Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

A Pinnu Láti Jẹ́ Kí Nǹkan Díẹ̀ Tẹ́ Wa Lọ́rùn

A Pinnu Láti Jẹ́ Kí Nǹkan Díẹ̀ Tẹ́ Wa Lọ́rùn

 Ìgbé ayé ìrọ̀rùn ni Madián àti Marcela ń gbé ní ìlú Medellin, lórílẹ̀-èdè Colombia. Wọ́n ń san owó gidi fún Madián lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀, torí náà, inú ilé ńlá ni wọn ń gbé. Àmọ́ ohun kan ṣẹlẹ̀ tó mú kí wọ́n ṣàyẹ̀wò ohun tí wọ́n kà sí pàtàkì jù láyé wọn. Wọ́n sọ pé: “Lọ́dún 2006, a lọ sí àpéjọ àkànṣe kan tó ní àkòrí náà ‘Ẹ jẹ́ Kí Ojú Yín Mú Ọ̀nà Kan’. Púpọ̀ nínú àwọn àsọyé àpéjọ náà dá lórí béèyàn ṣe lè jẹ́ kí àwọn nǹkan díẹ̀ tẹ́ ẹ́ lọ́rùn kó lè ráyè ṣe púpọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Bá a ṣe ń kúrò ní àpéjọ yìí, a rí i pé òdìkejì ohun tá a gbọ́ là ń ṣe. Gbogbo ohun tá a bá rí la máa ń rà, gbèsè sì kún nílè tá a máa san.”

 Lẹ́yìn àpéjọ náà, Madián àti Marcela bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn ìyípadà táá jẹ́ kí wọ́n dín àwọn nǹkan tara kù. Wọ́n sọ pé: “A dín ìnáwó wa kù. A kó lọ sí ilé tó kéré sí èyí tá à ń gbé tẹ́lẹ̀. A ta mọ́tò wa, a sì ra ọ̀kadà.” Láfikún, wọn ò lọ sáwọn ilé ìtajà ńlá mọ́ kí wọ́n má bàa ra àwọn nǹkan tí wọn ò nílò. Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í lo ọ̀pọ̀ àkókò láti bá àwọn aládùúgbò wọn sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì. Wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wọn tó ń fìtara ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. a

 Kò pẹ́ sígbà yẹn, Madián àti Marcela pinnu láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ Ọlọ́run nípa kíkó lọ sí ìjọ kékeré tó nílò ìrànlọ́wọ́ lábúlé kan. Ṣe ni Madián ní láti fi iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ kí wọ́n lè lọ. Ọ̀gá rẹ̀ ronú pé ìwà òmùgọ̀ ló fẹ́ hù bó ṣe sọ pé òun fẹ́ fiṣẹ́ sílẹ̀. Madián wá béèrè lọ́wọ́ ọ̀gá ẹ̀ pé: “Ẹ̀ ń gba owó tó pọ̀, àmọ́ ṣé ẹ láyọ̀?” Ọ̀gá rẹ̀ gbà pé òun ò láyọ̀, torí ó ní ọ̀pọ̀ ìṣòro tí òun fúnra ẹ̀ kò lè yanjú. Ó wá sọ fún ọ̀gá rẹ̀ pé: “Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni ohun tó ń fúnni láyọ̀, kì í ṣe iye owó téèyàn ní. Kíkọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ń mú kí èmi àti ìyàwó mi láyọ̀, ó sì wù wá kí ayọ̀ wa pọ̀ sí i, torí ẹ̀ lá ṣe pinnu láti máa lo ọ̀pọ̀ àkókò lẹ́nu iṣẹ́ yìí.

 Madián àti Marcela ní ìtẹ́lọ́rùn, wọ́n sì ń láyọ̀ torí wọ́n fi iṣẹ́ Ọlọ́run ṣáájú láyé wọn. Láti ọdún mẹ́tàlá sẹ́yìn, wọ́n ti sìn níbi tí àìní wà láwọn ìjọ tó wà lápá àríwá Colombia. Ní báyìí, àwọn náà ti di aṣáájú ọ̀nà àkànṣe, wọ́n sì ń gbádùn iṣẹ́ náà gan-an.

a Àwọn asáájú-ọ̀nà àkànṣe làwọn tí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yàn láti máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run láwọn agbègbè kan. A máa ń fún wọn lówó táṣẹ́rẹ́ láti bójú tó àwọn ìnáwó ojoojúmọ́.