Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 01

Ṣé Bíbélì Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́?

Ṣé Bíbélì Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́?

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo wa la máa ń béèrè ìbéèrè pàtàkì tó kan ìgbésí ayé wa, lára ẹ̀ ni ìdí tá a fi ń jìyà, ìdí tá a fi ń kú àti bí ọjọ́ ọ̀la wa ṣe máa rí. Àwọn nǹkan míì tá a tún máa ń ronú nípa ẹ̀ lójoojúmọ́ ni àtijẹ-àtimú àti bí ìdílé wa ṣe lè láyọ̀. Ọ̀pọ̀ èèyàn ti rí i pé yàtọ̀ sí pé Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì tó kan ìgbésí ayé wọn, ó tún fún wọn láwọn ìmọ̀ràn tó wúlò nípa bí wọ́n á ṣe máa gbé ìgbé ayé wọn lójoojúmọ́. Ṣé ìwọ náà gbà pé Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́?

1. Àwọn ìbéèrè wo ni Bíbélì dáhùn?

Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì yìí: Báwo ni ìwàláàyè ṣe bẹ̀rẹ̀? Kí nìdí tá a fi wà láyé? Kí nìdí táwọn èèyàn rere fi ń jìyà? Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú? Tó bá jẹ́ pé gbogbo èèyàn ló ń fẹ́ àlàáfíà, kí nìdí tí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè fi ń bára wọn jagun? Báwo ni ayé yìí ṣe máa rí lọ́jọ́ iwájú? Bíbélì rọ̀ wá pé ká wá ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí, àìmọye èèyàn ló sì ti rí i pé Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè yìí lọ́nà tó tẹ́ wọn lọ́rùn.

2. Báwo ni Bíbélì ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè gbádùn ìgbé ayé wa ojoojúmọ́?

Bíbélì fún wa láwọn ìmọ̀ràn tó wúlò gan-an. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ bí àwọn ìdílé ṣe lè ní ayọ̀ tòótọ́. Ó sọ ohun tá a lè ṣe tí ìdààmú bá gba ọkàn wa àti bá a ṣe lè gbádùn iṣẹ́ wa. Bá a ṣe ń jíròrò ohun tó wà nínú ìwé yìí, o máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn nǹkan yìí àtàwọn nǹkan míì. Ìwọ náà á wá gbà pé “gbogbo Ìwé Mímọ́ [gbogbo ohun tó wà nínú Bíbélì] . . . wúlò.”​—2 Tímótì 3:16.

A ò fi ìwé yìí rọ́pò Bíbélì o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló máa jẹ́ kí ìwọ fúnra ẹ lè fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Torí náà, a rọ̀ ẹ́ pé kó o ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tó wà ní ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan, kó o sì fi wéra pẹ̀lú ohun tó ò ń kọ́.

KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

Wo bí Bíbélì ṣe ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, kó o wo bó o ṣe lè gbádùn kíka Bíbélì àti ìdí tó fi yẹ kó o gba ìrànwọ́ kí ohun tó ò ń kà lè yé ẹ.

3. Bíbélì máa ń tọ́ni sọ́nà

Bíbélì dà bí iná tó mọ́lẹ̀ gan-an. Ó jẹ́ ká mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la, ó sì ń jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè ṣe ìpinnu tó dára.

Ka Sáàmù 119:105, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Èrò wo ni ẹni tó kọ sáàmù yìí ní nípa Bíbélì?

  • Kí lèrò tìẹ nípa Bíbélì?

4. Bíbélì lè dáhùn àwọn ìbéèrè wa

Obìnrin kan rí i pé Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè tó ti wà lọ́kàn ẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Nínú fídíò yẹn, kí ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan pàtàkì tí obìnrin yẹn fẹ́ mọ̀?

  • Báwo ni ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ń kọ́ ṣe ràn án lọ́wọ́?

Bíbélì rọ̀ wá pé ká máa béèrè ìbéèrè. Ka Mátíù 7:7, lẹ́yìn náà, kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Àwọn ìbéèrè wo lo ní tó o rò pé Bíbélì lè dáhùn?

5. Ìwọ náà lè gbádùn kíka Bíbélì

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń gbádùn kíka Bíbélì, ó sì ń ṣe wọ́n láǹfààní. Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Nínú fídíò yẹn, kí làwọn ọ̀dọ́ sọ nípa ìwé kíkà?

  • Kí nìdí táwọn ọ̀dọ́ yẹn fi fẹ́ràn kíka Bíbélì ju àwọn ìwé míì lọ?

Bíbélì máa ń tọ́ wa sọ́nà, ó máa ń tù wá nínú, ó sì máa ń fún wa nírètí. Ka Róòmù 15:4, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Báwo ni àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú àti ìrètí tó wà nínú Bíbélì ṣe rí lára rẹ?

6. Àwọn míì lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè lóye Bíbélì

Ọ̀pọ̀ ti rí i pé yàtọ̀ sí kí wọ́n dá ka Bíbélì, ó tún máa ń ṣàǹfààní gan-an tí wọ́n bá jíròrò ẹ̀ pẹ̀lú àwọn míì. Ka Ìṣe 8:26-31, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Kí la lè ṣe tá a bá fẹ́ lóye ohun tó wà nínú Bíbélì?​—Wo ẹsẹ 30 àti 31.

Ọkùnrin ará Etiópíà yẹn nílò ìrànlọ́wọ́ kí Ìwé Mímọ́ lè yé e. Ọ̀pọ̀ ti rí i pé ó máa ń ṣàǹfààní gan-an tí wọ́n bá jíròrò Bíbélì pẹ̀lú àwọn míì

ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Èèyàn kàn ń fàkókò ẹ̀ ṣòfò ni tó bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”

  • Kí lèrò tìẹ? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

KÓKÓ PÀTÀKÌ

Bíbélì fún wa láwọn ìmọ̀ràn tó wúlò nípa bá a ṣe máa gbé ìgbé ayé wa lójoojúmọ́, ó dáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì, ó máa ń tù wá nínú, ó sì ń fún wa nírètí.

Kí lo rí kọ́?

  • Àwọn ìmọ̀ràn tó wúlò wo ni Bíbélì fún wa?

  • Àwọn ìbéèrè pàtàkì wo ni Bíbélì dáhùn?

  • Kí ló wù ẹ́ láti mọ̀ nínú Bíbélì?

Ohun tó yẹ kó o ṣe

ṢÈWÁDÌÍ

Wo bí ìmọ̀ràn Bíbélì ṣe wúlò tó lóde òní.

“Ìlànà Bíbélì Wúlò Títí Láé” (Ilé Ìṣọ́ No. 1 2018)

Wo bí Bíbélì ṣe ṣèrànwọ́ fún ọkùnrin kan tó jẹ́ pé àtikékeré ló ti gbà pé òun ò já mọ́ nǹkan kan, tó sì máa ń bínú.

Mo Bẹ̀rẹ̀ Ìgbé Ayé Ọ̀tun 2:53

Wo àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì tó wúlò fún ìdílé.

“Ohun Méjìlá Tó Ń Mú Kí Ìdílé Láyọ̀” (Jí! No. 2 2018)

Wo ohun tí Bíbélì sọ nípa ẹni tó ń darí ayé. Ohun tó sọ yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn rò.

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?​—Èyí Tó Gùn 3:14