Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí ni Bíbélì Sọ Nípa Gbígba Ẹ̀mí Ẹnìkan Tó Ń Jẹ̀ Ìrora?

Kí ni Bíbélì Sọ Nípa Gbígba Ẹ̀mí Ẹnìkan Tó Ń Jẹ̀ Ìrora?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Bíbélì ò sọ̀rọ̀ nípa gbígba ẹ̀mí ẹnìkan tó ń jẹ ìrora gan-an. a Àmọ́ ohun tó sọ nípa ikú àti ìyè jẹ́ ká mọ ohun tó yẹ ká ṣe. Bíbélì dẹ́bi fún gbígba ẹ̀mí ẹnìkan, síbẹ̀ kò sọ pé tí ikú bá dé, gbogbo ohun tó bá gbà la gbọ́dọ̀ ká ṣáà lè dá ẹ̀mí wa sí.

 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ló dá wa, òun ni “orísun ìyè.” (Sáàmù 36:9; Ìṣe 17:28) Ẹ̀mí ṣeyebíye gan-an lójú Ọlọ́run, ìdí nìyẹn tí kò fi gbà wá láàyè láti gba ẹ̀mí ara wa tàbí ti ẹlòmíì. (Ẹ́kísódù 20:13; 1 Jòhánù 3:15) Bíbélì tún jẹ́ ká mọ̀ pé, ó yẹ ká máa ṣe àwọn nǹkan tó máa dáàbò bo ẹ̀mí wa àti tàwọn ẹlòmíì. (Diutarónómì 22:8) Èyí mú kó ṣe kedere sí wa pé Ọlọ́run fẹ́ ká mọyì ẹ̀mí gan-an.

Tí àìsàn gbẹ̀mí-gbẹ̀mí bá ń ṣe ẹni kan ńkọ́?

 Bíbélì ò fọwọ́ sí i pé kí ẹnì kan gba ẹ̀mí ẹlòmíì, kódà tẹ́ni náà bá ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú tán. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tí Ọba Sọ́ọ̀lù ṣèṣe gan-an lójú ogun, ó wá sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ń bá a di ìhámọ́ra pé kó gba ẹ̀mí òun. (1 Sámúẹ́lì 31:3, 4) Ìránṣẹ́ náà kọ̀ láti ṣe ohun tí ọba sọ. Àmọ́ nígbà tó yá, ọkùnrin kan parọ́ pé òun ti ṣe ohun tí Sọ́ọ̀lù fẹ́. Dáfídì sọ fún ọkùnrin náà pé ó ti jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, ojú tí Ọlọ́run sì fi wo ọ̀rọ̀ náà nìyẹn.​—2 Sámúẹ́lì 1:6-16.

Ṣó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tó bá gbà ká lè dá ẹ̀mí wa sí?

 Tó bá ti ṣe kedere pé ẹnì kan ò ní pẹ́ kú, Bíbélì ò ní ká ṣe gbogbo nǹkan tó bá gbà láti dá ẹ̀mí náà sí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ká ní ojú ìwòye tó tọ́ nípa ikú. Ìyẹn ni pé ọ̀tá wa ni ikú, ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún ló sì fà á tá a fi ń kú. (Róòmù 5:12; 1 Kọ́ríńtì 15:26) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sẹ́ni tó máa gbàdúrà pé kóun kú, síbẹ̀ kò yẹ ká máa bẹ̀rù ikú torí pé Ọlọ́run ti sọ pé òun máa jí àwọn òkú dìde. (Jòhánù 6:39, 40) Ẹni tó bá bọ̀wọ̀ fún ẹ̀mí á máa fún ara rẹ̀ ní ìtọ́jú tó dáa jù. Àmọ́ ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ká fi dandan dá ẹ̀mí wa sí nígbà tó ti ṣe kedere pé ikú ti dé tan.

Ṣé Ọlọ́run máa dárí ji àwọn tó gbẹ̀mí ara wọn?

 Bíbélì ò sọ pé àwọn tó bá pa ara wọn ò lè rí ìdáríjì. Lóòtọ́ ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ni, b àmọ́ Ọlọ́run mọ̀ pé tẹ́nì kan bá ní ìdààmù ọkàn, tí kì í fún ara rẹ̀ ní ìsinmi, tàbí tó bá ní àìsàn ọpọlọ, ó lè máa wá sí i lọ́kàn láti pa ara rẹ̀. (Sáàmù 103:13, 14) Ọlọ́run fi Bíbélì pèsè ìtùnú fún àwọn tó wà nínú ìdààmú. Ní àfikún síyẹn, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé, “àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” (Ìṣe 24:15) Èyí fi hàn pé ìrètí àjíǹde wà fáwọn tó dẹ́sẹ̀ tó burú gan-an, irú bí àwọn tó gbẹ̀mí ara wọn.

a Láwọn ìgbà míì àwọn dókítà máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ fáwọn tí wọ́n ń tọ́jú.

b Àwọn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run làwọn tí Bíbélì mẹ́nu bà pé wọ́n gbẹ̀mí ara wọn.​—2 Sámúẹ́lì 17:23; 1 Ọba 16:18; Mátíù 27:3-5.