Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ OGÚN

“Mo Ti Gbà Gbọ́”

“Mo Ti Gbà Gbọ́”

1. Sọ ohun tó ṣe Màtá, kí ló sì fà á?

MÀTÁ ń fojú inú wo ibojì Lásárù àbúrò rẹ̀ tí wọ́n yí òkúta dí lẹ́nu. Ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ pọ̀ lápọ̀jù. Bẹ́ẹ̀ ló ń rò ó pé ‘ṣé òun ò wá ní rí Lásárù àbúrò òun mọ́ náà nìyẹn?’ Láti ọjọ́ mẹ́rin sẹ́yìn tí Lásárù ti kú ni Màtá ò ti nísinmi, torí ṣe ni ọ̀fọ̀ gba ilé wọn kan, tí tonílé tàlejò sì ń rọ́ wá láti kí wọn àti láti tù wọ́n nínú.

2, 3. (a) Nígbà tí Màtá rí Jésù, báwo ló ṣe rí lára rẹ̀? (b) Kí ni ọ̀rọ̀ pàtàkì tí Màtá sọ fi hàn nípa irú ẹni tó jẹ́?

2 Ní báyìí, Jésù tó jẹ́ ọ̀rẹ́ Lásárù tímọ́tímọ́ jù ló wà lọ́dọ̀ Màtá yìí. Ó jọ pé inú Màtá tún bà jẹ́ bó ṣe rí Jésù, torí ká ló tètè dé ni, kò ní jẹ́ kí Lásárù kú rárá. Síbẹ̀síbẹ̀, ìtùnú gidi ló jẹ́ fún Màtá bó ṣe wà lọ́dọ̀ Jésù yìí níbi tó ti wá pàdé rẹ̀ níta ìlú Bẹ́tánì kékeré tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè yẹn. Kò sì pẹ́ tó dé ọ̀dọ̀ Jésù ẹlẹ́yinjú àánú tó máa ń báni dárò gan-an yìí, tí ara fi tù ú pẹ̀sẹ̀, tí ọkàn rẹ̀ sì fúyẹ́. Jésù bi Màtá láwọn ìbéèrè tó mú kó sọ ìgbàgbọ́ rẹ̀ àti èrò rẹ̀ nípa àjíǹde. Ọ̀rọ̀ tí òun àti Màtá jọ sọ yìí mú kí Màtá sọ ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì jù tó tíì sọ rí, ó ní: “Mo ti gbà gbọ́ pé ìwọ ni Kristi Ọmọ Ọlọ́run, Ẹni tí ń bọ̀ wá sí ayé.”—Jòh. 11:27.

3 Ọ̀rọ̀ tí Màtá sọ yìí fi hàn pé obìnrin tó ní ìgbàgbọ́ tó wúni lórí ni. Ohun díẹ̀ tí Bíbélì sọ fún wa nípa rẹ̀ kọ́ wa láwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tó lè mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára. Láti mọ bó ṣe rí bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká wo ibi tí Bíbélì ti kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa Màtá.

“Ìwọ Ń Ṣàníyàn, O sì Ń Ṣèyọnu”

4. Àwọn wo ló ń gbé pẹ̀lú Màtá? Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ sí àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta?

4 Ní ọ̀pọ̀ oṣù ṣáájú, nígbà tí Lásárù ṣì wà láàyè, tí ara rẹ̀ sì le, Jésù Kristi tó jẹ́ ẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ láyé fẹ́ dé bá wọn lálejò ní ilé Lásárù tó wà ní ìlú Bẹ́tánì. Tẹ̀gbọ́n tàbúrò ni Lásárù, Màtá àti Màríà. Wọ́n ti dàgbà, àmọ́ ẹ̀rí fi hàn pé inú ilé kan náà ni wọ́n ń gbé. Àwọn kan tó ń ṣèwádìí sọ pé ó lè jẹ́ Màtá ló dàgbà jù nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, torí ó jọ pé òun ló gbàlejò náà, òun sì ni wọ́n kọ́kọ́ máa ń dárúkọ nígbà míì. (Jòh. 11:5) A kò rí ẹ̀rí tó fi hàn pé èyíkéyìí nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ṣègbéyàwó rí. Àmọ́ ṣá, ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ni wọ́n jẹ́ sí Jésù. Nígbà tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù ní ilẹ̀ Jùdíà, níbi tí àwọn èèyàn ti kórìíra rẹ̀, tí wọ́n sì ń ta kò ó gan-an, ilé wọn ló dé sí. Ó sì dájú pé Jésù mọyì ibi tó tura tó máa ń dé sí yìí àti bí wọ́n ṣe ń tì í lẹ́yìn.

5, 6. (a) Kí nìdí tí ọwọ́ Màtá fi dí gan-an nígbà tí Jésù wá sílé wọn? (b) Kí ni Màríà ṣe nígbà tó rí àǹfààní tí wọ́n ní bí Jésù ṣe wà nílé wọn?

5 Màtá máa ń rí i dájú pé ilé àwọn tuni lára àti pé àwọn tọ́jú ẹni tí wọ́n bá gbà lálejò dáadáa. Akíkanjú òṣìṣẹ́ tí ọwọ́ rẹ̀ máa ń dí gan-an ni. Àfi bíi pé bó ṣe ń kúrò nídìí iṣẹ́ kan ló ń bọ́ sí òmíràn. Ohun kan náà ni Màtá ṣe nígbà tí Jésù wá sílé wọn. Kíá, ó ti múra láti filé pọntí fọ̀nà rokà fún àlejò rẹ̀ pàtàkì yìí àtàwọn tó bá a wá. Láyé ìgbà yẹn, ọwọ́ pàtàkì ni wọ́n fi ń mú àlejò ṣíṣe. Tí àlejò bá dé, wọ́n á fẹnu kò ó lẹ́nu, wọ́n á bọ́ bàtà rẹ̀, wọ́n á fi omi wẹ ẹsẹ̀ rẹ̀, wọ́n á sì fi òróró onílọ́fínńdà pa orí rẹ̀. (Ka Lúùkù 7:44-47.) Wọ́n á tún pèsè oúnjẹ tó dáa àti ibi tó dáa tó máa dé sí.

6 Màtá àti Màríà ní ọ̀pọ̀ iṣẹ́ tí wọ́n máa ṣe láti bójú tó àlejò wọn yìí. Ó dájú pé Màríà, táwọn èèyàn gbà pé ó fẹ́ràn ẹ̀kọ́ kíkọ́ ju Màtá lọ, ti kọ́kọ́ ń bá Màtá ṣiṣẹ́ kí àlejò wọn tó dé. Àmọ́ nígbà tí Jésù dé, nǹkan yí pa dà. Jésù rí i pé àǹfààní nìyẹn láti kọ́ àwọn tó wà níbẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn. Jésù kò dà bí àwọn olórí ìsìn ìgbà ayé rẹ̀, torí ó pọ́n àwọn obìnrin lé, ó sì máa ń kọ́ wọn nípa Ìjọba Ọlọ́run, èyí tí ìwàásù rẹ̀ dá lé. Màríà rí i pé àǹfààní ńlá rèé, ló bá jókòó síbi ẹsẹ̀ Jésù, ó ń gbọ́ gbogbo ohun tó ń sọ.

7, 8. Kí ló mú kí inú bẹ̀rẹ̀ sí í bí Màtá, kí ni ìbínú yẹn sì wá mú kó ṣe?

7 A lè fojú inú wo bí inú á ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í bí Màtá. Nítorí oríṣiríṣi oúnjẹ tó fẹ́ sè àti gbogbo iṣẹ́ tó máa ṣe láti tọ́jú àwọn àlejò rẹ̀, àníyàn rẹ̀ túbọ̀ ń pọ̀ sí i, ìpínyà ọkàn sì bá a. Bó ṣe ń lọ tó ń bọ̀ lẹ́nu kòkáárí oúnjẹ tó ń ṣe, tó ń rí i pé Màríà kàn jókòó láì ran òun lọ́wọ́, ǹjẹ́ ojú rẹ̀ kò ní kọ́rẹ́ lọ́wọ́? Ṣé kò ní máa dọ́gbọ́n mí àmíkanlẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tàbí kó fajú ro? Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ kò ní yani lẹ́nu. Kò kúkú lè dá gbogbo iṣẹ́ tó wà nílẹ̀ ṣe!

8 Nígbà tó yá, Màtá ò lè pa ọ̀rọ̀ náà mọ́ra mọ́. Ló bá já lu ọ̀rọ̀ Jésù, ó ní: “Olúwa, kò ha jámọ́ nǹkan kan fún ọ pé arábìnrin mi ti fi èmi nìkan sílẹ̀ láti bójú tó àwọn nǹkan? Sọ fún un, nígbà náà, kí ó dara pọ̀ ní ríràn mí lọ́wọ́.” (Lúùkù 10:40) Ọ̀rọ̀ líle ló sọ yìí. Bí àwọn Bíbélì kan ṣe túmọ̀ ìbéèrè Màtá ni pé: “Olúwa, ṣé o kò bìkítà ni . . . ?” Ó wá ní kí Jésù sọ fún Màríà pé kó pa dà sẹ́nu iṣẹ́.

9, 10. (a) Báwo ni Jésù ṣe dá Màtá lóhùn? (b) Báwo la ṣe mọ̀ pé Jésù kó bẹnu àtẹ́ lu gbogbo wàhálà tí Màtá ń ṣe?

9 Ìdáhùn Jésù lè ya Màtá lẹ́nu, bó ṣe ń ya ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń ka Bíbélì láti ìgbà yẹn wá lẹ́nu. Jésù rọra sọ pé: “Màtá, Màtá, ìwọ ń ṣàníyàn, o sì ń ṣèyọnu nípa ohun púpọ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, nǹkan díẹ̀ tàbí ẹyọ kan ṣoṣo ni a nílò. Ní tirẹ̀, Màríà yan ìpín rere, a kì yóò sì gbà á kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.” (Lúùkù 10:41, 42) Kí ni Jésù ní lọ́kàn? Ṣé ohun tó ń sọ ni pé Màtá fẹ́ràn nǹkan tara ju Ọlọ́run lọ ni? Ṣé ó wá ń bẹnu àtẹ́ lu gbogbo wàhálà tí Màtá ń ṣe láti gbọ́únjẹ aládùn ni?

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Màtá ‘ń ṣàníyàn, ó sì ń ṣèyọnu nípa ohun púpọ̀,’ ó fìrẹ̀lẹ̀ gba ìtọ́sọ́nà

10 Rárá o. Jésù mọ̀ dájú pé ẹ̀mí tó dáa àti ìfẹ́ tí Màtá ní ló fi ń ṣe é. Bákan náà, Jésù kò ka ṣíṣe àwọn èèyàn lálejò rẹpẹtẹ sí ohun tó burú. Ṣáájú ìgbà yẹn, Jésù pàápàá lọ síbi “àsè ìṣenilálejò rẹpẹtẹ” tí Mátíù sè fún un. (Lúùkù 5:29) Torí náà sísè tí Màtá se oúnjẹ kọ́ ni ò dáa, ohun tó fi sípò àkọ́kọ́ ló kù díẹ̀ káàtó. Oúnjẹ rẹpẹtẹ tó ń sè ló gbájú mọ́ tí kò fi rántí ohun tó ṣe pàtàkì jù. Kí ni ohun náà?

Jésù mọrírì bí Màtá ṣe ní ẹ̀mí aájò àlejò, ó sì mọ̀ pé ẹ̀mí tó dáa àti ìfẹ́ tó ní ló fi ń ṣe é

11, 12. Báwo ni Jésù ṣe rọra tọ́ Màtá sọ́nà?

11 Jésù, Ọmọ bíbí kan ṣoṣo ti Jèhófà Ọlọ́run, wá sílé Màtá kó lè kọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ òtítọ́. Kò sí ohun tó tún lè ṣe pàtàkì ju ìyẹn lọ, títí kan oúnjẹ aládùn àtàwọn ètò míì tí Màtá ń ṣe pàápàá. Ó dájú pé kò dùn mọ́ Jésù bí Màtá ṣe ń pàdánù àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ tó ní láti mú kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára sí i yìí, ṣùgbọ́n ó jẹ́ kí Màtá yan ohun tó fẹ́. * Àmọ́ bí Màtá ṣe tún wá ní kí Jésù lé Màríà dìde kí òun náà tún pàdánù àǹfààní yẹn kò bá a mu rárá.

12 Nítorí náà, ó rọra tọ́ Màtá sọ́nà bó ṣe fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ pe orúkọ rẹ̀ lẹ́ẹ̀mejì kí ọkàn rẹ̀ lè rọ̀. Ó fọkàn rẹ̀ balẹ̀ pé kò sídìí láti ‘máa ṣàníyàn, kó sì máa ṣèyọnu nípa ohun púpọ̀.’ Pé oúnjẹ ráńpẹ́ tí kò ju oríṣi kan tàbí méjì lọ ti tó, pàápàá nígbà tó ti jẹ́ àsìkò tí wọ́n fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Jésù wá sọ pé òun kò ní gba “ìpín rere” tí Màríà ti yàn kúrò lọ́wọ́ rẹ̀ rárá, ìyẹn ẹ̀kọ́ tó ń kọ́ lọ́dọ̀ òun.

13. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú ìtọ́sọ́nà tí Jésù fún Màtá?

13 Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ni àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi lónìí lè rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ wẹ́rẹ́ nílé Màtá yìí. Ara ẹ̀kọ́ náà ni pé a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ohunkóhun dí wa lọ́wọ́ bíbójútó “àìní [wa] nípa tẹ̀mí.” (Mát. 5:3) Lóòótọ́, ó dáa ká jẹ́ ọ̀làwọ́ àti akíkanjú òṣìṣẹ́ bíi ti Màtá, ṣùgbọ́n kò yẹ ká ‘máa ṣàníyàn, ká sì máa ṣèyọnu’ nípa ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì nígbà tá a bá ń ṣe àwọn èèyàn lálejò, ká má bàa pàdánù ohun tó ṣe pàtàkì jù. Tí àwa tí a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ bá gba ara wa lálejò, ìdí pàtàkì tí a fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká lè fún ara wa ní ìṣírí, ká sì jọ gbé ìgbàgbọ́ ara wa ró, kì í wulẹ̀ ṣe torí ká lè pèsè oúnjẹ rẹpẹtẹ fún àwọn àlejò wa tàbí torí ká lè lọ jẹ irú oúnjẹ bẹ́ẹ̀. (Ka Róòmù 1:11, 12.) Kódà tó bá tiẹ̀ jẹ́ oúnjẹ ráńpẹ́ la pèsè, irú ìkórajọ bẹ́ẹ̀ ṣì lè jẹ́ èyí tó ń gbéni ró.

Arákùnrin Wọn Tí Wọ́n Fẹ́ràn Gidigidi Kú, Ó sì Jíǹde

14. Kí ló jẹ́ ká mọ̀ dájú pé Màtá jẹ́ àpẹẹrẹ tó dáa tó bá dọ̀rọ̀ ká gba ìmọ̀ràn?

14 Ǹjẹ́ Màtá gba ìbáwí tó tuni lára tí Jésù fún un, tó sì kẹ́kọ̀ọ́ nínú rẹ̀? Ẹ̀rí wà pé ó gbà á. Torí nígbà tí àpọ́sítélì Jòhánù fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìtàn alárinrin kan nípa Lásárù àbúrò Màtá, ó sọ pé: “Wàyí o, Jésù nífẹ̀ẹ́ Màtá àti arábìnrin rẹ̀ àti Lásárù.” (Jòh. 11:5) Ọ̀pọ̀ oṣù lẹ́yìn ìbẹ̀wò Jésù sí ìlú Bẹ́tánì, tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ tán yìí ni ọ̀rọ̀ yìí ṣẹlẹ̀. Ìyẹn sì fi hàn gbangba pé Màtá kò bínú, kò sì ní ìkùnsínú sí Jésù nítorí ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ tó fún un. Ṣe ló fi ìmọ̀ràn náà sọ́kàn. Bákan náà, Màtá tún fi àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ tó dáa lélẹ̀ fún wa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, torí pé kò sí ẹnì kankan nínú wa tí kì í nílò ìtọ́sọ́nà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.

15, 16. (a) Kí ni Màtá ṣe nígbà tí àbúrò rẹ̀ ń ṣàìsàn? (b) Kí nìdí tí ìrètí Màtá àti Màríà fi já sí pàbó?

15 Nígbà tí Lásárù àbúrò Màtá ṣàìsàn, Màtá tọ́jú rẹ̀ lójú méjèèjì. Ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kí ara rẹ̀ lè yá. Síbẹ̀, ńṣe ni àìsàn Lásárù ń le sí i. Gbogbo ìgbà ni àwọn arábìnrin rẹ̀ méjèèjì ń wà lọ́dọ̀ rẹ̀, tí wọ́n ń tọ́jú rẹ̀. Màtá á máa wojú àbúrò rẹ̀ tó ń rù yìí, á sì máa rántí gbogbo ọdún tí wọ́n ti jọ ń gbé pọ̀, nígbà dídùn àti nígbà kíkan.

16 Nígbà tí Màtá àti Màríà rí i pé àìsàn Lásárù ti fẹ́ kọjá agbára wọn, wọ́n ránṣẹ́ sí Jésù. Ibi tó ti ń wàásù jẹ́ ìrìn ọjọ́ méjì síbi tí wọ́n wà. Iṣẹ́ tó ṣe ṣókí ni wọ́n rán sí Jésù, wọ́n ní: “Olúwa, wò ó! ẹni tí ìwọ ní ìfẹ́ni fún ń ṣàìsàn.” (Jòh. 11:1, 3) Wọ́n mọ̀ pé Jésù fẹ́ràn arákùnrin àwọn, wọ́n sì gbà gbọ́ pé á ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti ràn án lọ́wọ́. Bóyá wọ́n tiẹ̀ ń retí pé Jésù máa dé kó tó pẹ́ jù. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ṣe ni ìrètí wọn já sí pàbó. Ìdí ni pé Lásárù kú.

17. Kí ló ṣe Màtá ní kàyéfì, kí ló sì ṣe nígbà tó gbọ́ pé Jésù ti fẹ́rẹ̀ẹ́ wọ ìlú wọn?

17 Bí Màtá àti Màríà ṣe ń ṣọ̀fọ̀ arákùnrin wọn, ni wọ́n ń múra sílẹ̀ fún ìsìnkú rẹ̀, èrò sì ń wọ́ wá kí wọn láti Bẹ́tánì àti àgbègbè rẹ̀. Síbẹ̀ wọ́n kò gbọ́ nǹkan kan nípa Jésù. Bó ṣe túbọ̀ ń pẹ́ sí i lá máa ṣe Màtá ní kàyéfì. Níkẹyìn, lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́rin tí Lásárù ti kú, Màtá gbọ́ pé Jésù ti fẹ́rẹ̀ẹ́ wọ ìlú wọn. Màtá kì í fi nǹkan jáfara, torí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ń ṣọ̀fọ̀ lọ́wọ́, ó dìde láìsọ fún Màríà, ó sì sáré lọ pàdé Jésù.—Ka Jòhánù 11:18-20.

18, 19. Kí ni Màtá sọ pé òun mọ̀ pé ó máa ṣẹlẹ̀? Kí nìdí tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ fi wúni lórí?

18 Nígbà tí Màtá rí Jésù Ọ̀gá rẹ̀, ó sọ ohun tó ti ń dun òun àti Màríà láti ọjọ́ mélòó kan. Ó ní: “Olúwa, ká ní o ti wà níhìn-ín ni, arákùnrin mi kì bá kú.” Ṣùgbọ́n, Màtá nírètí àti ìgbàgbọ́ pé Jésù ṣì lè ṣe nǹkan kan nípa rẹ̀. Ìyẹn ló fi sọ pé: “Síbẹ̀, nísinsìnyí mo mọ̀ pé gbogbo nǹkan tí o bá béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, Ọlọ́run yóò fún ọ.” Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Jésù sì sọ ohun kan láti fi mú kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ túbọ̀ lágbára. Ó ní: “Arákùnrin rẹ yóò dìde.”—Jòh. 11:21-23.

19 Màtá rò pé ọ̀rọ̀ àjíǹde ọjọ́ iwájú ni Jésù ń sọ, ló bá dáhùn pé: “Mo mọ̀ pé yóò dìde nínú àjíǹde ní ọjọ́ ìkẹyìn.” (Jòh. 11:24) Ìgbàgbọ́ tí Màtá ní nínú àjíǹde wúni lórí. Àwọn kan lára àwọn aṣáájú ìsìn Júù, ìyẹn àwọn Sadusí, sọ pé kò sí àjíǹde, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀kọ́ yìí hàn kedere nínú Ìwé Mímọ́ tí Ọlọ́run mí sí. (Dán. 12:13; Máàkù 12:18) Ṣùgbọ́n Màtá mọ̀ pé Jésù kọ́ni pé àwọn òkú máa jíǹde, àti pé ó ti jí àwọn òkú dìde pàápàá, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tíì jí òkú tó pẹ́ tó ti Lásárù dìde rí. Màtá ò kúkú mọ ohun tó fẹ́ ṣẹlẹ̀.

20. Ṣàlàyé ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ mánigbàgbé tí Jésù sọ nínú Jòhánù 11:25-27 àti ọ̀rọ̀ tí Màtá fi fèsì.

20 Jésù wá sọ ọ̀rọ̀ mánigbàgbé kan, ó ní: “Èmi ni àjíǹde àti ìyè.” Òótọ́ sì ni, torí Jèhófà Ọlọrun ti fún Ọmọ rẹ̀ ní àṣẹ láti jí òkú dìde jákèjádò ayé lọ́jọ́ iwájú. Jésù wá bi Màtá pé: “Ìwọ ha gba èyí gbọ́ bí?” Ìyẹn ni Màtá fi fún un ní èsì tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ orí yìí. Ó gbà gbọ́ pé Jésù ni Kristi tàbí Mèsáyà, pé Jésù ni Ọmọ Jèhófà Ọlọ́run àti pé òun ni àwọn wòlíì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé yóò wá sí ayé.—Jòh. 5:28, 29; ka Jòhánù 11:25-27.

21, 22. (a) Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun mọ bí ẹ̀dùn ọkàn àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ ṣe rí? (b) Sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà àjíǹde Lásárù.

21 Ǹjẹ́ Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀ Jésù Kristi fi ojú pàtàkì wo àwọn tó bá ní irú ìgbàgbọ́ tí Màtá ní yìí? Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú Màtá lẹ́yìn náà fi hàn pé wọ́n fojú pàtàkì wò wọ́n. Màtá sáré lọ pe Màríà àbúrò rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó rí i pé ẹ̀dùn ọkàn Jésù pọ̀ gan-an nígbà tó ń bá Màríà àti ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọ́n jọ ń ṣọ̀fọ̀ sọ̀rọ̀. Màtá rí bó ṣe dun Jésù tó nígbà tó rí ìbànújẹ́ tí ikú ń fà, àní débi pé Jésù da omi lójú. Ó wá gbọ́ tí Jésù sọ pé kí wọ́n yí òkúta kúrò lẹ́nu ibojì Lásárù.—Jòh. 11:28-39.

22 Màtá tó ní àròjinlẹ̀ gan-an kò fẹ́ gbà, ó ní òkú náà ti pé ọjọ́ mẹ́rin, á sì ti máa rùn. Ni Jésù bá rán an létí pé: “Èmi kò ha sọ fún ọ pé bí ìwọ bá gbà gbọ́, ìwọ yóò rí ògo Ọlọ́run?” Màtá gbà gbọ́ lóòótọ́, ó sì rí ògo Jèhófà Ọlọ́run. Àní lójú ẹsẹ̀ níbẹ̀, Ọlọ́run fún Ọmọ rẹ̀ lágbára láti jí Lásárù dìde! Màtá kò ní gbàgbé àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ yìí láyé rẹ̀. Ìyẹn bí Jésù ṣe pàṣẹ pé, “Lásárù jáde wá!” Kò ní gbàgbé ìró wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ tó ń gbọ́ nínú ibojì nígbà tí Lásárù dìde tòun ti àwọn ọ̀já ìdìkú lára, tó rọra ń bọ̀ ní ẹnu ọ̀nà ibojì náà. Kò ní gbàgbé àṣẹ tí Jésù pa pé, “ẹ tú u, ẹ sì jẹ́ kí ó máa lọ.” Kò sì ní gbàgbé ìdùnnú tó ṣubú lu ayọ̀ fún wọn nígbà tí òun àti Màríà gbá Lásárù mọ́ra! (Ka Jòhánù 11:40-44.) Bí gbogbo ìbànújẹ́ ọkàn Màtá ṣe fò lọ nìyẹn!

Màtá jèrè ìgbàgbọ́ tó ní nínú Jésù, torí Jésù jí arákùnrin Màtá àti Màríà dìde

23. Kí ni Jèhófà àti Jésù fẹ́ ṣe fún ọ, kí lo sì gbọ́dọ̀ ṣe?

23 Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí fi hàn pé àjíǹde àwọn òkú kì í ṣe àlá tí kò lè ṣẹ àti pé ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ń múni láyọ̀ ni, ó sì tún jẹ́ ẹ̀rí pé àwọn òkú ti jíǹde láwọn ìgbà kan rí. (Jóòbù 14:14, 15) Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ máa ń fẹ́ láti san ẹ̀san fún àwọn tó ní ìgbàgbọ́, bí wọ́n ṣe san Màtá, Màríà àti Lásárù lẹ́san. Irú èrè tí ìwọ náà máa rí gbà lọ́dọ̀ wọn nìyí tó o bá ní ìgbàgbọ́ tó lágbára.

‘Màtá Ń Ṣèránṣẹ́’

24. Kí ni Bíbélì sọ kẹ́yìn nípa Màtá?

24 Bíbélì tún mẹ́nu kan Màtá lẹ́ẹ̀kan sí i. Ìyẹn jẹ́ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀sẹ̀ tí wọ́n pa Jésù. Jésù mọ̀ dáadáa pé òun máa tó jìyà, torí náà ó dé síbi tó tura tó sábà máa ń dé sí ní ìlú Bẹ́tánì. Ó ń rin ìrìn kìlómítà mẹ́ta láti ibẹ̀ lọ sí Jerúsálẹ́mù. Ó wá ṣẹlẹ̀ pé Jésù àti Lásárù ń jẹun nílé Símónì adẹ́tẹ̀, ibẹ̀ ni Bíbélì sì ti sọ̀rọ̀ nípa Màtá kẹ́yìn, ó ní: “Màtá sì ń ṣèránṣẹ́.”—Jòh. 12:2.

25. Kí nìdí tó fi jẹ́ ìbùkún ńlá láti ní irú àwọn obìnrin tó dà bíi Màtá nínú ìjọ lónìí?

25 Ẹ ò rí i pé akíkanjú òṣìṣẹ́ ni obìnrin yìí lóòótọ́! Nígbà tá a kọ́kọ́ kà nípa rẹ̀ nínu Bíbélì, iṣẹ́ ló ń ṣe. Nígbà tá a sì tún kà nípa rẹ̀ kẹ́yìn, iṣẹ́ ló ṣì ń ṣe, tó ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti tọ́jú àwọn tó wà láyìíká rẹ̀. Ìbùkún ńlá ló jẹ́ fún àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi lóde òní láti ní irú àwọn obìnrin tó dà bíi Màtá nínú ìjọ wọn. Ìyẹn àwọn obìnrin tó jẹ́ onígboyà àti ọ̀làwọ́, tí wọ́n ń fi ìgbàgbọ́ wọn hàn nípa bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ Ọlọ́run lójú méjèèjì, tí wọ́n sì ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Ǹjẹ́ Màtá ń bá iṣẹ́ rere rẹ̀ yìí nìṣó? Ó jọ pé ó ń bá a nìṣó. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ìwà tó bọ́gbọ́n mu ló ń hù yẹn, torí pé àwọn ìṣòro kan ṣì máa tó dojú kọ ọ́.

26. Kí ni ìgbàgbọ́ tí Màtá ní jẹ́ kó lè ṣe?

26 Ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn èyí, ìbànújẹ́ ńláǹlà bá Màtá bí wọ́n ṣe pa Jésù Ọ̀gá rẹ̀ tó fẹ́ràn gidigidi. Bákan náà, ṣáájú kí àwọn apààyàn alágàbàgebè yìí tó pa Jésù, wọ́n ti fẹ́ pa Lásárù náà, torí pé àjíǹde Lásárù mú kí ìgbàgbọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn túbọ̀ lágbára sí i. (Ka Jòhánù 12:9-11.) Ó sì dájú pé níkẹyìn, ikú ya Màtá àti àwọn ọmọ ìyá rẹ̀, bí wọ́n ṣe fẹ́ràn ara wọn tó. A kò mọ ìgbà tí èyí ṣẹlẹ̀ àti bó ṣe ṣẹlẹ̀, àmọ́ ohun tó dá wa lójú ni pé, ìgbàgbọ́ tó lágbára tí Màtá ní jẹ́ kó lè fara dà á dópin. Ìdí nìyẹn tó fi dára kí àwọn Kristẹni lóde òní tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Màtá.

^ ìpínrọ̀ 11 Láwùjọ àwọn Júù ti ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, wọn kì í sábà jẹ́ kí àwọn obìnrin kópa nínú ohun tó bá jẹ mọ́ ẹ̀kọ́ ìwé. Iṣẹ́ ilé ni wọ́n sábà máa ń kọ́ wọn jù. Torí náà, Màtá lè máa wò ó pé kò bọ́ sí i rárá kí obìnrin wá jókòó kalẹ̀ síbi tí olùkọ́ kan ti ń kọ́ni kó máa kẹ́kọ̀ọ́.