Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ṣé Àwọn Ẹranko Ń Lọ sí Ọ̀run?

Ṣé Àwọn Ẹranko Ń Lọ sí Ọ̀run?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Bíbélì kọ́ni pé nínú gbogbo ẹ̀dá tó wà láyé, àwọn èèyàn díẹ̀ ló máa lọ sí ọ̀run. (Ìfihàn 14:1, 3) Wọ́n ń lọ láti bá Jésù ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba àti àlùfáà. (Lúùkù 22:28-30; Ìfihàn 5:9, 10) Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn ló máa jí dìde sí orí ilẹ̀ ayé nínú Párádísè.—Sáàmù 37:11, 29.

 Kò síbì kankan tí Bíbélì ti sọ̀rọ̀ nípa ọ̀run èyíkéyìí tó wà fún ẹran ọ̀sìn tàbí fún ajá, ó sì nídìí tó fi rí bẹ́ẹ̀. Àwọn ẹranko ò lè ṣe àwọn ohun tó máa jẹ́ kí wọ́n tóótun láti gba “ìpè ti ọ̀run.” (Hébérù 3:1) Lára àwọn ohun náà ni níní ìmọ̀, ìgbàgbọ́ àti pípa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́. (Mátíù 19:17; Jòhánù 3:16; 17:3) Àwọn èèyàn nìkan ni Ọlọ́run fún nírètí láti wà láàyè títí láé.—Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17; 3:22, 23.

 Kí ẹ̀dá ayé tó lè lọ sí ọ̀run, ó gbọ́dọ̀ jíǹde. (1 Kọ́ríńtì 15:42) Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn àjíǹde mélòó kan. (1 Àwọn Ọba 17:17-24; 2 Àwọn Ọba 4:32-37; 13:20, 21; Lúùkù 7:11-15; 8:41, 42, 49-56; Jòhánù 11:38-44; Ìṣe 9:36-42; 20:7-12) Èèyàn ló sì jí dìde nínú gbogbo wọn, kì í ṣe ẹranko.

 Ṣé ẹranko ní ọkàn?

 Rárá. Bíbélì sọ pé ẹranko àti èèyàn jẹ́ ọkàn. (Nọ́ńbà 31:28) Nígbà tí Ọlọ́run dá ọkùnrin àkọ́kọ́, Ádámù, kò fún un ní ọkàn torí pé, ẹ̀yìn náà ló “di alààyè ọkàn.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:7, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé) Torí náà ohun méjì ló wà nínú ọkàn, àwọn ni: “erùpẹ̀ ilẹ̀” àti “èémí ìyè.”

 Ṣé ọkàn máa ń kú?

 Bẹ́ẹ̀ ni, Bíbélì kọ́ni pé ọkàn máa ń kú. (Léfítíkù 21:11, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé; Ìsíkíẹ́lì 18:20) Tí ikú bá dé, inú ilẹ̀ ni ẹranko àti èèyàn máa ń pa dà sí. (Oníwàásù 3:19, 20) Tàbí ká kúkú sọ pé wọn ò sí mọ́. a

 Ṣé ẹranko máa ń dẹ́ṣẹ̀?

 Rárá. Ẹ̀ṣẹ̀ dídá túmọ̀ sí pé ká ronú nípa ohun kan, ká mọ ohun kan lára tàbí ká ṣe ohun kan tó lòdì sí ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Kí ẹ̀dá kan tó lè dẹ́ṣẹ̀, ó ní láti ronú, kó sì ṣèpinnu, àmọ́ àwọn ẹranko ò lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ọgbọ́n àdámọ́ni tí wọ́n ní ni wọ́n fi ń ṣe nǹkan láàárín ìgbà kúkúrú tí wọ́n fi wà láàyè. (2 Pétérù 2:12) Lópin ọjọ́ ayé wọn, wọ́n á kú bí wọn ò tiẹ̀ dẹ́ṣẹ̀.

 Ṣé ó dáa kéèyàn ṣèkà fún ẹranko?

 Rárá. Ọlọ́run fún àwọn èèyàn láṣẹ lórí àwọn ẹranko àmọ́ kò fún wọn láṣẹ láti ṣe wọ́n ṣúkaṣùka. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; Sáàmù 8:6-8) Ire ẹranko kọ̀ọ̀kan jẹ Ọlọ́run lógún, títí kan àwọn ẹyẹ kékeré. (Jónà 4:11; Mátíù 10:29) Ọlọ́run pàṣẹ fáwọn tó ń sìn ín pé kí wọ́n máa gba ti àwọn ẹranko rò.—Ẹ́kísódù 23:12; Diutarónómì 25:4; Òwe 12:10.

a Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, wo orí 6 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?