Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Ni Òfin Mẹ́wàá Tó Wá Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run?

Kí Ni Òfin Mẹ́wàá Tó Wá Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Àwọn òfin tí Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́ ló ń jẹ́ Òfin Mẹ́wàá. Wọ́n tún máa ń pe àwọn òfin yìí ní Ọ̀rọ̀ Mẹ́wàá, ìyẹn ni ìtumọ̀ tààràtà ọ̀rọ̀ Hébérù náà, ʽaseʹreth had·deva·rimʹ. Ẹ̀ẹ̀mẹta ni ọ̀rọ̀ yìí fara hàn nínú ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ tó wà nínú Bíbélì, tí wọ́n mọ̀ sí Pentateuch (tàbí Tórà). (Ẹ́kísódù 34:28; Diutarónómì 4:13; 10:4) Lédè Gíríìkì, ohun tí òfin mẹ́wàá túmọ̀ sí ni deʹka (ìyen, mẹ́wàá) loʹgous (ìyẹn, ọ̀rọ̀). Òun ni wọ́n pa pọ̀ di ọ̀rọ̀ náà “Decalogue” táwọn èèyàn tún mọ̀ ọ́n sí.

 Ọlọ́run kọ Òfin Mẹ́wàá náà sára wàláà òkúta méjì, ó sì fún Mósè wòlíì rẹ̀ lórí Òkè Sínáì. (Ẹ́kísódù 24:12-18) Òfin Mẹ́wàá náà wà nínú Ẹ́kísódù 20:1-​17 àti Diutarónómì 5:6-21.

 Òfin Mẹ́wàá

  1.   Jèhófà Ọlọ́run nìkan ni kó o máa jọ́sìn.​—Ẹ́kísódù 20:3.

  2.   Má bọ̀rìṣà.​—Ẹ́kísódù 20:4-6.

  3.   Má lo orúkọ Ọlọ́run lọ́nà tí kò ní láárí.​—Ẹ́kísódù 20:7.

  4.   Máa pa Sábáàtì mọ́.​—Ẹ́kísódù 20:8-​11.

  5.   Máa bọlá fáwọn òbí rẹ.​—Ẹ́kísódù 20:12.

  6.   Má pààyàn.​—Ẹ́kísódù 20:13.

  7.   Má ṣe panṣágà.​—Ẹ́kísódù 20:14.

  8.   Má jalè.​—Ẹ́kísódù 20:15.

  9.   Má jẹ́rìí èké.​—Ẹ́kísódù 20:16.

  10.   Má ṣe ojúkòkòrò.​—Ẹ́kísódù 20:17.

 Kí nìdí tí ìyàtọ̀ fi máa ń wà nínú bí àwọn kan ṣe to Òfin Mẹ́wàá?

 Bíbélì ò fi nọ́ńbà kan pàtó sí òfin kọ̀ọ̀kan. Torí ẹ̀ ló ṣe jẹ́ pé èrò táwọn èèyàn ní nípa bó ṣe yẹ kí òfin náà tò tẹ̀ léra kò bára mu. Bá a ṣe tò ó lókè yìí ni ọ̀pọ̀ ṣe sábà máa ń tò ó. Àmọ́ báwọn kan ṣe ń to Òfin Mẹ́wàá yàtọ̀. Ibi tí ìyàtọ̀ yìí máa ń wà ni bí wọ́n ṣe to òfin àkọ́kọ́, ìkejì àti èyí tó gbẹ̀yìn. a

 Kí ni Òfin Mẹ́wàá wà fún?

 Ara Òfin Mósè ni Òfin Mẹ́wàá náà wà. Òfin Mósè ní nínú àwọn àṣẹ tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600), òun ló sì jẹ́ àdéhùn tàbí májẹ̀mú láàárín Ọlọ́run àti orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́. (Ẹ́kísódù 34:27) Ọlọ́run ṣèlérí fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé nǹkan á máa lọ dáadáa fún wọn tí wọ́n bá ń tẹ̀ lé Òfin Mósè. (Diutarónómì 28:1-​14) Àmọ́ ohun tí Òfin yẹn wà fún gangan ni pé, kó lè múra àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ de Mèsáyà tàbí Kristi tí Ọlọ́run ṣèlérí.​—Gálátíà 3:24.

 Ṣé ó di dandan káwọn Kristẹni máa pa Òfin Mẹ́wàá mọ́?

 Rárá. Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́ ni Ọlọ́run dìídì fún ní Òfin, tó fi mọ́ Òfin Mẹ́wàá. (Diutarónómì 5:2, 3; Sáàmù 147:19, 20) Òfin Mósè ò de àwọn Kristẹni, kódà a ti tú àwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù pàápàá “sílẹ̀ kúrò nínú Òfin.” (Róòmù 7:6) b “Òfin Kristi,” tó ní nínú gbogbo ohun tí Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa ṣe, ló rọ́pò Òfin Mósè.​—Gálátíà 6:2; Mátíù 28:19, 20.

 Ṣé Òfin Mẹ́wàá ṣì wúlò lónìí?

 Bẹ́ẹ̀ ni. Torí pé Òfin Mẹ́wàá jẹ́ ká mọ èrò Ọlọ́run, ó máa ṣe wá láǹfààní tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀. (2 Tímótì 3:16, 17) Àwọn ìlànà tó ṣeé gbára lé, táá máa wúlò lọ́jọ́ gbogbo, la gbé Òfin Mẹ́wàá náà kà. (Sáàmù 111:7, 8) Kódà, ọ̀pọ̀ nínú àwọn ìlànà yìí la gbé ohun tí àwọn èèyàn sábà máa ń pè ní Májẹ̀mú Tuntun kà.​—Wo “ Àwọn ìlànà látinú Òfin Mẹ́wàá tó fara hàn nínú Májẹ̀mú Tuntun.”

 Jésù kọ́ wa pé Òfin Mósè látòkè délẹ̀, tó fi mọ́ Òfin Mẹ́wàá, dá lórí òfin pàtàkì méjì. Ó ní: “‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.’ Èyí ni àṣẹ títóbi jù lọ àti èkíní. Èkejì, tí ó dà bí rẹ̀, nìyí, ‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’ Lórí àwọn àṣẹ méjì wọ̀nyí ni gbogbo Òfin so kọ́.” (Mátíù 22:34-​40) Torí náà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò retí káwọn Kristẹni máa tẹ̀ lé Òfin Mósè, wọ́n gbọ́dọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwọn èèyàn. Àṣẹ ni.​—Jòhánù 13:34; 1 Jòhánù 4:20, 21.

  Àwọn ìlànà látinú Òfin Mẹ́wàá tó fara hàn nínú Májẹ̀mú Tuntun

 Ìlànà

 Ibi Tó Ti Fara Hàn Nínú Májẹ̀mú Tuntun

 Jèhófà Ọlọ́run nìkan ni kó o máa jọ́sìn

 Ìṣípayá 22:8, 9

 Má bọ̀rìṣà

 1 Kọ́ríńtì 10:14

 Bọlá fún orúkọ Ọlọ́run

 Mátíù 6:9

 Máa jọ́sìn Ọlọ́run déédéé

 Hébérù 10:24, 25

 Máa bọlá fáwọn òbí rẹ

 Éfésù 6:1, 2

 Má pààyàn

 1 Jòhánù 3:15

 Má ṣe panṣágà

 Hébérù 13:4

 Má jalè

 Éfésù 4:28

 Má jẹ́rìí èké

 Éfésù 4:25

 Má ṣe ojúkòkòrò

 Lúùkù 12:15

a Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Jewish Encyclopedia sọ pé báwọn Júù ṣe sábà máa ń to òfin yìí ni pé, wọ́n ka ohun tó wà nínú Ẹ́kísódù orí 20 ẹsẹ 2 sí ‘ọ̀rọ̀’ àkọ́kọ́, wọ́n wá ka ohun tó wà nínú ẹsẹ 3 sí 6 sí òfin kan ṣoṣo, ìyẹn ìkejì. Àmọ́ àwọn Kátólíìkì ní tiwọn ka ohun tó wà nínú Ẹ́kísódù orí 20 ẹsẹ 1 sí 6 sí òfin kan ṣoṣo. Torí ẹ̀ ni wọ́n ṣe fi ohun tí ẹsẹ tó tẹ̀ lé e sọ, pé ká má lo orúkọ Ọlọ́run lọ́nà tí kò ní láárí, ṣe òfin kejì. Kí òfin náà lè pé mẹ́wàá, wọ́n wá pín àṣẹ tó gbẹ̀yìn sọ́nà méjì, èyí tó sọ pé a ò gbọ́dọ̀ ṣe ojúkòkòrò ìyàwó ọmọnìkejì àti ohun ìní rẹ̀.

b Róòmù 7:7 fi òfin kẹwàá ṣe àpẹẹrẹ “Òfin,” èyí jẹ́ ẹ̀rí pé Òfin Mẹ́wàá wà lára Òfin Mósè.