Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ki Ni Ẹ̀ṣẹ̀ Ìpilẹ̀ṣẹ̀?

Ki Ni Ẹ̀ṣẹ̀ Ìpilẹ̀ṣẹ̀?

Ohun tí Bíbélì sọ

Ádámù àti Éfà ni ẹ̀dá èèyàn tó kọ́kọ́ dẹ́ṣẹ̀. Wọ́n ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run nígbà tí wọ́n jẹ nínú “èso igi ìmọ̀ rere àti búburú,” wọ́n sì dẹ́ṣẹ̀ tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń pè ní ẹ̀ṣẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀. a (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17; 3:6; Róòmù 5:19) Ọlọ́run sọ fún Ádámù àti Éfà pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ èso igi yẹn nítorí pé igi yẹn dúró fún ọlá àṣẹ Ọlọ́run tàbí ẹ̀tọ́ tó ní láti pinnu ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́ fún àwọn ẹ̀dá èèyàn. Bí Ádámù àti Éfà ṣe jẹ nínú èso igi náà fi hàn pé tinú ara wọn ni wọ́n fẹ́ ṣe, wọ́n sì fẹ́ máa pinnu ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́ fúnra wọn. Ohun tí wọ́n ṣe yìí fi hàn pé wọn ò gbà pé Ọlọ́run lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ohun tó dáa fún wọn.

 Báwo ni “ẹ̀ṣẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀” náà ṣe kan Ádámù àti Éfà?

Torí pé wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀, Ádámù àti Éfà darúgbó, wọ́n sì kú níkẹyìn. Wọ́n ba àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ pàdánù àǹfààní tí wọ́n ní láti gbé títí láé pẹ̀lú ìlera pípé.​—Jẹ́nẹ́sísì 3:19.

 Báwo ni “ẹ̀ṣẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀” náà ṣe kan wá?

Àwọn ọmọ tí Ádámù àti Éfà bí náà jogún àìpé àti ẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ wọn. Èyí jọra pẹ̀lú ọ̀nà táwọn òbí máa ń gbà tàtaré àwọn àìsàn kan sára àwọn ọmọ wọn. (Róòmù 5:12) Torí náà, gbogbo ẹ̀dá èèyàn ni a bí “nínú ẹ̀ṣẹ̀” b tó túmọ̀ sí pé, a bí wa ní aláìpé, ó sì máa ń wù wá láti ṣe ohun tí kò tọ́.​—Sáàmù 51:5; Éfésù 2:3.

Torí ẹ̀ṣẹ̀ tàbí àìpé tá a ti jogún, à ń ṣàìsàn, à ń darúgbó, a sì ń kú. (Róòmù 6: 23) A tún ń jìyà àwọn àbájáde àṣìṣe tiwa fúnra wa àti tàwọn ẹlòmíì.​—Oníwàásù 8:9; Jémíìsì 3:2.

 Ṣé a lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn ohun tí “ẹ̀ṣẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀” náà ti fà?

Bẹ́ẹ̀ ni. Bíbélì sọ pé Jésù kú “kó lè jẹ́ ètùtù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.” (1 Jòhánù 4:10 àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé) Ẹbọ ìràpadà Jésù lè dá wa sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún fà, ká sì gbádùn àwọn ohun tí Ádámù àti Éfà pàdánù, ìyẹn ìrètí láti wà láàyè títí láé pẹ̀lú ìlera pípé.​—Jòhánù 3:16. c

 Àṣìlóye nípa “ẹ̀ṣẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀”

Àṣìlóye: Ẹ̀ṣẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ ò lè jẹ́ ká ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run láéláé.

Òótọ́: Ọlọ́run kò dá wa lẹ́bi fún ohun tí Ádámù àti Éfà ṣe. Ó mọ̀ pé aláìpé ni wá, kò sì retí pé ká ṣe ohun tó ju agbára wa lọ. (Sáàmù 103:14) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé à ń jìyà nítorí àìpé tá a jogún, a ṣì láǹfààní láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run.​—Òwe 3:32.

Àṣìlóye: Ìrìbọmi máa ń wẹ èèyàn mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀, torí náà, ó yẹ kí àwọn ọmọ ọwọ́ ṣèrìbọmi.

Òótọ́: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìrìbọmi jẹ́ ìgbésẹ̀ pàtàkì kéèyàn tó lè rí ìgbàlà, àmọ́ ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù nìkan ló lè wẹ ẹnì kan mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀. (1 Pétérù 3:21; 1 Jòhánù 1:7) Èèyàn gbọ́dọ̀ ní ìmọ̀ kó tó lè ní ìgbàgbọ́ tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, torí náà kò ṣeé ṣe fún ọmọ ọwọ́ láti ní ìgbàgbọ́. Fún ìdí èyí, Bíbélì ò fọwọ́ sí ìrìbọmi fún àwọn ọmọ ọwọ́. A ri ẹ̀rí èyí lọ́nà tó ṣe kedere láàárín àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀. Wọ́n ṣe ìrìbọmi fún “tọ́kùnrin tóbìnrin” tí wọ́n nígbàgbọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kì í ṣe àwọn ọmọ ọwọ́.​—Ìṣe 2:41; 8:12.

Àṣìlóye: Ọlọ́run gégùn-ún fún àwọn obìnrin torí pé Éfà ló kọ́kọ́ jẹ́ nínú èso tí Ọlọ́run kà léèwọ̀.

Òótọ́: Dípò kí Ọlọ́run gégùn-ún fún àwọn obìnrin, “ejò àtijọ́ náà, ẹni tí à ń pè ní Èṣù àti Sátánì,” ni Ọlọrun gégùn-ún fún torí òun ló sún Éfà dẹ́ṣẹ̀. (Ìfihàn 12:9; Jẹ́nẹ́sísì 3:14) Láfikún, Ádámù gan-an ni Ọlọ́run dá lẹ́bi pé ó jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, kì í ṣe ìyàwó rẹ̀.​—Róòmù 5:12

Kí nìdí tí Ọlọ́run fi sọ pe Ádámù máa jọba lé ìyàwó rẹ̀ lórí? (Jẹ́nẹ́sísì 3:16) Nígbà tí Ọlọ́run ń sọ̀rọ̀ yìí, kì í ṣe pé ó fara mọ́ irú ìwà bẹ́ẹ̀, ó kàn wulẹ̀ ń sọ àbàjáde búburú tí ẹ̀ṣẹ̀ náà máa fà fún wọn ni. Ọlọ́run ń fẹ́ kí ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀, kó máa bọlá fún un, kó sì máa fi ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ hàn sí gbogbo obìnrin.​— Éfésù 5:25; 1 Pétérù 3:7.

Àṣìlóye: Ìbálòpọ̀ láàárín ọkùnrin àti obìnrin ni ẹ̀ṣẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà.

Òótọ́: Ẹ̀ṣẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà kò lè jẹ́ ìbálòpọ̀ láàárín ọkùnrin àti obìnrin. Ìdí sì ni pé:

  • Ìgbà tí Ádámù ṣì dá wà tí kò tíì ní ìyàwó ni Ọlọ́run pàṣẹ fún un pé kó má ṣe jẹ nínú èso igi ìmọ̀ rere àti búburú..​—Jẹ́nẹ́sísì 2:17, 18.

  • Ọlọ́run fún Ádámù àti Éfà ní ìtọ́ni pé kí wọ́n ‘bímọ, kí wọ́n sì pọ̀’ ìyẹn ni pé kí wọ́n ní àwọn ọmọ. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Ìwà ìkà tó burú jáì ni kò bá jẹ́ ká ní Ọlọ́run fìyà jẹ tọkọtaya àkọ́kọ́ torí wọ́n ṣe ohun tó pa láṣẹ fún wọn pé kí wọ́n ṣe.

  • Ádámù àti Éfà dẹ́ṣẹ̀ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Éfà ló kọ́kọ́ dẹ́ṣẹ̀, lẹ́yìn náà ni ọkọ rẹ̀.​—Jẹ́nẹ́sísì 3:6.

  • Bíbélì fọwọ́ sí ìbálòpọ̀ láàárín ọkọ àti aya.​—Òwe 5:18, 19; 1 Kọ́ríńtì 7:3.

a Gbólóhùn náà “ẹ̀ṣẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀” kò sí nínú Bíbélì. Ká sòótọ́, ẹ̀ṣẹ̀ àkọ́kọ́ tí a ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ nínú Bíbélì ni ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn Sátánì àti irọ́ ńlá tó pa fún Éfà.​—Jẹ́nẹ́sísì 3:4,5; Jòhánù 8:44.

b Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà, “ẹ̀ṣẹ̀” kò túmọ̀ sí àṣìṣe nìkan, ó tún ń tọ́ka sí ipò àìpé tàbí ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti jogún.

c Tó o bá fẹ mọ púpọ̀ sí i nípa ẹbọ ìràpadà Jésù àti bá a ṣe lè jàǹfààní nínú rẹ̀, wo àpilẹ̀kọ náà “Báwo Ni Jésù Ṣe Ń Gbani Là?