Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ

Oníwàásù 3:11—“Ó Ti Ṣe Ohun Gbogbo Dáradára ní Àsìkò Tirẹ̀”

Oníwàásù 3:11—“Ó Ti Ṣe Ohun Gbogbo Dáradára ní Àsìkò Tirẹ̀”

 “Ó ti ṣe ohun gbogbo rèǹtèrente ní ìgbà tirẹ̀. Kódà ó ti fi ayérayé sí wọn lọ́kàn; síbẹ̀ aráyé ò lè rídìí iṣẹ́ tí Ọlọ́run tòótọ́ ti ṣe láé láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin.”—Oníwàásù 3:11, Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

 “Ó ti ṣe ohun gbogbo dáradára ní àsìkò tirẹ̀, ó sì ti fi èrò nípa ayérayé sí ọkàn ọmọ ènìyàn, síbẹ̀, wọn kò le ṣe àwárí ìdí ohun tí Ọlọ́run ti ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin.”—Oníwàásù 3:11, Bíbélì Mímọ́ Ní Èdè Yorùbá Òde Òní.

Ìtumọ̀ Oníwàásù 3:11

 “Ó ti ṣe ohun gbogbo rèǹtèrente ní ìgbà tirẹ̀.” Kì í ṣe ohun tó rẹwà lójú nìkan ni Ọ̀rọ̀ Hébérù tá a túmọ̀ sí “rèǹtèrente” ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Ó tún lè túmọ̀ sí kí nǹkan wà “létòlétò,” “lọ́nà tó yẹ,” tàbí “lọ́nà tó bá a mu.” (Oníwàásù 3:11, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé) Àwọn ohun tí Ọlọ́run dá àtàwọn ohun tó ń ṣe kí ìfẹ́ rẹ̀ lè ṣẹ jẹ́ ara àwọn iṣẹ́ rẹ̀ tó wà létòletò.—Dáníẹ́lì 2:21; 2 Pétérù 3:8; Ìfihàn 4:11.

 “Kódà ó ti fi ayérayé sí wọn lọ́kàn.” Ọlọ́run dá àwa èèyàn láti wà láàyè títí láé. (Sáàmù 37:29) Torí náà, ó máa ń wù wá láti wà láàyè títí lọ. Àmọ́, Ádámù àti Éfà tó jẹ́ tọkọtaya àkọ́kọ́ ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ fa ikú wá sórí ara wọn àtàwọn àtọmọdọ́mọ wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 3:17-19; Róòmù 5:12) Síbẹ̀, Ọlọ́run ṣèlérí láti “fún gbogbo ohun alààyè ní ohun tí wọ́n ń fẹ́,” títí kan bó ṣe ń wù wọ́n láti wà láàyè títí láé. (Sáàmù 145:16) Bíbélì sọ nípa ohun tí Jèhófà ṣe kí èèyàn lè láǹfààní láti wà láàyè títí láé.—Róòmù 6:23.

 “Aráyé ò lè rídìí iṣẹ́ tí Ọlọ́run tòótọ́ ti ṣe láé láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin.” Ọgbọ́n Ọlọ́run pọ̀ débi ti Bíbélì fi sọ pé ó “kọjá àwárí.” (Róòmù 11:33) Síbẹ̀, Ọlọ́run ṣe tán láti fi àwọn ohun tó fẹ́ ṣe han àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.—Émọ́sì 3:7.

Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Oníwàásù 3:11

 Ọba Sólómọ́nì ti ilẹ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́ ló kọ ìwé Oníwàásù, ọkùnrin yìí lókìkí gan-an torí ọgbọ́n tí Ọlọ́run fún un. Àwọn ìmọ̀ràn tó dá lórí ohun tó ṣe pàtàkì àtohun tí ò ní láárí nígbèésí ayé ló wà nínú ìwé yìí. (Oníwàásù 1:2, 3; 2:1, 17; 7:1; 12:1, 13) Ní orí kẹ́ta, àwọn ohun tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé ni Sólómọ́nì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Onírúurú nǹkan táwa èèyàn máa ń ṣe ló mẹ́nu kan. (Oníwàásù 3:1-8, 10) Ọlọ́run fáwa èèyàn lómìnira láti pinnu ohun tá a fẹ́ ṣe àtìgbà tá a fẹ́ ṣe é. (Diutarónómì 30:19, 20; Jóṣúà 24:15) Sólómọ́nì sọ pé ìgbà téèyàn bá ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, to sì fara mọ́ “àkókò” tí Ọlọ́run yàn láti ṣe àwọn nǹkan ló máa tó gbádùn iṣẹ́ àṣekára ẹ̀. Sólómọ́nì sì pe èyí ní “ẹ̀bùn Ọlọ́run.”—Oníwàásù 3:1, 12, 13.

 Wo fídíò yìí kó o lè mọ ohun tó wà nínú ìwé Oníwàásù.