Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Nìdí Tí Ìpakúpa Rẹpẹtẹ Fi Ṣẹlẹ̀? Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Kò Ṣe Fòpin Sí I?

Kí Nìdí Tí Ìpakúpa Rẹpẹtẹ Fi Ṣẹlẹ̀? Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Kò Ṣe Fòpin Sí I?

 Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tó ń béèrè àwọn ìbéèrè yìí ti pàdánù ẹnì kan, ìtùnú sì ni irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ń wá, kì í ṣe ìdáhùn nìkan. Èrò àwọn míì sì ni pé Ọlọ́run ló fa ìpakúpa yìí, èyí sì mú kó ṣòro fún wọn láti gba Ọlọ́run gbọ́.

Àwọn èrò tí kò tọ̀nà táwọn èèyàn ní nípa Ọlọ́run àti Ìpakúpa Rẹpẹtẹ

Irọ́: Ó burú láti béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba Ìpakúpa Rẹpẹtẹ.

 Òótọ́: Àwọn èèyàn tó nígbàgbọ́ tó lágbára gan-an ti bi Ọlọ́run ní ìbéèrè rí nípa ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìwà ibi. Bí àpẹẹrẹ, wòlíì Hábákúkù béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run pé: “Èé sì ti ṣe tí ìfiṣèjẹ àti ìwà ipá fi wà ní iwájú mi, èé sì ti ṣe tí aáwọ̀ fi ń ṣẹlẹ̀?” (Hábákúkù 1:3) Dípò kó bá Hábákúkù wí, Ọlọ́run jẹ́ kí àwọn ìbéèrè rẹ̀ wà nínú àkọsílẹ̀ Bíbélì fún gbogbo èèyàn láti kà.

Irọ́: Ọlọ́run kò bìkítà nípa ìyà tó ń jẹ aráyé.

 Òótọ́: Ọlọ́run kórìíra ìwà burúkú àti ìnira tí ìwà yìí máa ń yọrí sí. (Òwe 6:16-19) Nígbà ayé Nóà, bí ìwà ipá ṣe tàn kálẹ̀ “dùn [Ọlọ́run] ní ọkàn-àyà.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:5, 6) Ó dájú pé bí Ìpakúpa Rẹpẹtẹ ṣe máa dun Ọlọ́run gan-an nìyẹn.—Málákì 3:6.

Irọ́: Ọlọ́run ló fi Ìpakúpa Rẹpẹtẹ jẹ àwọn ẹ̀yà Júù níyà.

 Òótọ́: Ọlọ́run kò jẹ́ káwọn ará Róòmù pa ìlú Jerúsálẹ́mù run ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. (Mátíù 23:37–24:2) Látìgbà yẹn wá, Ọlọ́run kò dá ojú rere ṣe sí ẹ̀yà kan tàbí kó fìyà jẹ ẹ̀yà kan. Lójú Ọlọ́run, “kò sí ìyàtọ̀ láàárín Júù àti Gíríìkì.”—Róòmù 10:12.

Irọ́: Tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run wà lóòótọ́, tó sì jẹ́ onífẹ̀ẹ́ àti alágbára jù lọ, kò yẹ kó fàyè gba Ìpakúpa Rẹpẹtẹ.

 Òótọ́: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run kọ́ ló fa ìyà tó ń jẹ aráyé, àmọ́, nígbà míì ó máà ń fàyè gbà á fúngbà díẹ̀.—Jákọ́bù 1:13; 5:11.

Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba Ìpakúpa Rẹpẹtẹ?

 Ọlọ́run fàyè gba Ìpakúpa Rẹpẹtẹ torí ìdí kan náà tó fi fàyè gba gbogbo ìyà tó ń jẹ́ aráyé, ìyẹn sì ni láti yanjú ọ̀ràn tó ṣẹlẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn. Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé Èṣù ló ń ṣàkóso ayé yìí, kì í ṣe Ọlọ́run. (Lúùkù 4:1, 2, 6; Jòhánù 12:31) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àpilẹ̀kọ yòókù tó tan mọ́ àkòrí yìí ṣàlàyé ní kíkún ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà, síbẹ̀, a lè fi àwọn kókó pàtàkì méjì kan látinú Bíbélì ṣàlàyé ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìpànìyàn nípakúpa.

  1.   Ta ló fa ìpakúpa náà? Ọlọ́run sọ nǹkan tí òun retí kí Ádámù àti Éfà tó jẹ́ tọkọtaya àkọ́kọ́ ṣe, àmọ́ kò fipá mú wọn ṣe é. Wọ́n yàn láti pinnu ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́ fúnra wọn, ìpinnu tí kò dáa tí wọ́n ṣe yìí àti èyí táwọn èèyàn ti ń ṣe látayébáyé ti fa ìnira tó burú jáì fún aráyé. (Jẹ́nẹ́sísì 2:17; 3:6; Róòmù 5:12) Ohun tí ìwé Statement of Principles of Conservative Judaism sọ gẹ́lẹ́ nìyẹn, ó ní: “Èyí tó pọ̀ jù nínú ìyà tó ń jẹ aráyé lónìí ló jẹ́ pé bí a ṣe ṣí òmìnira wa lò ló fà á.” Àmọ́, dípò kí Ọlọ́run gba òmìnira tá a ní yìí pa dà lọ́wọ́ wa, ó gba àwa èèyàn láàyè láti yàn ohun tó wù wá.

  2.   Ọlọ́run máa mú gbogbo ìpalára tí Ìpakúpa Rẹpẹtẹ ti fà kúrò. Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa jí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tó ti kú dìde, títí kan àwọn tó kú nígbà Ìpakúpa Rẹpẹtẹ. Ó sì tún máa mú ìbànújẹ́ tí àwọn tó la Ìpakúpa Rẹpẹtẹ náà já máa ń ní nígbà tí wọn bá rántí àwọn nǹkan tó burú jáì tí ojú wọn ti rí kúrò. (Aísáyà 65:17; Ìṣe 24:15) Ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí aráyé mú kó dá wa lójú pé yóò mú àwọn ìlérí yìí ṣẹ.—Jòhánù 3:16.

 Ìgbàgbọ́ ọ̀pọ̀ lára àwọn tó la Ìpakúpa Rẹpẹtẹ tó wáyé náà já túbọ̀ ń lágbára, ìgbésí ayé wọn sì nítumọ̀ torí pé wọ́n lóye ìdí ti Ọlọ́run fi fàyè gba ìwà ibi àti bí Ọlọ́run á ṣe fòpin sí àwọn aburú tí ìwà ibi náà ti fà.