Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé A Ṣì Lè Gbára Lé Àwọn Ìlànà Bíbélì Lórí Ohun Tó Tọ́ àti Ohun Tí Kò Tọ́?

Ṣé A Ṣì Lè Gbára Lé Àwọn Ìlànà Bíbélì Lórí Ohun Tó Tọ́ àti Ohun Tí Kò Tọ́?

 Ọ̀pọ̀ èèyàn títí kan àwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni ló rò pé ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbálòpọ̀ àti ìgbéyàwó kò bóde mu mọ́. Ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ló ti yí ohun tí wọ́n fi ń kọ́ni pa dà lórí ọ̀rọ̀ ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́ kí ohun tí wọ́n fi ń kọ́ni lè bá èrò táwọn èèyàn ní mu. Ṣé ó ṣì yẹ ká máa gbára lé àwọn ìlànà Bíbélì lórí ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́? Bẹ́ẹ̀ ni. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀.

Àwa èèyàn nílò ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run ká lè mọ ohun tó tọ́

 Ọlọ́run dá wa pé ká máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà òun. Bíbélì sọ pé: “Kò sí ní ìkáwọ́ èèyàn tó ń rìn láti darí ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jeremáyà 10:23) Lóòótọ́, Jèhófà a Ọlọ́run dá wa lọ́nà tí a fi lè máa ṣe ìpinnu fúnra wa, àmọ́ kò fún wa ní agbára láti pinnu ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́ fúnra wa. Ìdí sì ni pé, ó fẹ́ ká gbẹ́kẹ̀ lé òun.—Òwe 3:5.

 Inú Bíbélì la ti máa rí ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run lórí ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. Ẹ jẹ́ ká wo ìdí méjì tó fi yẹ ká gbára lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run.

  •   Ọlọ́run ló dá wa. (Sáàmù 100:3) Jèhófà Ọlọ́run ni Ẹlẹ́dàá wa, torí náà ó mọ irú ẹni tá a jẹ́ gan-an, ohun tá a lè ṣe láti ní ìlera tó dáa, àtohun tó máa jẹ́ ká láyọ̀. Ó tún mọ ohun tó máa gbẹ̀yìn ẹ̀ tá a bá kọ̀ láti tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà òun. (Gálátíà 6:7) Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà fẹ́ ká gbádùn ayé wa. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pe Ọlọ́run ní “Ẹni tó ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tó ń jẹ́ kí o mọ ọ̀nà tó yẹ kí o máa rìn.”—Àìsáyà 48:17.

  •   Ọkàn wa lè tàn wá. Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé àwọn lè pinnu ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́ fúnra àwọn, káwọn ṣáà ti ṣe ohun tí ọkàn àwọn bá sọ, ìyẹn ohun tó bá wu àwọn tàbí ohun tí ọkàn àwọn fà sí. Àmọ́, Bíbélì sọ pé “ọkàn ń tanni jẹ ju ohunkóhun lọ, kò sóhun tí kò lè ṣe.” (Jeremáyà 17:9) Tí a ò bá jẹ́ kí àwọn ìlànà Ọlọ́run tọ́ wa sọ́nà, ọkàn wa lè mú ká ṣe ohun tá a máa kábàámọ̀ tó bá yá.—Òwe 28:26; Oníwàásù 10:2.

Ṣé ó yẹ káwọn olórí ẹ̀sìn máa fọwọ́ rọ́ àwọn ìlànà Bíbélì tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan?

 Rárá o! Bíbélì jẹ́ ká mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run àti bó ṣe fẹ́ ká máa hùwà. (1 Kọ́ríńtì 6:9-11; Gálátíà 5:19-23) Ọlọ́run fẹ́ káwọn èèyàn mọ òtítọ́ nípa òun. (1 Tímótì 2:3, 4) Torí náà, ohun tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló yẹ káwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run máa fi kọ́ni.—Títù 1:7-9.

 Ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n ti ń “sọ ohun tí wọ́n fẹ́ gbọ́” làwọn tí kò fẹ́ tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì máa ń lọ. (2 Tímótì 4:3) Síbẹ̀, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wa ní ìkìlọ̀ tó ń múni ronú jinlẹ̀ yìí, ó ní: “Àwọn tó ń sọ pé ohun tó dára burú àti pé ohun tó burú dára gbé.” (Àìsáyà 5:20) Ó ṣe kedere pé, Ọlọ́run máa ṣèdájọ́ àwọn aṣáájú ẹ̀sìn torí wọn ò kọ́ àwọn èèyàn ní òtítọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

Ṣé ohun tí Bíbélì kọ́ wa ni pé ká má ṣe gba àwọn èèyàn láyè láti ṣe ohun tí wọ́n fẹ́?

 Rárá o. Àwọn tó bá fẹ́ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run máa ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù Kristi, wọ́n sì máa ń fi ohun tó fi kọ́ni ṣèwà hù. Ó kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n má dá àwọn míì lẹ́jọ́, kàkà bẹ́ẹ̀ kí wọ́n máa fìfẹ́ hàn sí wọn, kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn.—Mátíù 5:43, 44; 7:1.

 Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé kí wọ́n máa tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run nínú gbogbo ohun tí wọ́n bá ń ṣe. Àmọ́, wọ́n tún gbọ́dọ̀ mọ̀ pé àwọn míì náà lè yàn láti ṣe ohun tó yàtọ̀ sí ohun tí Jésù fi kọ́ni. (Mátíù 10:14) Jésù ò kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa fi òṣèlú tàbí àwọn ọ̀nà míì fúngun mọ́ àwọn èèyàn láti ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́.—Jòhánù 17:14, 16; 18:36.

Àwọn àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì?

 Gbogbo àwọn tó bá ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì máa rí ìbùkún gbà ní báyìí àti lọ́jọ́ iwájú. (Sáàmù 19:8, 11) Lára wọn ni:

a Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.—Sáàmù 83:18.