Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Ni Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Ń Kọ́ Àwọn Èèyàn?

Kí Ni Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Ń Kọ́ Àwọn Èèyàn?

 Báwo la ṣe máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

 Ẹnì kan máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti lóye àwọn nǹkan tó wà nínú Bíbélì ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé. Ẹni náà máa lo ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! láti kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ kó o lè lóye àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì, á sì jẹ́ kó o mọ bí ohun tó o kọ́ náà ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. Wo fídíò yìí kó o lè mọ̀ sí i.

 Ṣé màá sanwó tí wọ́n bá fẹ́ kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́?

 Rárá o. Àṣẹ tí Jésù pa fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ lé. Jésù sọ pé: “Ọ̀fẹ́ ni ẹ gbà á, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fúnni.” (Mátíù 10:8) Bákan náà, a ò díye lé àwọn ìwé tá a fi máa kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn Bíbélì àti ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!

 Báwo ni ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe máa pẹ́ tó?

 Ẹ̀kọ́ ọgọ́ta (60) ló wà nínú ìwé náà. Ìwọ lo máa pinnu iye ìgbà tó o fẹ́ máa kẹ́kọ̀ọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ sábà máa ń fẹ́ ka ẹ̀kọ́ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.

 Báwo ni mo ṣe máa bẹ̀rẹ̀?

  1.  1. Kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù tó wà lórí ìkànnì wa. Ìsọfúnni tó o bá fi sínú fọ́ọ̀mù náà á jẹ́ kó rọrùn fún ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti kàn sí ẹ. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé a ò ní lo ìsọfúnni náà fún ohunkóhun míì.

  2.  2. Ẹnì kan máa kàn sí ẹ. Ẹni náà máa ṣàlàyé bí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe máa rí, á sì dáhùn ìbéèrè èyíkéyìí tó o bá ní.

  3.  3. Ìwọ àti onítọ̀hún á jọ sọ̀rọ̀ nípa bá á ṣe máa kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́. Ẹ lè ṣètò láti wà níbì kan náà nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí, ẹ sì lè ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lórí kámẹ́rà tàbí kẹ́ ẹ máa fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ síra yín. Ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí kì í sábà ju wákàtí kan lọ, àmọ́ ìwọ lo máa pinnu bóyá o fẹ́ kó jù bẹ́ẹ̀ lọ tàbí kó má tó bẹ́ẹ̀

 Ṣé mo lè kọ́kọ́ fi dánra wò?

 Bẹ́ẹ̀ ni. Tó o bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù lórí ìkànnì wa. Tí ẹnì kan bá kàn sí ẹ, sọ fún un pé o kàn fẹ́ kó kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ fúngbà díẹ̀ kó o lè mọ̀ bóyá wàá máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ. Ẹni náà máa lo ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! èyí tó ní ẹ̀kọ́ mẹ́ta. Ìyẹn á jẹ́ kó o mọ bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, á sì jẹ́ kó o pinnu bóyá wàá máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ.

 Tí mo bá gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ṣé ó pọn dandan kí n di Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

 Rárá o. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́ràn ká máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ a kì í fi dandan lé e pé káwọn èèyàn di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kàkà bẹ́ẹ̀, tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ la máa ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ ohun tí Bíbélì sọ, a sì gbà pé kálukú ló máa pinnu ohun tó máa gbà gbọ́.—1 Pétérù 3:15.

 Ṣé mo lè lo Bíbélì tèmi?

 Bẹ́ẹ̀ ni, ìtumọ̀ Bíbélì èyíkéyìí tó bá wù ẹ́ lo lè lò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a gbádùn ká máa lo Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, torí pé ó péye, ó sì rọrùn láti lóye, síbẹ̀ a mọ̀ pé àwọn èèyàn máa ń fẹ́ràn láti máa lo Bíbélì tó ti mọ́ wọn lára.

 Ṣé mo lè pe àwọn míì wá sí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà?

 Bẹ́ẹ̀ ni. O lè pe gbogbo ìdílé ẹ tàbí kó o pe àwọn ọ̀rẹ́ ẹ.

 Tó bá jẹ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà kan rí, ṣé mo tún lè bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ pa dà?

 Bẹ́ẹ̀ ni. Kódà, ó ṣeé ṣe kó o gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí ju ti tẹ́lẹ̀ lọ torí pé ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan tuntun tó bá ipò àwọn èèyàn mu la fi kún ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí, irú bíi fídíò. Wàá sì gbádùn ẹ̀, torí á jẹ́ kíwọ àti ẹni tó ń kọ́ ẹ jọ sọ̀rọ̀ dáadáa dípò kó kàn jẹ́ ìbéèrè àti ìdáhùn.

 Ṣé mo lè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láìjẹ́ pé ẹnì kan wá sọ́dọ̀ mi?

 Bẹ́ẹ̀ ni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn túbọ̀ máa ń lóye àwọn ẹ̀kọ́ yìí tó bá jẹ́ pé ẹnì kan ló ń kọ́ wọn, síbẹ̀ àwọn míì máa ń kọ́kọ́ fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ láyè ara wọn. Ohun Tá A Fi Ń Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó wà lórí ìkànnì wa ní onírúurú nǹkan tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ lóye àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì. Díẹ̀ lára wọn rèé:

  •   Fídíò Tó dá Lórí Bíbélì. Àwọn fídíò kéékèèké yìí ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì nínú Bíbélì.

  •   Ohun Tí Bíbélì Sọ. Àwọn àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ ká mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa ọ̀pọ̀ nǹkan táwọn èèyàn máa ń béèrè.

  •   Àlàyé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì. Wàá rí ohun tí àwọn ẹsẹ Bíbélì tọ́pọ̀ èèyàn mọ̀ dáadáa túmọ̀ sí.

  •   Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì (Lédè Gẹ̀ẹ́sì). Apá yìí ní àwọn ẹ̀kọ́ tó dáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì táwọn èèyàn ní, bíi: Ta ni Ọlọ́run? Kí nìdí tí nǹkan burúkú fi ń ṣẹlẹ̀ tá a sì ń jìyà? Ṣé Ọlọ́run máa fòpin sí ìyà tó ń jẹ aráyé?