Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ

Iya

Iya

Àwọn kan rò pé Ọlọ́run ló ń fìyà jẹ wá tàbí pé kò rí tiwá rò. Àmọ́ ṣé ohun tí Bíbélì fi kọni nìyẹn? Ìdáhùn Bíbélì lè yà ẹ́ lẹ́nu.

Ṣé Ọlọ́run ló ń fìyà jẹ wá?

“Ní tòótọ́, Ọlọ́run kì í ṣe burúkú.” Jóòbù 34:12.

OHUN TÁWỌN KAN SỌ

Àwọn kan sọ pé àmúwá Ọlọ́run ni gbogbo ohun tó bá dé bá ẹ̀dá láyé. Èyí máa ń mú kí wọ́n rò pé Ọlọ́run ló ń fìyà jẹ wá. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé bí àjálù bá ṣẹlẹ̀, wọ́n á ní Ọlọ́run ló fi àjálù náà pọ́n àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lójú.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Ìwé mímọ́ sọ ní kedere pé Ọlọ́run kọ́ ló ń fìyà jẹ wá. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé tí àdánwò bá dé bá wa, àṣìṣe ló máa jẹ́ tá a bá sọ pé: “Ọlọ́run ni ó ń dán mi wò.” Ìdí sì ni pé “a kò lè fi àwọn ohun tí ó jẹ́ ibi dán Ọlọ́run wò, bẹ́ẹ̀ ni òun fúnra rẹ̀ kì í dán ẹnikẹ́ni wò.” (Jákọ́bù 1:13) Torí náà, Ọlọ́run kọ́ ló ń fìyà jẹ wá. Ẹni ibi ló máa ń fìyà jẹ ẹlòmíì, àmọ́ “Ọlọ́run kì í ṣe burúkú.”—Jóòbù 34:12.

Tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run kọ́ ló ń fìyà jẹ wá, kí ló wá fa ìyà tó ń jẹ wá? Ọ̀kan lára ohun tó fà á ni pé a jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, èyí sì máa ń mú ká fẹ́ jẹ gàba lórí àwọn míì, wàhálà sì lè tibẹ̀ yọ. (Oníwàásù 8:9) Bákan náà, àwọn míì lè rìnrìn àrìnfẹsẹ̀sí kí wọ́n sì ṣe kòńgẹ́ aburú torí pé ìgbàkugbà ni àwọn “ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀” ń ṣẹlẹ̀. (Oníwàásù 9:11) Bíbélì tún kọ́ wa pé “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà,” ìyẹn Sátánì Èṣù tó jẹ́ “olùṣàkóso ayé yìí.” (Jòhánù 12:31; 1 Jòhánù 5:19) Àwọn ẹ̀rí yìí fi hàn pé Sátánì ló ń fìyà jẹ wá, kì í ṣe Ọlọ́run.

Ǹjẹ́ Ọlọ́run tiẹ̀ rí ìyà tó ń jẹ wá?

“Nínú gbogbo wàhálà wọn, ó jẹ́ wàhálà fún un.”Aísáyà 63:9.

OHUN TÁWỌN KAN SỌ

Àwọn kan rò pé Ọlọ́run ò rí tiwa rò rárá. Bí àpẹẹrẹ, òǹkọ̀wé kan sọ pé Ọlọ́run “kì í káàánú wa tá a bá ń jìyà.” Ohun tí òǹkọ̀wé yẹn fẹ́ fà yọ ni pé, tí Ọlọ́run bá tiẹ̀ wà, “kò ráyè tiwa rárá.”

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Bíbélì sọ ohun tó yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí òǹkọ̀wé náà sọ. Bíbélì kọ́ wa pé ó máa ń dun Ọlọ́run bá a ṣe ń jìyà àti pé ó máa fòpin sí ìjìyà láìpẹ́. Wo mẹ́ta nínú òótọ́ tó ń tuni nínú tí Bíbélì sọ.

Ọlọ́run rí bá a ṣe ń jìyà. Látìgbà táláyé ti dáyé, kò sí èékán omi kan tó bọ́ lójú àwa èèyàn tí Jèhófà * kò rí torí pé “ojú rẹ̀ títàn yanran” ń rí ohun gbogbo. (Sáàmù 11:4; 56:8) Àpẹẹrẹ kan ni ìgbà táwọn kan ń fojú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gbolẹ̀ láyé àtijọ́, Ọlọ́run sọ pé: “Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, mo ti rí ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ àwọn ènìyàn mi . . . níṣẹ̀ẹ́.” Àmọ́, ṣé ó kàn gbúròó pé wọ́n ń jìyà lásán ni? Rárá o, torí ó sọ pé: “Mo mọ ìrora tí wọ́n ń jẹ ní àmọ̀dunjú.” (Ẹ́kísódù 3:7) Ẹ ò rí i pé Ọlọ́run ń rí gbogbo ìyà tó ń jẹ wá títí kan èyí tí kò hàn sáwọn míì pàápàá. Òtítọ́ yìí lásán ń tù wá nínú.—Sáàmù 31:7; Òwe 14:10.

Ọlọ́run máa ń bá wa kẹ́dùn nígbà tá a bá ń jìyà. Kì í kàn ṣe pé Jèhófà Ọlọ́run ń ìyà tá à ń jẹ nìkan ni, ó tún máa ń dùn ún. Bí àpẹẹrẹ, ó ká Ọlọ́run lára gan-an nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àtijọ́ ń jìyà. Bíbélì sọ pé: “Nínú gbogbo wàhálà wọn, ó jẹ́ wàhálà fún un.” (Aísáyà 63:9) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ga jù wá lọ fíìfíì, ó máa ń bá wa kẹ́dùn nígbà tá a bá ń jìyà àfi bíi pé òun gangan ni nǹkan náà dé bá! Ẹ ò rí i pé ‘Jèhófà jẹ́ oníyọ̀ọ́nú, ó sì jẹ́ aláàánú.’ (Jákọ́bù 5:11) Bákan náà, Jèhófà máa ń fún wa lágbára láti fara da ìṣòro èyíkéyìí.—Fílípì 4:12, 13.

Ọlọ́run máa fòpin sí gbogbo ìyà tó ń jẹ wá. Bíbélì sọ pé, Ọlọ́run máa fòpin sí ìyà tó ń jẹ gbogbo èèyàn láyé yìí. Jèhófà máa lo Ìjọba rẹ̀ láti tún ipò ayé yìí ṣe. Bíbélì wá sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn, ó ní Ọlọ́run yóò “nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” (Ìṣípayá 21:4) Àwọn tó wá ti kú ńkọ́? Ọlọ́run máa jí wọn pa dà sáyé kí wọ́n lè gbádùn àwọn ìbùkún yìí. (Jòhánù 5:28, 29) Tó bá dìgbà yẹn, ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni á máa ro àròdùn nípa ìyà tó ti jẹ sẹ́yìn? Rárá o, torí Jèhófà ṣèlérí pé: “Àwọn ohun àtijọ́ ni a kì yóò sì mú wá sí ìrántí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wá sí ọkàn-àyà.”—Aísáyà 65:17. *

^ ìpínrọ̀ 13 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.

^ ìpínrọ̀ 15 Tó o bá fẹ́ mọ ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìyà fúngbà díẹ̀ àti bó ṣe máa fòpin sí i, lọ wo orí 8 àti 11 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.