Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

E+/taseffski/via Getty Images (Stock photo. Posed by model.)

Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!

Ìbànújẹ́ Túbọ̀ Ń Dorí Ọ̀pọ̀ Àwọn Ọ̀dọ́ Kodò​—Kí Ni Bíbélì Sọ?

Ìbànújẹ́ Túbọ̀ Ń Dorí Ọ̀pọ̀ Àwọn Ọ̀dọ́ Kodò​—Kí Ni Bíbélì Sọ?

 Lọ́jọ́ Monday, February 13, 2023, àjọ kan tó ń rí sí Ìkáwọ́ àti Ìdènà Àrùn ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà (ìyẹn àjọ CDC) gbé ìròyìn kan jáde. Wọ́n sọ pé tí a bá kó àwọn ọ̀dọ́ tó wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà jọ, ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdáméjì wọn ni inú wọn máa ń bà jẹ́ lọ́pọ̀ ìgbà, wọn ò sì nírètí.

 Dókítà Kathleen Ethier tó jẹ́ olùdarí apá tó ń bójú tó ìlera àwọn ọ̀dọ́ nínú àjọ yẹn (ìyẹn DASH), sọ pé: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìṣòro yìí ti wà tẹ́lẹ̀, àmọ́ ó ti wá kọjá bẹ́ẹ̀ lásìkò wa yìí. Ti àwọn ọ̀dọ́bìnrin ló tiẹ̀ wá yọyẹ́ jù torí pé ọ̀pọ̀ nínú wọn ló máa ń ronú àtipara wọn.”

 Ìròyìn náà sọ pé:

  •   Ohun tó ju ìdá kan nínú mẹ́wàá àwọn ọ̀dọ́bìnrin ni wọ́n ti fipá bálòpọ̀. Dókítà Ethier wá fi kún un pé: “Èyí bani nínú jẹ́ gan-an. Ìyẹn ni pé tí wọ́n bá kó ọ̀dọ́bìnrin mẹ́wàá jọ, ó kéré tán ọ̀kan nínú wọn ni wọ́n ti fipá bálòpọ̀.”

  •   Tí wón bá kó àwọn ọ̀dọ́bìnrin mẹ́ta jọ, ó kéré tán ọ̀kan nínú wọn ti ronú láti gbẹ̀mí ara rẹ̀.

  •   Ohun tó tó ìdá mẹ́ta nínú márùn-ún àwọn ọ̀dọ́bìnrin ni inú wọn máa ń bà jẹ́ nígbà gbogbo tí wọn ò sì nírètí.

 Àwọn ìròyìn yìí ba ni nínú jẹ́ gan-an. Torí ìgbà ọ̀dọ́ yẹ kó jẹ́ àsìkò téèyàn máa láyọ̀, tọ́kàn ẹ̀ sì máa balẹ̀. Kí ló lè fi àwọn ọ̀dọ́ lọ́kàn balẹ̀ bí wọ́n tiẹ̀ ní ìṣòro lónìí? Kí ni Bíbélì sọ?

Bíbélì sọ ohun táwọn ọ̀dọ́ lè ṣe

 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé nǹkan ò ní rorún rárá lásìkò yìí. Ó sọ pé, “àkókò tí nǹkan máa le gan-an, tó sì máa nira” la wà yìí. (2 Tímótì 3:1-5) Síbẹ̀, Bíbélì fún wa láwọn ìmọ̀ràn tó gbéṣé tó ti ran ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ kárí ayé lọ́wọ́ láìka ìṣòro tí wọ́n ní sí. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí Bíbélì yìí.

 Ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ọ̀dọ́ tó ń ronú láti gbẹ̀mí ara wọn

 Ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n sori kọ́, tí wọn ò láyò, tàbí tí wọ́n ní èrò òdì

 Ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ń halẹ̀ mọ́ tàbí ti orí Íńtánẹ́ẹ̀tì

 Ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ń fi ìṣekúṣe lọ̀ àti àwọn tí wọ́n fipá bá lòpọ̀

Bíbélì sọ ohun táwọn òbí lè ṣe

 Bíbélì sọ ohun táwọn òbí lè ṣe láti ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè borí àwọn ìṣòro tí wọ́n ní. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí Bíbélì yìí.