Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ

Jeremáyà 29:11​—⁠​“Mo Mọ Èrò Tí Mò Ń Gbà Si Yín”

Jeremáyà 29:11​—⁠​“Mo Mọ Èrò Tí Mò Ń Gbà Si Yín”

 “‘Mo mọ èrò tí mò ń rò nípa yín dáadáa,’ ni Jèhófà a wí, ‘èrò àlàáfíà, kì í ṣe ti àjálù, láti fún yín ní ọjọ́ ọ̀la kan àti ìrètí kan.’”​—Jeremáyà 29:11, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

 “‘Mo mọ erò tí mò ń gbà si yín, èrò alaafia ni, kì í ṣe èrò ibi. N óo mú kí ọjọ́ ọ̀la dára fun yín, n óo sì fún yín ní ìrètí.’”—Jeremáyà 29:11, Bíbélì Ìròyìn Ayọ̀.

Ìtumọ̀ Jeremáyà 29:11

 Jèhófà Ọlọ́run ṣèlérí fún àwọn tó ń sìn ín pé òun fẹ́ kí wọ́n gbádùn àlàáfíà lọ́jọ́ iwájú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àtijọ́ ni Ọlọ́run sọ ọ̀rọ̀ yìí fún, ohun tó ṣì ní lọ́kàn nìyẹn títí dòní. Òun ni “Ọlọ́run tó ń fúnni ní ìrètí.” (Róòmù 15:13) Ohun tó sì mú kó ṣe irú àwọn ìlérí bẹ́ẹ̀ nínú Bíbélì ni pé, ó fẹ́ “kí a lè ní ìrètí” pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.​—Róòmù 15:4.

Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Jeremáyà 29:11

 Ọ̀rọ̀ yìí wà nínú lẹ́tà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí gbà nígbà tí wọ́n ṣì wà nígbèkùn ní Bábílónì. b (Jeremáyà 29:1) Ọlọ́run sọ fún àwọn tó wà nígbèkùn pé wọ́n máa pẹ́ níbẹ̀, torí náà ó ní kí wọ́n kọ́ ilé, kí wọ́n gbin ọgbà, kí wọ́n fẹ́yàwó kí wọ́n sì bímọ. (Jeremáyà 29:4-9) Àmọ́, Ọlọ́run tún sọ fún wọn pé: “Tó bá ti pé àádọ́rin (70) ọdún tí ẹ ti wà ní Bábílónì, màá yí ojú mi sí yín, màá sì mú ìlérí mi ṣẹ láti mú yín pa dà wá sí [Jerúsálẹ́mù].” (Jeremáyà 29:10) Ọlọ́run tipa bẹ́ẹ̀ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òun ò ní gbàgbé wọn ó sì dájú pé wọ́n máa pa dà sílé ní Jerúsálẹ́mù.—Jeremáyà 31:16, 17.

 Ọlọ́run mú ìlérí tó ṣe fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ. Bó ṣe sọ tẹ́lẹ̀, Kírúsì Ọba Páṣíà ṣẹ́gun Bábílónì. (Àìsáyà 45:​1, 2; Jeremáyà 51:​30-32) Lẹ́yìn náà, Kírúsì ní kí àwọn Júù pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn. Lẹ́yìn àádọ́rin (70) ọdún tí wọ́n ti wà nígbèkùn, wọ́n pa dà sí Jerúsálẹ́mù.​—2 Kíróníkà 36:20-23; Ẹ́sírà 3:1.

 Bí ìlérí tí Ọlọ́run ṣe nínú Jeremáyà 29:11 ṣe ní ìmúṣẹ yìí fi àwọn tó ní ìrètí nínú ìlérí Ọlọ́run lónìí lọ́kàn balẹ̀. Lára àwọn ìlérí náà ni bí Ìjọba Ọlọ́run á ṣe mú kí àlàáfíà wà kárí ayé lábẹ́ ìṣàkóso Kristi Jésù.​—Sáàmù 37:10, 11, 29; Àìsáyà 55:11; Mátíù 6:⁠10.

Èrò Tí Kò Tọ́ Nípa Jeremáyà 29:11

 Èrò tí kò tọ́: Ọlọ́run ti wéwèé ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ẹnì kọ̀ọ̀kan.

 Òtítọ́: Ọlọ́run máa ń jẹ́ káwọn èèyàn fúnra wọn yan bí wọ́n ṣe máa gbé ìgbé ayé wọn. Ṣe ló darí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó wà nínú Jeremáyà 29:11 sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà ní Bábílónì bí àwùjọ èèyàn kan, ohun tó sì ní lọ́kàn fún àwùjọ èèyàn yẹn ni pé wọ́n máa ní àlàáfíà lọ́jọ́ iwájú. (Jeremáyà 29:⁠4) Àmọ́, Ọlọ́run gbà kí oníkálùkù fúnra rẹ̀ yàn bóyá òun máa jàǹfààní látinú ìlérí tó ṣe tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. (Diutarónómì 30:​19, 20; Jeremáyà 29:32) Àwọn tó yàn láti wá Ọlọ́run ṣe bẹ́ẹ̀ nípa gbígbàdúrà sí i látọkàn wá.​—Jeremáyà 29:12, 13.

 Èrò tí kò tọ́: Ọlọ́run máa mú kí àwọn tó ń sìn ín ní ọrọ̀.

 Òtítọ́: Ọ̀rọ̀ náà “áásìkí” tí àwọn Bíbélì kan lò nínú Jeremáyà 29:11 wá látinú ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí “àlàáfíà, ìlera àti kí ara yá gágá.” Nínú àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣáájú ẹsẹ yìí, kì í ṣe ọrọ̀ ni Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n kó lọ sí ìgbèkùn bí kò ṣe àlàáfíà àti ìlera ara. Gbogbo wọn lápapọ̀ ò ní kú àkúrun, wọ́n sì máa pà dà sí Jerúsálẹ́mù lọ́jọ́ kan.​—⁠Jeremáyà 29:​4-10.

Ka Jeremáyà orí 29 pẹ̀lú àwọn àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé tí wọ́n fi ṣàlàyé ọ̀rọ̀ àti àwọn atọ́ka etí ìwé.

a Jèhófà ni orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́ gangan.​—Sáàmù 83:18.

b Ìwé The Expositor’s Bible Commentary sọ nípa Jeremáyà 29:11 pé: “Ìlérí tí Yahweh [Jèhófà] ṣe yìí jẹ́ ọ̀kan lára ìlérí àgbàyanu tó lágbára jù lọ nínú Bíbélì tó jẹ́ ká rí bó ṣe fi ojú àánú hàn sí àwọn tó wà nígbèkùn yìí, àti níkẹyìn, tó jẹ́ kí wọ́n rí ìdí tí wọ́n fi ní láti máa fojú sọ́nà torí pé nǹkan máa tó ṣẹnuure.”​—Ìdìpọ̀ 7, ojú ìwé 360