Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwọn Wo Ló Ń Lọ sí Ọ̀run?

Àwọn Wo Ló Ń Lọ sí Ọ̀run?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Ọlọ́run yan ìwọ̀nba àwọn Kristẹni kan tó jẹ́ olóòótọ́ tó máa jíǹde sí ọ̀run tí wọ́n bá kú. (1 Pétérù 1:3, 4) Tí Ọlọ́run bá ti yàn wọ́n, wọ́n gbọ́dọ̀ máa rí i pé ìgbàgbọ́ wọn ò yẹ̀, kí wọ́n sì máa hùwà mímọ́, kí èrè tí wọ́n fẹ́ gbà lọ́run má bàa bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́.​—Éfésù 5:5; Fílípì 3:12-​14.

Kí làwọn tó ń lọ sí ọ̀run máa lọ ṣe níbẹ̀?

 Wọ́n máa bá Jésù jọba, wọ́n á sì tún jẹ́ àlùfáà pẹ̀lú rẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún [1,000] ọdún. (Ìṣípayá 5:9, 10; 20:6) Àwọn ló máa jẹ́ “ọ̀run tuntun” tàbí ìjọba tó máa wà lọ́run, èyí táá máa ṣàkóso “ilẹ̀ ayé tuntun” tàbí aráyé. Àwọn tó máa jọba lọ́run yìí máa sọ ayé dọ̀tun kí gbogbo nǹkan lè rí bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó rí látìbẹ̀rẹ̀.​—Aísáyà 65:17; 2 Pétérù 3:13.

Àwọn mélòó ni Ọlọ́run máa jí dìde sí ọ̀run?

 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] làwọn èèyàn tí Ọlọ́run máa jí dìde sí ọ̀run. (Ìṣípayá 7:4) Bó ṣe wà nínú Ìṣípayá 14:1-3, àpọ́sítélì Jòhánù rí ìran “Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà [tó] dúró lórí Òkè Ńlá Síónì, àti pẹ̀lú rẹ̀, ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì.” Nínú ìran yìí, Jésù ni “Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà” ṣàpẹẹrẹ. (Jòhánù 1:29; 1 Pétérù 1:19) “Òkè Ńlá Síónì” ṣàpẹẹrẹ ipò gíga tí Jésù àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tó máa bá a jọba lọ́run wà.​—Sáàmù 2:6; Hébérù 12:22.

 Bíbélì pe “àwọn tí a pè, tí a yàn” láti bá Jésù jọba ní “agbo kékeré.” (Ìṣípayá 17:14; Lúùkù 12:32) Ìyẹn fi hàn pé wọ́n máa kéré níye gan-an sí iye gbogbo àgùntàn tí Jésù ní.​—Jòhánù 10:16.

Èrò tí kò tọ́ táwọn èèyàn ní nípa àwọn tó ń lọ sọ́run

 Èrò tí kò tọ́: Gbogbo èèyàn rere ló ń lọ sọ́run.

 Òótọ́: Ọlọ́run ṣèlérí pé ọ̀pọ̀ nínú àwọn èèyàn rere máa wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé.​—Sáàmù 37:11, 29, 34.

  •   Jésù sọ pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó ti gòkè re ọ̀run.” (Jòhánù 3:13) Ohun tí Jésù sọ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn èèyàn rere tó kú ṣáájú rẹ̀, bíi Ábúráhámù, Mósè, Jóòbù àti Dáfídì ò lọ sọ́run. (Ìṣe 2:29, 34) Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n nírètí pé Ọlọ́run máa jí àwọn dìde sí ayé.​—Jóòbù 14:13-​15.

  •   “Àjíǹde èkíní” ni àjíǹde àwọn tó ń lọ sọ́run. (Ìṣípayá 20:6) Ó fi hàn pé àjíǹde míì máa wà, ìyẹn àjíǹde àwọn tó máa wà láyé.

  •   Bíbélì fi kọ́ni pé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, “ikú kì yóò . . . sí mọ́.” (Ìṣípayá 21:3, 4) Ó ní láti jẹ́ pé ayé ni ìlérí yìí á ti ṣẹ, torí wọn kì í kú lọ́run.

 Èrò tí kò tọ́: Kálukú ló máa yan èyí tó fẹ́, bóyá ọ̀run ló fẹ́ lọ àbí ayé ló fẹ́ wà.

 Òótọ́: Ọlọ́run ló máa ń pinnu àwọn Kristẹni olóòótọ́ tó máa gba “ẹ̀bùn eré ìje ti ìpè . . . sí òkè,” ìyẹn láti máa lọ gbé ní ọ̀run. (Fílípì 3:14) Kò sẹ́ni tó lè fúnra ẹ̀ yàn pé ọ̀run lòun ń lọ.​—Mátíù 20:20-​23.

 Èrò tí kò tọ́: Àwọn tí ọ̀run ò yẹ ló máa wà láyé títí láé.

 Òótọ́: Ọlọ́run pe àwọn tó máa wà láyé títí láé ní “àwọn ènìyàn mi,” “àwọn àyànfẹ́ mi” àti àwọn tó jẹ́ “alábùkún lọ́dọ̀ Jèhófà.” (Aísáyà 65:21-​23) Wọ́n máa di ẹni pípé, wọ́n á sì láǹfààní láti máa gbé láyé títí láé nínú párádísè, bí Ọlọ́run ṣe ní in lọ́kàn látìbẹ̀rẹ̀ pé kó rí fún aráyé.​—Jẹ́nẹ́sísì 1:28; Sáàmù 115:16; Aísáyà 45:18.

 Èrò tí kò tọ́: Kì í ṣe iye kan pàtó ni ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tí ìwé Ìṣípayá sọ̀rọ̀ rẹ̀, ó fi ṣàpèjúwe nǹkan ni.

 Òótọ́: Òótọ́ ni pé àwọn nọ́ńbà kan tó wà nínú Ìṣípayá ń ṣàpẹẹrẹ nǹkan kan, àmọ́ kì í ṣe gbogbo ẹ̀. Iye kan pàtó làwọn nọ́ńbà kan. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ̀rọ̀ nípa “orúkọ méjìlá ti àwọn àpọ́sítélì méjìlá ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” (Ìṣípayá 21:14) Wo ẹ̀rí tó mú ká gbà pé bákan náà lọ̀rọ̀ rí pẹ̀lú nọ́ńbà yìí, ìyẹn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000].

 Ìṣípayá 7:4 sọ̀rọ̀ nípa “iye àwọn tí a fi èdìdì dì, [tàbí tí Ọlọ́run ti yàn pé wọ́n á lọ sọ́run], ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì.” Tá a bá kà á sísàlẹ̀ díẹ̀, Bíbélì sọ̀rọ̀ àwọn míì tó fi wé àwọn yìí: “ogunlọ́gọ̀ ńlá, tí ẹnì kankan kò lè kà.” Ọlọ́run máa gba àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” yìí náà là. (Ìṣípayá 7:9, 10) Tó bá jẹ́ pé nǹkan míì ni ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì ń ṣàpẹẹrẹ, pé kì í ṣe iye kan pàtó ni, àwùjọ méjèèjì tí Bíbélì sọ̀rọ̀ wọn yìí ò ní ṣeé fi wéra. a

 Bákan náà, Bíbélì sọ pé àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì jẹ́ àwọn tí a “rà lára aráyé gẹ́gẹ́ bí àkọ́so.” (Ìṣípayá 14:4) Ọ̀rọ̀ náà “àkọ́so” ń tọ́ka sí àwùjọ kékeré kan tó ń ṣojú àwọn tó kù. Ó ń tọ́ka sí àwọn tó máa bá Kristi jọba lọ́run lé àìmọye àwọn tó máa wà láyé.​—Ìṣípayá 5:10.

a Ọ̀jọ̀gbọ́n Robert L. Thomas náà kọ̀wé lórí ọ̀rọ̀ nọ́ńbà tí ìwé Ìṣípayá 7:4 mẹ́nu bà yìí, ó ní: “Iye kan pàtó ni nọ́ńbà yìí, tá a bá fi wé àwọn tí ò níye tí orí keje ẹsẹ kẹsàn-án sọ̀rọ̀ rẹ̀. Tá a bá sọ pé ṣe ni nọ́ńbà yìí ń ṣàpẹẹrẹ nǹkan míì, a jẹ́ pé kò sí nọ́ńbà kankan nínú ìwé Ìṣípayá tó jẹ́ iye kan pàtó nìyẹn.”​—Ìwé Revelation 1-7: An Exegetical Commentary, ojú ìwé 474.