Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bó O Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná

Bó O Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná

 Ṣé ó pọn dandan kó o bẹ̀rẹ̀ sí i ṣọ́wó ná torí pé ipò ọrọ̀ ajé tó dẹnu kọlẹ̀ ti mú kí owó tó ń wọlé fún ẹ dínkù? Àwọn nǹkan bí àjàkálẹ̀ àrùn, àjálù, rògbòdìyàn ìṣèlú àti ogun abẹ́lé lè mú kí ipò ọrọ̀ ajé yará dẹnu kọlẹ̀ láàárín àkókò kúkúrú. Òótọ́ ni pé wàhálà ńlá ni ọ̀dá owó máa ń dá sílẹ̀, àmọ́ àwọn ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì á jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè máa rọra ná ìwọ̀nba owó tó wà lọ́wọ́ rẹ.

1. Gbà pé ohun tó ṣẹlẹ̀ ti ṣẹlẹ̀.

 Ìlànà Bíbélì: “Mo mọ . . . bí a ṣe ń ní púpọ̀ àti bí a ṣe ń jẹ́ aláìní.”​—Fílípì 4:12.

 Bó tilẹ̀ pé owó tó ń wọlé fún ẹ ò pọ̀ tó ti tẹ́lẹ̀ mọ́, o lè kọ́ bí wàá ṣe máa ná ìwọ̀nbá owó tó ń wọlé fún ẹ báyìí. Tó o bá gbà pé ohun tó ṣẹlẹ̀ ti ṣẹlẹ̀, tó o sì fara mọ́ ipò tó o wà báyìí, ó máa jẹ́ kí ìwọ àti ìdílé rẹ lè fara dà á.

 O lè wádìí bóyá ìjọba tàbí àwọn àjọ afẹ́nifẹ́re kan ṣètò ìrànwọ́ fáwọn aráàlú. Tó bá wà, má ṣe fàkókò ṣòfò, torí pé wọ́n máa ń fẹ́ káwọn tó bá nílò ìrànlọ́wọ́ tètè wá.

2. Ẹ fọwọ́ sowó pọ̀ nínú ìdílé.

 Ìlànà Bíbélì: “Láìsí ìfinúkonú, èrò á dasán, àmọ́ nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ agbani-nímọ̀ràn, àṣeyọrí á wà.”​—Òwe 15:22.

 Sọ bí nǹkan ṣe ń lọ fún ọkọ tàbí aya rẹ àtàwọn ọmọ rẹ. Tó o bá fara balẹ̀ jíròrò pẹ̀lú wọn, á ṣeé ṣe fún ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé láti mọ bí nǹkan ṣe ń lọ, wọ́n á sì lè fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àyípadà èyíkéyìí tó bá wáyé. Tí ẹnì kọ̀ọ̀kan bá ṣe ojúṣe ẹ̀ láti ṣọ́ nǹkan lò, tí ẹ ò sì fi nǹkan ṣòfò, owó tó ń wọlé fún yín á tó yín ná.

3. Ṣètò bẹ́ ẹ ṣe máa náwó.

 Ìlànà Bíbélì: ‘Ṣírò ohun tó o máa ná.’​—Lúùkù 14:28.

 Tó bá ti di pé kó o máa náwó tí ò tó nǹkan, ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé kó o mọ ibi tí gbogbo owó rẹ ń gbà lọ. Ṣètò bí wàá ṣe máa náwó. Kó o kọ́kọ́ ṣe àkọsílẹ̀ iye owó tó o rò pé á máa wọlé fún ẹ lóṣooṣù látàrí ìyípadà tó dé bá ẹ báyìí. Lẹ́yìn náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé o ò ní lè náwó bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́, ṣe àkọsílẹ̀ gbogbo owó tí wàá máa ná lóṣooṣù báyìí àti ohun tí wàá máa ná wọn lé lórí. Nínú owó tí wàá máa ná lóṣooṣù, gbìyànjú láti ya iye kan sọ́tọ̀ tí wàá máa fi pa mọ́ torí bí ìnáwó kan bá yọjú láìròtẹ́lẹ̀ tàbí tó wáyé ní pàjáwìrì.

 Ohun tó o lè ṣe: Tó o bá ń ṣírò ohun tó ò ń náwó lé lórí, má ṣe gbàgbé láti fi àwọn ohun kéékèèké tó o máa ń rà kún un. Ó máa yà ẹ́ lẹ́nu láti rí bí owó tó ò ń ná sórí àwọn nǹkan tí ò jọjú yẹn ṣe pọ̀ tó. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí ọkùnrin kan ṣírò ohun tó ń náwó lé lórí, ó wá rí i pé owó tóun ń ná sórí ṣingọ́ọ̀mù lọ́dọọdún pọ̀ gan-an ni!

4. Mọ ohun tó pọn dandan kó o náwó lé lórí, kó o sì ṣàtúnṣe tó yẹ.

 Ìlànà Bíbélì: “Máa wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù.”​—Fílípì 1:10.

 Fi owó tó ń wọlé fún ẹ wéra pẹ̀lú iye tó ò ń ná, kó o wá wo àwọn ohun tó o lè yọ kúrò tàbí tó o lè dínkù kówó tó ń wọlé fún ẹ lè tó ná. Àwọn ohun kan rèé tó yẹ kó o fún láfiyèsí:

  •   Ohun ìrìnnà. Tó o bá ní ju mọ́tò kan lọ, ṣé o lè ta ọ̀kan nínú ẹ̀? Tó bá jẹ́ mọ́tò ìgbàlóde lò ń lò, ṣé o lè tà á kó o sì ra èyí tọ́jọ́ ẹ̀ ti pẹ́ díẹ̀ tí kò ní máa fi bẹ́ẹ̀ ná ẹ lówó? Àbí o lè kúkú ta mótò ẹ, kó o sì máa wọ ọkọ̀ èrò tàbí kó o máa gun kẹ̀kẹ́?

  •   Eré ìnàjú. Tó o bá ń san àsansílẹ̀ owó kó o lè máa wo fíìmù lórí àwọn ìkànnì orí Íntánẹ́ẹ̀tì, ìkànnì alátagbà, tàbí èyí téèyàn ń sanwó fún, ṣó o lè fagi lé irú àsansílẹ̀ bẹ́ẹ̀, bó tiẹ̀ ṣe lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo péré? Ṣé o lè wá àwọn míì tówó wọ́n dín kù? Bí àpẹẹrẹ, ibì kan lè wà lágbègbè rẹ tó o ti lè yá ìwé orí kọ̀ǹpútà, ìwé tí wọ́n gba ohùn rẹ̀ sílẹ̀, àtàwọn fíìmù ní ẹ̀dínwó.

  •   Àwọn nǹkan èlò. Bá ìdílé rẹ sọ̀rọ̀ nípa bẹ́ ẹ ṣe lè máa ṣọ́ omi, iná mọ̀nàmọ́ná àti epo pẹtiròó lò. Ó lè dá bí ohun tí ò ṣe pàtàkì pé kẹ́ ẹ máa paná tẹ́ ò bá lò tàbí kẹ́ ẹ má máa ṣọ́ omi lò nílé ìwẹ̀, àmọ́ ó lè dín ìnáwó yín kù gan-an.

  •   Oúnjẹ. Má ṣe máa lọ sílé oúnjẹ láti lọ jẹun. Dípò ìyẹn, dáná oúnjẹ fúnra ẹ. Ṣètò nǹkan tó o máa jẹ, dípò tí wàá fi máa ra nǹkan kélekèle, oò ṣe rà á papọ̀, kó o sì sè é. Kó o sì lo èyí tó bá ṣẹ́ kù nígbà míì. Kó o tó lọ sọ́jà, kọ nǹkan tó o fẹ́ lọ rà sílẹ̀, ìyẹn ò ní jẹ́ kó o ra nǹkan tó o múra fún. Ra èso àti ewébẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde, torí pé kì í wọ́n púpọ̀. Má ṣe máa ra oúnjẹ pàrùpárù. O tiẹ̀ lè máa gbin nǹkan díẹ̀díẹ̀ fúnra ẹ.

  •   Aṣọ. Má kan ra aṣọ torí o fẹ́ wọṣọ ìgbàlóde, táṣọ tó o ní bá ti gbó ni kó o ra òmíràn. O lè lọ raṣọ níbi tí wọ́n ti ń ṣe ẹ̀dínwó, kódà o tiẹ̀ le ra àwọn aṣọ tí wọ́n ti lò tẹ́lẹ̀ rí àmọ́ tó ṣì dáa. Dípò tí wàá fi máa fi máṣíìnì gbẹ aṣọ, oò ṣe sá a sí oòrùn, ìyẹn máa dín owó iná tẹ́ ẹ̀ ń san kù.

  •   Kó o tó ra nǹkan. Kó o tó ra nǹkan, ó dáa kó o bi ara ẹ pé: ‘Ṣé agbára mi ká a? Ṣé mo nílò ẹ̀?’ Ṣé o lè ṣe sùúrù díẹ̀ kó o tó pààrọ̀ àwọn nǹkan tó o ti ní tẹ́lẹ̀, bíi fóònù, tẹlifíṣọ̀n tàbí mọ́tò? Àbí, ṣé o lè ta àwọn nǹkan tó ò lò mọ́? Ìyẹn máa jẹ́ kí nǹkan rọrùn fún ẹ, owó díẹ̀ á sì tún gbabẹ̀ wọlé.

 Ohun tó o lè ṣe: Tí owó tó ń wọlé fún ẹ bá ṣàdédé dínkù, ìyẹn lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú àwọn àṣà tó ti di bárakú fún ẹ tó sì ń gbọ́n ẹ lówó lọ, irú bíi sìgá, ọ̀tí tàbí tẹ́tẹ́. Tó o bá jáwọ́ nínú àwọn àṣà yìí, ó máa dín owó tó ò ń ná kù, ìlera rẹ á sì tún dáa sí i.

5. Sún mọ́ Ọlọ́run.

 Ìlànà Bíbélì: “Aláyọ̀ ni àwọn tó ń wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run.”​—Mátíù 5:3.

 Bíbélì fún wa ní ìmọ̀ràn tó dáa yìí, ó ní: “Ọgbọ́n jẹ́ ààbò bí owó ṣe jẹ́ ààbò, àmọ́ àǹfààní ìmọ̀ ni pé: Ọgbọ́n máa ń dá ẹ̀mí àwọn tó ní in sí.” (Oníwàásù 7:12) Inú Bíbélì lèèyàn ti lè rí irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn sì ti rí i pé báwọn ṣe ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì ti jẹ́ kí àwọn lè yẹ̀rà fún rírónù jù lórí ọ̀rọ̀ ìnàwó.​—Mátíù 6:31, 32.