Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú​—Ní Myanmar

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú​—Ní Myanmar

NÍ NǸKAN bí ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] ọdún sẹ́yìn, Jésù sọ pé: “Ìkórè pọ̀, ní tòótọ́, ṣùgbọ́n àwọn òṣìṣẹ́ kéré níye. Nítorí náà, ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè kí ó rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀.” (Lúùkù 10:2) Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí bá ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Myanmar mu. Kí nìdí? Ìdí ni pé nǹkan bíi mílíọ̀nù lọ́nà márùndínlọ́gọ́ta [55,000,000] èèyàn ló ń gbé orílẹ̀-èdè Myanmar, àmọ́ àwọn àkéde tó ń wàásù níbẹ̀ ò ju ẹgbẹ̀rún mẹ́rin àti ọgọ́rùn-ún méjì [4,200] lọ.

Inú wa dùn pé Jèhófà tó jẹ́ “Ọ̀gá ìkórè” náà ti ń rán àwọn òṣìṣẹ́ lọ sẹ́nu iṣẹ́ ìkórè yìí. Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ló ti filé fọ̀nà sílẹ̀, kí wọ́n lè wá sìn lórílẹ̀-èdè Myanmar tó wà nílẹ̀ Éṣíà. Kí ló mú kí wọ́n fi orílẹ̀-èdè wọn sílẹ̀? Kí ló ràn wọ́n lọ́wọ́ láti gbé ìgbésẹ̀ yìí? Àwọn ìbùkún wo sì ni wọ́n ń gbádùn? Ẹ jẹ́ ká gbọ́rọ̀ lẹ́nu wọn.

“Ẹ MÁA BỌ̀, A NÍLÒ ÀWỌN AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ SÍ I!”

Aṣáájú-ọ̀nà ni Arákùnrin Kazuhiro tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Japan. Lọ́jọ́ kan, wárápá ṣàdédé gbé e, ló bá dákú lọ gbọnrangandan, wọ́n sì gbé e lọ sílé ìwòsàn. Dókítà wá sọ fún un pé kò gbọ́dọ̀ wa mọ́tò fún ọdún méjì gbáko. Ọ̀rọ̀ yìí ká Kazuhiro lára gan-an, ó ronú pé, ‘Ṣé màá lè máa bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lọ báyìí?’ Ó wá gbàdúrà pé kí Jèhófà ran òun lọ́wọ́ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, kò sì fẹ́ fi iṣẹ́ náà sílẹ̀.

Kazuhiro àti Mari

Kazuhiro sọ pé: “Oṣù kan lẹ́yìn náà, ọ̀rẹ́ mi kan tó ń sìn ní Myanmar gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi. Ó pè mí, ó wá sọ fún mi pé: ‘Tó o bá wá sí Myanmar, o lè máa bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ẹ lọ níbí láìwa mọ́tò rárá torí pé àwọn bọ́ọ̀sì tó jẹ́ ọkọ̀ èrò la sábà máa ń wọ̀.’ Mo wá bi dókítà mi bóyá àìlera mi á lè jẹ́ kí n kó lọ sí Myanmar. Ohun tí dókítà náà sọ yà mí lẹ́nu, ó ní: ‘Dókítà kan wà ní Japan báyìí tó wá láti Myanmar, dókítà yìí mọ̀ nípa ohun tó ń ṣe ẹ́. Màá mú ẹ lọ bá a. Tí wárápá bá tún gbé ẹ, ó máa tọ́jú ẹ.’ Ohun tí dókítà yìí sọ mú kí n gbà pé Jèhófà ti dáhùn àdúrà mi.”

Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Kazuhiro kọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì ní Myanmar, ó sì sọ fún wọn pé ó wu òun àtìyàwó òun láti wá ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní Myanmar. Ọjọ́ márùn-ún péré lẹ́yìn náà ni ẹ̀ka ọ́fíìsì fún wọn lésì, wọ́n sọ pé, “Ẹ máa bọ̀, a nílò àwọn aṣáájú-ọ̀nà sí i!” Kazuhiro àti Mari ìyàwó rẹ̀ ta ọkọ̀ wọn méjèèjì, wọ́n gba ìwé àṣẹ ìwọ̀lú, wọ́n sì ra tíkẹ́ẹ̀tì ọkọ̀ òfuurufú. Ní báyìí, wọ́n ń láyọ̀ bí wọ́n ṣe ń sìn pẹ̀lú àwùjọ tó ń sọ èdè àwọn adití ní Mandalay. Kazuhiro sọ pé: “Àwọn ìrírí tá a ní ti jẹ́ ká gbà pé òótọ́ lọ́rọ̀ Jèhófà tó wà nínú Sáàmù 37:5 pé: ‘Yí ọ̀nà rẹ lọ sọ́dọ̀ Jèhófà, kí o sì gbójú lé e, òun yóò sì gbé ìgbésẹ̀.’ Èyí ti fún ìgbàgbọ́ wa lókùn gan-an.”

JÈHÓFÀ ṢÍ Ọ̀NÀ SÍLẸ̀

Lọ́dún 2014, a ṣe àkànṣe àpéjọ kan ní Myanmar. Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ló sì wá láti orílẹ̀-èdè míì fún àpéjọ náà. Lára wọn ni Arábìnrin Monique tó wá láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [34] ni, ó sọ pé: “Lẹ́yìn tí mo pa dà sílé, mo gbàdúrà pé kí Jèhófà tọ́ mi sọ́nà, kí n lè mọ ohun tó yẹ kí n fayé mi ṣe. Mo wá bá àwọn òbí mi sọ̀rọ̀ nípa bí mo ṣe lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. A pinnu pé á dáa kí n lọ sìn ní Myanmar, àmọ́ ó gba àkókò, ó sì gba ọ̀pọ̀ àdúrà kí n tó gbé ìgbésẹ̀ yẹn.” Monique ṣàlàyé ìdí tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀.

Monique àti Li

Ó ní: “Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n ‘gbéṣirò lé ohun tó máa ná wọn.’ Torí náà mo bi ara mi pé: ‘Ṣé owó tí mo ní lọ́wọ́ máa ká ohun tí mo fẹ́ ṣe yìí? Ṣé màá ríṣẹ́ lọ́hùn-ún, tí iṣẹ́ náà ò sì ní gbà mí lákòókò jù?’ ” Monique sọ pé: “Mo wá rí i pé owó tí mo ní ò lè ká ohun tí mo fẹ́ ṣe yìí.” Báwo ló ṣe wá rí owó tó nílò kó lè lọ sí Myanmar?​—Lúùkù 14:28.

Monique ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Lọ́jọ́ kan, ọ̀gá mi níbiiṣẹ́ sọ pé òun fẹ́ rí mi. Ẹ̀rù ti bà mí torí mo rò pé ó fẹ́ lé mi lẹ́nu iṣẹ́ ni. Àmọ́ nígbà tí mo dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ṣe ló dúpẹ́ lọ́wọ́ mi torí pé mo máa ń ṣiṣẹ́ kára. Ó wá sọ fún mi pé òun fẹ́ san owó àjẹmọ́nú kan fún mi. Nígbà tó máa san án, ló bá di iye tí mo nílò gẹ́lẹ́ láti lọ sìn ní Myanmar!”

Àtoṣù December 2014 ni Monique ti ń sìn ní Myanmar. Báwo ló ṣe rí lára rẹ̀ pé ó ń sìn níbi tí àìní gbé pọ̀? Ó sọ pé: “Inú mi dùn gan-an pé mo wá sìn níbí. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́ta ni mò ń darí báyìí. Lára wọn ni màmá àgbàlagbà kan tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàdínláàádọ́rin [67]. Tí mo bá dé ọ̀dọ̀ màmá, wọ́n á rẹ́rìn-ín sí mi, wọ́n á sì gbá mi mọ́ra. Lọ́jọ́ tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run, ṣe lomi bọ́ lójú wọn. Wọ́n sọ fún mi pé: ‘Ìgbà àkọ́kọ́ rèé láyé mi tí màá gbọ́ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. Bí ọmọ lo jẹ́ sí mi, àmọ́ o ti kọ́ mi ní nǹkan tó ṣe pàtàkì jù lọ láyé mi.’ Nígbà tí wọ́n sọ bẹ́ẹ̀, ṣe ni omijé bọ́ lójú tèmi náà. Irú àwọn ìrírí báyìí ti jẹ́ kí n rí i pé kò sóhun tó dà bíi kéèyàn lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀.” Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, Monique láǹfààní láti lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run.

Ohun míì tó tún mú káwọn kan wá sìn ní Myanmar ni ìròyìn orílẹ̀-èdè náà tó wà nínú Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Ọdún 2013. Bí àpẹẹrẹ, Arábìnrin Li ti lé lẹ́ni ọgbọ̀n [30] ọdún, orílẹ̀-èdè kan ní Éṣíà ló sì ń gbé. Iṣẹ́ tó ń ṣe máa ń gba àkókò rẹ̀, àmọ́ nígbà tó ka Ìwé Ọdọọdún náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ronú àtilọ sìn ní Myanmar. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo lọ sí àkànṣe àpéjọ tí wọ́n ṣe nílùú Yangon lọ́dún 2014, mo pàdé tọkọtaya kan tó ń sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ lágbègbè àwọn tó ń sọ èdè Chinese ní Myanmar. Torí pé mo gbọ́ èdè Chinese, mo pinnu láti lọ sìn ní Myanmar kí n lè ran àwùjọ tó ń sọ èdè yẹn lọ́wọ́. Èmi àti Monique la jọ bẹ̀rẹ̀ ètò, a sì jọ kó lọ sí Mandalay. Jèhófà ràn wá lọ́wọ́ gan-an torí pé a ríṣẹ́ tíṣà ní iléèwé kan náà, iṣẹ́ náà ò sì gbà wá lákòókò rárá. Yàtọ̀ síyẹn, a tún rílé sítòsí iléèwé náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ojú ọjọ́ máa ń móoru gan-an, a sì láwọn ìṣòro pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ míì, síbẹ̀ mò ń gbádùn iṣẹ́ ìsìn mi gan-an níbí. Ìgbé ayé ṣe-bó-o-ti-mọ láwọn èèyàn ń gbé ní Myanmar, wọ́n máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn, wọ́n sì máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí ìhìn rere. Inú mi ń dùn bí mo ṣe rí bí Jèhófà ṣe ń mú kí iṣẹ́ náà yára kánkán. Ó dá mi lójú pé ó wu Jèhófà pé kí n wá sìn níbí ni mo ṣe wà ní Mandalay.”

JÈHÓFÀ GBỌ́ ÀDÚRÀ WỌN

Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ ló ti rí bí Jèhófà ṣe máa ń dáhùn àdúrà. Bí àpẹẹrẹ Jumpei àtìyàwó rẹ̀ Nao ti lé lẹ́ni ọgbọ̀n [30] ọdún. Ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè àwọn adití ní Japan ni wọ́n ti ń sìn tẹ́lẹ̀. Kí wá nìdí tí wọ́n fi kó lọ sí Myanmar? Jumpei sọ pé: “Ọjọ́ pẹ́ témi àtìyàwó mi ti pinnu pé a máa lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ lórílẹ̀-èdè míì. Nígbà tó yá, arákùnrin kan tá a jọ wà níjọ tó ń sọ èdè àwọn adití ní Japan kó lọ sí Myanmar. Nígbà tó di May 2010, àwa náà kó lọ sí Myanmar bó tilẹ̀ jẹ́ pé owó díẹ̀ la ní. Ṣe làwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wà ní Myanmar gbà wá tọwọ́tẹsẹ̀!” Báwo ló ṣe rí lára wọn pé wọ́n ń sìn níjọ tó ń sọ èdè àwọn adití ní Myanmar? Jumpei sọ pé: “Àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ ìwàásù gan-an níbí. Ẹnu máa ń ya àwọn adití tá a bá fi àwọn fídíò tó wà lédè àwọn adití hàn wọ́n. Inú wa dùn gan-an pé a pinnu láti wá síbí ká lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà!”

Nao and Jumpei

Báwo ni Jumpei àti Nao ìyàwó rẹ̀ ṣe ń gbọ́ bùkátà ara wọn? Jumpei sọ pé: “Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta, a ti fẹ́rẹ̀ẹ́ ná gbogbo owó wa tán, a ò sì lówó tá a lè fi san owó ilé ọdún tó tẹ̀ lé e. Èmi àtìyàwó mi gbàdúrà gan-an lórí ọ̀rọ̀ yìí, Jèhófà sì dá wa lóhùn torí pé láìròtẹ́lẹ̀ ni ẹ̀ka ọ́fíìsì sọ wá di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe onígbà díẹ̀! A gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, Jèhófà náà ò sì já wa kulẹ̀ torí pé gbogbo ìgbà la máa ń rọ́wọ́ rẹ̀ lára wa.” Láìpẹ́ yìí, Jumpei àtìyàwó rẹ̀ lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run.

JÈHÓFÀ SÚN WỌN ṢIṢẸ́

Ẹni ọdún mẹ́tàlélógójì [43] ni Simone tó wá láti Italy. Ìyàwó rẹ̀ Anna ti pé ẹni ọdún mẹ́tàdínlógójì [37], New Zealand ló sì ti wá. Kí ló mú káwọn méjèèjì pinnu láti lọ sìn ní Myanmar? Anna sọ pé: “Ìwé Ọdọọdún 2013 tó sọ̀rọ̀ nípa Myanmar ni!” Simone sọ pé: “Inú wa dùn gan-an pé a wá sí Myanmar. Kò sí kòókòó-jàn-ánjàn-án níbí, ìyẹn sì jẹ́ kí n lè lo àkókò mi fún iṣẹ́ Jèhófà. Orí mi máa ń wú ti mo bá ń rí bí Jèhófà ṣe ń tọ́jú àwa tá à ń sìn níbi tí àìní gbé pọ̀.” (Sm. 121:5) Anna ìyàwó rẹ̀ sọ pé: “Mi ò láyọ̀ tó báyìí rí láyé mi. Ìgbésí ayé ṣe-bó-o-ti-mọ là ń gbé, ìyẹn sì jẹ́ kémi àtọkọ mi túbọ̀ ráyè fún ara wa, a ti wá mọwọ́ ara wa gan-an. Yàtọ̀ síyẹn, a ti láwọn ọ̀rẹ́ tuntun. Àwọn èèyàn máa ń gbọ́ ìwàásù gan-an níbi torí pé wọn kì í ṣe ẹ̀tanú sí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà!” Kí ló mú kó sọ bẹ́ẹ̀?

Simone àti Anna

Anna sọ pé: “Lọ́jọ́ kan, mo wàásù fún ọmọ yunifásítì kan lọ́jà, mo sì ṣèlérí pé màá pa dà wá. Nígbà tí mo pa dà lọ, ṣe ló pe ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan wá. Nígbà míì tí mo tún lọ, ó tún pe àwọn míì wá. Nígbà tó yá, ó tún mú àwọn míì wá. Ní báyìí, márùn-ún nínú wọn ni mò ń bá ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́.” Simone sọ pé: “Ará àwọn èèyàn níbí máa ń yá mọ́ọ̀yàn, ó sì máa ń wù wọ́n láti tẹ́tí sóhun tá a fẹ́ sọ. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́, kódà kò sí bá a ṣe lè bá gbogbo wọn ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́.”

Sachio àti Mizuho

Ìgbésẹ̀ wo làwọn kan gbé kí wọ́n tó pinnu láti lọ sìn ní Myanmar? Mizuho tó wá láti Japan sọ pé: “Ọjọ́ pẹ́ tó ti máa ń wu èmi àti Sachio ọkọ mi pé ká lọ sìn níbi tí àìní wà lórílẹ̀-èdè míì, àmọ́ a ò mọ orílẹ̀-èdè tá a máa lọ. Lẹ́yìn tá a ka Ìwé Ọdọọdún 2013 sọ̀rọ̀ nípa Myanmar, àwọn ìrírí tó wà nínú rẹ̀ wú wa lórí débi pé a bẹ̀rẹ̀ sí í ronú bóyá a lè lọ sìn níbẹ̀.” Sachio fi kún un pé: “A wá pinnu láti lọ lo ọ̀sẹ̀ kan nílùú Yangon, tó jẹ́ olú ìlú Myanmar ká lè wo bí ibẹ̀ ṣe rí. Ọ̀sẹ̀ kan tá a lò yẹn ló mú ká pinnu láti wá sìn níbí.”

ṢÉ ÌWỌ NÁÀ LÈ LỌ SÌN NÍBI TÍ ÀÌNÍ GBÉ PỌ̀?

Jane, Danica, Rodney, àti Jordan

Orílẹ̀-èdè Ọsirélíà ni Rodney àtìyàwó rẹ̀ Jane ti wá, wọ́n sì ti lé lẹ́ni àádọ́ta [50] ọdún. Àwọn àti Jordan ọmọ wọn ọkùnrin pẹ̀lú Danica ọmọbìnrin wọn ti ń sìn ní Myanmar látọdún 2010. Rodney sọ pé: “Inú wa dùn gan-an nígbà tá a rí pé ó wu àwọn èèyàn níbí láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run. Mo lè fi gbogbo ẹnu sọ pé kò sí ohun tó dùn tó kí ìdílé lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀.” Kí ló mú kó sọ bẹ́ẹ̀? Ó ní: “Ìgbésẹ̀ yìí ti mú kí ìdílé wa túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ lónìí ló jẹ́ pé àwọn nǹkan bíi fóònù, mọ́tò àti iṣẹ́ ló gbà wọ́n lọ́kàn. Àmọ́, iṣẹ́ ìwàásù ló gba àwọn ọmọ wa lọ́kàn, wọ́n sì ń kọ́ èdè tí wọ́n lè fi ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n ń kọ́ bí wọ́n ṣe lè máa wàásù fáwọn tí kò mọ̀ nípa Bíbélì, wọ́n sì ń kọ́ bí wọ́n ṣe ń dáhùn lédè tí wọ́n ń sọ nípàdé ìjọ. Lọ́rọ̀ kan, àwọn nǹkan tẹ̀mí ló gbà wọ́n lọ́kàn.”

Oliver àti Anna

Ẹni ọdún mẹ́tàdínlógójì [37] ni Oliver, Amẹ́ríkà ló sì ti wá. Ó sọ ìdí tó fi ń gba àwọn míì níyànjú pé kí wọ́n wá sìn níbi tí àìní gbé pọ̀, ó ní: “Bí mo ṣe kúrò níbi tó rọ̀ mí lọ́rùn níbi tí tẹbí tọ̀rẹ́ wà, tí mo wá sìn níbí, ti mú kí n túbọ̀ láyọ̀. Ìgbésẹ̀ yìí ti jẹ́ kí n túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé á dúró tì mí láìka ipòkípò tí mo bá wà. Bí mo ṣe ń sin Jèhófà pẹ̀lú àwọn tá ò mọra rí ti jẹ́ kí n rí i pé kò síbi tó dà bí ètò Ọlọ́run nínú ayé yìí.” Ní báyìí, Oliver àti Anna ìyàwó rẹ̀ ń fìtara wàásù fáwọn tó ń sọ èdè Chinese.

Trazel

Orílẹ̀-èdè Ọsirélíà ni Arábìnrin Trazel ti wá, ẹni ọdún méjìléláàádọ́ta [52] ni, ó sì ti ń sìn ní Myanmar látọdún 2004. Ó sọ pé: “Fún àwọn tó bá lè wá àyè fún un, á dáa kí wọ́n lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀. Mo ti rí i pé tó bá ń wu èèyàn láti sìn, Jèhófà máa bù kún ìsapá ẹni náà. Mi ò mọ̀ pé inú mi lè dùn tó yìí. Kí n sòótọ́, kò sóhun míì tí mo lè fayé mi ṣe tó lè fún mi nírú ayọ̀ àti ìbàlẹ̀ ọkàn tí mo ní.”

Ǹjẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn tó ń sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ ní Myanmar fún ìwọ náà níṣìírí kó o lè lọ sìn láwọn àgbègbè tí àìní gbé pọ̀. Ṣe ló dà bí ìgbà tí àwọn tó ń sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ ń ké sí wa pé, “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ rékọjá wá sí Myanmar, kẹ́ ẹ sì ràn wá lọ́wọ́!”