Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Ló Ń Jẹ́ Tórà?

Kí Ló Ń Jẹ́ Tórà?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Inú ọ̀rọ̀ Hébérù náà toh·rahʹ, ni ọ̀rọ̀ náà “Tórà” ti wá. A lè túmọ̀ rẹ̀ sí ìtọ́ni, “ẹ̀kọ́” tàbí “òfin.” a (Òwe 1:8; 3:1; 28:4, Bíbélì Mímọ́) Àwọn àpẹẹrẹ tó tẹ̀ lé e yìí jẹ́ ká mọ bí Bíbélì ṣe lo ọ̀rọ̀ Hébérù yìí.

  •   Toh·rahʹ sábà máa ń tọ́ka sí àwọn ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ nínú Bíbélì, ìyẹn Jẹ́nẹ́sísì, Ẹ́kísódù, Léfítíkù, Númérì àti Diutarónómì. Wọ́n tún máa ń pè é ní Pentateuch, tó wá látinú ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó túmọ̀ sí “ìwé alápá márùn-ún.” Mósè ló kọ Tórà, torí ẹ̀ ni wọ́n ṣe pè é ní “ìwé òfin Mósè.” (Jóṣúà 8:31; Nehemáyà 8:1) Ó ṣe kedere pé ojú kan ni ìwé márààrún yìí wà tẹ́lẹ̀, àmọ́ wọ́n wá pín in sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ kó lè rọrùn-ún lò.

  •   Toh·rahʹ ni wọ́n tún máa ń pe oríṣiríṣi òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, bí àpẹẹrẹ, “òfin [ìyẹn, toh·rahʹ] ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀,” “òfin nípa ẹ̀tẹ̀,” àti “òfin nípa Násírì.”​—Léfítíkù 6:25; 14:57; Númérì 6:13.

  •   Nígbà míì, toh·rahʹ máa ń tọ́ka sí ìtọ́ni àti ẹ̀kọ́, ó lè jẹ́ látọ̀dọ̀ àwọn òbí, àwọn tó gbọ́n tàbí Ọlọ́run fúnra rẹ̀.​—Òwe 1:8; 3:1; 13:14; Aísáyà 2:3.

Kí ló wà nínú Tórà tàbí Pentateuch?

  •   Bí Ọlọ́run ṣe ń bá aráyé lò látìgbà tó ti dá ọ̀run àti ayé títí di ìgbà ikú Mósè.​—Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28; Diutarónómì 34:5.

  •   Àwọn ohun tó wà nínú Òfin Mósè. (Ẹ́kísódù 24:3) Òfin tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [600] ló wà nínú Òfin Mósè. Èyí táwọn èèyàn mọ̀ jù ni òfin Shema, tàbí ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ àwọn Júù. Apá kan òfin Shema sọ pé: “Kí ìwọ sì fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo okunra rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.” (Diutarónómì 6:4-9) Jésù sọ pé èyí ni “àṣẹ títóbi jù lọ àti èkíní.”​—Mátíù 22:36-​38.

  •   Orúkọ Jèhófà fara hàn níbẹ̀ ní nǹkan bí ìgbà ẹgbẹ̀rún méjì ó dín igba [1,800]. Tórà ò dẹ́bi fún lílo orúkọ Ọlọ́run, kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni àwọn òfin inú Tórà sọ pé ó yẹ káwọn èèyàn Ọlọ́run máa pe orúkọ náà.​—Númérì 6:22-​27; Diutarónómì 6:13; 10:8; 21:5.

Èrò tí kò tọ́ táwọn èèyàn ní nípa Tórà

 Èrò tí kò tọ́: Títí láé làwọn òfin inú Tórà máa wà, a ò gbọ́dọ̀ pa wọ́n tì.

 Òótọ́: Àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì kan tọ́ka sí àwọn òfin pàtó kan tó wà nínú Tórà, bíi àwọn òfin tó kan Sábáàtì, iṣẹ́ àlùfáà àti Ọjọ́ Ètùtù, wọ́n sọ pé ó máa wà “títí láé” tàbí “láéláé.” (Ẹ́kísódù 31:16; 40:15; Léfítíkù 16:33, 34, Bíbélì Mímọ́) Àmọ́ ọ̀rọ̀ Hébérù tí Bíbélì lò nínú àwọn ẹsẹ yìí tún lè túmọ̀ sí ohun tó máa wà pẹ́, ó lè máà jẹ́ títí lọ gbére. b Lẹ́yìn tí àwọn èèyàn ti ń tẹ̀ lé májẹ̀mú inú Òfin Mósè fún ohun tó tó ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án [900] ọdún, Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé òun máa fi “májẹ̀mú tuntun” rọ́pò rẹ̀. (Jeremáyà 31:31-​33) Pẹ̀lú “sísọ tí ó sọ pé ‘májẹ̀mú tuntun,’ [Ọlọ́run] ti sọ [májẹ̀mú] ti ìṣáájú di aláìbódemu mọ́.” (Hébérù 8:7-​13) Ikú Jésù Kristi ni Ọlọ́run fi pilẹ̀ májẹ̀mú tuntun tó fi rọ́pò ti tẹ́lẹ̀ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì [2,000] sẹ́yìn.​—Éfésù 2:15.

 Èrò tí kò tọ́: Bíi Tórà tí wọ́n kọ sílẹ̀ náà ni àwọn òfin àtẹnudẹ́nu àwọn Júù àti ìwé Támọ́dì

 Òótọ́: Kò sí ẹ̀rí nínú Bíbélì pé Ọlọ́run fún Mósè ní òfin àtẹnudẹ́nu láfikún sí Tórà tó kọ sílẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Bíbélì sọ ni pé: “Jèhófà sì ń bá a lọ láti wí fún Mósè pé: ‘Kọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sílẹ̀.’” (Ẹ́kísódù 34:27) Òfin àtẹnudẹ́nu tí wọ́n pa dà kọ sílẹ̀, tí wọ́n mọ̀ sí Míṣínà ló fẹjú, tó wá di ìwé Támọ́dì. Àṣà àwọn Júù tó bẹ̀rẹ̀ látọ̀dọ̀ àwọn Farisí ló wà nínú òfin yìí. Àwọn àṣà yìí sì sábà máa ń ta ko ohun tí Tórà sọ. Ìdí nìyí tí Jésù fi sọ fún àwọn Farisí pé: “Ẹ ti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di aláìlẹ́sẹ̀nílẹ̀ nítorí òfin àtọwọ́dọ́wọ́ yín.”​—Mátíù 15:1-9.

 Èrò tí kò tọ́: Kò yẹ kí wọ́n fi Tórà kọ́ àwọn obìnrin.

 Òótọ́: Òfin Mósè sọ pé kí wọ́n máa ka gbogbo Òfin náà sí etí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, títí kan àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé. Kí nìdí? “Kí wọ́n bàa lè fetí sílẹ̀ àti kí wọ́n bàa lè kẹ́kọ̀ọ́, bí wọn yóò ti máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run [wọn], kí wọ́n sì kíyè sára láti mú gbogbo ọ̀rọ̀ òfin [náà] ṣe.”​—Diutarónómì 31:10-​12. c

 Èrò tí kò tọ́: Ọ̀rọ̀ àṣírí ló wà nínú Tórà.

 Òótọ́: Mósè, ẹni tó kọ Tórà, sọ pé ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ṣe kedere, gbogbo èèyàn ló sì wà fún, kì í ṣe ọ̀rọ̀ àṣírí. (Diutarónómì 30:11-​14) Ẹ̀kọ́ ìsìn àwọn Júù, ìyẹn Kabbalah, ló sọ pé ọ̀rọ̀ àṣírí wà nínú Tórà. Ohun tí wọ́n sì ‘dọ́gbọ́n hùmọ̀ lọ́nà àrékendá’ ni ẹ̀kọ́ ìsìn yìí fi máa ń ṣàlàyé Ìwé Mímọ́. d​—2 Pétérù 1:16.

a Wo ìwé The Strongest Strong’s Exhaustive Concordance of the Bible, tí wọ́n ṣe àtúnṣe sí, kókó 8451 lábẹ́ àkòrí náà, “Hebrew-Aramaic Dictionary-Index to the Old Testament.”

b Wo ìwé Theological Wordbook of the Old Testament, Ìdìpọ̀ Kejì, ojú ìwé 672 sí 673.

c Òfin àwọn Júù ò fọwọ́ sí i pé kí wọ́n fi Tórà kọ́ àwọn obìnrin, èyí sì ta ko ohun tí Tórà fúnra rẹ̀ sọ. Bí àpẹẹrẹ, ìwé Míṣínà sọ ohun tí Rábì Eliezer ben Hyrcanus sọ, pé: “Tẹ́nì kan bá fi Tórà kọ́ ọmọ rẹ̀ obìnrin, bí ẹni kọ́ ọ ní ìwàkiwà ló rí.” (Sotah 3:4) Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tún wà nínú ìwé Támọ́dì ti Jerúsálẹ́mù, pé: “Ó sàn ká dáná sun Tórà ju ká fi kọ́ àwọn obìnrin.”​—Sotah 3:19a.

d Bí àpẹẹrẹ, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopaedia Judaica sọ ohun tí ẹ̀kọ́ Kabbalah sọ nípa Tórà: “Oríṣiríṣi ọ̀nà lèèyàn lè tú ohun tó wà nínú Tórà sí torí pé oríṣiríṣi ìtumọ̀ ló ní.”—Ẹ̀dà kejì, Ìdìpọ̀ Kọkànlá, ojú ìwé 659.