Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ

Ẹ́kísódù 20:12​—“Bọlá fún Bàbá Rẹ àti Ìyá Rẹ”

Ẹ́kísódù 20:12​—“Bọlá fún Bàbá Rẹ àti Ìyá Rẹ”

 “Bọlá fún bàbá rẹ àti ìyá rẹ, kí ẹ̀mí rẹ lè gùn lórí ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa fún ọ.”​—Ẹ́kísódù 20:12, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

 “Bọ̀wọ fun baba on iya rẹ: ki ọjọ́ rẹ ki o le pẹ ni ilẹ ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fún ọ.”​—Ẹ́kísódù 20:12, Bíbélì Mímọ́.

Ìtumọ̀ Ẹ́kísódù 20:12

 Ọlọ́run pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbà àtijọ́ pé kí wọ́n bọ̀wọ̀ fún àwọn òbí wọn. Ìlérí tí Ọlọ́run fi kún àṣẹ náà yẹ kó mú kó rọrùn fún wọn láti pa á mọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni ò sí lábẹ́ Òfin Mósè, ìyẹn òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kó tíì yí pa dà. Àwọn ìlànà tí Ọlọ́run gbé Òfin rẹ̀ kà ṣì wúlò fún wa lónìí, torí náà, wọ́n ṣe pàtàkì fún àwa Kristẹni.​—Kólósè 3:20.

 Bí àwọn ọmọdé ní tàgbà tèwe bá ń bọ̀wọ̀ fún àwọn òbí wọn tí wọ́n sì ń gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu, wọ́n ń bọlá fún wọn nìyẹn. (Léfítíkù 19:3; Òwe 1:8) Kódà tí àwọn ọmọ bá dàgbà tí wọ́n sì ní ìdílé tiwọn, wọ́n á ṣì máa jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn òbí wọn jẹ wọ́n lógún. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n á rí í dájú pé àwọn òbí wọn ń rí ìtọ́jú tó péye gbà lọ́jọ́ ogbó wọn, tó bá sì gba pé kí wọ́n fi owó ràn wọ́n lọ́wọ́ wọ́n á ṣe bẹ́ẹ̀.​—Mátíù 15:4-6; 1 Tímótì 5:4, 8.

 Kíyè sí i pé bàbá àti ìyá ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ bọlá fún, wọ́n á sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé àwọn mọyì ojúṣe ìyá nínú ìdílé. (Òwe 6:20; 19:26) Ohun táwọn ọmọ náà gbọ́dọ̀ máa ṣe lóde òní nìyẹn.

 Àmọ́, àṣẹ tí Ọlọ́run pa pé kí àwọn ọmọ máa bọlá fáwọn òbí wọn kì í ṣe àṣẹ tí kò ní ààlà. Kò yẹ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa àṣẹ àwọn òbí wọn tàbí ti èèyàn mìíràn mọ́, tí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ bá máa mú kí wọ́n ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. (Diutarónómì 13:6-8) Bákàn náà, àwọn Kristẹni òde òní gbọ́dọ̀ “ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí alákòóso dípò èèyàn.”​—Ìṣe 5:29.

 Nínú Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó ṣèlérí pé “ẹ̀mí” àwọn ọmọ tó bá bọ̀wọ̀ fáwọn òbí wọn máa ‘gùn, nǹkan á sì máa lọ dáadáa fún wọn’ ní ilẹ̀ tí Ọlọ́run fi fún wọn. (Diutarónómì 5:16) Ìyà tí Ọlọ́run bá fi jẹ àwọn ọmọ tó ti dàgbà ṣùgbọ́n tí wọn ò ka òfin rẹ̀ sí tí wọ́n sì di ọlọ̀tẹ̀ sí àwọn òbí wọn ò ní tọ́ sírú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀. (Diutarónómì 21:​18-21) Lóòótọ́ ó ti pẹ́ táwọn òfin yẹn ti wà, àmọ́ àwọn ìlànà inú ẹ̀ ò kò pa dà. (Éfésù 6:​1-3) Gbogbo wa lọ́mọdé lágbà la máa jíhìn fún Ẹlẹ́dàá wa. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ò yí padà, ẹ̀mí àwọn ọmọ tó bá ṣègbọràn sí Ọlọ́run tí wọ́n sì bọlá fún àwọn òbí wọn máa gùn. Kódà, Ọlọ́run ṣèlérí pé wọ́n máa wà láàyè títí láé.​—1 Tímótì 4:8; 6:18, 19.

Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Ẹ́kísódù 20:12

 Àṣẹ tí Ọlọ́run pa fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nínú Ẹ́kísódù 20:12 yìí jẹ́ apá pàtàkì lára Òfin Mẹ́wàá. (Ẹ́kísódù 20:1-17) Àṣẹ tó wà nínú ẹsẹ tó ṣáájú rẹ̀ ṣàlàyé ojúṣe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sí Ọlọ́run, irú bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí wọ́n máa sin Ọlọ́run nìkan ṣoṣo. Òfin tó wà nínú ẹsẹ tó tẹ̀ lé e ṣàlàyé ojúṣe wọn sí ọmọnìkejì wọn, tó fi mọ́ òfin tó sọ pé kí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí ọkọ tàbí aya wọn kí wọ́n má sì jalè. Látàrí ìyẹn, ó ti wá dà bíi pé àṣẹ tó ní “bọlá fún bàbá àti ìyá rẹ” ló so ojúṣe méjèèjì pọ̀.

Ka Ẹ́kísódù orí 20 àti àwọn àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé tí wọ́n fi ṣàlàyé ọ̀rọ̀ àti àwọn atọ́ka etí ìwé.