Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ ÌGBÀGBỌ́ WỌN | NÓÀ

Ọlọ́run Pa Nóà “Mọ́ Láìséwu Pẹ̀lú Àwọn Méje Mìíràn”

Ọlọ́run Pa Nóà “Mọ́ Láìséwu Pẹ̀lú Àwọn Méje Mìíràn”

NÓÀ àti ìdílé rẹ̀ di ọwọ́ ara wọn mú pinpin bí òjò ti ń dà wìì-wìì-wìì láti ọ̀run. Jẹ́ ká wo ipò tí wọ́n máa wà nínú ọkọ̀ áàkì yẹn ná. Àtùpà elépo ni wọ́n tàn láti fi ríran nínú ọkọ̀ náà, atẹ́gùn ń fẹ́ lu iná àtùpà yìí, àmọ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ṣì jẹ́ kí òjìji wọn hàn nínú òkùnkùn tó ṣú bolẹ̀. Ṣe ni wọ́n lajú sílẹ̀ rekete bí wọ́n ti ń gbọ́ tí òjò ń dà yàà sórí òrùlé áàkì náà, tí ó sì ń bọ́ lu ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ lákọlákọ. Ó dájú pé ariwo òjò náà máa rinlẹ̀ gan-an, kódà á fẹ́ẹ̀ di wọ́n létí.

Ṣe ni Nóà á máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run bó ṣe ń wo ojú ìyàwó rẹ̀ tó jẹ́ olóòótọ́ àti àwọn ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ òṣìṣẹ́ kára àti àwọn ìyàwó wọn tí wọ́n jẹ́ igi lẹ́yìn ọgbà fún un. Ní àkókò tí nǹkan kò rọgbọ yìí, ó ṣeé ṣe kí ọkàn rẹ̀ balẹ̀ bó ṣe rí i pé àwọn tí òun nífẹ̀ẹ́ jù lọ ló wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ òun. Gbogbo wọn ló wà láàyè, kò sì sí nǹkan kan tó ṣe èyíkéyìí nínú wọn. Ó dájú pé Nóà máa gba àdúrà ìdúpẹ́ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdílé rẹ̀, á sì gbé ohùn rẹ̀ sókè dáadáa kí wọ́n lè gbọ́ ọ, nítorí ariwo òjò yẹn pọ̀ gan-an.

Nóà ní ìgbàgbọ́ tó lágbára gan-an. Ìgbàgbọ́ tí Nóà ní ló mú kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ dáàbò bo òun àti ìdílé rẹ̀. (Hébérù 11:7) Àmọ́, ṣé wọn ò wá nílò ìgbàgbọ́ mọ́ torí pé òjò ti bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀? Ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ o, wọ́n ṣì nílò ìgbàgbọ́ gan-an torí pé ìṣòro ṣì wà níwájú. Àwa náà nílò ìgbàgbọ́ lásìkò tí nǹkan ò fara rọ tí à ń gbé yìí. Ní báyìí, jẹ́ ká wo ohun tí a lè rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Nóà.

“OGÓJÌ Ọ̀SÁN ÀTI OGÓJÌ ÒRU”

Ní ìta áàkì náà, “ogójì ọ̀sán àti ogójì òru” ni òjò fi rọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 7:4, 11, 12) Omi náà bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ sí i ṣáá. Bí omi náà sì ti ń bo ayé lọ, Nóà rí i pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ ń dáàbò bo àwọn olódodo, lẹ́sẹ̀ kan náà ó ń fìyà jẹ àwọn èèyàn burúkú.

Ìkún-omi yìí ló paná ọ̀tẹ̀ kan tó ti rú yọ láàárín àwọn áńgẹ́lì. Ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan tí Sátánì hù ran ọ̀pọ̀ áńgẹ́lì ní ọ̀rún, ni wọ́n bá fi “ibi gbígbé tiwọn tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu” ní ọ̀run sílẹ̀, wọ́n wá sí ayé, wọ́n wá fẹ́ ìyàwó, wọ́n sì bí àwọn abàmì ọmọ tí wọ́n ń pè ní Néfílímù. (Júúdà 6; Jẹ́nẹ́sísì 6:4) Ó dájú pé ìdùnnú Sátánì ló máa jẹ́ bí ìwà ọ̀tẹ̀ yẹn ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í gbèèràn, torí pé ṣe ni ìyẹn túbọ̀ mú kí ìwà ìbàjẹ́ ẹ̀dá èèyàn pọ̀ sí i. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ẹ̀dá èèyàn ni ààyò nínú ìṣẹ̀dá Jèhófà tó wà lórí ilẹ̀ ayé.

Bí ìkún-omi náà ti ń pọ̀ sí i, ó di dandan kí àwọn áńgẹ́lì yẹn bọ́ ara èèyàn sílẹ̀, wọ́n sì para dà di ẹ̀mí àìrí, àmọ́ wọn ò ní lè gbé àwọ̀ èèyàn wọ̀ mọ́ láéláé. Torí náà, wọ́n fi àwọn ìyàwó wọn àti àwọn ọmọ wọn sílẹ̀ kí wọ́n bá ikún-omi yẹn lọ pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn èèyàn burúkú ayé ìgbà yẹn.

Láti ìgbà ayé Énọ́kù, ìyẹn nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún méje [700] ṣáájú ìgbà ayé Nóà ni Jèhófà ti ń kìlọ̀ fún àwọn èèyàn pé òun máa pa àwọn èèyàn burúkú tí kò ṣe ìfẹ́ òun run. (Jẹ́nẹ́sísì 5:24; Júúdà 14, 15) Àmọ́ ìyẹn ò ní kí wọ́n jáwọ́, kàkà kí ewé agbọ́n wọn dẹ̀, ṣe ló túbọ̀ ń le sí i, wọ́n ń ba ayé jẹ́ wọ́n sì túbọ̀ ń hu ìwà ipá. Àmọ́ gbogbo wọn ló ń ṣègbé lọ báyìí. Ṣé inú Nóà àti ìdílé rẹ̀ wá bẹ̀rẹ̀ sí í dùn bí ikú ṣe ń pa àwọn ẹni burúkú yẹn?

Rárá o! Inú Ọlọ́run aláàánú tí wọ́n ń sìn pàápàá kò dùn sí ohun tó ń ṣẹlẹ̀. (Ìsíkíẹ́lì 33:11) Jèhófà ti ṣe gbogbo nǹkan tó yẹ kí ọ̀pọ̀ nínú wọn lè rí ìgbàlà. Ó ti ní kí Énọ́kù kìlọ̀ fún àwọn èèyàn, ó sì ní kí Nóà kan áàkì. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ni Nóà àti ìdílé rẹ̀ ti ń ṣe iṣẹ́ àṣelàágùn nídìí áàkì gìrìwò náà, gbogbo èyí sì ṣojú àwọn èèyàn náà. Ìyẹn nìkan kọ́ o, Jèhófà tún ní kí Nóà “wàásù òdodo.” (2 Pétérù 2:5, Ìròhìn Ayọ̀) Nóà náà ṣe bíi ti Énọ́kù tó gbé láyé ṣáájú rẹ̀, ó kìlọ̀ fún àwọn èèyàn pé ìdájọ́ kan ń bọ̀ wá sórí ayé. Ǹjẹ́ wọ́n fetí sí ìkìlọ̀ náà? Jésù tó rí bí gbogbo nǹkan ṣe ń lọ láti ọ̀run nígbà yẹn, sọ nǹkan tí àwọn èèyàn ń ṣe nígbà ayé Nóà, ó ní: “Wọn kò sì fiyè sí i títí ìkún omi fi dé, tí ó sì gbá gbogbo wọn lọ.”—Mátíù 24:39.

Báwo ni nǹkan ṣe máa rí ná fún Nóà àti ìdílé rẹ̀ fún ogójì ọjọ́ àkọ́kọ́ lẹ́yìn tí Jèhófà ti ilẹ̀kùn áàkì náà? Bí òjò tó ń dà yàà sórí áàkì náà lákọlákọ, ó ṣeé ṣe kí àwọn mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ ti ní iṣẹ́ tí wọ́n á máa ṣe lójoojúmọ́. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè máa tọ́jú ara wọn, kí wọ́n máa bójú tó ibi tí wọ́n ń gbé, kí wọ́n sì máa ṣètọ́jú àwọn ẹranko tó wà nínú áàkì náà. Àmọ́ nígbà tó yá, ọkọ̀ tó tóbi fàkìàfakia yìí mì jìgìjìgì, ó fì sọ́tùn-ún fì sósì. Bí áàkì náà ṣe gbéra nílẹ̀ nìyẹn! Torí pé omi ti bo ibi gbogbo, áàkì náà bẹ̀rẹ̀ sí í wá sókè díẹ̀díẹ̀ títí tó fi “léfòó lókè ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 7:17) Ẹ ò rí i pé agbára Jèhófà Ọlọ́run Olódùmarè pọ̀ gan-an!

Ó dájú pé Nóà á ṣọpẹ́ pé òun àti ìdílé òun wà láìséwu. Yàtọ̀ síyẹn, á tún dúpẹ́ pé Jèhófà ṣíjú àánú wo ìdílé òun àti pé ó lo àwọn láti kìlọ̀ fún àwọn èèyàn tó pa run torí pé wọn ò wọ áàkì náà. Gbogbo ọdún tí wọ́n fi ṣe iṣẹ́ takuntakun tí Jèhófà gbé lé wọn lọ́wọ́ lè kọ́kọ́ dà bí ẹni ṣe àṣedànù lójú wọn. Àwọn èèyàn ò fetí sí wọn rárá! Tiẹ̀ rò ó wò ná, ṣáájú Ìkún-omi ó ṣeé ṣe kí Nóà ní àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò lọ́kùnrin lóbìnrin, ó sì lè ní àwọn ọmọ ẹ̀gbọ́n àti àwọn ọmọ àbúrò, àmọ́ kò sí ìkankan nínú wọn tó fetí sí i àyàfi ìyàwó rẹ̀, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìyàwó wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 5:30) Nísinsìnyí tí àwọn mẹ́jọ yẹn ti wà nínú áàkì láìséwu, ó dájú pé ọkàn wọn á balẹ̀ bí wọ́n ṣe ń rántí gbogbo àkókò tí wọ́n lò láti kìlọ̀ fún àwọn èèyàn kí wọ́n lè ronú pìwà dà, kí wọ́n sì rí ìgbàlà.

Jèhófà tó mú ìdájọ́ ṣẹ nígbà ayé Nóà kò tíì yí pa dà. (Málákì 3:6) Jésù Kristi sọ pé ọjọ́ tiwa náà dà “bí àwọn ọjọ́ Nóà.” (Mátíù 24:37) Àkókò wàhálà ńlá tí a wà yìí máa tó dópin nígbà tí Ọlọ́run bá pa àwọn èèyàn burúkú inú ayé yìí run. Lónìí, àwọn èèyàn Ọlọ́run ń kìlọ̀ fún gbogbo àwọn tó bá fẹ́ gbọ́. Ṣé wàá fetí sí ìkìlọ̀ yìí? Tó o bá ti mọ ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó ń gbani là yìí, ṣé ìwọ náà máa lọ sọ ohun tí o ti mọ̀ fún àwọn ẹlòmíì? Àpẹẹrẹ rere ni Nóà àti ìdílé rẹ̀ jẹ́ fún gbogbo wa lónìí.

NÓÀ ÀTI ÌDÍLÉ RẸ̀ “LA OMI JÁ LÁÌSÉWU”

Bí alagbalúgbú omi yẹn ṣe ń gbé áàkì náà lọ, àwọn tó wà nínú rẹ̀ kò ní ṣàì máa gbọ́ bí àwọn igi tí wọ́n fi kàn án ṣe ń dún, tí ó sì ń rọ́ kẹ̀kẹ̀. Ǹjẹ́ àyà Nóà bẹ̀rẹ̀ sí í já bí omi náà ti ń pọ̀ sí i tí ọwọ́ ìgbì náà sì ń le, àbí ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí í bà á pé áàkì náà lè dà wó? Rárá o. Èrò yẹn lè wá sọ́kàn àwọn tó ń ṣiyè méjì nípa ìtàn yẹn lóde òní, àmọ́ Nóà kò ṣe iyè méjì rárá. Bíbélì sọ pé: “Nípa ìgbàgbọ́ ni Nóà . . . kan ọkọ̀ áàkì.” (Hébérù 11:7) Ìgbàgbọ́ nínú kí ni? Jèhófà ti dá májẹ̀mú, ó ti ṣe àdéhùn tí kò lè yẹ̀ pé òun máa mú kí Nóà àti gbogbo àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ la Ìkún-omi náà já. (Jẹ́nẹ́sísì 6:18, 19) Ṣé Ẹni tó dá ọ̀run àti ayé àti gbogbo ohun alààyè tó wà nínú rẹ̀ ò wá lè ṣe é kí ọkọ̀ náà dúró digbí, kó má sì bà jẹ́? Ó dájú pé ó lè ṣe bẹ́ẹ̀! Nóà fọkàn tán Jèhófà pátápátá pé ó máa mú ìlérí Rẹ̀ ṣẹ. Jèhófà sì ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́, Nóà àti ìdílé rẹ̀ “la omi já láìséwu.”—1 Pétérù 3:20.

Lẹ́yìn ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, òjò náà dá. Tí a bá fi kàlẹ́ńdà òde òní ṣírò rẹ̀, nǹkan bí oṣù December ọdún 2370 kí wọ́n tó bí Jésù ló bọ́ sí. Àmọ́ ìdílé yìí ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wọn nínú áàkì ni. Áàkì tí àwọn ohun alààyè kún inú rẹ̀ fọ́fọ́ yìí nìkan ló léfòó téńté sórí omi tó kún bo gbogbo ayé, kódà ó yọ sókè ju àwọn òkè ńlá tí omi ti bò mọ́lẹ̀ lọ. (Jẹ́nẹ́sísì 7:19, 20) Ẹ wo iṣẹ́ ńlá tí Nóà àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, ìyẹn Ṣémù, Hámù àti Jáfẹ́tì á máa ṣe bí wọ́n ṣe ń fún àwọn ẹranko ní oúnjẹ, tí wọ́n ń tọ́jú ibi tí wọ́n kó wọn sí, tí wọn sì ń bójú tó wọn kí wọ́n má bàa ṣàìsàn. Kò yà wá lẹ́nu pé Ọlọ́run tó rọ gbogbo àwọn ẹranko rírorò lójú tó sì mú kí wọ́n rọrùn láti darí lè mú kí wọ́n wà bẹ́ẹ̀ ní gbogbo àkókò tí wọ́n fi wà nínú áàkì náà. *

Nóà ti ní láti fara balẹ̀ ṣàkọsílẹ̀ gbogbo bí nǹkan ṣe ń ṣẹlẹ̀. Àkọsílẹ̀ tó ṣe jẹ́ ká mọ ìgbà tí òjò náà bẹ̀rẹ̀ àti ìgbà tó parí. Ó tiẹ̀ tún jẹ́ ká mọ̀ pé àádọ́jọ [150] ọjọ́ ni omi náà fi kún bo ilẹ̀ ayé. Nígbà tó yá, omi náà bẹ̀rẹ̀ sí í fà. Ọjọ́ tí kò ṣeé gbàgbé lọjọ́ tí áàkì náà gúnlẹ̀ sí orí “òkè ńlá Árárátì.” Ìyẹn máa jẹ́ ní nǹkan bí oṣù April ọdún 2369 kí wọ́n tó bí Jésù. Òkè yẹn wà ní orílẹ̀-èdè Tọ́kì lóde òní. Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́tàléláàádọ́rin [73], ìyẹn ní oṣù June, ṣóńṣó orí àwọn òkè ńlá bẹ̀rẹ̀ sí í fara hàn. Oṣù mẹ́ta lẹ́yìn náà, ìyẹn ní oṣù September, Nóà ṣí apá kan lára òrùlé áàkì náà kúrò. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe iṣẹ́ tó rọrùn, ó dájú pé á mú kí ìmọ́lẹ̀ àti atẹ́gùn tó ń mú ara tuni fẹ́ wọ inú ọkọ̀ náà. Ṣáájú ìgbà yẹn, Nóà ti gbìyànjú láti mọ̀ bóyá àyíká ibi tí áàkì náà wà ti máa ṣeé gbé. Ó rán ẹyẹ ìwò kan jáde nínú áàkì, àmọ́ tí ẹyẹ náà bá ti fò lọ díẹ̀, á tún pa dà bà lé ọkọ̀ áàkì náà. Ó tún rán ẹyẹ àdàbà kan jáde, ṣe ni ìyẹn tún ń fò lọ fò bọ̀ sọ́dọ̀ Nóà títí tó fi rí ibi tó lè ṣe ìtẹ́ rẹ̀ sí.—Jẹ́nẹ́sísì 7:24–8:13.

Ó dájú pé Nóà mú ipò iwájú nínú ìjọsìn ìdílé, kódà ní àwọn àkókò tí kò rọgbọ

Ìjọsìn Ọlọ́run ló gbawájú jù lọ lára àwọn nǹkan tí Nóà ń ṣe lójoojúmọ́. A lè fọkàn yàwòrán bí ìdílé náà ṣe ń kóra jọ déédéé láti gbàdúrà tí wọ́n á sì jọ sọ̀rọ̀ nípa Baba wọn ọ̀run tó ń dáàbò bò wọ́n. Ojú Jèhófà ni Nóà ń wò fún gbogbo ìpinnu pàtàkì tó bá ń ṣe. Kódà lẹ́yìn odindi ọdún kan tó ti wà nínú áàkì náà tó sì rí i pé omi tó wà lórí ilẹ̀ ti “gbẹ tán” pátápátá, kò já ilẹ̀kùn, kó wá ní kí àwọn tó wà nínú áàkì náà máa jáde. (Jẹ́nẹ́sísì 8:14) Ṣe ló dúró láti gbọ́ ohun tí Jèhófà máa sọ!

Ọ̀pọ̀ nǹkan ni àwọn olórí ìdílé lè rí kọ́ lára ọkùnrin olóòótọ́ yìí. Ó fi ètò sí àwọn nǹkan tó ṣe, ó ṣiṣẹ́ kára, ó ní sùúrù, ó sì ń dáàbò bo àwọn tó wà lábẹ́ àbójútó rẹ̀. Èyí tó tiẹ̀ ṣe pàtàkì jù níbẹ̀ ni pé, ohun tí Jèhófà Ọlọ́run bá fẹ́ ló máa ń fi sí ipò àkọ́kọ́ nínú gbogbo nǹkan. Tí a bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Nóà ní gbogbo ọ̀nà yìí, àwa àti àwọn tí a nífẹ̀ẹ́ máa rí ìbùkún gbà.

“JÁDE KÚRÒ NÍNÚ ÁÀKÌ”

Nígbẹ̀yìn gbẹ́yín Jèhófà sọ ohun tí Nóà máa ṣe. Ó sọ fún Nóà pé: “Jáde kúrò nínú áàkì, ìwọ àti aya rẹ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ àti aya àwọn ọmọkùnrin rẹ pẹ̀lú rẹ.” Ìdílé náà ṣègbọràn sí Ọlọ́run, bí wọ́n sì ṣe ń bọ́ síta ni àwọn ẹranko náà ń tẹ̀ lé wọn. Báwo ni wọ́n ṣe jáde? Ṣé ńṣe ni gbogbo wọn bẹ̀rẹ̀ sí í rọ́ gìrìgìrì jáde nínú áàkì? Rárá o! Bíbélì sọ pé, “ní ìbámu pẹ̀lú ìdílé wọn ni wọ́n jáde kúrò nínú áàkì.” (Jẹ́nẹ́sísì 8:15-19) Bí Nóà àti ìdílé rẹ̀ ṣe jáde síta, afẹ́fẹ́ tútù tó wà lórí òkè ńlá ni wọ́n kọ́kọ́ mí símú. Bí wọ́n sì ti ń wo gbogbo àyíká láti orí òkè Árárátì tí wọ́n wà, wọ́n rí i pé gbogbo ilẹ̀ ayé ti mọ́ tónítóní. Kò sí àwọn Néfílímù mọ́, kò sí ìwà ipá mọ́, kódà àwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ àti gbogbo èèyàn oníwà burúkú ìgbà yẹn ti di àwátì! * Aráyé wá láǹfààní láti bẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé tuntun.

Nóà mọ ohun tó yẹ kó ṣe gan-an. Ìjọsìn Ọlọ́run ló fi bẹ̀rẹ̀. Nínú àwọn ẹranko tí wọ́n mú wọnú áàkì ní “méje-méje,” tí Ọlọ́run kà sí mímọ́, ó mú lára wọn, ó sì fi rú ẹbọ sísun sí Jèhófà lórí pẹpẹ kan tó mọ. (Jẹ́nẹ́sísì 7:2; 8:20) Ǹjẹ́ inú Jèhófà dùn sí ẹbọ yìí?

Ohun tí Bíbélì sọ nípa ohun tó ṣe yìí fini lọ́kàn balẹ̀. Ó ní: “Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ òórùn amáratuni.” Ẹ̀dùn ọkàn ló jẹ́ fún Ọlọ́run nígbà tí gbogbo ayé kún fún ìwà ipá, àmọ́ ní báyìí, òórùn amáratuni ni ó ń gbọ́. Inú rẹ̀ sì dùn bó ti ń rí i tí ìdílé olóòótọ́ tó wà lórí ilẹ̀ ayé báyìí ti pinnu láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n, Jèhófà kò retí pé wọn ò ní ṣe àṣìṣe. Ẹsẹ Bíbélì yẹn tún sọ pé: “Ìtẹ̀sí èrò ọkàn-àyà ènìyàn jẹ́ búburú láti ìgbà èwe rẹ̀ wá.” (Jẹ́nẹ́sísì 8:21) Tún wo ohun míì tí Jèhófà ṣe tó fi hàn pé ó máa ń ṣàánú àwọn èèyàn, ó sì máa ń mú sùúrù fún wọn.

Ọlọ́run ré ègún tó ti gé fún ilẹ̀ kúrò. Láti ìgbà tí Ádámù àti Éfà ti dẹ́ṣẹ̀ ni Ọlọ́run ti gé ègún yẹn, èyí kò sì jẹ́ kí ilẹ̀ so èso bó ṣe yẹ. Lámékì tó jẹ́ bàbá Nóà, ló sọ Nóà lórúkọ, ó sì ṣeé ṣe kí orúkọ yìí túmọ̀ sí “Ìsinmi” tàbí “Ìtùnú.” Lámékì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ọmọ òun yìí ló máa kó aráyé yọ lọ́wọ́ ègún yẹn. Ó dájú pé inú Nóà máa dùn gan-an nígbà tó mọ̀ pé àsọtẹ́lẹ̀ yẹn máa ṣẹ lójú òun àti pé ilẹ̀ ayé tún máa pa dà méso jáde dáadáa. Abájọ tí Nóà fi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ àgbẹ̀!—Jẹ́nẹ́sísì 3:17, 18; 5:28, 29; 9:20.

Nóà àti ìdílé rẹ̀ jáde láti inú ọkọ̀ sí orí ilẹ̀ tí Ọlọ́run ti fọ̀ mọ́

Nígbà yẹn náà ni Jèhófà fún gbogbo àtọmọdọ́mọ Nóà ní àwọn òfin tó ṣe kedere tí wọ́n á máa tẹ̀ lé ní ìgbésí ayé wọn. Lára òfin yìí ni pé wọn kò gbọ́dọ̀ pànìyàn tàbí kí wọ́n lo ẹ̀jẹ̀ lọ́nà tí kò bá òfin Ọlọ́run mu. Ọlọ́run tún bá aráyé dá májẹ̀mú pé òun kò ní fi ìkún-omi pa gbogbo nǹkan alààyè run lórí ilẹ̀ ayé mọ́. Kí ìlérí tí Ọlọ́run ṣe yìí lè dá aráyé lójú, ó fún wọn ní ohun àgbàyanu kan tí wọn ò tíì rí rí nínú ìṣẹ̀dà, ìyẹn òṣùmàrè. Títí dòní, gbogbo ìgbà tí a bá ti rí òṣùmàrè tó yọ lójú sánmà ló ń rán wa létí ìlérí onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà ti ṣe fún wa.—Jẹ́nẹ́sísì 9:1-17.

Ká ní ìtàn àròsọ lásán ni ìtàn Nóà ni, ó ṣeé ṣe ká máà gbọ́ nǹkan kan mọ́ nípa rẹ̀ lẹ́yìn òṣùmàrè yẹn. Òótọ́ ni Nóà gbé láyé, kódà àwọn ìgbà kan wà tí nǹkan ò fi bẹ́ẹ̀ lọ dáadáa fún un. Torí pé àwọn èèyàn máa ń pẹ́ láyé nígbà yẹn, ọkùnrin olóòótọ́ yìí ṣì tún lo àádọ́ta-dín-nírínwó [350] ọdún sí i láyé, àmọ́ ẹ̀dùn ọkàn ni àwọn ọdún yẹn jẹ́ fún un. Lọ́jọ́ kan Nóà ṣe àṣìṣe ńlá kan, ó lọ mutí yó, àmọ́ àṣìṣe yìí tún wá fẹjú sí i nígbà tí Kénáánì ọmọ-ọmọ rẹ̀ lọ dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì. Àkóbá ńlá ni ẹ̀ṣẹ̀ tí Kénáánì dá yìí fà fún àwọn ìdílé rẹ̀. Ẹ̀mí Nóà gùn débi pé, ojú rẹ̀ ló ṣe nígbà tí àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í bọ òrìṣà, tí wọ́n sì ń hùwà ipá nígbà ayé Nímírọ́dù. Àmọ́ ohun kan tó ṣì máa múnú rẹ̀ dùn ni pé, ó rí Ṣémù ọmọ rẹ̀ bó ṣe ní ìgbàgbọ́, tó sì jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà fún ìdílé rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 9:21-28; 10:8-11; 11:1-11.

Ó yẹ ká ní ìgbàgbọ́ bíi ti Nóà, ká jẹ́ olóòótọ́ láìka ìṣòro sí. Tí àwọn tó yí wa ká ò bá ka Ọlọ́run tòótọ́ sí tàbí tí wọn ò tiẹ̀ sìn ín mọ́, a gbọ́dọ̀ ṣe bíi ti Nóà, ká rí i dájú pé ìgbàgbọ́ wa nínú Ọlọ́run kò yẹ̀. Jèhófà mọyì irú àwọn olóòótọ́ èèyàn bẹ́ẹ̀ tí wọ́n lo ìfaradà. Ṣe ló rí bí Jésù Kristi ṣe sọ pé: “Ẹni tí ó bá fara dà á dé òpin ni ẹni tí a ó gbà là.”—Mátíù 24:13.

^ ìpínrọ̀ 17 Àwọn kan sọ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ṣe ni Ọlọ́run mú kí ara àwọn ẹranko yẹn balẹ̀ lọ́nà kan ṣá, bóyá ṣe ni wọ́n kàn ń sùn, tó fi jẹ́ pé oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ mọ níwọ̀n. Bóyá bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ohun kan tó dájú ni pé Jèhófà mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé òun máa dáàbò bo gbogbo àwọn tó bá wà nínú ọkọ̀ áàkì, wọ́n á sì là á já.

^ ìpínrọ̀ 22 Ohun míì tó tún di àwátì ni Ọgbà Édẹ́nì tí Ọlọ́run dá fún àwọn òbí wa àkọ́kọ́. Ó ṣeé ṣe kí ìkún-omi ti gbá gbogbo rẹ̀ lọ. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé àwọn Kérúbù tí wọ́n ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà àbáwọlé ọgbà náà lè pa dà sí ọ̀run. Bí iṣẹ́ tí wọ́n ti ń ṣe bọ̀ láti ẹgbẹ̀jọ [1600] ọdún ṣe parí nìyẹn.—Jẹ́nẹ́sísì 3:22-24.