Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Tẹ́nì Kan Bá Ń Jìyà, Ṣé Ọlọ́run Ló Fà Á?

Tẹ́nì Kan Bá Ń Jìyà, Ṣé Ọlọ́run Ló Fà Á?

LUZIA Ń FI ẸSẸ̀ ÒSÌ TIRO. Nígbà tó wà lọ́mọdé, ó ní àrùn rọmọlápárọmọlẹ́sẹ̀, àrùn burúkú tó máa ba iṣan ara jẹ́ ni àrùn yìí. Nígbà tí Luzia wà ní ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16], obìnrin kan tó ń bá ṣiṣẹ́ sọ fún un pé: “Ọlọ́run ló ń fi ìyà jẹ ẹ́ torí pé o jẹ́ aláìgbọ́ràn, o sì máa ń mú inú bí ìyá rẹ.” Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, ọ̀rọ̀ yẹn ṣì ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá Luzia.

NÍGBÀ TÍ WỌ́N SỌ FÚN DAMARIS PÉ Ó NÍ ÀRÙN JẸJẸRẸ INÚ ỌPỌLỌ, bàbá rẹ̀ bi í pé: “Kí lo ṣe tí irú nǹkan báyìí fi ṣẹlẹ̀ sí ẹ? Ó ní láti jẹ́ pé o ti ṣe ohun burúkú kan. Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run ṣe ń fìyà jẹ ẹ́.” Ọ̀rọ̀ yìí ba Damaris nínú jẹ́ gan-an.

Ọjọ́ pẹ́ tí àwọn èèyàn ti máa ń rò pé Ọlọ́run máa ń fi àìsàn jẹ èèyàn níyà. Ìwé Manners and Customs of Bible Lands sọ pé nígbà tí Jésù wà láyé, ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà gbọ́ pé “tí ẹnì kan bá ṣàìsàn, a jẹ́ pé mọ̀lẹ́bi rẹ̀ tàbí òun fúnra rẹ̀ ti dá ẹ̀ṣẹ̀ kan, Ọlọ́run sì ń fi àìsàn yẹn jẹ ẹ́ níyà.” Bákan náà, ìwé Medieval Medicine and the Plague jẹ́ ká mọ̀ pé ní àkókò tí ọ̀làjú bẹ̀rẹ̀ [láàárín ọdún 476 Sànmánì Kristẹni sí nǹkan bí ọdún 1500 Sànmánì Kristẹni], “àwọn kan gbà gbọ́ pé Ọlọ́run ló ń fi àrùn jẹ àwọn níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn.” Torí náà, nígbà tí àrùn burúkú kan pa ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn káàkiri ilẹ̀ Yúróòpù ní àárín ọdún 1301 sí ọdún 1400, ṣé Ọlọ́run ló fìyà jẹ wọ́n nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn? Àbí kòkòrò àrùn bacterial ló fà á bí àwọn oníṣègùn ṣe sọ? Àwọn kan lè máa rò pé, ṣé lóòótọ́ ni Ọlọ́run máa ń fi àìsàn jẹ ẹnì kan níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀? a

RÒ Ó WÒ NÁ: Tó bá jẹ́ pé àìsàn ni ìyà ẹ̀ṣẹ̀ tí Ọlọ́run fi ń jẹ èèyàn, ṣé Jésù Ọmọ rẹ̀ máa wo àwọn èèyàn sàn? Ṣé kì í ṣe pé Jésù ń sọ pé Ọlọ́run ò dájọ́ yẹn dáadáa? (Mátíù 4:23, 24) Ó dájú pé Jésù ò ní ṣe ohun tó lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run. Ó sọ pé: “Nígbà gbogbo ni mo ń ṣe ohun tí ó wù ú,” àti pé “gẹ́gẹ́ bí Baba ti fi àṣẹ fún mi láti ṣe, bẹ́ẹ̀ ni mo ń ṣe.”​—Jòhánù 8:29; 14:31.

Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé: “Kò sí àìṣèdájọ́ òdodo lọ́dọ̀” Jèhófà Ọlọ́run. (Diutarónómì 32:4) Bí àpẹẹrẹ, ó dájú pé Ọlọ́run ò ní já ọkọ̀ òfúúrufú kan lulẹ̀ kó sì pa ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn tó jẹ́ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ nítorí pé ó fẹ́ fìyà jẹ ẹnì kan nínú ọkọ̀ yẹn! Ká bàa lè mọ̀ pé onídájọ́ òdodo ni Ọlọ́run, Ábúráhámù ìránsẹ́ Ọlórun tó jẹ́ olódodo sọ pé, ó dájú pé Ọlọ́run ò ní “gbá olódodo lọ pẹ̀lú àwọn ẹni burúkú,” ó sọ pé, “kò ṣeé ronú kàn.” (Jẹ́nẹ́sísì 18:23, 25) Bíbélì tún jẹ́ ká mọ̀ pé “Ọlọ́run kì í ṣe burúkú,” bẹ́ẹ̀ ni, kì í “hùwà lọ́nà tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu!”​—Jóòbù 34:10-12.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ NÍPA ÌYÀ TÓ Ń JẸ WÁ

Ọlọ́run kọ́ ló ń fìyà jẹ wá nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa. Jésù mú kí òtítọ́ yìí ṣe kedere nígbà tí òun àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ rí ọkùnrin kan tí wọ́n bí ní afọ́jú. “Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Rábì, ta ni ó ṣẹ̀, ọkùnrin yìí ni tàbí àwọn òbí rẹ̀, tí a fi bí i ní afọ́jú?” Jésù dáhùn pé: “Kì í ṣe ọkùnrin yìí ni ó ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe àwọn òbí rẹ̀, ṣùgbọ́n ó jẹ́ kí a lè fi àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run hàn kedere nínú ọ̀ràn rẹ̀.’ ”​—Jòhánù 9:1-3.

Ìyàlẹ́nu ló máa jẹ́ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà nígbà tí Jésù fèsì pé kì í ṣe pé ọkùnrin náà tàbí àwọn òbí rẹ̀ ṣẹ̀ ló fi jẹ́ afọ́jú. Ìdí tó fi ní láti yà wọ́n lẹ́nu ni pé èrò tí àwọn èèyàn ní nígbà yẹn yàtọ̀. Kì í ṣe pé Jésù la ojú afọ́jú yìí nìkan, ó tún jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé èrò òdì ni tí wọ́n bá rò pé Ọlọ́run ló ń fi àìsàn jẹni níyà. (Jòhánù 9:6, 7) Ìtùnnú gbáà ló máa jẹ́ fún gbogbo àwọn tí àìsàn ń bá fínra láti mọ̀ pé Ọlọ́run kọ́ ló ń fìyà jẹ wọ́n.

Ṣé Jésù máa wo àwọn èèyàn sàn tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run ló ń fi ìyà jẹ wọ́n nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn?

Bíbélì fi dá wa lójú pé

  • “A kò lè fi àwọn ohun tí ó jẹ́ ibi dán Ọlọ́run wò, bẹ́ẹ̀ ni òun fúnra rẹ̀ kì í dán ẹnikẹ́ni wò.” (JÁKỌ́BÙ 1:13) Ó dájú pé àìsàn, ìrora àti ikú tó ti ń pọ́n aráyé lójú láti ọdún yìí wá máa di ohun àtijọ́.

  • Jésù yanjú ìṣòro gbogbo àwọn tó ń jìyà. (MÁTÍÙ 8:16) Bí Jésù ọmọ Ọlórun ṣe wo àwọn èèyàn sàn jẹ́ ká rí ohun tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe fún gbogbo aráyé.

  • Ọlórun ‘yóò nu omijé gbogbo kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.’​—ÌṢÍPAYÁ 21:3-5.

TA LÓ FÀ Á?

Kí ló wá dé tí ìyà fi pọ̀ tó báyìí láyé? Ó ti pẹ́ tí àwọn èèyàn ti ń béèrè ìbéèrè yìí. Tó bá jẹ́ pé kì í ṣe Ọlọ́run ló ń fìyà jẹ aráyé, ta wá ni? Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí.

a Lóòótọ́, nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì àwọn ìgbà kan wà tí Ọlọ́run fi àìsàn jẹ àwọn kan níyà nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kan tí wọ́n dá, àmọ́ lóde òní Bíbélì ò sọ fún wa pé Ọlọ́run máa ń fi àìsàn tàbí àjálù jẹ àwọn èèyàn níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.