Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 02

Bíbélì Sọ Pé Ọ̀la Ń Bọ̀ Wá Dáa

Bíbélì Sọ Pé Ọ̀la Ń Bọ̀ Wá Dáa

Oríṣiríṣi ìṣòro ló ń dojú kọ àwọn èèyàn kárí ayé. Ìṣòro náà sì ń fa ìbànújẹ́, àìbalẹ̀ ọkàn àti ìrora fún wọn. Ṣé ìwọ náà ti dojú kọ́ ìṣòro tó kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ rí? Ṣé ikú èèyàn rẹ, àìsàn tàbí nǹkan míì ló ń bà ẹ́ lọ́kàn jẹ́? O lè máa bi ara rẹ pé, ‘Ṣé nǹkan ṣì máa dáa báyìí?’ Bíbélì dáhùn ìbéèrè yìí lọ́nà tó fini lọ́kàn balẹ̀.

1. Kí ni Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn ìṣòro wa lọ́jọ́ iwájú?

Bíbélì sọ ìdí tí ìṣòro fi kún ayé yìí, àmọ́ ó tún sọ ìròyìn ayọ̀ fún wa pé àwọn ìṣòro náà ò ní pẹ́ dópin. Bíbélì sọ pé a ní “ọjọ́ ọ̀la kan àti ìrètí kan.” (Ka Jeremáyà 29:11, 12.) Àwọn ohun rere tá à ń retí yẹn máa jẹ́ ká lè fara da àwọn ìṣòro tá a ní báyìí, wọ́n á jẹ́ ká ní èrò tó dáa, wọ́n á sì jẹ́ ká láyọ̀ títí láé.

2. Kí ni Bíbélì sọ nípa bí ọjọ́ ọ̀la ṣe máa rí?

Bíbélì sọ bí ọjọ́ ọ̀la ṣe máa rí, ó ní “ikú ò ní sí mọ́, kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́.” (Ka Ìfihàn 21:4.) Àwọn ìṣòro tó ń mú káyé súni lónìí ò ní sí mọ́, irú bí ipò òṣì, ìrẹ́jẹ, àìsàn àti ikú. Bíbélì tún ṣèlérí pé àwọn èèyàn máa gbádùn ayé títí láé nínú Párádísè.

3. Kí ló máa jẹ́ kó dá ẹ lójú pé àwọn ohun tí Bíbélì sọ máa ṣẹ?

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń retí àwọn nǹkan rere, síbẹ̀ kò dá wọn lójú pé ọwọ́ wọn máa tẹ àwọn nǹkan náà. Àmọ́ àwọn ìlérí tó wà nínú Bíbélì yàtọ̀. Tá a bá “ń ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ kínníkínní,” ó máa dá wá lójú pé òótọ́ làwọn ìlérí yìí. (Ìṣe 17:11) Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìwọ fúnra ẹ máa rí i pé òótọ́ ni ohun tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la.

KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

Wo díẹ̀ lára àwọn ohun rere tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la. Wo bí àwọn ìlérí tó wà nínú Bíbélì ṣe ń jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn nírètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.

4. Bíbélì sọ pé a máa gbé ayé títí láé láìsí ìṣòro kankan mọ́

Wo àwọn ohun rere tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀. Àwọn wo ló wù ẹ́ jù? Kí sì nìdí?

Ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ohun rere yẹn, kó o sì dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Àǹfààní wo làwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí máa ṣe ẹ́? Àǹfààní wo ló máa ṣe ìdílé rẹ àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ?

Wo bó ṣe máa rí lára ẹ tó o bá ń gbé ayé nígbà tí

ẸNÌ KANKAN Ò NÍ . . .

GBOGBO ÈÈYÀN MÁA . . .

  • jẹ̀rora mọ́, a ò ní darúgbó mọ́, a ò sì ní kú mọ́.​—Àìsáyà 25:8.

  • rí àwọn èèyàn wọn tó ti kú nígbà tí wọ́n bá jíǹde sí ayé.​—Jòhánù 5:28, 29.

  • gbádùn ìlera tó pé, wọ́n á sì lágbára bíi ti ọ̀dọ́.​—Jóòbù 33:25.

  • ní ìdààmú ọkàn tàbí kó máa rántí ohun aburú tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn.​—Àìsáyà 65:17.

5. Àwọn ohun rere tí Bíbélì sọ máa tù ẹ́ nínú

Ọ̀pọ̀ èèyàn ni gbogbo nǹkan tojú sú, tí wọ́n sì tún ń bínú torí ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn. Àwọn kan tiẹ̀ ń gbìyànjú gan-an kí wọ́n lè sọ ayé dẹ̀rọ̀, àmọ́ wọn ò rí i ṣe. Wo bí ìlérí tó wà nínú Bíbélì pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa ṣe ń ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọwọ́ ní báyìí. Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Nínú fídíò yìí, kí làwọn ohun tó ń kó ìdààmú bá Rafika?

  • Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìwà ìrẹ́jẹ tí Rafika rí kò dópin, báwo ni Bíbélì ṣe ràn án lọ́wọ́?

Àwọn ohun rere tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la máa jẹ́ ká borí ẹ̀dùn ọkàn, ká sì máa láyọ̀ bá a ṣe ń fara da àwọn ìṣòro wa. Ka Òwe 17:22 àti Róòmù 12:12, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Ṣé o rò pé àwọn ohun rere tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la lè mú káyé ẹ dáa sí i ní báyìí? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Àlá tí ò lè ṣẹ làwọn ohun rere tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la.”

  • Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí ìwọ fúnra ẹ ṣèwádìí?

KÓKÓ PÀTÀKÌ

Àwọn ohun rere tí Bíbélì sọ jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Èyí ń múnú wa dùn, ó sì ń jẹ́ ká lè fara da àwọn ìṣòro wa ní báyìí.

Kí lo rí kọ́?

  • Kí nìdí tó fi yẹ ká mọ̀ nípa àwọn ohun rere tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú?

  • Kí ni Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la?

  • Báwo ni ìrètí tó o ní pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ ní báyìí?

Ohun tó yẹ kó o ṣe

ṢÈWÁDÌÍ

Kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa bí ìrètí pé nǹkan ń bọ̀ wá dáa ṣe lè fún ẹ lókun.

“Ǹjẹ́ Ó Ní Nǹkan Tí Ìrètí Lè Ṣe fún Wa?” (Jí!, May 8, 2004)

Kà nípa bí ìrètí pé nǹkan ń bọ̀ wá dáa ṣe ṣèrànwọ́ fáwọn tó ń ṣàìsàn ọlọ́jọ́ pípẹ́.

“Ǹjẹ́ Bíbélì Lè Ràn Mí Lọ́wọ́ Tí Mo Bá Ń Ṣàìsàn Ọlọ́jọ́ Pípẹ́?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)

Bó o ṣe ń wo fídíò yìí, fojú inú wo ara rẹ àti ìdílé rẹ pé ẹ̀ ń gbádùn ayé nínú Párádísè tí Bíbélì sọ.

Fojú Inú Wò Ó 3:37

Kà nípa bí ìgbésí ayé ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn kan ṣe yí pa dà nígbà tó mọ àwọn ohun rere tí Bíbélì sọ pé ó má ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la.

“Kò Ṣe Mí Mọ́ Bíi Pé Mo Gbọ́dọ̀ Yí Ayé Yìí Pa Dà” (Ilé Ìṣọ́, July 1, 2013)