Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—Ní Bulgaria

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—Ní Bulgaria

 Iṣẹ́ kékeré kọ́ làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Bulgaria ń ṣe kí wọ́n lè kọ́ àwọn èèyàn ní òtítọ́ nípa Ọlọ́run àti Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láwọn ilẹ̀ míì ló ń ṣí wá sí Bulgaria látọdún 2000, kí wọ́n lè wá ràn wọ́n lọ́wọ́. Àwọn ìṣòro wo ló wà nínú kéèyàn ṣí kúrò níbi tó ń gbé láti lọ wàásù nílẹ̀ òkèèrè? Àǹfààní wo ló wà nínú kéèyàn ṣe bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká gbọ́rọ̀ lẹ́nu àwọn kan tó ṣí wá sórílẹ̀-èdè Bulgaria.

Ohun Tó O Lè Ṣe Kó Lè Wù Ẹ́ Láti Lọ

 Darren, tó ń gbé ní England tẹ́lẹ̀ sọ pé: “Ó ti pẹ́ tó ti wà lọ́kàn wa pé ká lọ sìn nílẹ̀ míì tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Lẹ́yìn tí mo fẹ́ Dawn, ìyàwó mi, a kó lọ sí ìlú London ká lè ṣèrànwọ́ fáwọn tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lédè Russian. A gbìyànjú nígbà mélòó kan láti ṣí lọ sí ilẹ̀ míì, àmọ́ oríṣiríṣi nǹkan ò jẹ́ ká lè lọ. Lọ́kàn wa, a ti rò pé kò ní ṣeé ṣe. Àmọ́, ọ̀rẹ́ wa kan jẹ́ ká rí i pé pẹ̀lú bí nǹkan ṣe rí fún wa, ó yẹ kọ́wọ́ wa lè tẹ ohun tá à ń wá.” Ni Darren àti Dawn bá bẹ̀rẹ̀ sí í wá orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti túbọ̀ nílò àwọn tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tó sì máa ṣeé ṣe fún wọn láti ṣí lọ síbẹ̀. Lọ́dún 2011, wọ́n ṣí lọ sí Bulgaria.

Darren àti Dawn

 Nígbà táwọn tí kò fẹ́ ṣí lọ sílẹ̀ òkèèrè rí ayọ̀ táwọn tó ṣe bẹ́ẹ̀ ní, àwọn náà pinnu láti ṣe bẹ́ẹ̀. Giada tóun àti ọkọ ẹ̀ Luca ń gbé ní Ítálì tẹ́lẹ̀ sọ pé: “Mo rí àwọn Ẹlẹ́rìí tó nítara tí wọ́n ń fayọ̀ wàásù ní South America àti Áfíríkà. Ayọ̀ tí wọ́n ń rí àtàwọn ìrírí tí wọ́n ń sọ wú mi lórí gan-an. Ó mú kí n yí àwọn ohun tí mo fẹ́ ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run pa dà.”

Luca àti Giada

 Lọ́dún 2015, tọkọtaya kan tó ń jẹ́ Tomasz àti Veronika ṣí wá sí Bulgaria láti Czech Republic pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn méjì tó ń jẹ́ Klara àti Mathias. Kí ló mú kí wọ́n ṣí wá? Tomasz sọ pé: “A fara balẹ̀ wo àpẹẹrẹ àwọn tó ṣí lọ sí ilẹ̀ míì, títí kan àwọn mọ̀lẹ́bí wa tó ṣe bẹ́ẹ̀, a sì ronú lórí àwọn ìrírí tí wọ́n ti ní. Ayọ̀ tí wọ́n ń ní wu àwa náà, a sì máa ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ nínú ìdílé wa.” Ìlú Montana lórílẹ̀-èdè Bulgaria ni ìdílé yìí ti ń wàásù báyìí.

Klara, Tomasz, Veronika, àti Mathias

 Ẹlẹ́rìí kan tó ń jẹ́ Linda náà kó wá sí Bulgaria. Ó sọ pé: “Lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn, mo lọ sí Ecuador, mo sì rí àwọn kan tó ṣí wá síbẹ̀ láti wàásù. Ìyẹn ló mú kémi náà rò ó pé bóyá lọ́jọ́ kan, màá lè lọ síbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i.” Tọkọtaya kan tó ń jẹ́ Petteri àti Nadja, tí wọ́n wá láti Finland náà ronú nípa àpẹẹrẹ àwọn míì. Wọ́n ní: “Nínú ìjọ tá a wà nílé, a láwọn akéde tó nírìírí, tí wọ́n sì ti lọ sáwọn ibòmíì láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọn ò lè ṣe kí wọ́n má sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n wà lẹ́nu iṣẹ́ náà. Wọ́n máa ń sọ pé àwọn ọdún táwọn fi wàásù yẹn làwọn gbádùn jù láyé àwọn.”

Linda

Nadja àti Petteri

Bó O Ṣe Lè Múra Sílẹ̀

 Ó ṣe pàtàkì pé káwọn tó fẹ́ lọ sìn nílẹ̀ míì múra sílẹ̀. (Lúùkù 14:28-30) Nele tó wá láti Belgium sọ pé: “Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa béèyàn ṣe lè lọ sìn nílẹ̀ míì, mo gbàdúrà nípa ẹ̀, mo sì wo àwọn àpilẹ̀kọ tó sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ nínú àwọn ìwé wa. Mo kà wọ́n, mo sì rí àwọn nǹkan tó yẹ kí n ṣiṣẹ́ lé lórí.”

Nele (lápá ọ̀tún)

 Orílẹ̀-èdè Poland ni Kristian àti Irmina ti wá, wọ́n sì ti wà ní Bulgaria fún ohun tó lé lọ́dún mẹ́sàn-án báyìí. Wọ́n ní báwọn ṣe máa ń ṣèpàdé ní àwùjọ tó ń sọ èdè Bulgarian káwọn tó kúrò ní Poland ran àwọn lọ́wọ́ gan-an. Àwọn tó wà láwùjọ náà fún wọn níṣìírí, wọ́n sì kọ́ wọn lédè náà. Kristian àti Irmina sọ pé: “A ti wá rí i pé kò sóhun tó dáa tó kéèyàn yọ̀ǹda ara ẹ̀, kéèyàn sì rí bí Jèhófà Ọlọ́run ṣe ń pèsè àwọn ohun tóun nílò. Tó o bá sọ fún Jèhófà tinútinú pé ‘Èmi nìyí! Rán mi!’ ìwọ náà á lè ṣe àwọn nǹkan tí o ò ronú pé wàá lè ṣe.”—Àìsáyà 6:8.

Kristian àti Irmina

 Torí kí tọkọtaya kan tó ń jẹ́ Reto àti Cornelia tó wá láti Switzerland, lè múra sílẹ̀ kí wọ́n sì rí owó kó jọ, wọ́n pinnu pé àwọn máa dín àwọn ohun tí wọ́n ní kù. Wọ́n ní: “Nígbà tó ku ọdún kan ká kó lọ sí Bulgaria, a kọ́kọ́ lọ lo ọ̀sẹ̀ kan níbẹ̀ ká lè mọ bí orílẹ̀-èdè náà ṣe rí. A rí àwọn míṣọ́nnárì tó nírìírí níbẹ̀, wọ́n sì kọ́ wa láwọn ohun tá a lè ṣe.” Reto àti Cornelia tẹ̀ lé àwọn ìmọ̀ràn tó dáa yẹn, ó sì ti lé lógún (20) ọdún báyìí tí wọ́n ti wà ní Bulgaria.

Cornelia àti Reto pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn Luca àti Yannik

Bó O Ṣe Lè Fara Da Àwọn Ìṣòro Tó Bá Yọjú

 Àwọn tó bá ṣí lọ sórílẹ̀-èdè míì máa ń ní àwọn ìṣòro kan, síbẹ̀ wọ́n máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí ara wọn lè mọlé. (Ìṣe 16:9, 10; 1 Kọ́ríńtì 9:19-23) Ohun tó máa ń ṣòro jù fún wọn ni bí wọ́n ṣe máa kọ́ èdè tuntun. Luca tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Inú wa máa ń dùn gan-an tá a bá dáhùn lọ́rọ̀ ara wa nípàdé. Níbẹ̀rẹ̀, kò kọ́kọ́ rọrùn rárá fún èmi àtìyàwó mi láti dáhùn lédè Bulgarian. Ńṣe la dà bí ọmọdé tó ń kọ́ èdè. Kódà, ìdáhùn àwọn ọmọdé tó wà lórílẹ̀-èdè náà dáa ju tiwa lọ.”

 Ravil tó wá láti Jámánì sọ pé: “Àtikọ́ èdè máa ń sú mi. Àmọ́, mo sọ fúnra mi pé, ‘Má jẹ́ kíyẹn dà ẹ́ láàmú jàre, má sì jẹ́ kó ká ẹ lára jù tó o bá ṣàṣìṣe.’ Mo gbà pé bí kò ṣe rọrùn fún mi láti kọ́ èdè yìí kì í ṣe ìṣòro, ara iṣẹ́ ìsìn mi sí Jèhófà ni.”

Ravil àti Lilly

 Linda tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Mi ò létí èdè rárá. Èdè Bulgarian ò sì rọrùn láti kọ́, kódà ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń sú mi. Ńṣe ló máa ń jọ pé èèyàn dá wà tó bá wà láàárín àwọn tí kò gbọ́ èdè ẹ̀, tóun náà ò sì gbọ́ tiwọn. Kí àjọṣe mi pẹ̀lú Jèhófà má bàa bà jẹ́, èdè Swedish ni mo fi máa ń dá kẹ́kọ̀ọ́. Àmọ́ nígbà tó yá, mo gbọ́ èdè Bulgarian dáadáa torí àwọn ará ràn mí lọ́wọ́.”

 Àárò ilé tó máa ń sọ èèyàn tún nìṣòro míì. Àwọn tó bá ṣí lọ sílẹ̀ míì máa ń fi tẹbítọ̀rẹ́ sílẹ̀. Eva tóun àtọkọ ẹ̀ Yannis ṣí wá sí Bulgaria sọ pé: “Níbẹ̀rẹ̀, ó máa ń ṣe mí bíi pé mo dá wà. Torí náà, ohun tá a ṣe ni pé a máa ń bá àwọn èèyàn wa nílé sọ̀rọ̀ lóòrèkóòrè, a sì tún wá àwọn ọ̀rẹ́ tuntun níbí.”

Yannis àti Eva

 Àwọn ìṣòro míì tún wà. Robert àti Liana tí wọ́n wá láti Switzerland sọ pé: “Kò rọrùn rárá fún wa láti kọ́ èdè àti àṣà tuntun, bójú ọjọ́ sì ṣe máa ń rí nígbà òtútù ò mọ́ wa lára.” Àmọ́ torí pé tọkọtaya yìí lérò tó dáa, wọn ò jẹ́ káwọn ìṣòro náà mú kí wọ́n rẹ̀wẹ̀sì. Ní báyìí, wọ́n ti lo ọdún mẹ́rìnlá (14) ní Bulgaria, wọ́n sì ń fayọ̀ báṣẹ́ ìsìn wọn lọ níbẹ̀.

Robert àti Liana

Àwọn Ìbùkún Tí Wọ́n Rí

 Lilly sọ pé òun máa fẹ́ káwọn míì náà lọ wàásù níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Ó ní: “Ó ti jẹ́ kí n wá mọ Jèhófà láwọn ọ̀nà míì, ó sì ṣeé ṣe kí n má láǹfààní ẹ̀ ká ní mi ò kúrò nílé. Ó ti mú kí n túbọ̀ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, ìyẹn ń jẹ́ kí n sún mọ́ Jèhófà, kí n sì láyọ̀ àti ìfọ̀kànbalẹ̀.” Ravil ọkọ ẹ̀ náà sọ pé: “Ohun tó dáa jù téèyàn lè fayé ẹ̀ ṣe nìyí. Àǹfààní ńlá ni mo ní bí mo ṣe mọ àwọn Kristẹni tó nítara tó wá láti oríṣiríṣi ilẹ̀, tí wọ́n sì mọ bí wọ́n ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dáadáa. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni mo ti kọ́ lára wọn.”

 Ẹ̀mí tó dáa tí ọ̀pọ̀ àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn ní ti mú kó ṣeé ṣe láti ‘wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé.’ (Mátíù 24:14) Torí pé àwọn tó wá sí Bulgaria yọ̀ǹda ara wọn, wọ́n ti rí bí Jèhófà ṣe ń fún wọn lóhun tí ọkàn wọn fẹ́, tó sì ń mú kí gbogbo ohun tí wọ́n dáwọ́ lé yọrí sí rere.—Sáàmù 20:1-4.