fi jìyà gẹ́gẹ́ bí opó. Ó sì lè jẹ́ pé ohun tó fà á tó fi bu òṣùwọ̀n mẹ́fà, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ẹ̀kún ṣọ́bìrì mẹ́fà, fún Rúùtù ni pé kò lè gbé ju ìyẹn lọ.

^ ìpínrọ̀ 25 Rúùtù jẹ́ ọ̀kan lára àwọn obìnrin márùn-ún tí Bíbélì to orúkọ wọn sára ìlà ìdílé Jésù. Òmíràn tún ni Ráhábù, tó jẹ́ ìyá Bóásì. (Mát. 1:3, 5, 6, 16) Bíi ti Rúùtù, òun náà kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì.