Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ

Róòmù 15:13​—“Ǹjẹ́ Kí Ọlọ́run Ìrètí Kí Ó Fi Gbogbo Ayọ̀ òun Àlàáfíà Kún Yín”

Róòmù 15:13​—“Ǹjẹ́ Kí Ọlọ́run Ìrètí Kí Ó Fi Gbogbo Ayọ̀ òun Àlàáfíà Kún Yín”

 “Kí Ọlọ́run tó ń fúnni ní ìrètí fi gbogbo ayọ̀ àti àlàáfíà kún inú yín nítorí ẹ̀ ń gbẹ́kẹ̀ lé e, kí ìrètí yín lè túbọ̀ dájú nípasẹ̀ agbára ẹ̀mí mímọ́.”​—Róòmù 15:13, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

 “Ǹjẹ́ kí Ọlọ́run ìrètí kí ó fi gbogbo ayọ̀ òun àlàáfíà kún yín bí ẹ̀yin ti gbà á gbọ́, kí ẹ̀yin kí ó lè pọ̀ ní ìrètí nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́.”​—Róòmù 15:13, Bíbélì Mímọ́.

Ìtumọ̀ Róòmù 15:13

 Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí fi hàn pé ó wù ú kí Ọlọ́run fún àwọn onígbàgbọ́ bíi tiẹ̀ ní “ayọ̀ àti àlàáfíà.” Ìrètí tí Ọlọ́run ń fúnni àti ẹ̀mí mímọ́ ló sì ń mú kéèyàn láwọn ànímọ́ yìí.

 Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú. Róòmù 15:4 sọ pé: “Gbogbo ohun tí a kọ ní ìṣáájú [nínú Bíbélì] ni a kọ fún wa láti gba ẹ̀kọ́, kí a lè ní ìrètí nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú látinú Ìwé Mímọ́.” Bíbélì sọ bí Ọlọ́run ṣe máa fòpin sí àwọn ìṣòro tó ń mú ayé súni tá à ń dojú kọ, bí ipò òṣì, ìwà ìkà, àìsàn àti ikú. (Ìfihàn 21:4) Jésù Kristi ni Ọlọ́run máa lò láti mú àwọn ìlérí yìí ṣẹ, ìdí nìyẹn tí ọkàn wa fi balẹ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.​—Róòmù 15:12.

 Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run nìkan ni ìrétí tó ń fúnni fi máa “pọ̀” tàbí lédè míì á “túbọ̀” dá wa lójú. Tá a bá ṣe ń kẹ́kọ́ọ̀ nípa Ọlọ́run bẹ́ẹ̀ lá túbọ̀ máa dá wa lójú pé ẹni tó ṣeé sún mọ́ ni. (Àìsáyà 46:10; Títù 1:2) Ìrétí tí Ọlọ́run ń fúnni máa ń jẹ́ kéèyàn ní ayọ̀ àti àlàáfíà, kódà tó bá ń kojú onírúurú ìṣòro tó le.​—Róòmù 12:12.

 A lè ní àlàáfíà, ayọ̀, àti ìrétí nípasẹ̀ “ẹ̀mí mímọ́” tó jẹ́ agbára ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run. a Ọlọ́run ń lo ẹ̀mí mímọ́ láti mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ èyí sì ń jẹ́ ká ní ìrétí. Ẹ̀mí mímọ́ tún lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè láwọn ànímọ́ tó dáa, bí ayọ̀ àti àlàáfíà.​—Gálátíà 5:22.

Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àti Èyí Tó Tẹ̀ Lé Róòmù 15:13

 Àwọn Kristẹni tó ń gbé ní ìlú Róòmù ni wọ́n dìídì kọ lẹ́tà àwọn ara Róòmù sí. Díẹ̀ nínú àwọn Kristẹni yìí jẹ́ Júù nígbà tí àwọn kan kì í ṣe Júù. Pọ́ọ̀lù rọ gbogbo wọ́n láti ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè wà níṣọ̀kan kí wọ́n sì ní èrò inú kan náà láìka ti ìyàtọ̀ tó wà nínú àṣà àti ìlú ìbílẹ̀ wọn sí.​—Róòmù 15:6.

 Pọ́ọ̀lù rán àwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù létí pé ó ti pẹ́ tí Ọlọ́run ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ìgbà kan ń bọ̀ tí àwọn èèyàn láti gbogbo orílẹ̀-èdè á máa jọ́sìn òun níṣọ̀kan. Ìgbà mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Pọ́ọ̀lù fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù b láti ti ọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn. (Róòmù 15:9-12) Kókó inú ọ̀rọ̀ ẹ̀ ni pé: Àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè lè jàǹfààní látinú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristi bíi ti àwọn Júù. Nípa bẹ́ẹ̀, ìrètí kan náà ni àwọn Júù àti àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè ní. Torí náà, gbogbo àwọn tó wà ní ìjọ Róòmù gbọ́dọ̀ ‘tẹ́wọ́ gba ara wọn’ láìka irú ẹni tí wọ́n jẹ́ sí, ìyẹn ni pé kí wọ́n jẹ́ onínúure, kí wọ́n sì máa gba àwọn míì tọwọ́tẹsẹ̀.​—Róòmù 15:7.

a Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i ka àpilẹ̀kọ náà “Kí Ni Ẹ̀mí Mímọ́?

b Wọ́n tún máa ń pé Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù ní Májẹ̀mú Láéláé.