Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—Ní Brazil

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—Ní Brazil

NÍ ỌDÚN díẹ̀ sẹ́yìn, Rúbia (1) arábìnrin kan tó ti pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún báyìí lọ sọ́dọ̀ aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Sandra (2), tó ń sìn ní ìjọ kékeré kan ní gúúsù orílẹ̀-èdè Brazil. Nígbà ìbẹ̀wò náà, ohun kan ṣẹlẹ̀ tó wú Rúbia lórí gan-an débi tó fi ṣe àwọn ìyípadà kan nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Kí lohun náà? Ẹ jẹ́ ká gbọ́ látẹnu Rúbia fúnra rẹ̀.

“ÌYÀLẸ́NU LÓ JẸ́ FÚN MI”

“Sandra mú mi lọ sọ́dọ̀ obìnrin kan tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ń lọ lọ́wọ́, obìnrin náà sọ fún Sandra pé: ‘Àwọn ọ̀dọ́bìnrin mẹ́ta kan wà níbi iṣẹ́ mi tí wọ́n sọ pé àwọn fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ mo sọ fún wọn pé àfi kí wọ́n dúró dìgbà tó máa kàn wọ́n. Mo mọ̀ pé àwọn tó o máa kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ jálẹ̀ ọdún yìí ti wà nílẹ̀.’ Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún mi. Ṣé pé àwọn èèyàn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà ní láti máa dúró dìgbà tó máa kàn wọ́n! Ní ìjọ tí mo ti wá, ó ṣòro fún mi láti rí ẹnì kan ṣoṣo kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Lójú ẹsẹ̀, nínú ilé ẹni tá a lọ kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ yẹn ló ti wù mí gan-an pé kí n ran àwọn èèyàn tó wà ní ìlú kékeré yẹn lọ́wọ́. Láìpẹ́ sígbà yẹn, mo fi ìlú ńlá tí mò ń gbé sílẹ̀, mo sì kó lọ sí ìlú kékeré tí Sandra ti ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà.”

Kí ni ohun tí Rúbia ṣe yìí yọrí sí? Ó sọ pé: “Láàárín oṣù méjì tí mo débẹ̀, mo ti ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Kò sì pẹ́ tí ọ̀pọ̀ èèyàn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fi ń dúró de èmi náà bí wọ́n ṣe ń dúró de Sandra!”

Ó RONÚ NÍPA IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ RẸ̀, Ó SÌ TÚN ÈRÒ PA

Diego (3), arákùnrin kan tó ti lé díẹ̀ lọ́mọ ogún ọdún báyìí ṣe ìbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn aṣáájú-ọ̀nà mélòó kan tí wọ́n ń sìn ní Prudentópolis, ìlú kékeré kan tó wà ní gúúsù orílẹ̀-èdè Brazil. Ohun tó rí nígbà ìbẹ̀wò náà wọ̀ ọ́ lọ́kàn; kódà ó mú kó ronú nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó sì tún èrò pa. Ó sọ pé: “Ní ìjọ tí mo wà, mi ò fi ọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi, wákàtí díẹ̀ ni mo fi ń wàásù lóṣooṣù. Àmọ́, nígbà tí mo ṣe ìbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn aṣáájú-ọ̀nà yẹn tí mo sì gbọ́ àwọn ìrírí tí wọ́n ti ní lẹ́nu iṣẹ́ náà, mo rí i pé nígbà tí èmi kò fi ọwọ́ tó ṣe pàtàkì mú iṣẹ́ ìsìn mi, ńṣe làwọn ń fayọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn tiwọn. Nígbà tí mo rí bí wọ́n ṣe ń láyọ̀ tára wọn sì ń yá gágá, ó wù mí pé kí ìgbésí ayé tèmi náà nítumọ̀ bíi tiwọn.” Lẹ́yìn ìbẹ̀wò yẹn, Diego bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà.

Bíi ti Diego, ṣé ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí tó ń lọ sóde ẹ̀rí tó sì ń lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ nìwọ náà, síbẹ̀ tó dà bíi pé ńṣe lo kàn ń lọ ṣáá àmọ́ tí kò gbádùn mọ́ ẹ? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ o lè ṣe àwọn ìyípadà kan nínú ìgbésí ayé rẹ tó máa mú kí ìwọ náà láyọ̀ tó o bá lọ sìn níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i? Òótọ́ ni pé ó lè má rọrùn fún ẹ láti fi ìgbésí ayé gbẹdẹmukẹ sílẹ̀. Àmọ́ ohun tí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ti ṣe nìyẹn. Wọ́n ti fìgboyà yí àwọn ohun tí wọ́n fi ṣe àfojúsùn wọn àti ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe pa dà kí wọ́n lè sin Jèhófà ní kíkún sí i. Ẹ jẹ́ ká tún wo àpẹẹrẹ ẹlòmíì tó ń jẹ́ Bruno.

OLÙDARÍ ẸGBẸ́ AKỌRIN TÀBÍ ÒJÍṢẸ́?

Ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, Bruno (4) tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n báyìí, jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ orin kan tó gbajúmọ̀, ó fẹ́ láti di olùdarí ẹgbẹ́ akọrin. Kódà, ó tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ débi pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n ké sí i láti wá darí àwọn ẹgbẹ́ akọrin. Èyí sì lè fún un láǹfààní láti ríṣẹ́ tó máa sọ ọ́ di ọlọ́rọ̀. Bruno sọ pé: “Síbẹ̀, ó ń ṣe mí bíi pé ohun kan wà tí mi ò tíì ní nínú ìgbésí ayé mi. Mo ti ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà, ṣùgbọ́n mo mọ̀ pé mi ò fi gbogbo ọkàn mi sìn ín, ìyẹn sì da ọkàn mi láàmú. Mo sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára mi fún Jèhófà nínú àdúrà, mo sì tún bá àwọn arákùnrin tí wọ́n ní ìrírí sọ̀rọ̀ nínú ìjọ. Lẹ́yìn ti mo ti gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò dáadáa, mo pinnu láti fi iṣẹ́ ìsìn mi sí ipò àkọ́kọ́, mo fi ilé ẹ̀kọ́ orin sílẹ̀, mo sì lọ sí ibi tí wọ́n ti túbọ̀ nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i.” Kí ni ìpinnu tó ṣe yìí yọrí sí?

Bruno kó lọ sí Guapiara tó jẹ́ nǹkan bí ọ̀tàlérúgba [260] kìlómítà sí ìlú São Paulo. (Àwọn olùgbé ibẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún méje.) Ìyípadà ńlá gbáà lèyí jẹ́. Ó sọ pé: “Mo kó lọ sínú ilé kékeré kan tí kò ní fìríìjì, tẹlifíṣọ̀n tàbí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Síbẹ̀, àwọn ohun tí mi ò ní rí wà níbẹ̀, irú bí ọgbà ewébẹ̀ àti igi eléso!” Ìjọ kékeré kan ni Bruno ti ń sìn níbẹ̀. Lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀, ó máa ń di oúnjẹ, omi àtàwọn ìtẹ̀jáde sínú báàgì rẹ̀, á gun alùpùpù rẹ̀, á sì lọ wàásù ní àwọn ìgbèríko. Ọ̀pọ̀ àwọn tó wà ní agbègbè yẹn ni kò tíì gbọ́ ìhìn rere rí. Ó sọ pé: “Mò ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí ó tó méjìdínlógún. Bí mo ṣe ń rí i táwọn akẹ́kọ̀ọ́ yìí ń ṣe ìyípadà nínú ìgbésí ayé wọn ń fún mi láyọ̀ gan-an!” Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ní báyìí, ọwọ́ mi ti wá tẹ ohun tí mi ò tíì ní nínú ìgbésí ayé mi, ìyẹn ni ìbàlẹ̀ ọkàn téèyàn máa ń ní tó bá fi àwọn ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú Ìjọba Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́. Ì bá má ṣeé ṣe fún mi láti gbádùn gbogbo èyí ká sọ pé àwọn nǹkan tara ni mò ń lépa.” Báwo ni Bruno ṣe ń gbọ́ bùkátà ara rẹ̀ ní Guapiara? Ó rẹ́rìn-ín músẹ́, ó sì sọ pé: “Mò ń kọ́ àwọn èèyàn ní gìtá.” Bí ẹni ń ṣiṣẹ́ olùdarí orin náà ṣì ni.

“ŃṢE NI MO NÍ LÁTI DÚRÓ”

Ọ̀rọ̀ Mariana (5), tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún báyìí jọ ti Bruno. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ amòfin tó ń mówó gọbọi wọlé ló ń ṣe, síbẹ̀ kò ní ojúlówó ìtẹ́lọ́rùn. Ó sọ pé: “Ńṣe ló ń ṣe mí bíi pé mò ‘ń lépa ẹ̀fúùfù.’” (Oníw. 1:17) Ọ̀pọ̀ arákùnrin àti arábìnrin gbà á nímọ̀ràn pé kó ronú nípa ṣíṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Lẹ́yìn tó ronú díẹ̀ lórí ìmọ̀ràn yìí, oun àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́ta, Bianca (6), Caroline (7) àti Juliana (8) pinnu láti lọ ran ìjọ kan lọ́wọ́ ní Barra do Bugres, ìlú àdádó kan tó wà nítòsí orílẹ̀-èdè Bòlífíà, tó sì fi ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà jìn sí ilé wọn. Kí ló wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà?

Mariana sọ pé: “Oṣù mẹ́ta ni mo ní lọ́kàn láti lò níbẹ̀. Àmọ́ nígbà tí oṣù mẹ́tà náà ń parí lọ, mo ti ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́ẹ̀ẹ́dógún! Ká sòótọ́, gbogbo wọn ló nílò ìrànlọ́wọ́ kí wọ́n lè tẹ̀síwájú nínú òtítọ́. Torí náà, kò rọrùn fún mi láti sọ fún wọn pé mò ń lọ. Ńṣe ni mo ní láti dúró.” Ohun tí àwọn arábìnrin tí wọ́n jọ lọ náà sì pinnu láti ṣe nìyẹn. Ṣé iṣẹ́ tuntun tí Mariana dáwọ́ lé yìí wá mú kí ìgbésí ayé rẹ̀ nítumọ̀ sí i? Ó sọ pé: “Ti pé Jèhófà ń lò mí láti mú kí àwọn èèyàn yí ìgbésí ayé wọn padà sí rere ń fi mí lọ́kàn balẹ̀. Ìbùkún ló jẹ́ fún mi pé mò ń fi àkókò mi àti okun mi ṣe ohun tó ní láárí.” Caroline sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, ó ní: “Tí mo bá dùbúlẹ̀ lálẹ́, ọkàn mi máa ń balẹ̀ pé mo ti lo ara mi fún àwọn nǹkan tó ní í ṣe pẹ̀lú Ìjọba Ọlọ́run. Bí mo ṣe máa ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi lọ́wọ́ ló máa ń wà lọ́kàn mi ṣáá. Ó wú mi lórí bí mo ṣe ń rí i tí wọ́n ń tẹ̀síwájú. Mo ti wá rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ náà pé: ‘Ẹ tọ́ ọ wò, kí ẹ sì rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere.’”—Sm. 34:8.

Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin kárí ayé tí iye wọn ń pọ̀ sí i ń ‘yọ̀ǹda ara wọn tinútinú’ láti lọ wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run láwọn ibi àdádó. Ẹ sì wo bí inú Jèhófà ṣe máa dùn tó pé wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀! (Sm. 110:3; Òwe 27:11) Àwọn tó fínnú fíndọ̀ yọ̀ǹda ara wọn lọ́nà yìí máa ń rí ìbùkún Jèhófà gbà lọ́pọ̀ yanturu.—Òwe 10:22.