Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—Ní Rọ́ṣíà

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—Ní Rọ́ṣíà

NÍ ỌDÚN 1991, inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà dùn gan-an nígbà tí ìjọba mú òfin tó fi de iṣẹ́ ìwàásù wọn látọjọ́ pípẹ́ kúrò, tó sì fi orúkọ wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Nígbà yẹn, ìwọ̀nba díẹ̀ làwọn tó máa rò pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀ á pọ̀ sí i ní ìlọ́po mẹ́wàá tí wọ́n á sì wá di ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́sàn-án [170,000] bó ṣe rí lónìí! Ilẹ̀ òkèèrè ni àwọn kan lára àwọn oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ òṣìṣẹ́ kára yìí ti wá gbé ní orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, kí wọ́n lè kópa nínú ìkórè tẹ̀mí tó ń lọ lọ́wọ́ ní orílẹ̀-èdè náà. (Mát. 9:37, 38) Ẹ jẹ́ ká gbọ́rọ̀ látẹnu díẹ̀ lára wọn.

ÀWỌN ARÁKÙNRIN YỌ̀ǸDA ARA WỌN LÁTI GBÉ ÀWỌN ÌJỌ RÓ

Ọmọ ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n [28] ni Arákùnrin Matthew tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nígbà tí wọ́n mú òfin tí wọ́n fi de iṣẹ́ ìwàásù wa ní orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà kúrò. Ní àpéjọ àgbègbè kan tí wọ́n ṣe ní ọdún yẹn, ọ̀kan nínú àwọn àsọyé tó gbọ́ níbẹ̀ dá lórí ìrànlọ́wọ́ tí àwọn ìjọ tó wà ní Ìlà Oòrùn Yúróòpù nílò. Bí àpẹẹrẹ, alásọyé yẹn mẹ́nu ba ìjọ kan tó wà ní ìlú St. Petersburg ní orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan ṣoṣo ló wà níbẹ̀, kò sì sí alàgbà kankan. Síbẹ̀, àwọn akéde tó wà níbẹ̀ ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó tó ọgọ́rùn-ún mélòó kan! Arákùnrin Matthew sọ pé: “Látìgbà tí mo ti gbọ́ àsọyé náà, mi ò yé ronú nípa orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, torí náà mo gbàdúrà sí Jèhófà mo sì sọ fún un pé ó wù mí kí n lọ síbẹ̀.” Arákùnrin Matthew ta púpọ̀ nínú nǹkan tó ní, ó tọ́jú owó pamọ́, ó wá kó lọ sí orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ní ọdún 1992. Báwo ni nǹkan ṣe rí fún un nígbà tó débẹ̀?

Matthew

Matthew sọ pé: “Ó ṣòro fún mi láti jíròrò ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pẹ̀lú àwọn èèyàn torí pé mi ò gbọ́ èdè wọn dáadáa.” Ó tún ṣòro fún mi láti rílé gbé. “Mi ò lè ka iye ìgbà tí mo kó Iáti ilé kan lọ sí ilé mìíràn láìròtẹ́lẹ̀.” Láìka àwọn ìṣòro tó kọ́kọ́ ní sí, ó sọ pé: “Ìpinnu tí mo ṣe láti kó lọ sí orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ni ìpinnu tó dára jù lọ tí mo ṣe ní ìgbésí ayé mi.” Ó tún sọ pé: “Bí mo ṣe wá sìn níbí ti kọ́ mi láti gbára lé Jèhófà pátápátá, mo sì ń rí ọwọ́ rẹ̀ lára mi ní onírúurú ọ̀nà.” Nígbà tó yá, Arákùnrin Matthew di alàgbà àti aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, ó sì ti ń sìn báyìí ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà nítòsí ìlú St. Petersburg.

Ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] ni Hiroo nígbà tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ní ọdún 1999 ní orílẹ̀-èdè Japan, ọ̀kan nínú àwọn olùkọ́ rẹ̀ wá gbà á níyànjú pé kó lọ sìn ní ilẹ̀ òkèrè. Hiroo ti gbọ́ pé wọ́n nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i ní orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èdè wọn. Ó tún ṣe ohun kan tó máa ràn án lọ́wọ́. Ó sọ pé: “Mo lọ sí orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà fún oṣù mẹ́fà, ṣùgbọ́n torí pé òtútù máa ń mú gan-an níbẹ̀, oṣù November ni mo lọ kí n lè mọ̀ bóyá màá lè fara da òtútù náà.” Lẹ́yìn ìgbà òtútù náà, ó padà sí orílẹ̀-èdè Japan ó sì ń gbé ìgbé ayé ṣe-bó-o-ti-mọ kó lè rí owó tó máa fi padà sí orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà kó sì máa gbé níbẹ̀.

Hiroo àti Svetlana

Ní báyìí, Hiroo ti gbé ní orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà fún ọdún méjìlá, ó sì ti sìn ní ìjọ tó pọ̀. Nígbà míì, òun nìkan ni alàgbà tó wà nínú ìjọ, táá sì máa bójú tó akéde tó lé ní ọgọ́rùn-ún. Nínú ìjọ kan péré lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, ó máa ń bójú tó apá tó pọ̀ jù lọ nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn, ó máa ń darí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ó tún máa ń ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sọ́dọ̀ ọ̀pọ̀ àwọn ará. Nígbà tí Hiroo ronú nípa àwọn ọdún tó ti lò níbẹ̀, ó sọ pé: “Mo láyọ̀ pé mo lè ran àwọn arákùnrin àti arábìnrin lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà.” Báwo ni iṣẹ́ ìsìn ní ibi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i ṣe nípa lórí ìgbésí ayé Hiroo? Ó sọ pé: “Kí n tó lọ sí orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, alàgbà àti aṣáájú-ọ̀nà ni mí, àmọ́ ńṣe ló dà bíi pé lẹ́yìn tí mo débí ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ wá ní àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú Jèhófà. Mo ti kọ́ láti túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nínú ohun gbogbo.” Ní ọdún 2005, Hiroo fẹ́ Arábìnrin Svetlana, wọ́n sì jọ ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà.

Michael àti Olga pẹ̀lú Marina àti Matthew

Ọmọ ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [34] ni Matthew, àbúrò rẹ̀ Michael jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n [28], orílẹ̀-èdè Kánádà sì làwọn méjèèjì ti wá. Àwọn méjèèjì lọ sí orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, ẹnú sì yà wọ́n nígbà tí wọ́n rí iye àwọn ẹni tuntun tó ń wá sí ìpàdé, àmọ́ tó jẹ́ pé àwọn arákùnrin díẹ̀ ló ń bójú tó wọn. Matthew sọ pé: “Igba [200] èèyàn ló wá sí ìjọ tí mo lọ, alàgbà kan tó ti darúgbó àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ ló sì bójú tó gbogbo apá ìpàdé náà. Nígbà tí mo rí bí nǹkan ṣe rí, mo pinnu láti kó lọ síbẹ̀ kí n lè ràn wọ́n lọ́wọ́.” Ọdún 2002 ló kó lọ sí orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà.

Lẹ́yìn ọdún mẹ́rin, Michael náà kó lọ sí orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ó sì wá rí i pé wọ́n ṣì nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i níbẹ̀. Ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni Michael, wọ́n ní kó máa bójú tó àkọsílẹ̀ ìnáwó, ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ àti ìpínlẹ̀ ìwàásù. Wọ́n tún ní kó máa ṣe iṣẹ́ akọ̀wé ìjọ, kó máa sọ àsọyé, kó sì tún máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣètò àwọn àpéjọ kó sì máa bá wọn kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Kódà, títí dòní a ṣì nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i nínú àwọn ìjọ tó wà níbẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bíbójútó onírúurú iṣẹ́ nínú ìjọ kò rọrùn, Michael tó ti di alàgbà báyìí, sọ pé: “Inú mi máa ń dùn, ayọ̀ mi sì máa ń kún tí mo bá ń ran àwọn ará lọ́wọ́. Kò sí nǹkan míì tí mo lè fi ìgbésí ayé mi ṣe jùyẹn lọ!”

Nígbà tó yá, Matthew fẹ́ Marina, Michael náà sì fẹ́ Olga. Àwọn tọkọtaya méjèèjì àti ọ̀pọ̀ àwọn ará míì tó yọ̀ǹda ara wọn ń bá a lọ ní ríran àwọn ìjọ tó wà níbẹ̀ lọ́wọ́.

ÀWỌN ARÁBÌNRIN ONÍTARA KÓPA NÍNÚ IṢẸ́ ÌKÓRÈ NÁÀ

Tatyana

Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] ni Tatyana lọ́dún 1994 nígbà tí àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe mẹ́fà wá sìn ní ìjọ wọn ní orílẹ̀-èdè Ukraine. Orílẹ̀-èdè Czech Republic, Poland àti Slovakia ni wọ́n ti wá. Inú Tatyana máa ń dùn gan-an tó bá ti rántí wọn, ó wá sọ pé: “Aṣáájú-ọ̀nà onítara ni wọ́n, wọ́n kóni mọ́ra, wọ́n máa ń gba ti àwọn ẹlòmíì rò, wọ́n sì mọ Bíbélì dáadáa.” Ó rí bí Jèhófà ṣe bù kún wọn torí pé wọ́n yọ̀ǹda ara wọn, ó wá pinnu pé ‘èmi náà fẹ́ dà bíi wọn.’

Àpẹẹrẹ rere àwọn aṣáájú-ọ̀nà náà jẹ́ ohun ìṣírí fún Tatyana gan-an débi pé nígbà ọlidé, òun àti àwọn ará míì máa ń lọ sí àwọn ìpínlẹ̀ tó wà níbi àdádó ní orílẹ̀-èdè Ukraine àti Belarus kí wọ́n lè lọ wàásù ní àwọn ìpínlẹ̀ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan kò tíì dé rí. Ó máa ń gbádùn iṣẹ́ ìwàásù tí wọ́n máa ń ṣe níbẹ̀ débi tó fi pinnu pé òun á mú iṣẹ́ ìsìn òun gbòòrò sí i nípa lílọ sí orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Ó kọ́kọ́ lọ síbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ láti lọ kí arábìnrin kan tó ti kó lọ síbẹ̀ láti ilẹ̀ òkèèrè, ó sì tún wá iṣẹ́ tó lè máa ṣe láti fi ti iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tó ń ṣe lẹ́yìn. Nígbà tó sì di ọdún 2000, ó kó lọ sí orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Báwo ni àwọn ìyípadà yìí ṣe rí lára Tatyana?

Tatyana sọ pé: “Torí pé mi ò lè dá ilé gbà, ṣe ni mo ní láti háyà iyàrá kan nínú ilé táwọn míì ń gbé, àmọ́ kò rọrùn. Ìgbà míì tiẹ̀ wà tó máa ń ṣe mí bíi pé kí n pa dà sílé. Àmọ́, Jèhófà máa ń jẹ́ kí n rí i pé màá jàǹfààní tí mo bá ń bá iṣẹ́ ìsìn mi nìṣó.” Tatyana ti ń sìn gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì ní orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà báyìí. Ó wá sọ pé: “Gbogbo ọdún tí mo ti lò ní ilẹ̀ òkèèrè ti jẹ́ kí n ní àwọn ìrírí tó gbádùn mọ́ni. Pàápàá jù lọ, wọ́n ti fún ìgbàgbọ́ mi lókun.”

Masako

Orílẹ̀-èdè Japan, ni Masako ti wá, ó ti lé ní ẹni àádọ́ta [50] ọdún báyìí, tipẹ́tipẹ́ ló ti wù ú pé kó sìn gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì, àmọ́ àìlera ò jẹ́ kó lè ṣe é. Síbẹ̀, nígbà tí ara Masako túbọ̀ le sí i, ó pinnu láti kó lọ sí orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà kó lè ṣe nínú iṣẹ́ ìkórè náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn láti rí ilé tó bójú mu àti iṣẹ́ gidi, ó ń kọ́ àwọn èèyàn ní èdè Japanese, ó sì ń ṣe iṣẹ́ ìmọ́tótó nínú ilé àwọn èèyàn láti fi ti iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ lẹ́yìn. Kí ló ràn án lọ́wọ́ láti máa bá iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ nìṣó?

Nígbà tí Masako ń ronú nípa ọdún mẹ́rìnlá [14] tó ti lò ní orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, ó sọ pé: “Ayọ̀ tí mo ní nínú iṣẹ́ ìsìn mi pọ̀ ju àwọn ìṣòro tí mo dojú kọ lọ. Téèyàn bá ń wàásù níbi tí wọ́n ti nílò àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run, ó máa ń jẹ́ kí ọwọ́ èèyàn dí, ó sì máa ń gbádùn mọ́ni.” Ó tún sọ pé: “Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún mi, torí mo ti rí i ní tààràtà bí Jèhófà ṣe ń pèsè gbogbo ohun tí mo nílò bí oúnjẹ, aṣọ àti ibùgbé.” Láfikún sí bí Masako ṣe ń sìn níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i ní orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, ó tún lọ́wọ́ sí iṣẹ́ ìkórè tó ń lọ lọ́wọ́ ní ìlú Kyrgyzstan. Ó tún ń ran àwọn àwùjọ tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì, èdè Chinese àti èdè Uighur lọ́wọ́. Ní báyìí, ó ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà ní ìlú St. Petersburg.

ÀWỌN ÌDÍLÉ Ń KÓPA NÍNÚ IṢẸ́ NÁÀ, WỌ́N SÌ Ń RÍ ÌBÙKÚN GBÀ

Inga àti Mikhail

Nítorí ìṣòro ìṣúnná owó, ọ̀pọ̀ àwọn ìdílé máa ń kó lọ sí ilẹ̀ òkèèrè kí nǹkan lè túbọ̀ rọrùn fún wọn. Àmọ́, bíi ti Ábúráhámù àti Sárà tó gbé láyé àtijọ́, torí kí àwọn ìdílé míì lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn ni wọ́n ṣe máa ń kó lọ sí ilẹ̀ òkèèrè. (Jẹ́n. 12:1-9) Wo àpẹẹrẹ Mikhail àti Inga, tọkọtaya kan tó kó láti orílẹ̀-èdè Ukraine lọ sí orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ní ọdún 2003. Kò pẹ́ tí wọ́n débẹ̀ ni wọ́n rí i pé ọ̀pọ̀ àwọn tó wà níbẹ̀ ni wọ́n fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Mikhail sọ pé: “Nígbà kan, a lọ wàásù ní àdúgbò kan tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan kò tíì dé rí. A rí bàbá àgbà kan, bó ṣe ṣí ilẹ̀kùn ló bi wá pé, ‘Ṣé oníwàásù ni yín?’ A sọ pé bẹ́ẹ̀ ni, ló bá ní: ‘Mo mọ̀ pé ẹ máa wá lọ́jọ́ kan. Ó ṣe tán, ọ̀rọ̀ Jésù ò lè lọ láìní ìmúṣẹ.’ Ó wá tọ́ka sí ohun tó wà nínú ìwé Mátíù 24:14.” Mikhail tún sọ pé: “Ní àdúgbò yẹn, a tún rí àwọn obìnrin mẹ́wàá kan tí wọ́n ń lọ sí Ṣọ́ọ̀ṣì Onítẹ̀bọmi, wọ́n lọ́kàn rere, òùngbẹ òtítọ́ sì ń gbẹ wọ́n. Wọ́n ní ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, tí wọ́n fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní gbogbo òpin ọ̀sẹ̀. Ọ̀pọ̀ wákàtí ni a fi dáhùn àwọn ìbéèrè tí wọ́n ń bi wá, a jọ kọ àwọn orin Ìjọba Ọlọ́run, a sì jọ jẹ oúnjẹ alẹ́ pa pọ̀. Tí mo bá ń rántí àwọn àkókò tá a lò pẹ̀lú wọn, inú mi máa ń dùn gan-an ni.” Mikhail àti Inga ti rí i pé iṣẹ́ ìsìn wọn ní ibi tí a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i ti jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn dénú, ó sì ti mú kí wọ́n ní ìtẹ́lọ́rùn kí wọ́n sì máa láyọ̀. Ní báyìí, wọ́n ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká.

Oksana, Aleksey àti Yury

Ní ọdún 2007, tọkọtaya kan tí orúkọ wọn ń jẹ́ Yury àti Oksana tí wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè Ukraine, ṣe ìbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, wọ́n ti tó ẹni ọdún márùndínlógójì [35]. Wọ́n mú ọmọ wọn Aleksey, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlá [13] báyìí dání. Wọ́n rí àwòrán orílẹ̀-èdè Rọ́síà, ó wá hàn kedere sí wọn pé ọ̀pọ̀ àgbègbè ló wà níbẹ̀ láìsí oníwàásù kankan. Oksana sọ pé: “Lẹ́yìn tá a rí àwòrán orílẹ̀-èdè náà, ó wá dá wa lójú pé wọ́n nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Èyí mú ká pinnu láti kó lọ sí orílẹ̀-èdè Rọ́síà.” Kí ló tún ràn wọ́n lọ́wọ́? Yury sọ pé: “Kíka irú àpilẹ̀kọ bíi ‘Ǹjẹ́ O Lè Sìn ní Ilẹ̀ Òkèèrè?’ tó wà nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa, ti ràn wá lọ́wọ́. * A lọ ṣèbẹ̀wò sí àgbègbè tí ẹ̀ka ọ́fíìsì sọ pé ká ti lọ sìn, a sì wá ilé àti iṣẹ́ tí a ó fi máa gbọ́ bùkátà.” Ní ọdún 2008, wọ́n kó lọ sí orílẹ̀-èdè Rọ́síà.

Nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ dé ibẹ̀, kò rọrùn láti rí iṣẹ́, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n sì máa ń kó láti inú ilé kan sí òmíràn. Yury wá sọ pé: “Ìgbà gbogbo la máa ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ kí a má bàa rẹ̀wẹ̀sì, a sì ń bá iṣẹ́ ìwàásù wa nìṣó torí a mọ̀ pé Jèhófà máa tì wá lẹ́yìn. A máa ń rí bí Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ tí a bá ti ń fi Ìjọba rẹ̀ sí ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wa. Iṣẹ́ ìsìn wa ti túbọ̀ fún ìdílé wa lókun nípa tẹ̀mí.” (Mát. 6:22, 33) Ipa wo ni iṣẹ́ ìsìn ní ibi tí a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i ti ní lórí Aleksey? Oksana sọ pé: “Àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún Aleksey. Nígbà tó pé ọmọ ọdún mẹ́sàn-án, ó ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, ó sì ṣe ìrìbọmi. Nítorí a nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i níbẹ̀, ó máa ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ nígbà tí wọ́n bá gba ọlidé. Inú wa máa ń dùn bí a ṣe ń rí ìfẹ́ àti ìtara tó ní fún iṣẹ́ ìwàásù.” Yury àti Oksana ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe báyìí.

“OHUN KAN ṢOṢO TÓ DÙN MÍ”

Bí a ṣe rí i nínú ìrírí àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìkórè yìí, lílọ sí ibòmíràn ká lè mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa gbòòrò sí i gba pé ká ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Jèhófà. Lóòótọ́, àwọn tó kó lọ sí ibi tí a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i máa ń dojú kọ àwọn ìpèníjà, àmọ́ wọ́n máa ń rí ayọ̀ àtọkànwá tó wà nínú wíwàásù fún àwọn èèyàn tó fẹ́ gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Ṣé ìwọ náà máa fẹ́ kópa nínú iṣẹ́ ìkórè yìí ní àwọn ibi tí a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi ti Yury tó pinnu láti sìn ní ibi tí a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i, ó ní: “Ohun kan ṣoṣo tó dùn mí ni pé mi ò tètè bẹ̀rẹ̀.”

^ ìpínrọ̀ 20 Wo Ilé Ìṣọ́, October 15, 1999, ojú ìwé 23 sí 27.